ǸJẸ́ O MỌ̀?
Álóè wo ni wọ́n máa ń lò láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì?
Bíbélì sọ pé, álóè wà lára àwọn èròjà tí wọn máa ń fi ṣe lọ́fínńdà tí wọ́n ń fín sára aṣọ àti bẹ́ẹ̀dì. (Sáàmù 45:8; Òwe 7:17; Orin Sólómọ́nì 4:14) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ara igi Agarwood (ìyẹn irú igi Aquilaria) ni àwọn álóè tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ti wá. Bí igi náà bá ṣe ń jẹrà, á bẹ̀rẹ̀ sí í sun òróró àti oje olóòórùn dídùn. Wọ́n á wá lọ igi tó ti jẹrà náà títí tó fi máa rí lẹ́búlẹ́bú bí àtíkè. Èyí tó rí lẹ́búlẹ́bú yìí ni wọ́n pè ní “álóè” tí wọ́n máa ń tà.
Bíbélì tiẹ̀ fi àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wé “àwọn ọ̀gbìn álóè tí Jèhófà gbìn.” (Númérì 24:5, 6) Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ àfiwé nípa bí igi Agarwood ṣe máa ń rí. Igi yìí máa ń ga tó ọgbọ̀n [30] mítà, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì máa ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Lóòótọ́ kò sí irú igi yìí ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti òde òní, àmọ́ ìwé náà, A Dictionary of the Bible sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mo igi álóè àtàwọn igi míì níbẹ̀, kò túmọ̀ sí pé wọn ò ní àwọn igi wọ̀nyí nígbà náà lọ́hùn-ún ní agbègbè Àfonífojì Jọ́dánì tí nǹkan tí rọ̀ṣọ̀mù, tí àwọn èèyàn ibẹ̀ sì pọ̀ gan-an.”
Irú àwọn ọrẹ ẹbọ wo ni àwọn àlùfáà máa ń gbà nínú Tẹ́ńpìlì?
Òfin Ọlọ́run sọ pé gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ fi rúbọ ní Tẹ́ńpìlì gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó dára jù lọ. Ọlọ́run kò ní gba ẹbọ èyíkéyìí tó bá ti ní àbààwọ́n. (Ẹ́kísódù 23:19; Léfítíkù 22:21-24) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, òǹkọ̀wé Júù kan tó ń jẹ́ Philo sọ pé àwọn àlùfáà nígbà yẹn máa ń yẹ àwọn ẹran wò “láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀” kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ara àwọn ẹran náà dá ṣáṣá àti pé “kò sí àbùkù kankan lára wọn.”
Bákan náà, ọ̀mọ̀wé E. P. Sanders sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì gba àwọn kan láyè nínú tẹ́ńpìlì láti máa ta ẹran àti ẹyẹ tí àwọn àlùfáà ti yẹ̀ wò dáadáa tí wọ́n sì rí pé wọ́n yẹ fún ìrúbọ. Àwọn tó ń tajà tún máa fún àwọn oníbàárà wọn ní ohun kan tó dà bí rìsíìtì tó máa fi hàn pé ẹran tàbí ẹyẹ náà kò ní àbààwọ́n.”
Ní ọdún 2011, àwọn awalẹ̀pìtàn rí ohun tó dà bíi rìsíìtì yẹn ní agbègbè tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n rí òǹtẹ̀ tí wọn fi amọ̀ ṣe, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí wọ́n rí yìí ni wọ́n ń lò ṣáájú ìgbà ayé Jésù títí di nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlógójì [37] lẹ́yìn tí Jésù kú. Wọ́n fi èdè Árámáíkì kọ ọ̀rọ̀ méjì sára rẹ̀ tí àwọn awalẹ̀pìtàn túmọ̀ sí “Mímọ́ fún Ọlọ́run.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì máa ń fi àwọn òǹtẹ̀ yìí sára àwọn nǹkan tó wà fún ìrúbọ tàbí àwọn ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ.