Rírìn Pẹlu Ọkan-aya Ti Ó Ṣọ̀kan
“Fun mi ní ìtọ́ni, Óò Jehofa . . . Mú ọkan-aya mi ṣọ̀kan lati bẹru orukọ rẹ.”—ORIN DAFIDI 86:11, NW.
1. Bawo ni Jehofa ṣe ń san èrè fun awọn aduroṣinṣin rẹ̀?
‘ÓÒ JEHOFA, iwọ ni Ọlọrun, iwọ nikan.’ (Orin Dafidi 86:8, 10, NW) Dafidi yin Ọlọrun lati inu ọkan-aya ti ó kún dẹ́dẹ́ fun imọriri. Àní ṣaaju ki Dafidi tó di ọba lori gbogbo Israeli paapaa, Jehofa ti dá a nídè kuro lọwọ Saulu ati kuro lọwọ awọn ará Filistini. Fun idi yii, oun lè kọrin pe: “Oluwa ni àpáta mi; ati odi mi, ati olugbala mi; fun ẹni-iduro-ṣinṣin ni ododo ni iwọ ó fi ara rẹ hàn ni iduro-ṣinṣin ni ododo.” (2 Samueli 22:2, 26) Jehofa ti pa iranṣẹ rẹ̀ aduroṣinṣin mọ́ la ọpọlọpọ adanwo ja. Dafidi lè fi igbẹkẹle ati igbọkanle rẹ̀ sinu Ọlọrun aduroṣinṣin rẹ̀, ṣugbọn oun nilo itọsọna tí ń baa lọ. Dafidi gbadura ẹ̀bẹ̀ si Ọlọrun nisinsinyi pe: “Fun mi ní ìtọ́ni, Óò Jehofa, nipa ọ̀nà rẹ.”—Orin Dafidi 86:11, NW.
2. Bawo ni Jehofa ti ṣe ipese fun jíjẹ́ ẹni ti a kọ́ lati ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá?
2 Dafidi kò ní ohunkohun ṣe pẹlu awọn èrò tabi ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn ti ayé. Oun fẹ́ lati di ẹni ti a ‘kọ́ lati ọ̀dọ̀ Oluwa wá,’ gẹgẹ bi wolii Ọlọrun ti sọ ọ́ lẹhin ìgbà naa. (Isaiah 54:13) Ó ṣeeṣe fun Dafidi lati ronujinlẹ lori kìkì iwe mẹsan-an ti Bibeli ti ó wà larọọwọto ni ọjọ rẹ̀. Sibẹ, ìtọ́ni yẹn lati ọ̀dọ̀ Jehofa ṣeyebiye fun un! Nipa didi ẹni ti a kọ́, awa lonii lè jàsè lori gbogbo iwe 66 ti Bibeli, ati lori ọpọ yanturu iwe-ikẹkọọ Ijọba ti a pese nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” bakan naa. (Matteu 24:45, NW) Bii Dafidi, ẹ jẹ ki a képe Jehofa, ki ẹmi rẹ̀ lè ràn wá lọwọ lati wá inu “ohun wọnni tí Ọlọrun ti pèsè silẹ fun awọn ti ó fẹ́ ẹ, . . . àní, ohun ijinlẹ ti Ọlọrun.”—1 Korinti 2:9, 10.
3. Ni awọn ọ̀nà wo ni ìtọ́ni Bibeli lè gbà ṣanfaani fun wa?
3 Bibeli ní idahun si gbogbo ibeere ati iṣoro ti ó lè dide ninu igbesi-aye wa. “Nitori ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ́ fun kíkọ́ wa, pe nipa suuru ati itunu iwe-mimọ ki a lè ni ireti.” (Romu 15:4) Gbígba itọni lati ọ̀dọ̀ Jehofa sinu yoo fun wa lókun lati farada awọn inira, yoo tù wá ninu ni awọn akoko isorikọ, yoo sì mú ki ireti Ijọba naa maa mọ́lẹ̀-yòò ninu ọkan-aya wa. Ǹjẹ́ ki awa rí inudidun ninu kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ninu rironujinlẹ lori rẹ̀ “lọ́sàn-án ati lóru,” nitori pe ọgbọ́n ti a gbekari Bibeli di ‘igi ìyè fun awọn ti ó dì í mú, ibukun sì ni fun ẹni ti ó dì í mú ṣinṣin.’—Orin Dafidi 1:1-3; Owe 3:13-18; tun wo Johannu 17:3.
