Jehofa, Olùṣe Awọn Ohun Àgbàyanu-ńlá
“Iwọ tobi o sì ń ṣe awọn ohun àgbàyanu-ńlá; iwọ ni Ọlọrun, iwọ nikan.”—ORIN DAFIDI 86:10, NW.
1, 2. (a) Bawo ni awọn ìhùmọ̀ eniyan ti nipa lori ayé? (b) Nibo ni a ti lè rí ireti nipa awọn ohun didara jù?
ENIYAN ode-oni lè fọ́nnu pe awọn ìhùmọ̀ṣe oun jẹ àgbàyanu-ńlá—awọn ọgbọ́n ihumọ ti iná ẹlẹtiriki, eto títa àtagbà awọn ihin-iṣẹ nipasẹ tẹlifoonu, wáyà, redio, ati tẹlifiṣọn, fidio, ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́, irin-ajo ninu ọkọ̀ ofuurufu ayára-bí-àṣá, ati ìmọ̀-iṣẹ́-ẹ̀rọ oni-kọmputa. Iwọnyi ti sọ ayé di adugbo kanṣoṣo. Ṣugbọn ẹ wo iru adugbo ti eyi jẹ́! Dipo alaafia, aasiki, ati ànító fun gbogbo eniyan, araye ni a kó ìyọnu bá nipasẹ awọn ogun apanirun, iwa-ọdaran, ìkópayàbáni, biba ayika jẹ́, ati òṣì. Awọn ohun ìjà runlé-rùnnà ti ó sì wà kaakiri yika ayé, bi o tilẹ jẹ́ pe wọn dinku ni iye, ṣì lè pa iran eniyan run ni ọpọlọpọ ìgbà leralera. Awọn oniṣowo ikú, awọn olùṣe nǹkan ija-ogun runlé-rùnnà, ń baa lọ lati ṣe iṣẹ́-òwò titobi julọ lori ilẹ̀-ayé. Awọn olówó tubọ ń lówó sii, ti awọn òtòṣì sì tubọ ń tòṣì sii. Ẹnikẹni ha lè pese ọ̀nà abajade eyikeyii bi?
2 Bẹẹni! Nitori Ẹnikan wà ti ó mú ìdáǹdè daniloju, “ẹni ti ó ga ju . . . ẹni ti ó ga,” Jehofa Ọlọrun. (Oniwasu 5:8) Ó mí sí kíkọ awọn orin, eyi ti ó pese itunu ati imọran ọlọgbọn pupọpupọ fun awọn akoko idaamu. Lara wọn ni Orin Dafidi 86 (NW), eyi ti ó ní akọle rirọrun naa: “Adura Dafidi Kan.” Ó jẹ́ adura kan ti o lè sọ di tìrẹ.
Ẹni ti A Pọ́nlójú Ṣugbọn ti Ó Duroṣinṣin
3. Ni awọn akoko wọnyi, apẹẹrẹ afunni niṣiiri wo ni Dafidi pese fun wa?
3 Dafidi kọ orin yii nigba ti ó wà labẹ ipọnju. Awa lonii, ti a ń gbé la “ikẹhin ọjọ” eto-igbekalẹ ti Satani, “ìgbà ewu” wọnyi já, dojukọ awọn adanwo kan-naa. (2 Timoteu 3:1; tun wo Matteu 24:9-13.) Bii tiwa, Dafidi niriiri awọn àníyàn ati ìkárísọ nitori awọn iṣoro ti ó ṣubú tẹ̀ ẹ́. Ṣugbọn oun kò yọnda ki awọn adanwo naa mú igbẹkẹle oniduuroṣinṣin rẹ̀ ninu Ẹlẹdaa rẹ̀ di alailagbara. Ó kigbe jade pe: “Dẹtí rẹ silẹ, Óò Jehofa. Dá mi lóhùn, nitori ti mo jẹ́ ẹni ti a pọ́nlójú ati òtòṣì. Óò daabobo ọkàn mi, nitori ti mo jẹ́ aduroṣinṣin. Gba iranṣẹ rẹ—ti ń ní igbẹkẹle ninu rẹ là—ìwọ ni Ọlọrun mi.”—Orin Dafidi 86:1, 2, NW.
