Ṣiṣẹ́sin Jehofa Pẹ̀lú Ìdùnnú-Ayọ̀ Ọkàn-Àyà
“Gbogbo ègún wọ̀nyí yóò sì wá sórí rẹ . . . nítorí tí ìwọ kò fi ayọ̀ inúdídùn sin Jehofa Ọlọrun rẹ pẹ̀lú yíyọ ayọ̀ àti ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà.”—DEUTERONOMI 28:45-47, NW.
1. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sin Jehofa jẹ́ onídùnnú-ayọ̀, níbikíbi tí wọ́n bá ti ń siṣẹ́sìn ín?
ÀWỌN ìránṣẹ́ Jehofa jẹ́ onídùnnú-ayọ̀, yálà wọ́n ń ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀ ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀-ayé. Àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ “àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀” hó ìhó onídùnnú-ayọ̀ nígbà tí a fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, kò sì sí iyèméjì pé ìdùnnú-ayọ̀ ni àwọn ògídímèje áńgẹ́lì ọ̀run fi ‘ń mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣẹ.’ (Jobu 38:4-7; Orin Dafidi 103:20, NW) Ọmọkùnrin àyànfẹ́ Jehofa jẹ́ “ọ̀gá oníṣẹ́” onídùnnú-ayọ̀ ní ọ̀run, ó sì ń rí inúdídùn nínú ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin náà Jesu Kristi lórí ilẹ̀-ayé. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, “nitori ìdùnnú-ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀ ó farada òpó igi oró, ó tẹ́ḿbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.”—Owe 8:30, 31, NW; Heberu 10:5-10; 12:2, NW.
2. Kí ni ó ń pinnu bóyá àwọn ọmọ Israeli yóò ní ìrírí ìbùkún tàbí ègún?
2 Àwọn ọmọ Israeli ní ìrírí ìdùnnú-ayọ̀ nígbà tí wọ́n ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí i ńkọ́? A kìlọ̀ fún wọn pé: “[Gbogbo ègún] ó sì wà lórí rẹ fún àmì àti fún ìyanu, àti lórí irú-ọmọ rẹ láéláé: Nítorí tí ìwọ kò fi ayọ̀ sin OLUWA Ọlọrun rẹ, àti inúdídùn, nítorí ọ̀pọ̀ ohun gbogbo: Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe máa sin àwọn ọ̀tá rẹ tí OLUWA yóò rán sí ọ, nínú ebi, àti nínú òùngbẹ, àti nínú ìhòhò, àti nínú àìní ohun gbogbo: òun ó sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́.” (Deuteronomi 28:45-48) Ìbùkún àti ègún fi àwọn tí wọ́n jẹ́ àti àwọn tí wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ Jehofa hàn. Irú ègún bẹ́ẹ̀ tún jẹ́rìí sí i pé kò lè sí fífi ìlànà àti ète Ọlọrun tàfàlà, bẹ́ẹ̀ ni kò lè sí kíkẹ́gàn wọn. Nítorí pé àwọn ọmọ Israeli kọ̀ láti kọbiara sí ìkìlọ̀ Jehofa níti ìsọdahoro àti ìkóninígbèkùn, Jerusalemu di “ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.” (Jeremiah 26:6) Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a máa ṣègbọràn sí Ọlọrun kí a sì gbádùn ojúrere rẹ̀. Ìdùnnúayọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ìbùkún àtọ̀runwá tí àwọn oníwà-bí-Ọlọ́run ní ìrírí rẹ̀.
Bí A Ṣe Lè Ṣiṣẹ́sìn Pẹ̀lú “Ìdùnnú-Ayọ̀ Ọkàn-Àyà”