4. Niti awọn ìwà wa, apẹẹrẹ wo ni Jesu gbé kalẹ fun wa?
4 Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu, ti a tun pè ni “Ọmọ Dafidi,” sábà maa ń wo Jehofa fun ìtọ́ni. (Matteu 9:27)a Ó sọ pe: “Ọmọ kò lè ṣe ohunkohun fun ara rẹ̀, bikose ohun ti ó bá ri pe Baba ń ṣe: nitori ohunkohun ti ó bá ń ṣe, wọnyi ni Ọmọ sì ń ṣe bẹẹ gẹgẹ.” “Emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi ń sọ nǹkan wọnyi.” (Johannu 5:19; 8:28) Jesu fi awokọṣe lélẹ̀ fun wa ‘ki a lè maa tọ ipasẹ rẹ̀.’ (1 Peteru 2:21) Ṣáà rò ó wò ná! Bi a bá kẹkọọ gẹgẹ bi Jesu ti nilati ṣe, ninu ipo eyikeyii awa yoo lè hùwà gẹgẹ bi Jehofa yoo ti fẹ́ ki a hùwà. Ọ̀nà Jehofa ni ó maa ń jẹ́ ọ̀nà títọ́ nigba gbogbo.
5. Ki ni “otitọ”?
5 Dafidi polongo tẹle e pe: “Emi yoo rìn ninu otitọ rẹ.” (Orin Dafidi 86:11, NW) Ẹgbẹrun ọdun kan lẹhin naa, Pilatu, ní sísọrọ si Ọmọ Dafidi, Jesu, beere pe: “Ki ni otitọ?” Ṣugbọn Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ dahun ibeere yẹn, ní sisọ fun Pilatu pe: Ijọba mi kìí ṣe ti ayé yii,” ní fifikun un pe: “Iwọ wi pe, ọba ni emi í ṣe. Nitori eyi ni a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo sì ṣe wá si ayé, ki emi kí ó lè jẹrii si otitọ.” (Johannu 18:33-38) Jesu tipa bayii sọ ọ́ di mímọ̀ nihin-in pe otitọ naa kó afiyesi jọ sori Ijọba ti Messia. Nitootọ, gbogbo ẹṣin-ọrọ Bibeli jẹ́ ìsọdimímọ́ orukọ Jehofa nipasẹ Ijọba yẹn.—Esekieli 38:23; Matteu 6:9, 10; Ìfihàn 11:15.
6. Niti rírìn ninu otitọ, ki ni awa nilati ṣọ́ra fun?
6 Ki ni ó tumọsi lati rìn ninu otitọ? Ó tumọsi lati sọ ireti Ijọba naa di ìdàníyàn-ọkàn pataki ninu igbesi-aye wa. Awa gbọdọ gbé ìgbé-ayé otitọ Ijọba naa. Awa gbọdọ jẹ́ aláìdàníyàn meji ninu fifi ire Ijọba si ipo akọkọ, ki a jẹ onitara ni ibamu pẹlu anfaani ti a ní ninu jijẹrii si otitọ Ijọba naa, tẹle apẹẹrẹ Jesu. (Matteu 6:33; Johannu 18:37) Awa kò lè maa farahẹ ninu otitọ, ni wiwulẹ ṣe iṣẹ-isin gbà-mápòóòrọ́wọ́mi sibẹ lakooko kan-naa ki a maa tẹ́ araawa lọ́rùn nipa gbígba ọ̀nà ẹ̀rọ lati lọwọ ninu eré-ìtura àṣerégèé tabi lati kowọnu iṣẹ-igbesi-aye ti ń jẹ akoko tabi “sìnrú . . . fun Ọrọ̀.” (Matteu 6:24, NW) A lè sọnu sinu ọ̀kan lara awọn oju-ọna àbùjá wọnni, láìní rí ọ̀nà pada soju ‘ọ̀nà tóóró ti ń sinni lọ si ìyè’ mọ́. Ẹ maṣe jẹ́ ki a ṣakolọ kuro loju ọ̀nà yẹn! (Matteu 7:13, 14) Atobilọla Olùtọ́ni wa, Jehofa, nipasẹ Ọ̀rọ̀ ati eto-ajọ rẹ̀, tan imọlẹ si oju-ọna naa, ni wiwi pe: “Eyiyii ni ọ̀nà, ẹ maa rìn ninu rẹ̀, nigba ti ẹyin bá yí sí apa ọ̀tún, tabi nigba ti ẹyin bá yí sí apa òsì.”—Isaiah 30:21.