4. Bawo ni a ṣe nilati fi igbọkanle wa hàn?
4 A lè ni igbọkanle, gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe, pe “Ọlọrun itunu gbogbo,” Jehofa, yoo yí etí rẹ̀ si ilẹ̀-ayé yii yoo sì fetisilẹ si awọn adura onirẹlẹ wa. (2 Korinti 1:3, 4) Nipa níní igbẹkẹle lọna kíkún ninu Ọlọrun wa, awa lè tẹle amọran Dafidi pe: “Kó ẹrù rẹ lọ si ara Oluwa, oun ni yoo sì mú ọ duro: oun kì yoo jẹ́ kí ẹsẹ̀ olododo ki ó yẹ̀ lae.”—Orin Dafidi 55:22.
Ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ Pẹlu Jehofa
5. (a) Bawo ni awọn itumọ kan ti a fiṣọraṣe ṣe yí aṣiṣe awọn akọwe Ju padà? (b) Ni ọ̀nà wo ni orin Dafidi ìkarùndínláàádọ́rùn-ún ati ìkẹrìndínláàádọ́rùn-ún gbà gbé Jehofa ga? (Wo akiyesi ẹsẹ-iwe.)
5 Ninu Orin ìkẹrìndínláàádọ́rùn-ún, Dafidi lo ọ̀rọ̀ naa “Óò Jehofa” ní ìgbà 11. Adura Dafidi ti gbóná janjan tó, ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ rẹ̀ pẹlu Jehofa sì ti ṣe pẹkipẹki tó! Nigba ti ó yá, iru ìlò orukọ Ọlọrun lọna ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ bẹẹ wá di ohun ti kò dùn-úngbọ́ létí awọn akọwe Ju, ni pataki julọ awọn Soferimu. Wọn mú ibẹru igbagbọ nipa ohun-asán kan ti ṣíṣi orukọ naa pè dagba. Ní pípa otitọ naa tì pe eniyan ni a ti dá ni aworan Ọlọrun, wọn kọ̀ lati fihàn pe animọ tí awọn eniyan pẹlu ń fihàn jẹ́ ti Ọlọrun. Nitori naa nibi 7 ninu awọn ifarahan orukọ atọrunwa 11 ninu ẹsẹ iwe mimọ Heberu ti orin Dafidi kan yii, wọn fi orúkọ-oyè naa ʼAdho-naiʹ (Oluwa) rọ́pò orukọ naa YHWH (Jehofa). A lè kún fun imoore pe New World Translation of the Holy Scriptures, ati ọpọ awọn itumọ ti a fiṣọra ṣe miiran bakan naa, ti dá orukọ atọrunwa naa pada si ibi titọna rẹ̀ ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Gẹgẹ bi iyọrisi, ipo-ibatan wa pẹlu Jehofa ni a tẹnumọ gẹgẹ bi ó ti yẹ ki o jẹ́.a
6. Ni awọn ọ̀nà wo ni a lè gbà fihàn pe orukọ Jehofa ṣeyebiye fun wa?
6 Adura Dafidi ń baa lọ pe: “Fi ojurere hàn sí mi, óò Jehofa, nitori iwọ ni mo ń képè sibẹ ni gbogbo ọjọ. Mú ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀ nitori si ọ, Óò Jehofa ni mo gbé ọkàn mi gan-an soke.” (Orin Dafidi 86:3, 4, NW) Ṣakiyesi pe Dafidi ń baa lọ lati képe Jehofa “ni gbogbo ọjọ.” Nitootọ, oun sábà maa ń gbadura la gbogbo òru já, gẹgẹ bi ìgbà ti ó jẹ́ ìsáǹsá ninu aginju. (Orin Dafidi 63:6, 7) Bakan naa lonii, awọn Ẹlẹ́rìí kan nigba ti a bá fi ìfipábánilòpọ̀ tabi ìfipákọluni oniwa ọdaran miiran halẹ̀ mọ́ wọn ti kigbe soke pe Jehofa. Nigba miiran iyọrisi alayọ ti o mú wá ti yà wọn lẹnu.b Orukọ Jehofa ṣeyebiye fun wa, àní gẹgẹ bi ó ti ṣe fun “Jesu Kristi, ọmọ Dafidi,” nigba ti ó wà lori ilẹ̀-ayé. Jesu kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati gbadura fun isọdimimọ orukọ Jehofa ó sì sọ ohun ti orukọ naa duro fun di mímọ̀ fun wọn.—Matteu 1:1; 6:9; Johannu 17:6, 25, 26.