3. Kí ni ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ jẹ́?
3 Àwọn ọmọ Israeli níláti ṣiṣẹ́sin Jehofa “pẹ̀lú yíyọ ayọ̀ ńlá àti ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní òde-òní pẹ̀lú. Láti yọ̀ túmọ̀ sí “láti ni ayọ̀-ìdùnnú; láti kún fún ìdùnnú-ayọ̀.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a mẹ́nukan ọkàn-àyà ti ara-ìyára nínú Ìwé Mímọ́, kò lè ronú tàbí wòye níti gidi. (Eksodu 28:30) Lájorí iṣẹ́ rẹ̀ ni láti máa tú ẹ̀jẹ̀ tí ń fún àwọn sẹ́ẹ̀lì ara lókun jáde. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àwọn ọ̀ràn tí ó pọ̀ jùlọ, Bibeli tọ́ka sí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ, èyí tí ó rékọjá ibùjókòó ìfẹ́ni, ìsúnniṣe, àti òye. A sọ pé ó dúró fún “apá àárín gbùngbùn ní gbogbogbòò, inú lọ́hùn-ún, nítorí náà ó sì dúró fún ọkùnrin ti inú bí ó ṣe ń fi araarẹ̀ hàn nínú gbogbo onírúurú ìgbòkègbodò rẹ̀, nínú ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ìfẹ́ni, èrò-ìmọ̀lára, ìtara-gbígbóná, ète, èrò-inú rẹ̀, ìwòye, ìronúwòye, ọgbọ́n rẹ̀, ìmọ̀, òye-iṣẹ́, èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti ìrònú rẹ̀, agbára ìrántí rẹ̀ àti ìmọ̀lára rẹ̀.” (Ìwé ìròyìn Journal of the Society of Biblical Literature and Exegesis, 1882, ojú-ìwé 67) Ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa wémọ́ ìmọ̀lára àti èrò-ìmọ̀lára, títíkan ìdùnnú-ayọ̀ wa.—Johannu 16:22.
4. Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa Ọlọrun pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà?
4 Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà? Ojú-ìwòye gbígbéṣẹ́ àti onímọrírì nípa àwọn ìbùkún àti àwọn àǹfààní tí Ọlọrun fún wa ń rannilọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, a lè fi ìdùnnú-ayọ̀ ronú lórí àǹfààní tí a ní láti ṣe “iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀” sí Ọlọrun òtítọ́. (Luku 1:74, NW) Àǹfààní tí ó tan mọ́ ọn ni ti jíjẹ́ orúkọ mọ́ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Isaiah 43:10-12) A tún lè fi ìdùnnú-ayọ̀ ti mímọ̀ pé títẹ̀lé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń mú inú rẹ̀ dùn kún un. Ẹ sì wo irú ìdùnnú-ayọ̀ tí a ń rí nínú títan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti jáde kúrò nínú òkùnkùn!—Matteu 5:14-16; fiwé 1 Peteru 2:9.
5. Kí ni orísun ìdùnnú-ayọ̀ oníwà-bí-Ọlọ́run?
5 Síbẹ̀, ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn níní ìrònú gbígbéṣẹ́. Àǹfààní ń bẹ nínú níní ojú-ìwòye gbígbéṣẹ́. Ṣùgbọ́n ìdùnnú-ayọ̀ oníwà-bí-Ọlọ́run kì í ṣe ohun kan tí a lè mú jáde nípa mímú àwọn ìwà kan dàgbà. Ó jẹ́ èso ẹ̀mí Jehofa. (Galatia 5:22, 23) Bí a kò bá ní irú ìdùnnú-ayọ̀ bẹ́ẹ̀, ó lè pọndandan fún wa láti ṣe àtúnṣebọ̀sípò láti lè yẹra fún ríronú tàbí híhùwà ní àwọn ọ̀nà kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí ó lè mú ẹ̀mí Ọlọrun bínú. (Efesu 4:30) Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a yàsọ́tọ̀ gédégbé fún Jehofa, ẹ máṣe jẹ́ kí a bẹ̀rù pé àìsí ìdùnnú-ayọ̀ àtọkànwá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹ̀rí pé a kò ní ìtẹ́wọ́gbà àtọ̀runwá. Aláìpé ni wá a sì lè ní ìmọ̀lára ìrora, ìbànújẹ́, àti ìsoríkọ́ pàápàá nígbà mìíràn, ṣùgbọ́n Jehofa lóye wa. (Orin Dafidi 103:10-14) Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ní rírántí pé Ọlọrun ní ń fúnni ní ìdùnnú-ayọ̀ tí ó jẹ́ ti èso rẹ̀. Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yóò dáhùn irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ yóò sì mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti ṣiṣẹ́sìn ín pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà.—Luku 11:13.
