Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kìíní Sáàmù
KÍ NI orúkọ tó yẹ ká máa pe ìwé Bíbélì kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé orin ìyìn sí Jèhófà Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa ló kúnnú rẹ̀? Orúkọ tó bá a mu jù lọ ni Sáàmù tàbí Orin Ìyìn. Àwọn orin adùnyùngbà tó ń sọ nípa àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Ọlọ́run ní àtàwọn iṣẹ́ ńlá tó ṣe ló wà nínú ìwé Bíbélì tó gùn jù lọ yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ sì tún wà nínú rẹ̀. Àwọn tó kọ orin wọ̀nyí fi púpọ̀ nínú orin wọn sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn nígbà ìṣòro. Láti ìgbà ayé wòlíì Mósè ni kíkọ ìwé Sáàmù ti bẹ̀rẹ̀ títí di ẹ̀yìn ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé láti ìgbèkùn. Èyí fi hàn pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ni kíkọ ìwé yìí gbà kó tó parí. Mósè, Dáfídì Ọba àtàwọn míì ló kọ ọ́. Ìtàn sì fi hàn pé Ẹ́sírà àlùfáà ló to ìwé Sáàmù gẹ́gẹ́ bó ṣe wà báyìí.
Látìgbà ìjímìjí ni wọ́n ti pín àwọn orín inú ìwé Sáàmù sí ìsọ̀rí tàbí ìwé márùn-ún. Àwọn ìsọ̀rí náà nìyí: (1) Sáàmù 1 sí 41; (2) Sáàmù 42 sí 72; (3) Sáàmù 73 sí 89; (4) Sáàmù 90 sí 106; àti (5) Sáàmù 107 sí 150. Àwọn orí tó wà ní ìsọ̀rí àkọ́kọ́ nìkan ni àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ lé lórí. Yàtọ̀ sí sáàmù mẹ́ta kan, Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ni Bíbélì fi hàn pé ó kọ gbogbo sáàmù tó kù nínú ìsọ̀rí yìí. Bíbélì ò sọ ẹni tó kọ Sáàmù 1, 10 àti 33.
“ỌLỌ́RUN MI NI ÀPÁTA MI”
Sáàmù kìíní fi hàn pé aláyọ̀ ni ẹni tó bá ní inú dídùn sí òfin Jèhófà, nígbà tí sáàmù kejì dá lórí Ìjọba Ọlọ́run.a Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run ló pọ̀ jù nínú àwọn sáàmù tó wà ní ìsọ̀rí yìí. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 3 sí 5, 7, 12, 13 àti 17 jẹ́ ẹ̀bẹ̀ nípa ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Sáàmù kẹjọ sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe tóbi lọ́ba ní ìfiwéra pẹ̀lú èèyàn tí kò já mọ́ nǹkan kan.
Dáfídì fi hàn pé Jèhófà ni Ẹni tó ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tó kọ ọ́ lórin pé: “Ọlọ́run mi ni àpáta mi. Èmi yóò sá di í.” (Sáàmù 18:2) Ó fi Sáàmù 19 yin Jèhófà pé òun ni Ẹlẹ́dàá àti Olùfúnnilófin. Ní Sáàmù 20, ó sọ pé Jèhófà ni Olùgbàlà, ó sì yìn ín ní Sáàmù 21 pé ó jẹ́ Olùgbàlà fún Ọba tó fòróró yàn. Sáàmù 23 fi hàn pé Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùtàn Ńlá, nígbà tí Sáàmù 24 fi hàn pé òun ni Ọba ògo.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:1, 2—Kí ni “nǹkan òfìfo” táwọn orílẹ̀-èdè ń sọ lábẹ́lẹ̀? “Nǹkan òfìfo” ọ̀hún ni àníyàn táwọn ìjọba èèyàn ń ṣe ṣáá láti rí i pé ìjọba wọn ò dópin. Òfìfo lèyí sì jẹ́ torí pé pàbó ni gbogbo rẹ̀ yóò já sí. Àbí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè lè borí bí wọ́n ṣe mú ìdúró wọn “lòdì sí Jèhófà àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀” yìí?
2:7—Kí ni “àṣẹ àgbékalẹ̀ Jèhófà”? Òun ni májẹ̀mú Ìjọba tí Jèhófà bá Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n dá.—Lúùkù 22:28, 29.