7. Awọn apẹẹrẹ wo ni a ní nipa gbígbé ti Jehofa ń gbé ọkàn awọn iranṣẹ rẹ̀ soke, bawo sì ni a ṣe nilati dahunpada?
7 Dafidi gbé ọkàn rẹ̀, gbogbo araarẹ̀, soke si Jehofa. Ó fun wa niṣiiri lati ṣe bakan naa, ni sisọ ni Orin Dafidi 37:5 pe: “Fi ọ̀nà rẹ lé Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; oun ó sì mú un ṣẹ.” Nipa bayii ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ wa si Jehofa fún un lati mú ọkàn wa yọ̀ ni a kò ni ṣalaidahun. Ọpọ awọn olupawatitọmọ iranṣẹ Jehofa ń baa lọ lati rí ayọ ńlá ninu iṣẹ-isin rẹ̀—laika inira, inunibini, ati ailera si. Awọn ará wa ti wọn wà ni agbegbe ti ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ni Africa, iru bii Angola, Liberia, Mozambique, ati Zaire, ti ń baa lọ lati fi iṣẹ-isin Jehofa si ipo akọkọ ninu igbesi-aye wọn.c Ó ti jẹ́ ki wọn yọ̀ ninu ikore tẹmi yanturu nitootọ. Gẹgẹ bi wọn ti farada a, bẹẹ gan-an ni awa gbọdọ ṣe. (Romu 5:3-5) Bi a sì ti ń farada, a fi dá wa lójú pe: “Ìran naa jẹ́ ti ìgbà kan ti a yàn, yoo maa yára si igbẹhin, . . . kì yoo pẹ́.” (Habakkuku 2:3) Pẹlu igbọkanle ati igbẹkẹle patapata ninu Jehofa, ǹjẹ́ ki awa pẹlu maa “yára si igbẹhin.”
Iwarere-iṣeun Jehofa
8. Ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ wo ni a lè ní pẹlu Jehofa, bawo sì ni o ṣe fi iwarere-iṣeun rẹ̀ hàn?
8 Dafidi ṣe ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ onimọlara jijinlẹ siwaju sii pe: “Nitori iwọ, Óò Jehofa, dára o sì ṣetan lati dariji; ati iṣeun-ifẹ naa si gbogbo awọn wọnni ti ń kè pè ọ́ pọ̀ yanturu. Tẹ́tísílẹ̀, Óò Jehofa, si adura mi; ki o sì fiyesilẹ si ohùn awọn ìpàrọwà mi. Ni ọjọ idaamu mi emi yoo képè ọ́ nitori ti iwọ yoo dá mi lóhùn.” (Orin Dafidi 86:5-7, NW) “Óò Jehofa”—leralera ni ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ ọ̀rọ̀ yii mú wa layọ! Ó jẹ́ ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ kan ti a lè mú dàgbà lemọlemọ nipasẹ adura. Dafidi gbadura ni akoko miiran pe: “Awọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà-èwe mi ati awọn iṣọtẹ mi ni ki iwọ jọwọ maṣe ranti. Gẹgẹ bi inurere rẹ ni ki iwọ funraarẹ ranti mi, nititori iwarere iṣeun rẹ, Óò Jehofa.” (Orin Dafidi 25:7, NW) Jehofa ni ẹ̀dàyà-àpẹẹrẹ iwarere-iṣeun gan-an—ninu pipese irapada Jesu, ninu fifi aanu hàn fun awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ronupiwada, ati ninu rírọ̀jò iṣeun-ifẹ sori awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ aduroṣinṣin ati onimọriri.—Orin Dafidi 100:3-5; Malaki 3:10.