Nígbà Tí Kò Bá Sí Ìdùnnú-Ayọ̀
6. Bí kò bá sí ìdùnnú-ayọ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun, kí ni a níláti ṣe?
6 Bí iṣẹ́-ìsìn wa kò bá ní ìdùnnú-ayọ̀, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ a lè dẹ̀rìn nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa tàbí kí a tilẹ̀ fihàn pé a jẹ́ aláìṣòótọ́ sí i pàápàá. Nítorí ìdí èyí, yóò jẹ́ ohun tí ó bọ́gbọ́nmu láti gbé ète ìsúnniṣe wa yẹ̀wò tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ àti tàdúrà-tàdúrà kí a sì ṣe àwọn àtúnṣebọ̀sípò tí ó bá pọndandan. Láti lè ní ìdùnnú-ayọ̀ tí Ọlọrun ń fúnni, ìfẹ́ gbọ́dọ̀ sún wa láti ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, àti èrò-inú wa. (Matteu 22:37, NW) A kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú ìṣarasíhùwà abánidíje, nítorí Paulu kọ̀wé pé: “Bí awa bá wà láàyè nipa ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò nipa ẹ̀mí pẹlu. Ẹ máṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹlu ara wa lẹ́nìkínní kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nìkínní kejì.” (Galatia 5:25, 26, NW) A kì yóò ní ìdùnnú-ayọ̀ tòótọ́ bí a bá ń ṣiṣẹ́sìn nítorí pé a fẹ́ láti ta àwọn ẹlòmíràn yọ tàbí láti máa wá ògo.
7. Báwo ni a ṣe lè konámọ́ ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà wa?
7 Ìdùnnú-ayọ̀ wà nínú gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa sì Jehofa. Nígbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyàsímímọ́ sí Ọlọrun, a fi tìtara-tìtara dáwọ́lé ọ̀nà ìgbésí-ayé Kristian. A kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ a sì ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìpàdé wa déédéé. (Heberu 10:24, 25) Ó fún wa ní ìdùnnú-ayọ̀ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Síbẹ̀, bí ìdùnnú-ayọ̀ wa bá ti dínkù ńkọ́? Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé, kíkópa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́—níti tòótọ́, nínípìn-ín ní kíkún nínú gbogbo apá ẹ̀ka ìsìn Kristian—níláti fún ìgbésí-ayé wa ní ìdúródéédéé tẹ̀mí kí ó sì konámọ́ ìfẹ́ tí a ti ní lákọ̀ọ́kọ́ àti ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà wa àtẹ̀yìnwá. (Ìṣípayá 2:4) Nígbà náà a kì yóò dàbí àwọn kan tí wọn kò ní ìdùnnú-ayọ̀ tí wọ́n sì máa ń nílò ìtìlẹ́yìn tẹ̀mí nígbà gbogbo. Inú àwọn alàgbà máa ń dùn láti ṣèrànwọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan a gbọ́dọ̀ gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọrun. Kò sí ẹlòmíràn tí ó lè ṣe èyí fún wa. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a fi ṣe ìfojúsùn wa láti tẹ̀lé ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ déédéé Kristian gẹ́gẹ́ bí ìlànà kí a baà lè gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa fún Jehofa kí a sì ní ìdùnnú-ayọ̀ tòótọ́.
8. Èéṣe tí ẹ̀rí-ọkàn mímọ́gaara fi ṣe pàtàkì bí a bá fẹ́ láti jẹ́ onídùnnú-ayọ̀?
8 Bí a bá níláti ní ìdùnnú-ayọ̀ tí ó jẹ́ èso ẹ̀mí Ọlọrun, a nílò ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́ gaara. Níwọ̀n ìgbà tí Ọba Dafidi ti Israeli ṣì ń gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ìdààmú ọkàn dé bá a. Níti tòótọ́, ó dàbí ẹni pé mùdùnmúdùn ìgbésí-ayé rẹ̀ pòórá, ó sì lè ti ṣàìsàn nípa ti ara. Ẹ wo irú ìtura tí ó ní nígbà tí ìrònúpìwàdà àti ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wáyé! (Orin Dafidi 32:1-5) A kò lè ní ìdùnnú-ayọ̀ bí a bá ń fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wúwo pamọ́. Ìyẹn lè mú kí a gbé ìgbésí-ayé onídààmú. Dájúdájú, kì í ṣe ọ̀nà tí a lè gbà ní ìrírí ìdùnnú-ayọ̀ nìyẹn. Ṣùgbọ́n ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrònúpìwàdà ń mú ìtura wá ó sì ń mú kí a jèrè ẹ̀mí onídùnnú-ayọ̀ padà.—Owe 28:13.
