“Wọ́n Ga Bí Igi Kédárì Ní Lẹ́bánónì”
LÓRÍ àwọn òkè lílẹ́wà ti Lẹ́bánónì, a lè rí àwọn igi tí a mọ̀ sí Arz Ar-rab, tó túmọ̀ sí “Àwọn Kédárì Olúwa.” Àwọn igi gíga fíofío wọ̀nyí, tí ń léwé lára ní tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, tó bo àwọn òkè náà nígbà kan rí, ni a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì ní nǹkan bí àádọ́rin ìgbà—kò sí igi mìíràn táa mẹ́nu kàn tó o.
Nígbà tí Ìwé Mímọ́ ń ṣàpèjúwe àwọn igi kédárì gàgàrà ti Lẹ́bánónì, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “ààyò” àti “ọlọ́lá ọba.” (Orin Sólómọ́nì 5:15; Ìsíkíẹ́lì 17:23) Títóbi tí igi kédárì tóbi àti bó ṣe lálòpẹ́, ló fi jẹ́ pé tipẹ́tipẹ́ làwọn èèyàn ti ń lò ó fún kíkọ́lé àti kíkan ọkọ̀ òkun àti fún ṣíṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú ilé. Òórùn ìtasánsán igi náà àti àwọ̀ pupa yòò rẹ̀ fani mọ́ra gan-an, àwọn èròjà alágbára tó sì wà nínú oje rẹ̀ kì í jẹ́ kí ó tètè ju tàbí kí kòkòrò jẹ ẹ́. Àwọn igi náà ga lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, wọ́n tóbi fàkìà-fakia, wọ́n lè ga tó mítà mẹ́tàdínlógójì, kí wọ́n sì fẹ̀ tó mítà méjìlá, wọ́n ní gbòǹgbò tó jinlẹ̀ dòò, tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Àbájọ tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n òde òní nípa igbó fi pè wọ́n ní “adé ògo lágbo àwọn igi”!
Lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, Ìsíkíẹ́lì, tí í ṣe òǹkọ̀wé Bíbélì, fi Mèsáyà wé ẹ̀ka kédárì, tí Ọlọ́run tìkára rẹ̀ gbìn. (Ìsíkíẹ́lì 17:22) Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ Hébérù fún “kédárì” wá láti inú ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “láti dúró gbọn-in gbọn-in.” Lónìí pẹ̀lú, ó yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Mèsáyà, èyíinì ni Jésù Kristi, “dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́” kí wọ́n “di alágbára ńlá,” bí igi kédárì gíga, tó rọ́kú. (1 Kọ́ríńtì 16:13) Báwo ni èyí ṣe lè ṣeé ṣe? Nípa fífi ìdúró gbọn-in dènà àwọn ìwà tó lòdì sí Kristẹni, kí a sì máa faradà á láìyẹsẹ̀ ní ipa ọ̀nà ìwà títọ́ àti ìfọkànsin Ọlọ́run. Àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì pè ní “àwọn olódodo . . . [tí] wọ́n ga bí igi kédárì ní Lẹ́bánónì.”—Sáàmù 92:12, The New English Bible.