9. Imudaniloju wo ni awọn ẹlẹṣẹ oluronupiwada nilati fi sọ́kàn?
9 Ó ha yẹ ki a bọkànjẹ́ lori awọn asiṣe ìgbà ti o ti kọja bi? Bi a bá ti ń rìn ni ọ̀nà títọ́ nisinsinyi, a o mú ara wa yá gágá nigba ti a bá ranti imudaniloju aposteli Peteru fun awọn onironupiwada pe “akoko itura” yoo wá lati ọdọ Jehofa. (Iṣe 3:19) Ẹ jẹ ki a sunmọ Jehofa pẹkipẹki ninu adura nipasẹ Olurapada wa, Jesu, ẹni ti ó fi tifẹtifẹ sọ pe: “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹyin ti ń ṣíṣẹ̀ẹ́, ti a sì di ẹrù wúwo lé lori, emi ó sì fi isinmi fun yin. Ẹ gba ajaga mi si ọrùn yin, ki ẹ sì maa kọ́ ẹkọ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkàn ni emi; ẹyin ó sì rí isinmi fun ọkàn yin.” Bi awọn Ẹlẹ́rìí aduroṣinṣin ti ń gbadura si Jehofa lonii ni orukọ ṣiṣeyebiye ti Jesu, wọ́n ń rí itura nitootọ.—Matteu 11:28, 29; Johannu 15:16.
10. Iyọri-ọla wo ni iwe Orin Dafidi fifun iṣeun-ifẹ Jehofa?
10 Iwe Orin Dafidi tọka si “iṣeun-ifẹ” Jehofa ni iye ti ó ju ọgọrun-un ìgbà lọ. Iru iṣeun-ifẹ bẹẹ pọ̀ yanturu dajudaju! Ninu ẹsẹ mẹrin rẹ̀ akọkọ, Orin ìkejìdínlọ́gọ́fà rọ awọn iranṣẹ Ọlọrun lati dupẹ lọwọ Jehofa, ni títún un sọ nigba mẹrin pe “nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ̀ wà titi akoko titilọ gbére.” Orin Dafidi ìkẹrìndínlógóje tẹnumọ animọ asọnidọ̀wọ́n ti “iṣeun-ifẹ rẹ̀” ni ìgbà 26. Ni ọ̀nà yoowu ki a ti gbà ṣàṣìṣe—ati gẹgẹ bi Jakọbu 3:2 (NW) ṣe sọ, “gbogbo wa ni a ń kọsẹ̀ nigba pupọ”—ǹjẹ́ ki a muratan lati wá idariji Jehofa, ki a ni igbọkanle nipa aanu ati iṣeun-ifẹ rẹ̀. Iṣeun-ifẹ rẹ̀ jẹ́ ìfihànsóde iduroṣinṣin rẹ̀ siha ọdọ wa. Bi a bá ń fi iduroṣinṣin baa lọ lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun, oun yoo fi ifẹ oniduuroṣinṣin rẹ̀ hàn ninu fifun wa lokun lati koju gbogbo adanwo.—1 Korinti 10:13.
