Ìwọ Ha Ń Yán Hànhàn Láti Ṣiṣẹ́ Sìn ní Kíkún Sí I Bí?
LAURA sọ pé: “Inú bí mi sí Jèhófà. Mo gbàdúrà gbàdúrà pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro ìṣúnná owó wa, kí n baà lè máa bá ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà nìṣó—ṣùgbọ́n pàbó ló já sí. Mo ní láti fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Mo tún gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé, mo ń jowú àwọn tí wọ́n lè máa bá a nìṣó.”
Tún gbé ọ̀ràn Michael, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan nínú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yẹ̀ wò. Ó ti ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó. (Tímótì Kíní 3:1) Nígbà tí ohun tí ó ń yán hànhàn fún kò tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ọkàn rẹ̀ bà jẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi fẹ́ kí a gbé òun yẹ̀ wò fún àǹfààní náà mọ́. Ó sọ pé: “N kò lè fara da ìrora ìjákulẹ̀ kankan mọ́.”
Ìwọ ha ti ní ìrírí tí ó fara jọ ìyẹn bí? O ha ti ní láti fi àǹfààní ìṣàkóso Ọlọ́run kan tí o yàn láàyò sílẹ̀ bí? Fún àpẹẹrẹ, ó ha ti pọn dandan fún ọ láti dáwọ́ ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún dúró bí? Àbí o ti ń yán hànhàn fún àwọn ẹrù iṣẹ́ ìjọ kan tí a fà lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́? Ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé, ó nífẹ̀ẹ́ gan-an láti ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ṣùgbọ́n àyíká ipò rẹ kò yọ̀ǹda fún ọ.
Ìwé Òwe sọ pé: “Ìrètí pípẹ́ mú ọkàn ṣàìsàn.” (Òwe 13:12) Ní pàtàkì, èyí lè rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá rí àǹfààní náà gan-an tí o ń retí gbà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ha pèsè ìjìnlẹ̀ òye, ìtùnú, àti ìrètí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá nírìírí irú ìjákulẹ̀ bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ní tòótọ́, Orin Dáfídì ìkẹrìnlélọ́gọ́rin sọ ìmọ̀lára tí ìránṣẹ́ Jèhófà kan ní, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ ìfẹ́ ọkàn tí ó ní nípa iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
Ìmọrírì Ọmọ Léfì Kan
Àwọn ọmọkùnrin Kórà, àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ṣiṣẹ́ sìn ní tẹ́ńpìlì Jèhófà, tí wọ́n sì ka àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wọn sí gidigidi, ni wọ́n kọ Orin Dáfídì ìkẹrìnlélọ́gọ́rin sílẹ̀. Ọ̀kan nínú wọn kígbe tìyanutìyanu pé: “Àgọ́ rẹ wọnnì ti ní ẹwà tó, Olúwa àwọn ọmọ ogun! Ọkàn mi ń fà ní tòótọ́, ó tilẹ̀ pe òǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa: àyà mi àti ara mi ń kígbe sí Ọlọ́run alààyè.”—Orin Dáfídì 84:1, 2.
Ọmọ Léfì yí yán hànhàn fún ṣíṣiṣẹ́ sìn nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ìrísí ilẹ̀ ọ̀nà Jerúsálẹ́mù lásán fi fà á lọ́kàn mọ́ra. Ó sọ pé: “Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ, wọn sọ ọ́ di kànga.” (Orin Dáfídì 84:6) Bẹ́ẹ̀ ni, àgbègbè tí ó sábà ń gbẹ táútáú dà bí ẹkùn ilẹ̀ tí omi rin gbingbin.
Nítorí pé onísáàmù náà jẹ́ ọmọ Léfì tí kì í ṣe àlùfáà, ọ̀sẹ̀ kan péré láàárín oṣù mẹ́fà ni ó lè ṣiṣẹ́ sìn ní tẹ́ńpìlì. (Kíróníkà Kíní 24:1-19; Kíróníkà Kejì 23:8; Lúùkù 1:5, 8, 9) Yóò lo àkókò rẹ̀ tí ó ṣẹ́ kù ní ilé nínú ọkàn nínú àwọn ìlú àwọn ọmọ Léfì. Nítorí náà, ó kọrin pé: “Ológoṣẹ́ rí ilé, àti alápàńdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀, níbi tí yóò gbé máa pa àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ sí, àní ní pẹpẹ rẹ̀ wọnnì, Olúwa àwọn ọmọ ogun, Ọba mi àti Ọlọ́run mi.” (Orin Dáfídì 84:3) Ẹ wo bí ọmọ Léfì náà yóò ti láyọ̀ tó, bí òun bá dà bí àwọn ẹyẹ tí wọ́n ní ibùgbé wíwàpẹ́títí nínú tẹ́ńpìlì!