2:12—Ọ̀nà wo làwọn aláṣẹ ayé lè gbà “fi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu”? Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ńṣe lẹni tó bá fẹnu koni lẹ́nu ń fi hàn pé òun jẹ́ ọ̀rẹ́ àti ẹni tó dúró ṣinṣin sí ẹni tó fẹnu kò lẹ́nu. Wọ́n tún máa ń fi í kí àlejò káàbọ̀ pẹ̀lú. Ẹsẹ Bíbélì yìí ní kí àwọn ọba ayé fẹnu ko Ọmọ náà lẹ́nu, ìyẹn ni pé kí wọ́n kí i káàbọ̀ kí wọ́n sì gbà pé òun ni Mèsáyà Ọba.
3:àkọlé—Kí nìdí tí wọ́n fi kọ àkọlé sórí àwọn sáàmù kan? Nígbà míì, irú àkọlé bẹ́ẹ̀ máa ń sọ ẹni tó kọ sáàmù náà, ó sì tún lè sọ ipò tí ẹni náà wà nígbà tó kọ ọ́. Irú èyí ló wà lókè Sáàmù 3. Àkọlé yẹn tún lè ṣàlàyé ohun tí orin náà wà fún (Sáàmù 4 àti 5), kó sì tún sọ bí wọ́n ṣe máa kọ orin náà (Sáàmù 6).
3:2:—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “Sélà” túmọ̀ sí? Àwọn èèyàn gbà pé ó dúró fún ìdánudúró díẹ̀ nítorí àtiṣe àṣàrò. Ó lè jẹ́ orin nìkan ni wọ́n máa dá dúró tàbí kó jẹ́ àtorin àti ohun èlò ìkọrin. Ìdí tí wọ́n fi ń dánu dúró bẹ́ẹ̀ ni pé, wọ́n fẹ́ kí sáàmù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ lórin náà lè túbọ̀ wọni lọ́kàn. Kò yẹ ká pe sélà yìí nígbà tá a bá ń ka ìwé Sáàmù fún àwùjọ.
11:3—Àwọn ìpìlẹ̀ wo ni wọ́n ya lulẹ̀? Àwọn ni àwọn ìpìlẹ̀ tí aráyé wà lórí rẹ̀, ìyẹn òfin, ètò àti ìdájọ́ òdodo. Bí nǹkan wọ̀nyí bá dojú rú, ńṣe ni gbogbo nǹkan máa di rúdurùdu, kò sì ní sí ìdájọ́ òdodo. Tọ́rọ̀ bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí “olódodo” fi gbogbo ọkàn gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.—Sáàmù 11:4-7.
21:3—Kí ló ṣe pàtàkì nípa “adé wúrà tí a yọ́ mọ́”? Bóyá adé gidi nibí yìí ń wí o tàbí ńṣe ló kàn dúró fún ògo tí Dáfídì gbà nítorí ọ̀pọ̀ ìṣẹ́gun rẹ̀, Bíbélì kò sọ. Àmọ́ ṣá, ẹsẹ yìí jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó ń sọ nípa adé tí Jèhófà fún Jésù lọ́dún 1914 nígbà tó jọba. Adé wúrà tí adé náà jẹ́ fi hàn pé ìṣàkóso Jésù ta ìṣàkóso èyíkéyìí yọ.
22:1, 2—Kí ló mú kí Dáfídì rò pé Jèhófà ti fòun sílẹ̀? Àwọn ọ̀tá Dáfídì ni í lára gan-an débi pé ‘ọkàn rẹ̀ dà bí ìda, ó sì yọ́ jinlẹ̀-jinlẹ̀ níhà inú rẹ̀.’ (Sáàmù 22:14) Lójú ẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà ti fòun sílẹ̀. Bó ṣe rí lára Jésù náà nìyẹn nígbà tí wọ́n kàn án mọ́gi. (Mátíù 27:46) Ọ̀rọ̀ Dáfídì yìí jẹ́ ká rí ìṣarasíhùwà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èèyàn ẹlẹ́ran ara nígbà tí ìṣòro kà á láyá. Ṣùgbọ́n tá a bá wo àdúrà Dáfídì tó wà nínú Sáàmù 22:16-21, a óò rí i pé Dáfídì ṣì nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:1. Kò yẹ ká máa bá àwọn tí kò fẹ́ràn Jèhófà kẹ́gbẹ́.—1 Kọ́ríńtì 15:33.
