Ori 11
Jerusalemu ti Ilẹ̀-Ayé ní Ìfiwéra Pẹlu Jerusalemu ti Òkè-Ọ̀run
1. (a) Iparun Jerusalemu yoo ha jẹ́ ohun titun kan bi? (b) Eeṣe ti ki yoo fi jẹ́ jamba fun gbogbo iran eniyan bi Jerusalemu ba tun jiya iparun lẹẹkan sii?
AWỌN ti wọn jẹ́ Ju nipa ti ara lonii ti pinnu pe Jerusalemu ti Aarin Gbùngbùn Ila-Oorun Ayé yoo wà titilae. Awọn eniyan Kristẹndọm paapaa ṣì ní ọ̀wọ̀ giga fun ilu yẹn nibi ti Jesu ti pari iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀. Ṣugbọn njẹ gbogbo eyi ha pese idaniloju pe ilu naa yoo maa baa lọ lati wà titi bi? O ti jiya iparun tẹlẹri, ní 607 B.C.E. lati ọwọ́ awọn ara Babiloni ati ní 70 C.E. lati ọwọ́ awọn ara Romu. Yoo ha jẹ́ jamba fun gbogbo iran eniyan bi o ba tun jiya iparun lẹẹkan sii bi? Bẹẹkọ, a kò nilo ilu yẹn ki ibukun majẹmu Abrahamu to ṣàn dé ọdọ iran eniyan. Koda a kọwe nipa Abrahamu pe: “Nitori ti ó ń reti ilu ti ó ní ipilẹ; eyi ti Ọlọrun tẹ̀dó ti ó si kọ́.”—Heberu 11:10.
2. (a) Bawo ni aposteli Paulu ṣe fihan pe Jerusalemu kan ti ó ga ju wà? (b) Ta ni Olówó-Orí Jerusalemu yẹn, awọn wo si ni awọn ọmọ ti ó bi fun un?
2 Aposteli Paulu kọwe pe: “Ṣugbọn Jerusalemu ti oke jẹ́ ominira, eyi tii ṣe iya wa.” (Galatia 4:26) O fi i hàn nibẹ pe Jerusalemu ti ọ̀run bá Sara ṣe rẹ́gí oun sì ni ètò-àjọ ti ó dabi iyawo Abrahamu Gigaju naa, Jehofa Ọlọrun. Nitori naa, awọn ọmọkunrin “Jerusalemu ti oke” ni awọn Kristian ti a fi ẹmi bi, bii ti Paulu.
“Jerusalemu ti Oke” Di Ilu Ọlọba Kan
3. (a) Nigba wo ni Jehofa Ọlọrun funraarẹ bẹrẹsii ṣakoso? (b) Nibo ni a ti gbé Jesu Kristi gori itẹ, ipa wo ni eyi si ní lori ipo ọba Jehofa funraarẹ?
3 “Jerusalemu ti oke” ti wá gbe irisi ti ọlọba wọ̀ lati igba ti “akoko awọn keferi” ti pari ní 1914. (Luku 21:24) Lati igba naa lọ, Orin Dafidi 97:1 (NW) bẹrẹsii ṣiṣẹ: “Jehofa fúnraarẹ̀ di ọba! Jẹ ki ayé ki o yọ̀.” Bakan naa Orin Dafidi 99:1, 2 (NW) naa ṣiṣẹ pẹlu: “Jehofa funraarẹ ti jọba. . . . Jehofa tobi ní Sioni, o si ga ju gbogbo awọn eniyan lọ.” Ní 1914 akoko tó fun un lati fopin sí itẹmọlẹ Ijọba naa ti ó wà ninu ìlà ọlọba ti Dafidi, bi a ti ṣoju fun un lati Jerusalemu ilu ọlọba tẹlẹri naa. Nitori naa, o gbé Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, gori itẹ gẹgẹ bi Ọba ní ọwọ́ ọtun Oun fúnraarẹ̀ ní “Jerusalemu ti oke,” Jerusalemu ti oke ọ̀run, ti ó tipa bayii sọ ọ di ilu ọlọba. Ipo ọba Jehofa fúnraarẹ̀ ni a fun lokun tabi mú gbooro sii nipa gbigbe Jesu Kristi gori itẹ gẹgẹ bi Ọba.
4. Nipasẹ awọn iṣẹlẹ wo ni “Jerusalemu ti oke” fi di ilu ọlọba lati 1914?
4 Nitori naa lẹhin ibi Ijọba ọ̀run naa ní 1914 ati lẹhin ti a ti lé Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ kuro ní ọ̀run, o baamu gẹẹ lati kede pe: “Nigba yii ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati [ọla aṣẹ, NW] ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisun awọn arakunrin wa jade, ti ń fi wọn sun niwaju Ọlọrun wa lọsan ati loru.” (Ìfihàn 12:1-10) “Ọla aṣẹ ti Kristi rẹ̀” jẹ́ fun Ẹni yii lati ṣakoso gẹgẹ bi Ọba ní “Jerusalemu ti oke.” Nitootọ, o di ilu ọlọba kan ní ọdun alami asọtẹlẹ naa 1914.
