“Èmi Yóò Máa Rìn Nínú Òtítọ́ Rẹ”
“Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.”—SM. 86:11.
1-3. (a) Báwo ló ṣe yẹ kí òtítọ́ Bíbélì rí lára wa? Ṣàpèjúwe. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
NÍ Ọ̀PỌ̀ orílẹ̀-èdè, kì í ṣe ohun tuntun pé káwọn èèyàn máa dá ohun tí wọ́n rà pa dà. Kódà, táwọn èèyàn bá ra ọjà lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, ó máa ń ju mẹ́ta nínú ọjà mẹ́wàá tí wọ́n máa ń dá pa dà. Ìdí sì ni pé ọjà náà lè má dáa tó bí wọ́n ṣe pọ́n ọn tàbí kó lábùkù. Ó sì lè jẹ́ pé kò wù wọ́n mọ́. Torí náà, wọ́n lè fi pààrọ̀ nǹkan míì tàbí kí wọ́n gba owó wọn pa dà.
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè dá ọjà tá ò fẹ́ mọ́ pa dà tàbí ká fi pààrọ̀ nǹkan míì, àmọ́ a ò jẹ́ fi òtítọ́ Bíbélì tá a ti kọ́ pààrọ̀ nǹkan míì, bẹ́ẹ̀ la ò sì ní “tà á.” (Ka Òwe 23:23; 1 Tím. 2:4) Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ nǹkan la yááfì ká lè sọ òtítọ́ di tiwa. Lára ẹ̀ ni pé, a lo àkókò wa láti kẹ́kọ̀ọ́ tàbí pé a fi iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé sílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àjọṣe àwa àtàwọn míì lè ti yí pa dà, kódà a ti yí ìwà àti ọ̀nà tá à ń gbà ronú pa dà, a sì ti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Síbẹ̀, àwọn ohun tá a yááfì ò tó nǹkan kan tá a bá fi wé àwọn ìbùkún tá a ti rí gbà.
3 Ká lè mọ bí òtítọ́ Bíbélì ti ṣeyebíye tó, Jésù ṣe àpèjúwe nípa ọkùnrin arìnrìn-àjò kan tó rí péálì àtàtà. Nígbà tí ọkùnrin náà rí péálì iyebíye kan, péálì yẹn jọ ọ́ lójú débi pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló “ta gbogbo ohun tí ó ní,” ó sì rà á. (Mát. 13:45, 46) Òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló dà bíi péálì yẹn. Nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn nǹkan míì látinú Bíbélì, a mọyì rẹ̀ débi pé tinútinú la fi yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó má bàa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Tá a bá mọyì òtítọ́ yìí, a ò ní “tà á,” ìyẹn ni pé a ò ní fi tàfàlà láé. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn èèyàn Jèhófà ti jẹ́ kí òtítọ́ iyebíye yìí bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ó dájú pé a ò ní jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa láé! Tá ò bá fẹ́ kí òtítọ́ yìí bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, pé ká máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (Ka 3 Jòhánù 2-4.) Tá a bá fẹ́ máa rìn nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ máa darí ìgbésí ayé wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Báwo làwọn kan ṣe ta òtítọ́, kí sì nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló yẹ ká ṣe tá ò fi ní ṣe irú àṣìṣe ńlá yìí? Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́?”
KÍ NÌDÍ TÁWỌN KAN FI ‘TA’ ÒTÍTỌ́?
4. Kí nìdí táwọn kan fi ‘ta’ òtítọ́ nígbà ayé Jésù?
4 Nígbà ayé Jésù, àwọn kan wà tó kọ́kọ́ gba ẹ̀kọ́ Jésù, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n pa ẹ̀kọ́ náà tì. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jésù bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu, àwọn èèyàn náà tẹ̀ lé e lọ sí òdìkejì Òkun Gálílì. Jésù wá sọ ohun kan tó yà wọ́n lẹ́nu, ó sọ pé: “Láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò ní ìyè kankan nínú ara yín.” Dípò kí wọ́n sọ pé kí Jésù ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn, ṣe ni ọ̀rọ̀ yẹn bí wọn nínú, wọ́n wá sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?” Torí náà, “ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.”—Jòh. 6:53-66.
5, 6. (a) Kí ló ti mú káwọn kan fi òtítọ́ sílẹ̀ lónìí? (b) Báwo lẹnì kan ṣe lè fi òtítọ́ sílẹ̀ láìfura?