1:2. Kò yẹ ká jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá lọ láìgbé ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìjọsìn wa sí Ọlọ́run yẹ̀ wò.—Mátíù 4:4.
4:4. Nígbà tínú bá ń bí wa, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká ṣọ́ ẹnu wa, kó má di pé a lọ sọ ohun tá a máa padà kábàámọ́.—Éfésù 4:26.
4:5. Ìgbà tó bá jẹ́ pé ẹ̀mí tó dára la fi ń rú ẹbọ tẹ̀mí tá à ń rú, tí ìwà wa sì bá àwọn ìlànà Jèhófà mu nìkan ni ẹbọ wa lè jẹ́ “ẹbọ òdodo.”
6:5. Kí nìdí téèyàn ì bá tún fi fẹ́ wà láàyè bí kò ṣe pé kéèyàn lè máa yin Jèhófà?—Sáàmù 115:17.
9:12. Nítorí kí Jèhófà lè fìyà jẹ ẹni tó tàjẹ̀ sílẹ̀ ló ṣe ń wá ìtàjẹ̀sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó máa ń rántí “igbe ẹkún àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.”
15:2, 3; 24:3-5. Olùjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́, kó má ṣe búra èké tàbí kó fọ̀rọ̀ èké bani jẹ́.
15:4. Ńṣe ló yẹ ká máa sa gbogbo ipá wa láti mú ọ̀rọ̀ wa ṣẹ kódà tó bá tiẹ̀ nira fún wa láti mú un ṣẹ, àyàfi tá a bá rí i pé ohun tá a ṣèlérí láti ṣe kò bá Bíbélì mu.
15:5. Àwa olùjọsìn Jèhófà kò gbọ́dọ̀ máa lo owó lọ́nà àìtọ́.
17:14, 15. Ohun tó jẹ “àwọn ènìyàn ètò àwọn nǹkan yìí” lógún ni bí wọ́n á ṣe rí towó ṣe, bí wọ́n á ṣe fẹ́yàwó kí wọ́n sì bímọ, àti bí wọ́n á ṣe rí ogún fi sílẹ̀ fọ́mọ. Ní ti Dáfídì, ohun tó jẹ ẹ́ lógún nígbèésí ayé ni bó ṣe máa lórúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run kó lè máa ‘rí ojú rẹ̀,’ ìyẹn ni pé kó rí ojú rere Jèhófà. Nígbàkigbà tí Dáfídì bá “jí” tó sì rí àwọn ìlérí àti ìdánilójú tí Jèhófà fún un, ó máa ń ‘tẹ́ ẹ lọ́rùn pé òun rí ìrísí Ọlọ́run,’ èyí tó túmọ̀ sí pé inú rẹ̀ máa ń dùn pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. Ǹjẹ́ àwọn ìṣúra tẹ̀mí kọ́ ló yẹ kó jẹ àwa náà lógún bíi ti Dáfídì?
19:1-6. Bí àwọn ìṣẹ̀dá tí kì í ronú, tí kì í sì í sọ̀rọ̀ bá ń yin Jèhófà lógo, mélòó-mélòó làwa tá a lè ronú, tá a lè sọ̀rọ̀, tá a sì lè ṣe ìjọsìn?—Ìṣípayá 4:11.
19:7-11. Àwọn ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ká máa ṣe máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an!
19:12, 13. Àṣìṣe àti ìwà ìkùgbù jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó yẹ ká máa sá fún.
19:14. Kì í ṣe ohun tá a bá ń ṣe nìkan ló yẹ ká máa kíyè sára nípa rẹ̀, ó yẹ ká tún máa ṣọ́ra nípa ohun tá à ń sọ àti ohun tá à ń rò.
“ÌWỌ TI GBÈJÀ MI NÍTORÍ ÌWÀ TÍTỌ́ MI”
Tọkàntọkàn àti tìpinnu-tìpinnu ni Dáfídì fi sọ ọ́ nínú sáàmù méjì àkọ́kọ́ tó wà ní ìsọ̀rí yìí, pé òun yóò pa ìwà títọ́ òun mọ! Ó kọ ọ́ lórin pé: “Ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi.” (Sáàmù 26:11) Nígbà tó ń gbàdúrà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, ó ní: “Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 32:3) Dáfídì mú un dá àwọn èèyàn Jèhófà tó jẹ́ adúróṣinṣin lójú pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.”—Sáàmù 34:15.