Ì bá ti rọrùn fún ọmọ Léfì náà láti bọkàn jẹ́ nítorí pé kò lè ṣiṣẹ́ sìn nínú tẹ́ńpìlì nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n, inú rẹ̀ dùn láti lè ṣiṣẹ́ sìn bí àǹfààní tí a fún un ti tó, ó sì mọ̀ dájú pé, ìfọkànsìn pátápátá fún Jèhófà yẹ fún irú ìsapá náà. Kí ní ran ọmọ Léfì olùṣòtítọ́ yìí lọ́wọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀?
Kọ́ Láti Ní Ìtẹ́lọ́rùn
Ọmọ Léfì náà sọ pé: “Ọjọ́ kan nínú àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ. Mo fẹ́ kí n kúkú máa ṣe adènà ní ilé Ọlọ́run mi, jù láti máa gbé àgọ́ ìwà búburú.” (Orin Dáfídì 84:10) Ó mọrírì pé, lílo ọjọ́ kan péré nínú ilé Jèhófà jẹ́ àǹfààní aláìṣeé-díyelé. Ọmọ Léfì náà sì ní ju ọjọ́ kan lọ dáadáa láti ṣiṣẹ́ sìn nínú tẹ́ńpìlì. Ìtẹ́lọ́rùn tí ó ní pẹ̀lú àwọn àǹfààní tí ó ní mú kí ó fi ìdùnnú kọrin.
Àwa náà ńkọ́? Àwa ha ń rántí àwọn ìbùkún tí a ń rí gbà, tàbí a ha ní ìtẹ̀sí láti gbàgbé àwọn àǹfààní tí a ti ní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bí? Nítorí ìfọkànsìn wọn sí i, Jèhófà ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àwọn àǹfààní àti ẹrù iṣẹ́ gbígbòòrò. Èyí ní àwọn ẹrù iṣẹ́ wíwúwo ti ṣíṣàbójútó, ìṣolùṣọ́ àgùntàn, ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, àti onírúurú apá mìíràn ti iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní nínú. Ṣùgbọ́n wọ́n tún kan àwọn ohun ṣíṣeyebíye mìíràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà.
Fún àpẹẹrẹ, gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni yẹ̀ wò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àǹfààní wíwàásù ìhìn rere tí a ní wé níní tí a ní ‘ìṣúra nínú àwọn ohun ìlò tí a fi amọ̀ ṣe.’ (Kọ́ríńtì Kejì 4:7) Ìwọ ha ń wo irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣúra tí kò ṣeé díye lé bí? Jésù Kristi, ẹni tí ó mú ipò iwájú nínú ìgbòkègbodò wíwàásù Ìjọba, wò ó lọ́nà yẹn, ní fífi àwòṣe lélẹ̀. (Mátíù 4:17) Pọ́ọ̀lù wí pé: “Níwọ̀n bí a ti ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí . . . , àwa kò . . . juwọ́ sílẹ̀.”—Kọ́ríńtì Kejì 4:1.
Àwọn ìpàdé Kristẹni pẹ̀lú jẹ́ ìpèsè mímọ́ ọlọ́wọ̀ tí a kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú. Ní àwọn ìpàdé wa, a ń rí ìtọ́ni pàtàkì gbà, a sì ń gbádùn ìkẹ́gbẹ́pọ̀ tí a nílò. Ní àwọn ìpàdé, a tún lè sọ ìgbàgbọ́ àti ìrètí wa jáde ní gbangba, nípa dídáhùn déédéé àti nípa kíkópa nínú ìtólẹ́sẹẹsẹ ní àwọn ọ̀nà míràn. (Hébérù 10:23-25) Ní tòótọ́, àwọn ìpàdé wa jẹ́ ìpèsè tí a ní láti ṣìkẹ́!