5 Lónìí, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan ti jẹ́ kí òtítọ́ bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Àwọn kan ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ torí wọn ò fara mọ́ àwọn òye tuntun tó ń dé, àwọn míì sì ti jẹ́ kí ohun tí arákùnrin kan ṣe tàbí tó sọ mú wọn kọsẹ̀. Ìbáwí táwọn kan gbà ló jẹ́ kí wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, èdèkòyédè táwọn kan sì ní pẹ̀lú Kristẹni míì ló jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì ti jẹ́ kí èrò àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn alátakò kó sí wọn lórí. Èyí ti mú kí àwọn kan dìídì fi Jèhófà àti ètò rẹ̀ sílẹ̀. (Héb. 3:12-14) Báwo ni ò bá ṣe dùn tó ká ní wọ́n jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jésù bí àpọ́sítélì Pétérù ti ṣe! Nígbà tí Jésù bi àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé ṣé àwọn náà máa fi òun sílẹ̀ lọ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Pétérù dá a lóhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 6:67-69.
6 Díẹ̀díẹ̀ làwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi òtítọ́ sílẹ̀ láìfura. Ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bí ọkọ̀ ojú omi kan tí omi rọra ń gbé lọ díẹ̀díẹ̀ kúrò ní etíkun. Bíbélì sọ pé ṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń “sú lọ” kúrò nínú òtítọ́. (Héb. 2:1) Àwọn tó sú lọ yàtọ̀ sáwọn tó dìídì fi òtítọ́ sílẹ̀ torí pé wọn ò mọ̀ọ́mọ̀ fi òtítọ́ sílẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń ṣe ohun táá mú kí wọ́n jìnnà sí Jèhófà. Tí wọn ò bá sì ṣọ́ra, wọ́n á pàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà. Kí ló yẹ ká ṣe kírú àjálù bẹ́ẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa?
KÍ LÓ YẸ KÁ ṢE KÁ MÁ BÀA FI ÒTÍTỌ́ SÍLẸ̀?
7. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ fi òtítọ́ sílẹ̀?
7 Ká má bàa fi òtítọ́ sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ gba gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà gbọ́, ká sì máa pa wọ́n mọ́. Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbà pé òtítọ́ Bíbélì ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa, ká sì máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Ọba Dáfídì gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.” (Sm. 86:11) Bíi ti Dáfídì, àwa náà gbọ́dọ̀ pinnu pé bíná ń jó, bíjì ń jà, àá máa rìn nínú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn nǹkan tá a ti yááfì, kó sì máa ṣe wá bíi pé ká pa dà sídìí wọn. Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀, a gbọ́dọ̀ di òtítọ́ mú ṣinṣin. A ò lè gba àwọn kan gbọ́, ká sì pa àwọn tó kù tì. Ó ṣe tán, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa rìn nínú “òtítọ́ gbogbo.” (Jòh. 16:13) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan márùn-ún tó ṣeé ṣe ká ti yááfì ká lè ra òtítọ́. Ìyẹn á mú ká túbọ̀ dúró lórí ìpinnu wa pé a ò ní pa dà sídìí àwọn nǹkan tá a ti yááfì.—Mát. 6:19.
8. Tí Kristẹni kan bá ń fàkókò rẹ̀ ṣòfò, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó sú lọ kúrò nínú òtítọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.
8 Àkókò wa. Ká má bàa sú lọ kúrò nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé à ń fọgbọ́n lo àkókò wa. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè máa fàkókò ṣòfò nídìí íńtánẹ́ẹ̀tì, ìgbafẹ́, tẹlifíṣọ̀n tàbí àwọn nǹkan míì tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí, wọ́n lè gba àkókò tá a fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí àkókò tá à ń lò fún àwọn nǹkan míì nínú ìjọsìn wa. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Emma.a Àtikékeré ni Emma ti fẹ́ràn kó máa gẹṣin. Gbogbo àkókò tí ọwọ́ rẹ̀ bá dilẹ̀ ló máa ń gun ẹṣin. Nígbà tó yá, ó rí i pé òun ti ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí eré náà, èyí sì mú kó ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí arábìnrin Cory Wells tó máa ń gun ẹṣin dárà nígbà kan.b Ní báyìí, Emma ń gbádùn bó ṣe ń lo àkókò rẹ̀ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, tó sì tún ń lo àkókò pẹ̀lú tẹbí tọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. Èyí ti mú kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kọ́kàn rẹ̀ sì balẹ̀ torí ó mọ̀ pé nǹkan gidi lòun ń fi àkókò òun ṣe.