Ọmọbinrin “Jerusalemu ti Oke”
5, 6. (a) Ninu Ìfihàn 21:1, 2, ilu titun iṣapẹẹrẹ wo ni Johannu ri? (b) Lati ọdọ ta ni a ti nawọ́ ikinikaabọ ọlọ́lá ti a tò lẹsẹẹsẹ sinu Sekariah 9:9, 10 jade, ati ní awọn ọ̀rọ̀ wo?
5 Ní eyi ti ó ju ọdun mẹẹdọgbọn lọ lẹhin iparun Jerusalemu lati ọwọ́ ẹgbẹ ogun Romu ní 70 C.E., a fun aposteli Johannu ní awọn iran agbayanu ti wọn wà ninu iwe Ìfihàn. Ninu Ìfihàn 21:1, 2, Johannu sọrọ nipa “Jerusalemu Titun” kan. Awọn wọnni ti wọn parapọ di “Jerusalemu Titun” yii ni wọn fi pẹlu idunnu ki Ọba ti a ṣẹṣẹ fi jẹ́ ti ó wá ní orukọ Jehofa kaabọ, gan-an gẹgẹ bi a ti ke si wọn lati ṣe ninu Sekariah 9:9, 10, ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi:
6 “Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; hó, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiyesi i, Ọba rẹ ń bọ̀ wá sọdọ rẹ: ododo ni oun, o si ní igbala; o ní irẹlẹ, o si ń gun kẹtẹkẹtẹ . . . Emi o si ke kẹ̀kẹ́ kuro ní Efraimu, ati ẹṣin kuro ní Jerusalemu, a o si ke ọrun ogun kuro: yoo si sọrọ alaafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yoo si jẹ́ lati okun de okun, ati lati odò titi de opin ayé.”
7. Lati ọdọ awọn wo ni asọtẹlẹ yẹn ti ní imuṣẹ lakooko “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” isinsinyi, ní ọna wo sì ni?
7 Asọtẹlẹ yii ní imuṣẹ lapakan nigba ti Jesu Kristi fi pẹlu ayọ-iṣẹgun gun kẹtẹkẹtẹ wọ Jerusalemu ní 33 C.E. Lati 1919 wá ó ti wá ní paríparì imuṣẹ rẹ̀ lori àṣẹ́kù Israeli tẹmi. Kò si ipinya laaarin awọn mẹmba àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo naa, bii iru eyi ti ó bẹsilẹ laaarin awọn ẹ̀yà Efraimu ati Jerusalemu igbaani, olu-ilu ijọba ẹlẹya meji ti Juda. Nipa ṣiṣiṣẹsin papọ ní iṣọkan fun awọn ire Ijọba Messia fun ète mimu asọtẹlẹ Jesu ninu Matteu 24:14 ati Marku 13:10 ṣẹ, wọn ń baa lọ lati maa kókìkí Ọba aṣẹgun naa, Jesu Kristi. Ninu iṣọkan ti kò ṣeeja wọn ń fi pẹlu iduroṣinṣin tẹriba fun iṣakoso ọlọba rẹ̀ laaarin “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” isinsinyi.—Matteu 24:3, NW.
8. (a) Awọn wo ni o kuna lati ki Ọba aṣẹgun naa kaabọ? (b) Si ibo ati si ki ni awọn ẹni bẹẹ ń tòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ?
8 Si itiju wọn, papọ pẹlu Jerusalemu ti Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli, awọn gbajúgbajà orilẹ-ede Kristian ti wọn parapọ di Kristẹndọm kò kí Ọba aṣẹgun naa ti ó wá ní orukọ Jehofa kaabọ. Sibẹsibẹ, awọn kan wà ti wọn jẹ́ ẹlẹ́rìí Ẹni naa ti oun wá ní orukọ rẹ̀, ti wọn ń fi tayọtayọ sin In ninu tẹmpili Rẹ̀. (Isaiah 43:10-12) A ti ṣí oju wọn nipa tẹmi lati rii wi pe Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli ati gbogbo awọn orilẹ-ede yooku ti wọn wà ninu ati lẹhin ode UN ti rìn jinna nisinsinyi ninu ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ si “ibi kan ti a ń pè ní Har–mageddoni ní ede Heberu.” (Ìfihàn 16:16) Ogun Ọlọrun Olodumare ti sunmọle!