11. Bawo ni igbesẹ lati ọ̀dọ̀ awọn alagba ṣe lè mú awọn imọlara ẹ̀bi kuro?
11 Awọn akoko lè wà nigba ti awọn ẹlomiran lè mú wa kọsẹ̀. Ìlòkulò ti ero-imọlara tabi ti ara nigba ọmọde ti fi imọlara ẹ̀bi tabi àìjámọ́-nǹkan patapata sára awọn kan. Iru ojiya ipalara bẹẹ lè képe Jehofa, pẹlu igbọkanle pe oun yoo dahun. (Orin Dafidi 55:16, 17) Alagba oninuure kan lè ní ọkàn-ìfẹ́ ninu ríran iru ẹni bẹẹ lọwọ lati gba otitọ naa pe kìí ṣe ẹjọ ojiya ipalara naa. Nigba ti ó bá yá lẹhin naa, ikesini bi ọ̀rẹ́ lati ìgbà-dé-ìgbà lori tẹlifoonu lati ọdọ alagba naa lè ran ẹni yẹn lọwọ titi di ìgbà ti oun lọkunrin (tabi lobinrin) bá tó lè ‘gbé ẹrù-ìnira naa’ nigbẹhin-gbẹhin.—Galatia 6:2, 5.
12. Bawo ni awọn hílàhílo ti ṣe di pupọ, ṣugbọn bawo ni a ṣe lè koju wọn lọna aṣeyọrisirere?
12 Ọpọlọpọ ipo oníhílàhílo miiran wà ti awọn eniyan Jehofa nilati bá jà lonii. Bẹrẹ pẹlu Ogun Agbaye I ni 1914, awọn àjábá kàǹkà-kàǹkà bẹrẹ sii pọ́n ilẹ̀-ayé yii lójú. Gẹgẹ bi Jesu ṣe sọtẹlẹ, wọn jẹ́ “ibẹrẹ awọn ìrora hílàhílo.” Hílàhílo ti di pupọ bi a ti tubọ ń tẹsiwaju sii wọnu “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” (Matteu 24:3, 8, NW) “Ìgbà kukuru” Eṣu ń lọ ni kẹrẹkẹrẹ si ògógóró opin. (Ìfihàn 12:12) “Bii kinniun kan ti ń ké ramuramu” ti ń wá ẹran-ọdẹ kiri, Elénìní ńlá yẹn ń lo gbogbo ẹ̀tàn-ìkọ̀kọ̀ ti ó wà larọọwọto lati yà wá kuro lara agbo Ọlọrun ki ó sì pa wá run. (1 Peteru 5:8) Ṣugbọn oun kì yoo kẹ́sẹjárí! Nitori pe, bii Dafidi, awa fidii igbẹkẹle wa mulẹ ṣinṣin patapata sọdọ Ọlọrun wa kanṣoṣo, Jehofa.
13. Bawo ni awọn òbí ati awọn ọmọ wọn ṣe lè janfaani lati inu iwarere-iṣeun Jehofa?
13 Laiṣiyemeji, Dafidi tẹ aini naa lati gbarale iwarere-iṣeun Jehofa mọ́ ọmọkunrin rẹ̀ Solomoni lọ́kàn. Nipa bayii, Solomoni lè fun ọmọkunrin tirẹ̀ fúnraarẹ̀ nitọọni pe: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹkẹle Oluwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ. Mọ̀ ọ́n ni gbogbo ọ̀nà rẹ: oun ó sì maa tọ́ ipa-ọna rẹ. Maṣe ọlọgbọn ni ojú ara rẹ; bẹru Oluwa, ki o sì kuro ninu ibi.” (Owe 3:5-7) Awọn òbí lonii nilati kọ́ awọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ wọn bakan naa ni bi wọn yoo ti figbẹkẹle gbadura si Jehofa ati ọ̀nà ti wọn yoo gbà koju awọn ìfipákọluni ninu ayé ọlọ́kàn-àyà yíyigbì yii—iru bii ikimọlẹ ojúgbà ni ile-ẹkọ ati awọn ìdẹwò lati dẹ́ṣẹ̀ iwapalapala. Fifi awọn ilana Bibeli silo pẹlu awọn ọmọ rẹ lojoojumọ lè tẹ ifẹ gidi fun Jehofa ati igbarale e taduratadura mọ́ awọn ọmọ rẹ lọ́kàn.—Deuteronomi 6:4-9; 11:18, 19.
Awọn Iṣẹ́ Alailafiwe ti Jehofa
14, 15. Ki ni diẹ lara awọn iṣẹ́ aláìláfiwé ti Jehofa?