Ìmọ̀ràn tó wà nínú Sáàmù 37 wúlò gan-an ni fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àwa tí à ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí! (2 Tímótì 3:1-5) Sáàmù 40:7, 8 sọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi, ó ní: “Kíyè sí i, mo ti dé, nínú àkájọ ìwé ni a ti kọ ọ́ nípa mi. Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” Sáàmù tó kẹ́yìn ní ìsọ̀rí yìí jẹ́ igbe ìrànlọ́wọ́ tí Dáfídì ké sí Jèhófà láwọn ọdún tí ìpọ́njú dé bá a lẹ́yìn tí òun àti Bátí-ṣébà dẹ́ṣẹ̀. Ó wá kọrin pé: “Ní tèmi, ìwọ ti gbèjà mi nítorí ìwà títọ́ mi.”—Sáàmù 41:12.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
26:6—Bíi ti Dáfídì, báwo la ṣe ń rìn yí ká pẹpẹ Jèhófà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ? Pẹpẹ tí ibí yìí ń wí dúró fún fífẹ́ tí Jèhófà fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba ẹbọ tí Jésù Kristi fi ra aráyé padà. (Hébérù 8:5; 10:5-10) Tá a bá ti ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ yẹn, à ń rìn yí ká pẹpẹ Jèhófà nìyẹn.
29:3-9—Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń gbé yọ nígbà tó fi ohùn Jèhófà wé sísán ààrá, èyí tó ń ṣe ohun ìyanu bó ṣe ń sán? Àrágbáyamúyamù agbára Jèhófà ni o!
31:23—Báwo ni Jèhófà ṣe ń san ẹ̀san lọ́nà tí ó peléke fún ẹni tí ń hùwà ìrera? Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ni ẹ̀san tí ibí yìí ń wí. Tí olódodo bá ṣèèṣì ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó, Jèhófà yóò bá a wí, ìyẹn sì ni ẹ̀san tirẹ̀. Níwọ̀n bí onírera kò ti ní yí padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ní tirẹ̀, Jèhófà yóò fìyà tó gbópọn jẹ ẹ́ láti fi san ẹ̀san fún un lọ́nà tó peléke.—Òwe 11:31; 1 Pétérù 4:18.
33:6—Kí ni “ẹ̀mí ẹnu” Jèhófà yìí? Ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run tàbí ẹ̀mí mímọ́ ni, èyí tí Ọlọ́run fi dá gbogbo ohun tí ń bẹ ní ìsálú ọ̀run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1, 2) Ìdí tí ibí yìí fi pè é ní ẹ̀mí ẹnu Jèhófà ni pé bí èémí tó lágbára ṣe ń jáde ni Jèhófà ṣe lè rán an lọ sí ọ̀nà jíjìn láti lọ ṣe nǹkan kan.
35:19—Kí ni ìtumọ̀ ẹ̀bẹ̀ tí Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó má ṣe jẹ́ kí àwọn tó kórìíra òun ṣẹ́jú? Bí àwọn ọ̀tá Dáfídì bá ń ṣẹ́jú, yóò fi hàn pé inú wọn ń dùn pé ọwọ́ àwọn ti ba Dáfídì. Dáfídì wá ń gbàdúrà pé kí èrò ibi wọn sí òun má ṣe ṣẹ.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
26:4. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká yẹra fún àwọn tó máa ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tàbí àwọn tó máa ń díbọ́n pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ wa kí wọ́n lè mú ètekéte wọn ṣẹ, yálà nílé ìwé tàbí níbi iṣẹ́. Ó sì bọ́gbọ́n mu pé ká yẹra fáwọn apẹ̀yìndà tó ń ṣe bíi pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àtàwọn tó máa ń ṣe bíi pé wọ́n jẹ́ Kristẹni tòótọ́ àmọ́ tí wọ́n máa ń yọ́lẹ̀ ṣe àìdáa.
26:7, 12; 35:18; 40:9. A ní láti máa yin Jèhófà láàárín àwọn ará ní ìpàdé Kristẹni.