Michael, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, ka àwọn ìbùkún wọ̀nyí sí gidigidi, ó sì ní ìmọrírì tí ó jinlẹ̀ fún wọn. Ṣùgbọ́n ìjákulẹ̀ tí ó ní, nítorí tí kò lè ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà mú kí ìmọrírì rẹ̀ fún wọn dín kù fún ìgbà díẹ̀. Nípa pípadà ronú lórí wọn, ó ṣeé ṣe fún un láti jèrè ìwàdéédéé rẹ̀ pa dà, kí ó sì fi sùúrù dúró de Jèhófà.
Kàkà tí a óò fi nímọ̀lára àìnítẹ̀ẹ́-lọ́rùn nítorí àìní àǹfààní kan pàtó, yóò dára kí a tún àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bù kún wa yẹ̀ wò, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti ṣe.a Bí a kò bá rí ohun púpọ̀, a ní láti tún un wò, ní bíbéèrè pé kí Jèhófà la ojú wa kí a lè rí àwọn àǹfààní wa tí a ní àti àwọn ọ̀nà tí ó ń gbà bù kún wa, tí ó sì gbà ń lò wá fún ìyìn rẹ̀.—Òwe 10:22.
Ó tún ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé, àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀, irú bí ipò alábòójútó, ń béèrè fún àwọn ìtóótun kan pàtó. (Tímótì Kíní 3:1-7; Títù 1:5-9) Nítorí náà, a ní láti yẹ ara wa wò dáradára, ní wíwo àgbègbè èyíkéyìí tí a ti ní láti sunwọ̀n sí i, kí a sì sapá gidigidi láti sunwọ̀n sí i.—Tímótì Kíní 4:12-15.
Má Ṣe Rẹ̀ Wẹ̀sì
Bí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan kò bá tẹ̀ wá lọ́wọ́, kò yẹ kí a parí èrò sí pé, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ń gbádùn rẹ̀ ju àwọn tí kò gbádùn rẹ̀ lọ tàbí pé ó ń fawọ́ ire sẹ́yìn fún wa. Dájúdájú, kò yẹ kí a jẹ́ kí ìlara mú wa rò pé àwọn wọ̀nyí ti rí àǹfààní wọn gbà lọ́nà tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, nípasẹ̀ ojúsàájú ẹ̀dá ènìyàn dípò nípasẹ̀ ìṣètò ìṣàkóso Ọlọ́run. Ṣíṣàníyàn lórí irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí owú, asọ̀, àní kí a tilẹ̀ juwọ́ sílẹ̀ pátápátá.—Kọ́ríńtì Kíní 3:3; Jákọ́bù 3:14-16.
Laura, tí a mẹ́nu kàn ní ìṣáájú, kò juwọ́ sílẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó ronú jinlẹ̀ lórí ìbínú àti owú tí ó ń jẹ. Laura gbàdúrà sí Ọlọ́run léraléra fún ìrànlọ́wọ́ láti lè sẹ́pá ìmọ̀lára òdì tí ó ní, tí kò jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún un láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ó tún wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin tí ó tóótun nínú ìjọ, ó sì ní ìdánilójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun. Ó wí pé: “Jèhófà fún mi ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Bí èmi àti ọkọ mi kò tilẹ̀ lè ṣe aṣáájú ọ̀nà nisinsìnyí, a ṣìkẹ́ àkókò tí a ṣe é, a sì rí okun gbà láti inú àwọn ìrírí tí a ti kó jọ. A tún ń ran ọmọkùnrin wa tí ó ti dàgbà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí ó ń ṣe.” Nítorí jíjẹ́ onítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ó ṣeé ṣe fún Laura nísinsìnyí láti “yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀” nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n ń ṣe.—Róòmù 12:15.
Gbé Àwọn Góńgó Tí O Lè Lé Bá Kalẹ̀
Níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí a ní ní lọ́ọ́lọ́ọ́ kò sọ pé kí a dẹ́kun gbígbé àwọn àfikún góńgó ìṣàkóso Ọlọ́run kalẹ̀. Ní jíjíròrò àjíǹde ti ọ̀run, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú.” Ó tún wí pé: “Dé àyè tí a ti tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní rírìn létòlétò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yí.” (Fílípì 3:13-16) Àwọn góńgó ìṣàkóso Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti nàgà síwájú. Ṣùgbọ́n, ìpèníjà náà ni láti jẹ́ kí wọ́n jẹ́ èyí tí ọwọ́ wa lè tẹ̀.