9. Bawo ni ọjọ-ọla Jerusalemu ori ilẹ̀-ayé ṣe wà ní iyatọ gedegbe si ti Jerusalemu Titun?
9 Ọjọ iwaju Jerusalemu ori ilẹ̀-ayé jẹ́ eyi ti ó korò, ṣugbọn ti Jerusalemu Titun ń dan yanran yanran. Nigba ti ó ba ṣe, awọn “iwo mẹwaa” ti oṣelu “ẹranko ẹhanna,” ati “ẹranko” naa fúnraarẹ̀, yoo yijupada ni kikoriira eto-igbekalẹ agbere naa, Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye. Wọn yoo fi ikoriira wọn rírorò hàn lodisi Jerusalemu ori ilẹ̀-ayé ti wọn ń wárí fún lọna ti isin, wọn yoo sì pa a run bi ẹni pe pẹlu ina ajonirun. (Ìfihàn 17:16) Ṣugbọn dajudaju wọn kò ní lè fi ọwọ́ kan Jerusalemu Titun ti ọ̀run naa.
10. Bawo ni Jerusalemu ori ilẹ̀-ayé ṣe ń tọ ipa ọna ti ó yatọ si ti awọn Kristian ti a fi ẹmi bi ati “ogunlọgọ nla,” awọn alabaakẹgbẹpọ wọn?
10 Àṣẹ́kù awọn Kristian ti a fi ẹmi bi ti ń reti lati di apakan Jerusalemu Titun ti ọ̀run naa ń baa lọ lati maa kókìkí Ọba Ọkọ-Iyawo naa, Jesu Kristi, papọ pẹlu “ogunlọgọ nla” ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa miiran. Ninu ọna igbegbeesẹ oniduroṣinṣin yii, wọn duro yatọ gedegbe si Jerusalemu atijọ naa. Gbara lati igba titẹ Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli dó, ilu Jerusalemu nibi ti awọn ti o pọju jẹ Ju nisinsinyi ń tẹ̀lé ipasẹ ọna awọn olugbe Jerusalemu ti ọrundun kìn-ín-ní. Labẹ agbara idari isin ti ń fọni loju, o ṣi ń baa lọ lati kọ Jesu Kristi, Ẹni naa ti ó ní ẹtọ ati agbara lati ṣakoso ninu Ijọba ọ̀run.
11, 12. (a) Awọn wo ní pato ni wọn mu asọtẹlẹ Jesu ti ó yẹ fun afiyesi ninu Matteu 24:14 ṣẹ? (b) Ki ni Society ti wọn ń ṣiṣẹ pẹlu rẹ̀ ní ní Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli lonii?
11 Nitootọ, lati opin Akoko Awọn Keferi ní 1914, “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ti ń ṣakoso ninu awọn ọ̀run, lai kò ṣee fojuri fun eniyan. Bi o tilẹ ri bẹẹ, lati igba ti awọn ara Britain ti fi agbara gba Jerusalemu ninu Ogun Agbaye I ti Imulẹ Awọn Orilẹ-Ede si ti fun Britain ní aṣẹ lori rẹ̀, ihinrere Ijọba ọ̀run naa ní ọwọ́ Messia Ọmọkunrin Dafidi ni a ti ń waasu “ní gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede,” gan-an gẹgẹ bi Jesu Kristi funraarẹ ti sọ tẹ́lẹ̀.—Matteu 24:14.
12 Imuṣẹ asọtẹlẹ ti ó yẹ fun afiyesi yii ni a ti muṣẹ lati ọwọ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa labẹ abojuto Watch Tower Bible and Tract Society. Society yii tilẹ ní ẹ̀ka ile-iṣẹ kan ní Tel Aviv, lati ibi tí a ti ń ṣe itọsọna igbokegbodo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa la gbogbo ipinlẹ Israeli já. Awọn ijọ Ẹlẹ́rìí alaapọn fun Jehofa tun wà ti ń polongo ihinrere Ijọba ní ilẹ yẹn pẹlu.
13. (a) Ki ni yoo tẹ̀lé ṣiṣe aṣepari wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun lẹkun-unrẹrẹ? (b) Njẹ a o ha nilo Jerusalemu ori ilẹ̀-ayé miiran lae bi, koda lati fi itẹwọgba ki Dafidi kaabọ lati inu ajinde?
13 Jesu Kristi sọ asọtẹlẹ pe lẹhin ṣiṣe aṣepari wiwaasu “ihinrere ijọba yii” lẹkun-unrẹrẹ, “opin” yoo de sori eto-igbekalẹ awọn nǹkan ayé yii. (Matteu 24:14) Nitori naa nisinsinyi opin Jerusalemu ori ilẹ̀-ayé ti sunmọle. Ní akoko yii, kò dabi ẹni pe aini kankan wa fun kíkọ́ Jerusalemu miiran si àyè ti ogbologbo nì, koda lati fi itẹwọgba kí ọba Jerusalemu nigba kan ri, Dafidi, kaabọ lati inu ajinde kuro ninu iku labẹ Ijọba Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti atọmọdọmọ rẹ̀ ọba, Jesu Kristi. (Johannu 5:28, 29) Sibẹsibẹ, ó ṣeeṣe ki a mu Dafidi padabọ si agbegbe naa nibi ti ó ti ṣiṣẹsin Jehofa Ọlọrun rí.