Ibẹru Bibojumu
7. Bawo ni a ṣe lè ‘mú àyà wa sọ̀kan’?
7 Adura Dafidi ń baa lọ ni ẹsẹ 11 (NW) pe: “Mú ọkan-aya mi sọ̀kan lati bẹru orukọ rẹ.” Bii Dafidi, a nilati fẹ́ ki ọkan-aya wa jẹ́ aláìpínyẹ́lẹyẹ̀lẹ, ki ó pé pérépéré, ninu ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun. Eyi bá imọran Mose mu pe: “Ǹjẹ́ nisinsinyi, Israeli, ki ni OLUWA Ọlọrun rẹ ń beere lọdọ rẹ, bikoṣe lati maa bẹru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati maa rìn ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, lati maa fẹ́ ẹ, ati lati maa sin OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àyà rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, lati maa pa ofin OLUWA mọ́, ati ilana rẹ̀, ti mo fi lélẹ̀ fun ọ ni àṣẹ ni oni, fun ire rẹ?” (Deuteronomi 10:12, 13) Fun ire wa ni, nitootọ, pe a ń fi gbogbo ìtara sinu ṣiṣiṣẹsin Jehofa. Nipa bayii a ń fi ibẹru bibojumu hàn nipa orukọ rẹ̀ tí ó lókìkí. Orukọ Jehofa tumọ ni olówuuru si “Ó Mú Kí Ó Wà,” ni pataki ni titọka si múmú awọn ète atobilọla rẹ̀ wá sí ipari. Ó tún duro fun ọla-aṣẹ onipo-ajulọ rẹ̀ lori gbogbo agbaye. Ni ṣiṣiṣẹsin pẹlu ibẹru ọlọ́wọ̀ fun ọláńlá Ọlọrun, a kì yoo pa wá léte dà nipa ibẹru eniyan kíkú. Ọkan-aya wa kì yoo pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Kaka bẹẹ, awa yoo bẹru lati ṣe ohunkohun ti kò dùn mọ́ Jehofa Onidaajọ Onipo-ajulọ ati Oluwa Ọba-alaṣẹ, ẹni ti ó di iwalaaye wa gan-an mú ni ọwọ rẹ̀.—Isaiah 12:2; 33:22.
8, 9. (a) Ki ni ó tumọsi lati maṣe “jẹ apakan ayé”? (b) Awọn igbesẹ wo ni a nilati gbé nitori pe a jẹ́ ‘àfiṣèranwò’?
8 Àní ni oju ẹ̀gàn ati inunibini paapaa, awa yoo tẹle apẹẹrẹ aláìbẹ̀rù ti Jesu ninu ṣíṣàìjẹ́ apakan ayé buburu ti ó yí wa ká. (Johannu 15:17-21) Eyi kò tumọsi pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu nilati maa gbé gẹgẹ bii anìkàndágbé tabi ki wọn farapamọ sinu ilé awọn ajẹ́jẹ̀ẹ́-anìkàndágbé. Jesu sọ ninu adura si Baba rẹ̀ pe: “Emi kò gbadura pe, ki iwọ ki o mú wọn kuro ni ayé, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ́ kuro ninu ibi. Wọn kìí ṣe ti ayé, gẹgẹ bi emi kìí ti í ṣe ti ayé. Sọ wọn di mímọ́ ninu otitọ: otitọ ni ọ̀rọ̀ rẹ. Gẹgẹ bi iwọ ti rán mi wá si ayé, bẹẹ ni emi sì rán wọn si ayé pẹlu.” (Johannu 17:15-18) Bii Jesu, a rán wa jade lati polongo otitọ Ijọba naa. Jesu ṣeésúnmọ́. Awọn eniyan ni a tù lara nipa ọ̀nà ti ó ń gbà kọni. (Fiwe Matteu 7:28, 29; 11:28, 29; Johannu 7:46.) Ó nilati rí bakan naa pẹlu wa.
