Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2022 Christian Congregation of Jehovah’s Witnesses
JANUARY 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KÍRÓNÍKÀ 1–3
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 911 ¶3-4
Àkọsílẹ̀ Ìlà Ìdílé
Orúkọ Àwọn Obìnrin. Nígbà míì, wọ́n máa ń kọ orúkọ àwọn obìnrin sínú àkọsílẹ̀ ìlà ìdílé tí ìdí bá wà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n dárúkọ Sáráì (Sérà) nínú Jẹ́nẹ́sísì 11:29, 30, torí ọ̀dọ̀ ẹ̀ ni ọmọ tá a ṣèlérí ti máa wá kìí ṣe nípasẹ̀ ìyàwó míì tí Ábúráhámù fẹ́. Àpẹẹrẹ obìnrin míì ni Mílíkà ìyá ìyá Rèbékà, tó jẹ́ ìyàwó Ísákì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n dárúkọ ẹ̀ kó lè hàn pé Rèbékà tan mọ́ Ábúráhámù, níwọ̀n bí Ísákì ò ti gbọ́dọ̀ mú ìyàwó látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. (Jẹ 22:20-23; 24:2-4) Yàtọ̀ síyẹn, ní Jẹ́nẹ́sísì 25:1, Bíbélì dárúkọ Kétúrà ìyẹn ìyàwó míì tí Ábúráhámù fẹ́. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì lẹ́yìn tí Sérà kú, àti pé agbára ìbímọ ẹ̀ ṣì ń ṣiṣẹ́ lẹ́yìn ogójì ọdún tí Jèhófà mú kó sọjí pa dà. (Ro 4:19; Jẹ 24:67; 25:20) Bákan náà, ó tún jẹ́ ká rí i pé àwọn ará Mídíánì àti àwọn ẹ̀yà Arébíà tan mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
Bíbélì tún dárúkọ Líà, Réṣẹ́lì, àti àwọn wáhàrì Jékọ́bù, títí kan àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bí. (Jẹ 35:21-26) Èyí jẹ́ ká lóye ìdí tí Jèhófà fi ṣe àwọn nǹkan tó ṣe fún àwọn ọmọ Jékọ́bù. Ohun tó jọ èyí náà ló mú kí wọ́n kọ orúkọ àwọn obìnrin míì sínú àkọsílẹ̀ ìlà ìdílé. Ohun míì tó tún lè jẹ́ ká kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ni tó bá jẹ́ àwọn ọmọbìnrin ló gba ogún ìdílé wọn. (Nọ 26:33) Àmọ́ ọ̀rọ̀ Támárì, Ráhábù àti Rúùtù ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìdí ni pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ló sì jẹ́ kí wọ́n di ìyá ńlá Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi. (Jẹ 38; Rut 1:3-5; 4:13-15; Mt 1:1-5) Àwọn ibòmíì tá a ti dárúkọ àwọn obìnrin nínú àkọsílẹ̀ ìlà ìdílé wà ní 1 Kíróníkà 2:35, 48, 49; 3:1-3, 5.
FEBRUARY 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KÍRÓNÍKÀ 10-12
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 1058 ¶5-6
Ọkàn
Máa Fi “Ọkàn Tó Pé” Sin Jèhófà. Ọkàn wa gbọ́dọ̀ wà ní ipò tó dáa kó tó lè ṣiṣẹ́ dáadáa, àmọ́ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa lè pínyà. Dáfídì gbàdúrà pé: “Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀ kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ,” ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ohun téèyàn nífẹ̀ẹ́ àtohun tó ń kóni lọ́kàn sókè lè pín ọkàn èèyàn níyà. (Sm 86:11) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè wá di “aláàbọ̀-ọkàn,” ìyẹn kò gbóná kò tutù nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Sm 119:113; Ifi 3:16) Ẹnì kan tún lè máa ṣe ojú ayé (tàbí ọkàn àti ọkàn lólówuuru), ìyẹn ni pé kéèyàn máa gbìyànjú láti sin ọ̀gá méjì tàbí kó máa sọ ohun kan jáde lẹ́nu nígbà tó jẹ́ pé nǹkan míì ló wà lọ́kàn ẹ̀. (1Kr 12:33; Sm 12:2, àlàyé ìsàlẹ̀) Jésù dẹ́bi fún àwọn tó máa ń hu irú ìwà àgàbàgebè bẹ́ẹ̀.—Mt 15:7, 8.
Ẹni tó bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn kò gbọ́dọ̀ máa ṣojú ayé tàbí kó jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn ẹ̀ níyà, kàkà bẹ́ẹ̀ ó gbọ́dọ̀ máa fi ọkàn tó pé sin Ọlọ́run. (1Kr 28:9) Ó gba ìsapá kí èèyàn tó lè fi ọkàn tó pé sin Ọlọ́run torí ọkàn ń tanni jẹ, kìkì ibi ló sì máa ń rò. (Jer 17:9, 10; Jẹ 8:21) Àwọn nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ọkàn tó pé sin Ọlọ́run ni: àdúrà àtọkànwá (Sm 119:145; Ida 3:41), ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé (Ẹsr 7:10; Owe 15:28), ká máa fi ìtara wàásù ìhìn rere náà (fi wé Jer 20:9), ká sì máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn sin Jèhófà.—Fi wé 2Ọb 10:15, 16.