26:8; 27:4. Ǹjẹ́ àwọn ìpàdé ìjọ máa ń wù wá láti lọ?
26:11. Bí Dáfídì ṣe ń sọ ìpinnu rẹ̀ láti pa ìwà títọ́ mọ́ náà ló ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà ra òun padà. Bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, ó dájú pé a lè pa ìwà títọ́ wa mọ́.
29:10. Jíjókòó tí Jèhófà jókòó sórí “àkúnya omi” fi hàn pé Jèhófà lè ṣèkáwọ́ agbára òun fúnra rẹ̀ dáadáa.
30:5. Ìfẹ́ ló gbawájú nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà, kì í ṣe ìbínú.
32:9. Jèhófà kò fẹ́ ká dà bíi ti ìbaaka tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá tó nà án ní patiyẹ ló ń gbọ́ràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ kó jẹ́ pé òye tá a ní nípa ohun tó ń fẹ́ ló ń mú ká máa pinnu láti ṣègbọràn sóun.
33:17-19. Kò sí ètò tí ọmọ aráyé lè gbé kalẹ̀ tó lè gbani là bó ti wù kí ètò náà lágbára tó. Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ nìkan ni ká gbẹ́kẹ̀ lé.
34:10. Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ gbáà lèyí jẹ́ fáwọn tó fi ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo láyé wọn!
39:1, 2. Táwọn ẹni burúkú bá fẹ́ gbọ́rọ̀ lẹ́nu wa kí wọ́n lè fi ṣèpalára fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa, ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe ni pé ká fi ‘ìdínu tí ó rí bí ẹ̀ṣọ́ dí ẹnu wa’ ká sì dákẹ́.
40:1, 2. Tá a bá ní ìrètí nínú Jèhófà, a ó lè borí ìdààmú ọkàn, yóò wá dà bí ìgbà téèyàn ń ‘gòkè bọ̀ láti inú kòtò tí ń ké ramúramù, láti inú ẹrẹ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀.’
40:5, 12. Bó ti wù kí àjálù tàbí ìkùdíẹ̀-káàtó wa pọ̀ tó, wọn ò ní lè borí wa tá a bá ń rántí pé àwọn ìbùkún tá a ti rí gbà ‘pọ̀ níye ju èyí tá a lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ lọ.’
“Ìbùkún Ni fún Jèhófà”
Sáàmù mọ́kànlélógójì tó wà ní ìsọ̀rí yìí ń tuni nínú, wọ́n sì ń fúnni níṣìírí gan-an! Yálà a wà nínú ìṣòro tàbí ẹ̀rí ọkàn ń yọ wá lẹ́nu nítorí àṣìṣe wa, apá yìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lágbára gan-an lè fún wa lókun àti ìṣírí. (Hébérù 4:12) Ọ̀rọ̀ inú àwọn sáàmù yìí fún wa láwọn ìtọ́sọ́nà tó jíire nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa. Bí a ṣe ń kà á ló túbọ̀ ń dá wa lójú pé inú ìṣòro yòówù kí a wà, Jèhófà kò ní kọ̀ wá sílẹ̀.
Ọ̀rọ̀ tó gbẹ́yìn àwọn sáàmù tó wà ní ìsọ̀rí àkọ́kọ́ yìí ni: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì láti àkókò tí ó lọ kánrin, àní dé àkókò tí ó lọ kánrin. Àmín àti Àmín.” (Sáàmù 41:13) Ǹjẹ́ àwọn sáàmù tá a gbé yẹ̀ wò yìí ò mú ká fẹ́ láti fi ìyìn fún Jèhófà?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Sáàmù kejì ti kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ nígbà ayé Dáfídì.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Bí àwọn ìṣẹ̀dá tí kò lè ronú, tí kò sì lè sọ̀rọ̀ bá ń yin Jèhófà lógo, mélòó-mélòó làwa ẹ̀dá èèyàn!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Dáfídì ló kọ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú sáàmù kìíní sí ìkọkànlélógójì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ o mọ sáàmù tó fi hàn pé Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá lọ láìgbé ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìjọsìn rẹ sí Ọlọ́run yẹ̀ wò
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn ìràwọ̀: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda United States Naval Observatory
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn ìràwọ̀, ojú ìwé 18 àti 19: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda United States Naval Observatory
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn ìràwọ̀: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda United States Naval Observatory