9 Ìwà atúraká-bí-ọ̀rẹ́ tí ń baa lọ, ìmúra ti ó gbadunmọni ati ìrísí, ijumọsọrọpọ mímọ́ ati oninuure wa, nilati jẹ ki awa ati ihin-iṣẹ wa ṣetẹwọgba fun awọn eniyan ọlọ́kàn-títọ́. A gbọdọ yẹra fun aṣọ wúruwùru, ati aláwà níwọ̀ntúnsọ̀nsì, awọn ibakẹgbẹ ti ó lè ṣamọna si lilọwọ ninu awọn ohun ti ayé, ati ọ̀nà igbesi-aye aláìníjàánu, ti kò ní ilana ti a ń rí ninu ayé yí wa ká. Ní bi a ti “fi wá ṣe ìran wò fun ayé, ati fun angẹli, ati fun eniyan,” a wà lẹnu iṣẹ́ fun wakati 24 lojoojumọ lati ṣiṣẹsin ati lati gbé gẹgẹ bii Kristian awofiṣapẹẹrẹ. (1 Korinti 4:9; Efesu 5:1-4; Filippi 4:8, 9; Kolosse 4:5, 6) Ọkan-aya wa gbọdọ ṣọ̀kan fun ète yii.
10. Bawo ni Jehofa ṣe ń ranti awọn wọnni ti wọn mú àyà wọn ṣọ̀kan ninu iṣẹ-isin mimọ?
10 Awa ti a mú ọkan-aya wa ṣọ̀kan ninu ibẹru orukọ Jehofa, tí a ń ṣàṣàrò lori awọn ète atobilọla rẹ̀ ti a sì ń fi iṣẹ-isin mimọ kún igbesi-aye wa, ni Jehofa yoo ranti. “Nitori ti ojú Oluwa ń lọ síwá sẹ́hìn ni gbogbo ayé, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkan pípé si ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kronika 16:9) Ni titọka lọna alasọtẹlẹ si ọjọ wa, Malaki 3:16 kà pe: “Nigba naa ni awọn tí ó bẹru Oluwa ń bá ara wọn sọrọ nigbakugba; Oluwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́, a sì kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti ó bẹru Oluwa, ti wọn sì ń ṣe àṣàrò orukọ rẹ̀.” Ǹjẹ́ ki ọkan-aya wa ṣọ̀kan ninu ibẹru pipeye yẹn nipa Jehofa!
Iṣeun-ifẹ Jehofa
11. Bawo ni a o ṣe fi iṣeun-ifẹ Jehofa hàn siha awọn aduroṣinṣin?
11 Adura Dafidi ti gbónájanjan tó! Ó ń baa lọ pe; “Mo kókìkíyìn ọ́, Óò Jehofa Ọlọrun mi, pẹlu gbogbo ọkan-aya mi, emi yoo sì fògo fun orukọ rẹ titi akoko titilọ gbére, nitori iṣeun-ifẹ rẹ tobi siha ọ̀dọ̀ mi, o sì ti dá ọkàn mi nídè kuro ninu Sheol, ibi rírẹlẹ̀ julọ rẹ̀.” (Orin Dafidi 86:12, 13, NW) Fun ìgbà keji ninu orin Dafidi yii, Dafidi yin Jehofa fun iṣeun-ifẹ Rẹ̀—ifẹ aduroṣinṣin Rẹ̀. Ifẹ yii ga tobẹẹ debi pe ó lè gbanilà ninu awọn ipo ti nǹkan ti jọbi pe kò lè ṣeeṣe. Nigba ti Saulu ń lé e kiri ninu aginju, Dafidi ti lè nimọlara bii rírápálá lọ sí igun kan kí ó sì kú sibẹ. Ńṣe ni ó dabi ṣiṣe pẹ̀kírẹ̀kí pẹlu Sheol rírẹlẹ̀ julọ—kòtò isà-òkú. Ṣugbọn Jehofa dá a nídè! Ní ọ̀nà kan-naa, Jehofa sábà maa ń mú itura wá fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ode-oni ni awọn ọ̀nà agbayanu, ó sì tún ti ti awọn olupa iwatitọmọ ti wọn ti farada pẹlu iṣotitọ titi dé ojú ikú paapaa lẹhin. Gbogbo awọn aduroṣinṣin yoo gba èrè wọn, àní nipa ajinde bi ó bá pọndandan.—Fiwe Jobu 1:6-12; 2:1-6, 9, 10; 27:5; 42:10; Owe 27:11; Matteu 24:9, 13; Ìfihàn 2:10.b