14 Pẹlu idaniloju ti ó jinlẹ Dafidi sọ pe: “Kò si ọ̀kankan ti ó dàbí rẹ laaarin awọn ọlọrun, Óò Jehofa, bẹẹ ni kò sí awọn iṣẹ eyikeyii ti ó dàbí tìrẹ.” (Orin Dafidi 86:8, NW) Awọn iṣẹ Jehofa tobi ju, wọn tobilọla ju, wọn lọ́láńlá ju bi eniyan eyikeyii ti lè ronuwoye lọ. Gẹgẹ bi imọ-ijinlẹ ode-oni ti wò ó fírí, àgbáńlá-ayé ti a dá—ìgbòòrò-yéye rẹ̀, iṣọkan rẹ̀, ìgbórínlọ́lá rẹ̀—ti jẹ́ eyi ti ó tubọ tóbi lọna ti ó yanilẹnu ju ohunkohun ti Dafidi lè fòyemọ̀ lọ. Sibẹ, oun ni a sún lati sọ pe: “Awọn ọrun ń sọrọ ògo Ọlọrun; ati ofuurufu ń fi iṣẹ ọwọ rẹ̀ hàn.—Orin Dafidi 19:1.
15 Awọn iṣẹ Jehofa ni a ṣapejuwe kedere lọna agbayanu, pẹlu, ninu ọ̀nà ti ó gbà sọ ilẹ̀-ayé lọ́jọ̀ ti ó sì mura rẹ̀ silẹ, ní mímú ki ọ̀sán ati òru, awọn ìgbà, akoko ifunrugbin ati ikore, ati ọpọ jaburata awọn ohun ti ń mú idunnu wa fun igbadun ọjọ-ọla eniyan ṣeeṣe. Ẹ sì wo bi a ti dá awa funraawa lọna agbayanu tó ti a sì mura wa silẹ, ki a baa lè gbadun awọn iṣẹ Jehofa ti wọn yí wa ká!—Genesisi 2:7-9; 8:22; Orin Dafidi 139:14.
16. Ki ni ìfihànsóde titobi julọ nipa iwarere-iṣeun Jehofa, ti ń ṣamọna si awọn iṣẹ́ aláìláfiwe siwaju sii wo?
16 Lẹhin ti awọn òbí wa akọkọ ti ṣaigbọran si Ọlọrun, ní dídá awọn idaamu ti ń yọ ilẹ̀-ayé lẹnu titi di òní olónìí yii silẹ, Jehofa nitori ifẹ rẹ̀ ṣe iṣẹ àgbàyanu-ńlá ninu rírán Ọmọkunrin rẹ̀ wá sori ilẹ̀-ayé lati polongo Ijọba Ọlọrun ati lati kú gẹgẹ bi irapada fun araye. Eyi ti o tún pabambari! Jehofa wá jí Kristi dìde lẹhin naa lati jẹ́ Ọba alabaakẹgbẹ rẹ̀ ti a yàn. (Matteu 20:28; Iṣe 2:32, 34) Lati inu awọn eniyan aduroṣinṣin Ọlọrun tilẹ ti yan “ẹ̀dá titun” ẹlẹ́mìí-ìṣoore lori ẹgbẹ́ awujọ “ayé titun” ti yoo ṣakoso pẹlu Kristi gẹgẹ bi “ọrun titun” ti yoo ni araadọta-ọkẹ lọna araadọta-ọkẹ awọn eniyan ti a jí dide ninu. (2 Korinti 5:17; Ìfihàn 21:1, 5-7; 1 Korinti 15:22-26) Awọn iṣẹ Jehofa yoo tipa bayii lọ siwaju si òtéńté ológo kan! Niti tootọ, a lè fi iyanu ké jade pe: “Óò Jehofa, . . . iwarere-iṣeun rẹ ti pọ̀ yanturu tó, eyi ti o ti fi pamọ fun awọn wọnni ti ń bẹru rẹ!—Orin Dafidi 31:17-19, NW.