Akoko kan fun Yiyọ Ayọ̀
14, 15. (a) Bawo ni aposteli Johannu ṣe ṣapejuwe Jerusalemu Titun ologo naa ati isọkalẹ rẹ̀ lati ọ̀run wa fun ibukun iran eniyan? (b) Eeṣe ti akoko tiwa fi jẹ́ akoko kan fun yiyọ ayọ̀, iṣẹlẹ wo fun ayọ̀ agbaye ni ó sunmọle?
14 Jerusalemu Titun ni a sopọ pẹlu eto-igbekalẹ awọn nǹkan titun ologo. Aposteli Johannu wi pe: “Mo si ri ọ̀run titun kan ati ayé titun kan: nitori pe ọ̀run ti iṣaaju ati ayé ti iṣaaju ti kọja lọ; òkun kò sì sí mọ́. Mo si ri ilu mímọ́ nì, Jerusalemu titun, ń ti ọ̀run sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọọ fun ọkọ rẹ̀. Mo sì gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ nì wá, ń wí pe: Kiyesi i, agọ Ọlọrun wà pẹlu awọn eniyan, oun o si maa ba wọn gbe, wọn o si maa jẹ́ eniyan rẹ̀, ati Ọlọrun tikaraarẹ yoo wà pẹlu wọn.” (Ìfihàn 21:1-3) Nipa bayii, Jerusalemu Titun yoo jẹ́ ibukun fun gbogbo iran eniyan.
15 Eyi mu ki akoko tiwa jẹ́ akoko kan fun yiyọ ayọ̀. Lati fi kun yiyọ ayọ̀ yii, iṣẹlẹ kan ti ó jẹ́ fun ire agbaye ati fun ayọ̀ agbaye sunmọle. O jẹ́ ti igbeyawo ẹkunrẹrẹ iye awọn ti ẹgbẹ iyawo naa, Jerusalemu Titun, pẹlu Jesu Kristi Ọba. Bi a ti kọ ọ́ sinu Ìfihàn 19:6-9 pe: “Mo [aposteli Johannu] si gbọ bi ẹni pe ohùn ọpọlọpọ eniyan, ati bi iro omi pupọ, ati bi iro àrá nlanla, ń wi pe Halleluiah: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, ń jọba. Ẹ jẹ́ ki a yọ̀, ki inu wa ki o si dun gidigidi, ki a sì fi ogo fun un: nitori pe igbeyawo Ọdọ-Agutan [Jesu Kristi] dé, aya rẹ̀ si ti mura tan. Oun ni a si fifun pe ki ó wọ aṣọ ọgbọ wíwẹ́ ti ó funfun gboo: nitori pe aṣọ ọgbọ wíwẹ́ nì ni iṣẹ ododo awọn eniyan mímọ́. O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Ibukun ni fun awọn ti a pè si ase alẹ igbeyawo Ọdọ-Agutan.”
16. (a) Nipa igbeyawo rẹ̀ pẹlu Ọdọ-Agutan naa ní ọ̀run, ta ni Jerusalemu Titun wa di iya fun? (b) Jerusalemu Titun naa yoo wá jẹ́ ibukun kan ni ibaamu kikun pẹlu ki ni?
16 Isopọ yii pẹlu Ọdọ-Agutan naa Jesu Kristi ninu igbeyawo yoo tumọsi ayọ̀ ti kò ṣee fi ẹnu sọ fun Jerusalemu Titun iṣapẹẹrẹ naa ní ọ̀run. Nipasẹ rẹ̀ oun yoo di “oninudidun iya awọn ọmọ.” (Orin Dafidi 113:9) Bẹẹni, oun yoo di iya ti ọ̀run fun gbogbo eniyan, alaaye ati oku, ti ọkọ rẹ̀ onifẹẹ rà pada nipasẹ ẹbọ eniyan pipe rẹ̀ ní ọrundun 19 sẹhin. Ní ibamu kikun pẹlu majẹmu Jehofa ti ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹhin pẹlu Abrahamu, Jerusalemu Titun naa yoo wa jẹ́ ibukun fun gbogbo idile ori ilẹ̀-ayé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 96]
Ninu eto-igbekalẹ awọn nǹkan titun, Jerusalemu Titun yoo bukun gbogbo iran eniyan