12. Bawo ni awujọ alufaa ti ṣe jẹ́ oníwà-ìkùgbùù ati oníwà òṣìkà-agbonimọ́lẹ̀, ki ni yoo sì jẹ́ èrè wọn?
12 Nipa awọn oninunibini Dafidi kigbe jade pe: “Óò Ọlọrun, awọn ọ̀yájú funraawọn ti dide soke lodisi mi; ati apejọ awọn oníwà òṣìkà-agbonimọ́lẹ̀ gan-an ti dọdẹ ọkàn mi, wọn kò sì tíì gbé ọ ka iwaju araawọn.” (Orin Dafidi 86:14, NW) Lonii, awọn alufaa-ṣọọṣi Kristẹndọm ti wà lara awọn oninunibini naa. Awọn wọnyi tànmọ́-ọ̀n pe wọn ń jọsin Ọlọrun ṣugbọn wọn fi orukọ oyè naa “Oluwa” rọ́pò orukọ mimọ rẹ̀ wọn sì gbé e kalẹ gẹgẹ bii Mẹtalọkan ti o jẹ́ ohun ijinlẹ kan ti a kò mẹnukan nibikibi ninu Bibeli nitootọ. Iyẹn ti jẹ́ ìwà-ìkùgbùù tó! Ni afikun si eyi, wọn gbiyanju lati sún awọn agbara oṣelu lati fofin de awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ki wọn sì fi wọn sẹ́wọ̀n, gẹgẹ bi wọn ti ń ṣe titi di bayii ni ọpọ awọn orilẹ-ede lọna ti ó yanilẹnu yika ilẹ̀-ayé. Awọn aláṣọ gbàgẹ̀rẹ̀ asọ̀rọ̀-òdì sí orukọ Ọlọrun wọnyi yoo ká èrè wọn, papọ pẹlu gbogbo awọn ìpín bi-aṣẹwo ti Babiloni Nla.—Ìfihàn 17:1, 2, 15-18; 19:1-3.
13. Awọn animọ wo ni Jehofa fihàn ninu sísọ iwarere-iṣeun rẹ̀ di mímọ̀?
13 Ninu ifiwera alayọ adura Dafidi ń baa lọ pe: “Ṣugbọn iwọ, Óò Jehofa, ni Ọlọrun alaaanu ati oloore-ọfẹ, ti ó lọ́ra lati binu tí ó sì pọ̀ yanturu ní iṣeun-ifẹ ati òótọ́.” (Orin Dafidi 86:15, NW) Adáratayọ, nitootọ, ni iru awọn animọ Ọlọrun wa bẹẹ. Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi mú wa pada sẹhin si Oke Sinai nigba ti Mose beere lati rí ògo Jehofa. Jehofa fèsì pe: “Emi óò mú gbogbo oore mi kọja niwaju rẹ, emi ó sì pe orukọ OLUWA niwaju rẹ.” Ṣugbọn ó kilọ fun Mose pe: “Iwọ kò lè rí ojú mi: nitori ti kò sí eniyan kan tì í rí ojú mi, ti sìí yè.” Lẹhin ìgbà naa, Jehofa sọkalẹ ninu awọsanma, ni pipolongo pe: “OLUWA, OLUWA, Ọlọrun alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti o pọ̀ ni oore ati otitọ.” (Eksodu 33:18-20; 34:5, 6) Dafidi ṣayọlo awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ninu adura rẹ̀. Iru awọn animọ Jehofa bẹẹ ní itumọ gidigidi fun wa ju ìrísí ara eyikeyii lọ! Lati inu iriri tiwa funraawa, awa kò ha mọriri iwarere-iṣeun Jehofa gẹgẹ bi a ti ṣapẹẹrẹ rẹ̀ ninu awọn ànímọ́-ìwà rere wọnyi bi?
“Àmì kan Ti Ó Tumọsi Iwarere-iṣeun”
14, 15. Bawo ni Jehofa ṣe ṣaṣepari “àmì kan ti ó tumọsi iwarere-iṣeun” fun awọn iranṣẹ rẹ̀?
