Jerúsálẹ́mù àti Tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì
A PÈ é ní “ìjẹ́pípé ẹwà ìfanimọ́ra” àti “ìlú Ọba títóbi lọ́lá.” (Sm 48:2; 50:2; Ida 2:15) Jerúsálẹ́mù ni olú ìlú orílẹ̀-èdè Ọlọ́run. (Sm 76:2) Lẹ́yìn tí Dáfídì gba ìlú náà mọ́ àwọn ará Jébúsì lọ́wọ́ tó sì sọ ọ́ di olú ìlú rẹ̀, a pe ìlú náà ní “Ìlú Ńlá Dáfídì” tàbí “Síónì,” ní ṣókí.—2Sa 5:7.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jerúsálẹ́mù wà níbi tó fara sin, ó di ìlú tó lókìkí gan-an, nítorí pé Ọlọ́run fi orúkọ rẹ̀ sínú ìlú náà. (Di 26:2) Ibẹ̀ ni ibùdó ìjọsìn àti ti ìṣàkóso fún orílẹ̀-èdè náà.
Orí òkè tó ga tó àádọ́ta lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [750] mítà láàárín ọ̀wọ́ àwọn òkè Jùdíà ni Jerúsálẹ́mù wà. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ‘ìgafíofío’ rẹ̀, ó sì sọ pé àwọn olùjọsìn ń “gòkè lọ” síbẹ̀. (Sm 48:2; 122:3, 4) Àfonífojì ló yí ìlú ìgbàanì náà ká: Àfonífojì Hínómù wà ní ìwọ̀ oòrùn àti àríwá, àfonífojì olójú ọ̀gbàrá Kídírónì sì wà ní ìlà oòrùn. (2Ọb 23:10; Jer 31:40) Ojúsun omi Gíhónìa tó wà ní Àfonífojì Kídírónì àti Ẹ́ń-rógélì tó wà ní gúúsù ló ń pèsè omi mímu tí kò níyọ̀, èyí sì ṣe pàtàkì nígbà táwọn ọ̀tá bá ń gbéjà kò wọ́n.—2Sa 17:17.
Ìlú Dáfídì la fi àwọ̀ pupa kùn nínú àwòrán tó wà lójú ewé 21. Nígbà ìṣàkóso Dáfídì àti Sólómọ́nì, ìlú náà gbòòrò lọ sí apá ìhà àríwá tó fi dé Ófélì (àwọ̀ ewéko) àti Òkè Móráyà (àwọ̀ aró). (2Sa 5:7-9; 24:16-25) Ní orí òkè yẹn ni Sólómọ́nì kọ́ tẹ́ńpìlì tó kàmàmà sí fún Jèhófà. Ìwọ tiẹ̀ fojú inú wo bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùjọsìn ti ń wọ́ lọ tìrítìrí sí “òkè ńlá Jèhófà” fún àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún! (Sek 8:3) Àwòrán àwọn ojú ọ̀nà tó já síra, èyí tí a yà sójú ewé 17 túbọ̀ mú kó rọrùn láti rin irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀.
Tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, tí wọ́n fi wúrà àti àwọn òkúta iyebíye ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé tí a náwó sí jù lọ láyé ńbí. Pabanbarì rẹ̀ sì ni pé Jèhófà ló pèsè àwòrán bí wọ́n ṣe máa kọ́ ọ. Gẹ́gẹ́ bí o ti lè rí i nínú àwòrán yìí, àwọn àgbàlá ńláńlá àti ilé ìṣàbójútó ló wà lápá ọ̀tún àti lápá òsì tẹ́ńpìlì náà. Ó máa dára kí o wá àyè láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn.—1Ọb 6:1–7:51; 1Kr 28:11-19; Heb 9:23, 24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Hesekáyà Ọba dí ojúsun omi yìí ó sì la ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan tó lọ já síbi odò adágún kan ní apá ìwọ̀ oòrùn.—2Kr 32:4, 30.
[Ihe Osise/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù/Sólómọ́nì
TẸ́ŃPÌLÌ ÀTI ÀYÍKÁ RẸ̀ NÍ ÀKÓKÒ SÓLÓMỌ́NÌ
Àwọn Ohun Tó Wà Ní Tẹ́ńpìlì
1. Ibi Mímọ́ Jù Lọ
2. Ibi Mímọ́
3. Gọ̀bì
4. Bóásì
5. Jákínì
6. Pẹpẹ Bàbà
7. Òkun Dídà
8. Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ẹrù
9. Àwọn Ìyẹ̀wù Ẹ̀gbẹ́
10. Yàrá Ìjẹun
11. Àgbàlá Inú Lọ́hùn-ún
INÚ ỌGBÀ TẸ́ŃPÌLÌ
Òkè Móráyà
Yàrá Ìjẹun
Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ẹrù
Àwọn Ìyẹ̀wù Ẹ̀gbẹ́
Ibi Mímọ́ Jù Lọ
Bóásì
Ibi Mímọ́
Gọ̀bì
Pẹpẹ Bàbà
Jákínì
Àgbàlá Inú Lọ́hùn-ún
Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ẹrù
Òkun Dídà
Ófélì
Ojúde Ìlú?
Ẹnubodè Omi?
ÌLÚ DÁFÍDÌ
Òkè Síónì
Ààfin Dáfídì
Ẹnubodè Ìsun Omi
Odi Ti Mánásè?
Ilé Gogoro Hánánélì
Ilé Gogoro Méà
Ẹnubodè Àgùntàn
Ẹnubodè Ẹ̀sọ́
Ẹnubodè Àbẹ̀wò
Ẹnubodè Ẹṣin
ÀFONÍFOJÌ KÍDÍRÓNÌ
Odi Apá Ìsàlẹ̀?
Gíhónì
Ihò omi tí wọ́n gbẹ́ nígbà tó yá
ÀFONÍFOJÌ TÍRÓPÓÓNÌ
Ẹnubodè Òkìtì-eérú (Àpáàdì) (Ẹlẹ́bọ́tọ)
Ẹ́ń-rógélì
Ẹnubodè Àfonífojì
ÀFONÍFOJÌ HÍNÓMÙ
Ẹnubodè Igun
Ilé Gogoro Àwọn Ààrò Ìyan-nǹkan
Odi Fífẹ̀
Ẹnubodè Éfúráímù
Gbàgede Ìlú
Ẹnubodè Ìlú Àtijọ́
Odi Àríwá Àtijọ́
ÌHÀ KEJÌ
Ẹnubodè Ẹja
[Àwòrán]
Ófélì
Ilé Ọmọbìnrin Fáráò
Ààfin Sólómọ́nì
Ilé Igbó Lẹ́bánónì
Gọ̀bì Ọlọ́wọ̀n
Gọ̀bì Ìtẹ́
Òkè Móráyà
Àgbàlá Títóbi
Tẹ́ńpìlì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
‘Ìlú Dáfídì’ ló wà lápá iwájú. Tẹ́ńpìlì ló wà níbi tó tẹ́ pẹrẹsẹ (lápá ẹ̀yìn)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwòrán ‘Ìlú Dáfídì’ ìgbàanì àti ti tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì tí a fi kọ̀ǹpútà yà