Àwọn góńgó tí ọwọ́ wa lè tẹ̀ jẹ́ èyí tí ó lọ́gbọ́n nínú, tí a sì lè lé bá. (Fílípì 4:5) Èyí kò túmọ̀ sí pé, ọwọ́ wa kò lè tẹ góńgó kan tí ó nílò ọ̀pọ̀ ọdún iṣẹ́ àṣekára. A lè lé irú góńgó ọlọ́jọ́ pípẹ́ kan bẹ́ẹ̀ bá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nípa gbígbé ọ̀wọ́ góńgó, tàbí ìgbésẹ̀ agbedeméjì kalẹ̀. Ìwọ̀nyí lè jẹ́ àmì fún ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí. Kíkẹ́sẹjárí nínú ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan yóò pèsè ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn bí a ṣe ń bá a nìṣó, dípò ìjákulẹ̀.
Ìwàdéédéé Gbígbámúṣé
Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé, nítorí àwọn àyíká ipò àti ìkù-díẹ̀-káàtó wa, àwọn àǹfààní kan lè má tẹ̀ wá lọ́wọ́. Gbígbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi góńgó lè yọrí sí kìkì ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́. A ní láti gbé irú àwọn góńgó bẹ́ẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó kéré tán fún ìgbà díẹ̀. Ṣíṣe èyí kò ní ṣòro bí a bá gbàdúrà fún ìtẹ́lọ́rùn oníwà-bí-Ọlọ́run, tí a sì fi ṣíṣe ìfẹ́ inú Jèhófà ṣe olórí àníyàn wa. Nígbà tí a bá ń nàgà fún àǹfààní, ògo Jèhófà—kì í ṣe bí àṣeyọrí àwa fúnra wa ti tó—ni ó ṣe pàtàkì. (Orin Dáfídì 16:5, 6; Mátíù 6:33) Bíbélì sọ fún wa lọ́nà yíyẹ pé: “Ká iṣẹ́ rẹ lé Olúwa lọ́wọ́, a óò sì fi ìdí ìrò inú rẹ kalẹ̀.”—Òwe 16:3.
Ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò Orin Dáfídì ìkẹrìnlélọ́gọ́rin, a lè rí i pé, onísáàmù náà fi irú ìwà bẹ́ẹ̀ hàn sí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, Jèhófà sì bù kún un jìngbìnnì. Ní àfikún sí i, sáàmù yí ń bá a nìṣó láti máa ṣàǹfààní fún àwọn ènìyàn Jèhófà títí di òní olónìí.
Pẹ̀lú gbígbáralé Jèhófà tàdúràtàdúrà, ìwọ lè mú kí ìyánhànhàn rẹ fún àwọn àfikún àǹfààní wà déédéé pẹ̀lú níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn tí o ń gbádùn nísinsìnyí. Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn láti ṣe púpọ̀ sí i mú kí o pàdánù ìmọrírì fún àwọn ohun tí o ní nísinsìnyí àti ìdùnnú ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà títí láé. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, nítorí èyí ń yọrí sí ayọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ ọmọ Léfì náà ti fi hàn pé: “Jèhófà àwọn ọmọ ogun, aláyọ̀ ni ọkùnrin náà ti ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.”—Orin Dáfídì 84:12, NW.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ náà, “Iwọ Ha Mọrírì Awọn Ohun Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ Bí?” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1988.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
Góńgó Tí A Lè Gbé Kalẹ̀
Kíka Bíbélì lójoojúmọ́.—Jóṣúà 1:8; Mátíù 4:4
Mímú agbára ìwòye wa sunwọ̀n sí i nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́.—Hébérù 5:14
Mímú ipò ìbátan tí ó túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Ọlọ́run.—Orin Dáfídì 73:28
Mímú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èso ti ẹ̀mí dàgbà.—Gálátíà 5:22, 23
Mímú kí àdúrà wa túbọ̀ jẹ́ ojúlówó.—Fílípì 4:6, 7
Dídi oníwàásù àti olùkọ́ tí ó já fáfá sí i.—Tímótì Kíní 4:15, 16
Kíka ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! kọ̀ọ̀kan àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀.—Orin Dáfídì 49:3
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ní gbígbé àwọn góńgó ara ẹni kalẹ̀, fi ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́