Ìbínú Mi Tàbí Ìlera Mi?
TA NI inú kìí bí? Ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. Nígbà mìíràn ìwọ̀n ìbínú díẹ̀ ni a lè dáláre. Ṣugbọn, kìí ha ṣe òtítọ́, níti gidi, pé ìbínú wa (tàbí bí ó ti pọ̀ tó) sábà máa ń jẹ́ èyí tí kò ṣeé dáláre?
Bibeli sọ fún wa pé: “Dákẹ́ inú-bíbí, kí o sì kọ ìkannú sílẹ̀: máṣe ìkanra, kí o má baà ṣe búburú pẹ̀lú.” (Orin Dafidi 37:8) Báwo ni irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ṣe bọ́gbọ́nmu tó? Ó ha lè nípalórí ìlera rẹ fún ìgbà pípẹ́títí bí?
Nínú ẹ̀ka-ìpín rẹ̀ “Health (Ìlera),” ìwé-ìròyìn The New York Times sọ pé:
“Àwọn ènìyàn tí wọ́n sábà máa ń fi ìmọ̀lára lílágbára hàn lójijì lọ́nà oníwà-ipa tàbí tí wọ́n jókòó kalẹ̀ ní fífìbínú hàn sí gbogbo ìgbójúfonidá èyíkéyìí tí wọ́n bá kíyèsí lè máa ṣe púpọ̀ ju mímú araawọn wà ní ipò àìgbádùnmọ́ni lọ. Wọ́n lè máa ṣekúpa araawọn.
“Láìpẹ́ yìí àwọn olùṣèwádìí ti ṣàkójọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni òtítọ́ ìpìlẹ̀ tí ń dábàá pé ìbínu tí ó ti di bárakú ń pa ara lára débi pé ó jẹ́ ọ̀kan-náà pẹ̀lú, tàbí kí ó tilẹ̀ tayọ, sìgá mímu, ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ àti oúnjẹ tí ó kún fún ọ̀rá gẹ́gẹ́ bí okùnfà ewu lílágbára kan fún ikú àìtọ́jọ́.
“‘Àwọn ìwádìí wa fihàn pé ìbínú onífura, akóguntini dọ́gba pẹ̀lú jàm̀bá ìlera mìíràn tí a mọ̀ nípa rẹ̀,’ ni Dókítà Redford Williams, olùṣèwádìí kan nínú ìṣègùn nípa ìhùwà ní Ibùdó Ìṣègùn Yunifásítì ti Duke sọ.”
Àwọn ìwádìí fihàn pé àwọn tí wọ́n ń hùwà rékọjá àlà sí àwọn ìṣòro tí ó wọ́pọ̀ nínú ìgbésí-ayé ojoojúmọ́ ń mú àwọn omi ìsúnniṣe másùnmáwo tí ó pọ̀ jù jáde. Ìbínú rangbandan wọn àtìgbàdégbà lè fa àìwàdéédé láàárín irú àwọn èròjà-ọlọ́ràá-inú-sẹ́ẹ̀lì tí ń dáàbòboni ati èyí tí ń panilára, ní fífi wọ́n sínú ewu òkùnrùn ọkàn-àyà-òun-ihò-ẹ̀jẹ̀.
Àwọn díẹ̀ lè dáhùnpadà pé, ‘Ṣùgbọ́n bí mo ṣáà ti rí nìyẹn’ tàbí, ‘Mo dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ ni.’ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn kò túmọ̀sí pé o kò lè yípadà, nípa fífi òtítọ́-inú gbìyànjú làti fi àmọ̀ràn Ọlọrun sílò. Nínú Bibeli tìrẹ, ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ràn rẹ̀ nípa ìbínú àti ẹ̀hónú tí a kọ sínú Owe 14:29, 30; 22:24, 25; Efesu 4:26; Jakọbu 1:19, 20.
Fífi ọgbọ́n àtọ̀runwá yẹn sílò lè mú ìlera rẹ sunwọ̀n síi kí ó sì mú ìwàláàyè rẹ gùn síi. Ìwé-ìròyìn Times sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèwádìí sọ pé àwọn oníbìínú ènìyàn lè dín ewu ikú ṣáájú àkókò kù nípa yíyí àwọn ìhùwàpadà akóguntini, láìgbagbẹ̀rẹ́ padà.”