14 Dafidi tọrọ ibukun Jehofa lẹẹkan sii, ni sisọ pe: “Yíjú sí mi ki o sì ṣojurere sí mi. Fi okun rẹ fun iranṣẹ rẹ, ki o sì gba ọmọkunrin iranṣẹbinrin rẹ là. Bá mi ṣaṣepari àmì kan ti ó tumọsi iwarere-iṣeun, ki awọn wọnni ti ń koriira mi lè rí i ki ojú sì tì wọn. Nitori ti iwọ funraarẹ, Óò Jehofa, ti ràn mi lọwọ o sì ti tù mí ninu.” (Orin Dafidi 86:16, 17, NW) Dafidi mọ̀ daju pe gẹgẹ bi ‘ọmọkunrin iranṣẹbinrin Jehofa,’ oun pẹlu gbọdọ jẹ́ ti Jehofa. Bakan naa ni ó rí pẹlu gbogbo wa lonii ti a ti ya igbesi-aye wa si mimọ fun Jehofa ti a sì ń ṣẹrú ninu iṣẹ-isin rẹ̀. A nilo okun igbala Jehofa nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀. Fun idi yii, a ń beere lọwọ Ọlọrun wa lati bá wa ṣaṣepari “àmì kan ti ó tumọsi iwarere-iṣeun.” Iwarere-iṣeun Jehofa kó awọn animọ rere ti a ṣẹ̀ṣẹ̀ jiroro tán yii mọra. Lori ipilẹ yii, àmì, tabi apẹẹrẹ wo ni a lè reti pe ki Jehofa fifun wa?
15 Jehofa ni Olufunni ni “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pípé” ó sì jẹ́ ọlọ́làwọ́, gẹgẹ bi Jesu ti mú un dá wa loju, ninu fifi “ẹmi mimọ rẹ̀ fun awọn ti ó ń beere lọdọ rẹ̀.” (Jakọbu 1:17; Luku 11:13) Ẹmi mimọ—iru ẹbun alaiṣeediyele wo lati ọdọ Jehofa ni eyi jẹ́! Nipasẹ ẹmi mimọ, Jehofa ń pese ayọ ọkan-aya, àní ni akoko inunibini paapaa. Nipa bayii, awọn aposteli Jesu, nigba ti wọn wà ninu ẹjọ́ fun iwalaaye wọn, lè fi tayọtayọ polongo pe Ọlọrun a maa fi ẹmi mimọ rẹ̀ fun awọn wọnni ti wọn ń ṣegbọran sí i gẹgẹ bi oluṣakoso. (Iṣe 5:27-32) Ayọ ẹmi mimọ ṣaṣepari “àmì kan ti ó tumọsi iwarere-iṣeun” fun wọn leralera.—Romu 14:17, 18.
16, 17. (a) Àmì iwarere-iṣeun rẹ̀ wo ni Jehofa fifun Paulu ati Barnaba? (b) Àmì wo ni a fifun awọn ará Tessalonika ti a ṣenunibini si?
16 Nigba irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun wọn la Asia Kekere kọja, Paulu ati Barnaba dojukọ awọn inira, àní inunibini mimuna paapaa. Nigba ti wọn waasu ni Antioku ti Pisidia, awọn Ju kọ ihin-iṣẹ wọn silẹ. Fun idi yii, wọn yiju si awọn eniyan orilẹ-ede. Ki ni ó yọrisi? “Nigba ti awọn Keferi sì gbọ́ eyi, wọn yọ̀, wọn sì yin ọ̀rọ̀ Ọlọrun lógo: gbogbo awọn ti a yàn si ìyè ainipẹkun si gbagbọ.” Ṣugbọn awọn Ju fa irukerudo, debi pe awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun wọnni ni a lé jade kuro ni orilẹ-ede naa. Ǹjẹ́ awọn ati awọn onigbagbọ titun naa ha sọretinu nipa eyi bi? Ki a má ri! Kaka bẹẹ, “awọn ọmọ-ẹhin sì kún fun ayọ ati fun ẹmi mimọ.” (Iṣe 13:48, 52) Jehofa fun wọn ní àmì iwarere-iṣeun rẹ̀ yẹn.
17 Lẹhin naa, ijọ titun ti ó wà ni Tessalonika ni a fi sabẹ inunibini. Eyi mú ki aposteli Paulu kọ lẹta itunu kan, ní gbigboriyin fun ifarada wọn labẹ ipọnju. Wọn “ti gba ọ̀rọ̀ naa ninu ipọnju ọpọlọpọ, pẹlu ayọ ẹmi mimọ.” (1 Tessalonika 1:6) “Ayọ ẹmi mimọ” ń baa lọ lati fun wọn lokun gẹgẹ bi àmì kan ti ó hàn gbangba lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ẹni ti ó jẹ́ alaaanu ati oloore-ọfẹ, ti ó lọ́ra lati binu, ti ó sì pọ̀ yanturu ni iṣeun-ifẹ ati otitọ.