9. Tá a bá ń lé àwọn nǹkan tara, báwo nìyẹn ṣe lè mú ká pa òtítọ́ tì?
9 Àwọn nǹkan tara. Tá a bá fẹ́ máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn ju bó ti yẹ lọ. Nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn nǹkan tẹ̀mí ló jẹ wá lógún jù, kì í ṣe nǹkan tara. Inú wa dùn gan-an láti yááfì àwọn nǹkan tara ká lè ra òtítọ́. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a lè máa rí i pé àwọn míì ń ra àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tàbí kí wọ́n máa gbádùn àwọn nǹkan tuntun tó lòde. Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe wá bíi pé a fi nǹkan du ara wa bá a ṣe yááfì àwọn nǹkan tara. Ìyẹn lè mú kí àwọn ohun kòṣeémáàní tá a ní má tẹ́ wa lọ́rùn mọ́, ká wá bẹ̀rẹ̀ sí í lé nǹkan tara. Èyí jẹ́ ká rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Démà. Ìfẹ́ tó ní fún “ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí” mú kó pa iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tì. (2 Tím. 4:10) Kí nìdí tí Démà fi pa Pọ́ọ̀lù tì? Ó lè jẹ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tara ju iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe fún Jèhófà tàbí kó jẹ́ pé ó ti sú u láti máa yááfì àwọn nǹkan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, Bíbélì ò sọ. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ káwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn débi tá a fi máa gbé òtítọ́ iyebíye sọ nù.
10. Kí la ò gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ máa rìn nínú òtítọ́?
10 Àjọṣe àwa àtàwọn míì. Tá a bá fẹ́ máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn tí kò sin Jèhófà kó èèràn ràn wá. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí pa dà. Àwọn kan fara mọ́ ohun tá a gbà gbọ́, àwọn míì sì di alátakò paraku. (1 Pét. 4:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń sapá gan-an kí àárín wa lè gún, tá a sì máa ń ṣenúure sí wọn, síbẹ̀ a ò ní pa òfin Jèhófà tì torí pé a fẹ́ tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìwé 1 Kọ́ríńtì 15:33 jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà nìkan ló yẹ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́.
11. Báwo la ṣe lè yẹra fún èròkerò àti ìwàkiwà?
11 Èròkerò àti ìwàkiwà. Gbogbo àwọn tó ń rìn nínú òtítọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. (Aísá. 35:8; ka 1 Pétérù 1:14-16.) Nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, gbogbo wa la ṣe àwọn àyípadà kan ká lè máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Kódà, àyípadà ńlá làwọn kan tiẹ̀ ṣe. Èyí ó wù kó jẹ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ìwà ìbàjẹ́ tó kúnnú ayé yìí má bàa sọ wá di aláìmọ́. Kí lá jẹ́ ká yẹra fún ìwà àìmọ́ àti ìṣekúṣe? Ó yẹ ká máa ronú nípa ohun tó ná Jèhófà kó lè sọ wá di mímọ́, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ iyebíye Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi. (1 Pét. 1:18, 19) Torí náà, tá a bá fẹ́ máa jẹ́ mímọ́ nìṣó lójú Jèhófà, àfi ká máa rántí nígbà gbogbo pé ohun iyebíye ni ìràpadà Jésù tí Jèhófà fi wẹ̀ wá mọ́.
12, 13. (a) Irú ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àwọn àjọ̀dún tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu? (b) Kí la máa jíròrò báyìí?
12 Àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn ọmọ iléèwé wa àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lè fẹ́ ká jọ máa ṣe àwọn ayẹyẹ kan. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ lọ́wọ́ sí àwọn àṣà àtàwọn àjọ̀dún tí inú Jèhófà ò dùn sí? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. A lè ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa nípa ibi tí irú àwọn àjọ̀dún bẹ́ẹ̀ ti ṣẹ̀ wá. Tá a bá ń rántí ìdí tí àwọn àjọ̀dún yẹn ò fi bá Ìwé Mímọ́ mu, á dá wa lójú pé a ṣì ń rìn lójú ọ̀nà “tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.” (Éfé. 5:10) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a sì gbà pé òótọ́ lohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a ò ní ‘wárìrì nítorí ènìyàn.’—Òwe 29:25.
13 Kì í ṣe ọjọ́ kan péré la fẹ́ fi rìn nínú òtítọ́, títí láé la ó máa rìn nínú rẹ̀. Àmọ́ kí lá jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́? Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́ta tá a lè ṣe.
TÚBỌ̀ PINNU PÉ WÀÁ MÁA RÌN NÍNÚ ÒTÍTỌ́
14. (a) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká pinnu pé a ò ní fi òtítọ́ sílẹ̀? (b) Kí nìdí tí ọgbọ́n, ìbáwí àti òye fi ṣe pàtàkì?