17. Niti awọn iṣẹ́ Jehofa, bawo ni a ṣe ń mú Orin Dafidi 86:9 ṣẹ nisinsinyi?
17 Awọn iṣẹ Jehofa ti ode-iwoyi ní ohun ti Dafidi ṣapejuwe rẹ̀ ni Orin Dafidi 86:9 (NW) ninu pe: “Gbogbo awọn orilẹ-ede ti iwọ ti ṣe yoo funraawọn wá, wọn yoo sì tẹriba mọ́lẹ̀ niwaju rẹ, Óò Jehofa, wọn yoo sì fi ògo fun orukọ rẹ.” Lẹhin pípe awọn aṣẹku ninu ẹ̀dá titun rẹ̀, “agbo kekere” ti awọn ajogun Ijọba jade kuro lati inu araye tán, Jehofa ti ń baa lọ lati kó “gbogbo orilẹ-ede” “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” jọ, araadọta-ọkẹ eniyan ti awọn pẹlu lo igbagbọ ninu ẹ̀jẹ̀ Jesu ti a ta silẹ. Awọn wọnyi ni oun ti gbéró di eto-ajọ alagbara kan, ẹgbẹ́ awujọ yika-aye kanṣoṣo ti awọn olùfẹ́ alaafia lori ilẹ̀-ayé lonii. Ni ṣiṣakiyesi eyi, awọn ogun ọrun tẹ ori araawọn ba niwaju Jehofa, ni pipolongo pe: “Ibukun, ati ògo, ati ọgbọ́n, ati idupẹ, ati ọlá ati agbara, ati okun jẹ́ ti Ọlọrun wa lae ati laelae.” Ogunlọgọ nla naa tun fògo fun orukọ Jehofa, ni ṣiṣiṣẹsin in “ní ọ̀sán ati ní òru,” pẹlu ireti líla opin ayé yii já ati wíwà láàyè titilae lori paradise ilẹ̀-ayé kan.—Luku 12:32; Ìfihàn 7:9-17, NW; Johannu 10:16.
Ìtóbilọ́lá Jehofa
18. Bawo ni Jehofa ti ṣe fihàn pe oun jẹ́ ‘Ọlọrun kanṣoṣo’?
18 Dafidi pe afiyesi si ipò jíjẹ́ Ọlọrun ti Jehofa tẹle e ni wiwi pe: “Iwọ tobi o sì ń ṣe awọn ohun àgbàyanu-ńlá; iwọ ni Ọlọrun, iwọ nikan.” (Orin Dafidi 86:10, NW) Lati ìgbà laelae, ni Jehofa ti ń fihàn pe oun, nitootọ, ni ‘Ọlọrun kanṣoṣo.’ Farao oníwà òṣìkà-agbonimọ́lẹ̀ ti Egipti ni ó ṣàyàgbàǹgbà pe Mose nija pe: “Ta ni Jehofa, ti emi fi nilati ṣegbọran si ohùn rẹ̀ lati rán Israeli lọ? Emi kò mọ Jehofa rárá.” Ṣugbọn oun mọ bi Jehofa ti tobilọla tó laipẹ! Ọlọrun Olodumare tẹ́ awọn ọlọrun Egipti ati awọn alufaa pidánpidán lógo nipa rírán awọn ìyọnu alájàálù, ní pípa awọn ọmọkunrin àkọ́bí Egipti, ti ó sì pa Farao ati ọ̀tọ̀kùlú ẹgbẹ́-ọmọ-ogun rẹ̀ ninu Òkun Pupa. Niti tootọ, kò sí ẹni ti ó dabii Jehofa laaarin awọn ọlọrun!—Eksodu 5:2; 15:11, 12.
19, 20. (a) Nigba wo ni orin Ìfihàn 15:3, 4 yoo ní ìkọjáde gígadabú julọ rẹ̀? (b) Bawo ni a ṣe lè ṣajọpin ninu iṣẹ́ Jehofa nisinsinyi paapaa?