18. Bawo ni awọn ará wa ni iha Ila-oorun Europe ṣe fi imọriri hàn fun iwarere-iṣeun Jehofa?
18 Ni awọn akoko aipẹ yii, Jehofa ti fi iwarere-iṣeun rẹ̀ hàn siha ọ̀dọ̀ awọn ará oluṣotitọ ni iha Ila-oorun Europe, ni kíkó itiju bá awọn wọnni ti ó ti koriira wọn—awọn oninunibini wọn tẹlẹri. Bi o tilẹ jẹ pe ẹnu aipẹ yii ni wọn ní itura kuro ninu itẹniloriba ọpọ ẹwadun, awọn ará ọ̀wọ́n wọnyi ṣì nilati farada sibẹ, nitori pe ọoọlọpọ ni awọn inira ti iṣunna-owo dojukọ. Bi o ti wu ki o ri, “ayọ ẹmi mimọ” wọn ń fun wọn nítùnú. Ayọ ti ó tubọ tobi wo ni wọn ìbá ní ju pe ki wọn maa lo ominira wọn ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ninu mímú ẹ̀rí gbooro lọ? Ọpọlọpọ eniyan ń fetisilẹ si wọn, gẹgẹ bi awọn irohin lori apejọpọ ati iribọmi ti fihàn.—Fiwe Iṣe 9:31.
19. Bawo ni a ṣe lè sọ awọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 86:11 di tiwa funraawa gan-an?
19 Gbogbo ohun ti a ti jiroro ninu ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yii ati ti iṣaaju ṣe gbohungbohun adura gbígbóná janjan ti Dafidi si Jehofa pe: “Fun mi ní ìtọ́ni, Óò Jehofa . . . Mú ọkan-aya mi ṣọ̀kan lati bẹru orukọ rẹ.” (Orin Dafidi 86:11, NW) Ẹ jẹ ki a sọ awọn ọ̀rọ̀ wọnni ti ó jẹ́ ẹsẹ iwe mimọ wa fun 1993 di tiwa gan-an gẹgẹ bi a ti ń fi gbogbo ọkan-aya ṣiṣẹ ni itilẹhin fun awọn ire Ijọba naa ati ni imọriri iwarere-iṣeun ti kì í tán ti Ọlọrun wa kanṣoṣo, Jehofa Oluwa Ọba-alaṣẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹgẹ bi “iru-ọmọ” ti a sọtẹlẹ naa, Jesu ni ajogun fun ijọba ti Dafidi ati fun idi eyi oun ni “Ọmọ Dafidi” ní èrò itumọ gidi ati nipa tẹmi.—Genesisi 3:15; Orin Dafidi 89:29, 34-37.
b Fun awọn apẹẹrẹ ode-oni, wo Yearbook of Jehovah’s Witnesses, itẹjade ti 1974, oju-iwe 113 si 212; 1985, oju-iwe 194 si 197; 1986, oju-iwe 237 si 238; 1988, oju-iwe 182 si 185; 1990, oju-iwe 171 si 172; 1992, oju-iwe 174 si 181.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni a fihàn nipa gbigbadura pe, “Fun mi ní ìtọ́ni, Óò Jehofa”?
◻ Ki ni a ní lọ́kàn pẹlu jíjẹ́ ki a mú ọkan-aya wa ṣọ̀kan lati bẹru orukọ Jehofa?
◻ Bawo ni Jehofa yoo ṣe fi iṣeun-ifẹ rẹ̀ hàn siha awọn aduroṣinṣin?
◻ Bawo ni Jehofa ṣe ń bá wa ṣaṣepari “àmì kan ti ó tumọsi iwarere-iṣeun”?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹsẹ iwe mimọ fun 1993: “Fun mi ní ìtọ́ni, Óò Jehofa . . . Mú ọkan-aya mi ṣọ̀kan lati bẹru orukọ rẹ.”—Orin Dafidi 86:11, NW.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jehofa ni àpáta ati odi-agbara fun awọn wọnni ti wọn ń rìn taarata ninu otitọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ni Apejọpọ Agbaye “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀” ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni St. Petersburg, Russia, ni June, 46,214 pésẹ̀ ti a sì baptisi 3,256. Awọn wọnyi ti ń mú araawọn janfaani iwarere-iṣeun Jehofa lọna agbayanu, pẹlu “ayọ ẹmi mimọ” tó!