14 Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ kó o sì máa ronú lé ohun tó o kà. Bó o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ máa jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ. Ìyẹn á mú kó o túbọ̀ mọyì òtítọ́ kó o sì pinnu pé o ò ní fi í sílẹ̀ láé. Yàtọ̀ síyẹn, Òwe 23:23 tún gbà wá níyànjú pé ká ra “ọgbọ́n àti ìbáwí àti òye.” Ìmọ̀ Bíbélì tá a ní nìkan ò tó, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì tá a mọ̀ máa darí ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́. Òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá ní máa jẹ́ ká rí bí gbogbo Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe máa ṣe wá láǹfààní. Ọgbọ́n ló máa jẹ́ ká fi gbogbo ohun tá à ń kọ́ sílò. Nígbà míì sì rèé, òtítọ́ máa ń bá wa wí ní ti pé ó máa ń jẹ́ ká rí àwọn ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe. Á dáa ká tètè máa ṣe àwọn àtúnṣe yìí torí Bíbélì sọ pé ìbáwí ṣeyebíye ju fàdákà lọ.—Òwe 8:10.
15. Báwo ni òtítọ́ ṣe dà bíi bẹ́líìtì tó ń dáàbò bò wá?
15 Ìkejì, pinnu pé wàá jẹ́ kí òtítọ́ máa darí ìgbésí ayé rẹ lójoojúmọ́. Bíbélì fi òtítọ́ wé àmùrè tàbí bẹ́líìtì tí wọ́n máa ń dè mọ́ abẹ́nú. (Éfé. 6:14) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ọmọ ogun máa ń fi bẹ́líìtì de abẹ́nú wọn kó lè dáàbò bo ikùn wọn. Àmọ́ kí bẹ́líìtì náà tó lè dáàbò bo ọmọ ogun kan, ó gbọ́dọ̀ dè é pinpin torí tí bẹ́líìtì rẹ̀ bá ṣe dẹngbẹrẹ, kò ní ṣe é láǹfààní kankan. Báwo ni òtítọ́ tá a fi wé bẹ́líìtì ṣe ń dáàbò bò wá? Tá a bá ń jẹ́ kí òtítọ́ darí wa nígbà gbogbo, a ò ní máa ronú lọ́nà tí kò tọ́, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Tá a bá kojú àdánwò, òtítọ́ Bíbélì máa jẹ́ ká dúró lórí ìpinnu wa láti ṣe ohun tó tọ́. Ó dájú pé ọmọ ogun kan ò ní lọ sójú ogun láìde bẹ́líìtì rẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwa náà gbọ́dọ̀ pinnu pé a ò ní bọ́ bẹ́líìtì òtítọ́ láé tàbí ká jẹ́ kó ṣe dẹngbẹrẹ. Ó yẹ ká dè é mọ́ abẹ́nú wa pinpin, ìyẹn ni pé ká jẹ́ kí òtítọ́ máa darí wa lójoojúmọ́. Iṣẹ́ míì tí bẹ́líìtì àwọn ọmọ ogun máa ń ṣe ni pé ó ń jẹ́ kí wọ́n ríbi fi idà wọn sí. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.
16. Tá a bá ń fi òtítọ́ kọ́ àwọn míì, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká dúró nínú òtítọ́?
16 Ìkẹta, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa fi òtítọ́ kọ́ àwọn èèyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá di idà tẹ̀mí tí í ṣe “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” mú gírígírí. (Éfé. 6:17) Ó yẹ kí gbogbo wa sapá ká lè túbọ̀ jáfáfá nínú ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni, ká sì fi “ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tím. 2:15) Bá a ṣe ń fi Bíbélì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ra òtítọ́ kí wọ́n sì fi ẹ̀kọ́ èké sílẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á túbọ̀ máa jinlẹ̀ lọ́kàn tiwa náà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, títí láé la ó máa rìn nínú òtítọ́.
17. Kí ló mú kí òtítọ́ ṣeyebíye sí ẹ?
17 Ẹ̀bùn ńlá ni òtítọ́ tí Jèhófà fi jíǹkí wa. Ìdí ni pé ẹ̀bùn yìí ló jẹ́ ká ní ohun tó ṣeyebíye jù lọ láyé yìí, ìyẹn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba wa ọ̀run. Gbogbo ohun tá a mọ̀ báyìí ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tí Jèhófà ṣì máa kọ́ wa lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà ṣèlérí pé títí láé lòun á máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, mọyì òtítọ́ kó o sì jẹ́ kó ṣeyebíye sí ẹ bíi péálì àtàtà. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti “ra òtítọ́, má sì tà á” láé. Bíi ti Dáfídì, ìwọ náà á lè ṣèlérí fún Jèhófà pé: “Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.”—Sm. 86:11.
a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.
b Lórí Tẹlifíṣọ̀n JW, lọ sábẹ́ ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ ÀTI ÌRÍRÍ > ÒTÍTỌ́ Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ PA DÀ.