19 Gẹgẹ bi Ọlọrun kanṣoṣo, Jehofa ti bẹrẹ sii ṣe awọn ohun àgbàyanu-ńlá ni imurasilẹ fun dídá awọn olujọsin rẹ̀ onigbọran nídè kuro ni Egipti ode-oni—aye Satani. Ó ti jẹ́ ki a kede awọn idajọ atọrunwa rẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀-ayé gẹgẹ bi ẹ̀rí kan nipasẹ igbetaasi iwaasu ti ó gbòòrò julọ ninu gbogbo ìtàn, ní titipa bayii mú asọtẹlẹ Jesu ni Matteu 24:14 ṣẹ. Laipẹ, “opin” gbọdọ dé, nigba ti Jehofa yoo fi ìtóbilọ́lá rẹ̀ hàn ní ìwọ̀n ti kò gbà ṣẹlẹ rí nipa pípa gbogbo iwa-buburu rẹ́ lori ilẹ̀-ayé. (Orin Dafidi 145:20) Nigba naa ni orin Mose ati orin Ọdọ-agutan naa yoo dé ògógóró kan pe: “Titobi ati ìyanu ni awọn iṣẹ rẹ, Oluwa Ọlọrun Olodumare; ododo ati otitọ ni ọ̀nà rẹ, iwọ Ọba awọn orilẹ-ede. Ta ni kì yoo bẹru, Oluwa, ti kì yoo sì fi ògo fun orukọ rẹ? nitori iwọ nikanṣoṣo ni mímọ́.”—Ìfihàn 15:3, 4.
20 Ǹjẹ́ ki awa ni ipa tiwa jẹ́ onitara ninu bíbá awọn ẹlomiran sọrọ nipa awọn ète gbígbórínlọ́lá ti Ọlọrun wọnyi. (Fiwe Iṣe 2:11, NW) Jehofa yoo maa baa lọ lati ṣe awọn ohun titobi ati àgbàyanu-ńlá ni ọjọ wa ati titi ọjọ-ọla, gẹgẹ bi ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa ti ó kàn yoo ti ṣapejuwe.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Alaye Bibeli kan ti a tẹ̀ ni 1874 fa ọ̀rọ̀ Andrew A. Bonar yọ ni wiwi pe: “Pupọ julọ, àní pupọ pupọ julọ, nipa ìwà ti a mọ̀ mọ Ọlọrun ni ó wà, orukọ ológo rẹ̀, ti a fihàn ni opin Orin Dafidi [ìkárùndínláàádọ́rùn-ún]. Eyi lè ṣalaye idi ti omiran fi tẹle, ‘Adura Dafidi Kan,’ ti o fẹrẹẹ kún fun ìwà Jehofa ní ibaradọgba. Kókó pataki Orin Dafidi [ìkẹrìndínláàádọ́rùn-ún] yii ni orukọ Jehofa.”
b Wo oju-iwe 28 itẹjade Ji! ti June 22, 1984, (Gẹẹsi) ti a tẹjade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
c Fun kulẹkulẹ, wo aworan isọfunni naa “Irohin Ọdun Iṣẹ-isin 1992 ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Kari-aye,” ti yoo farahan ninu itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà January 1, 1993.
Iwọ Ha Níran Bi
◻ Eeṣe ti a fi nilati sọ adura Orin Dafidi 86 di tiwa?
◻ Bawo ni a ṣe lè rí ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ pẹlu Jehofa?
◻ Bawo ni Jehofa ṣe fi iwarere-iṣeun rẹ̀ hàn si wa?
◻ Ki ni diẹ lara awọn iṣẹ́ aláìláfiwé ti Jehofa?
◻ Bawo ni Jehofa ṣe jẹ́ ‘Ọlọrun kanṣoṣo’ niti ìtóbilọ́lá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ninu “ayé titun” ti ń bọ̀, awọn iṣẹ́ àgbàyanu-ńlá Jehofa yoo maa baa lọ lati jẹrii si ògo ati iwarere-iṣeun rẹ̀