Fífi Ìdùnnú-Ayọ̀ Dúró
9, 10. (a) Ìlérí wo ni Abrahamu rí gbà, ṣùgbọ́n ọ̀nà wo ni ó ti ṣeé ṣe kí a gbà dán ìgbàgbọ́ àti ìdùnnú-ayọ̀ rẹ̀ wò? (b) Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu?
9 Ohun kan ni láti ní ìdùnnú-ayọ̀ nígbà tí a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ète àtọ̀runwá ṣùgbọ́n ohun mìíràn ni ó jẹ́ láti máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ onídùnnú-ayọ̀ bí ọdún ti ń gorí ọdún. A lè fi ọ̀ràn ti Abrahamu olùṣòtítọ́ ṣe àkàwé èyí. Lẹ́yìn tí ó ti gbìdánwò láti fi ọmọkùnrin rẹ̀ Isaaki rúbọ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọrun, áńgẹ́lì kan jẹ́ ìhìn-iṣẹ́ yìí fún un pé: “Èmi tìkáraàmi ni mo fi búra, ni OLUWA wí, nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì dù mí ní ọmọ rẹ, ọmọ rẹ náà kanṣoṣo: Pé ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí i èmi óò mú irú-ọmọ rẹ bísíi bí ìràwọ̀ ojú-ọ̀run, àti bí iyanrìn etí òkun; irú-ọmọ rẹ ni yóò sì ni ẹnubodè àwọn ọ̀tá wọn; àti nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé: nítorí ti ìwọ ti gba ohun mi gbọ́.” (Genesisi 22:15-18) Láìsí iyèméjì, ìdùnnú-ayọ̀ Abrahamu kún àkúnwọ́sílẹ̀ nítorí ìlérí yìí.
10 Abrahamu ti lè retí pé Isaaki ni yóò jẹ́ “irú-ọmọ” náà nípasẹ̀ ẹni tí ìbùkún tí a ṣèlérí náà yóò gbà wá. Ṣùgbọ́n àwọn ọdún tí ń gorí ọdún láìsí ohunkóhun tí ó yanilẹ́nu tí a tipasẹ̀ Isaaki múṣẹ ti lè dán ìgbàgbọ́ àti ìdùnnú-ayọ̀ Abrahamu àti ìdílé rẹ̀ wò. Mímú tí Ọlọrun mú ìlérí náà dá Isaaki lójú àti lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọkùnrin rẹ̀ fi ọkàn wọn balẹ̀ pé wíwá Irú-Ọmọ náà ṣì jẹ́ ní ọjọ́-ọ̀la, èyí sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ìgbàgbọ́ àti ìdùnnú-ayọ̀ wọn mú. Bí ó ti wù kí ó rí, Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu kú láìrí ìmúṣẹ àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ aláìní ìdùnnú-ayọ̀ ti Jehofa. (Heberu 11:13) Àwa pẹ̀lú lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìdùnnú-ayọ̀ bí a ṣe ń dúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀.
Ìdùnnú-Ayọ̀ Láìka Inúnibíni Sí
11. Èéṣe tí a fi lè jẹ́ onídùnnú-ayọ̀ láìka inúnibíni sí?
11 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jehofa, a lè ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà, àní bí a bá tilẹ̀ ń jìyà inúnibíni. Jesu pe àwọn wọnnì tí a ṣe inúnibíni sí nítorí tirẹ̀ ní aláyọ̀, aposteli Peteru sì wí pé: “Ẹ máa bá a lọ lati máa yọ̀ níwọ̀n bí ẹ ti jẹ́ alájọpín ninu awọn ìjìyà Kristi, kí ẹ̀yin lè yọ̀ kí ẹ sì ní ayọ̀ púpọ̀ pẹlu nígbà ìṣípayá ògo rẹ̀. Bí a bá ń gàn yín nitori orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀, nitori pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọrun, ti bà lé yín.” (1 Peteru 4:13, 14, NW; Matteu 5:11, 12) Bí o bá ń farada inúnibíni àti ìjìyà nítorí òdodo, o ní ẹ̀mí Jehofa àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, ó sì dájú pé ìyẹn ń fikún ìdùnnú-ayọ̀ rẹ.
12. (a) Èéṣe tí a fi lè kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni a lè rí kọ́ láti inú ọ̀ràn ti ọmọ Lefi kan tí ó wà ní ìgbèkùn?
12 A lè kojú àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ nítorí pé Ọlọrun ni Ibi-Ìsádi wa. Èyí ni a mú ṣe kedere nínú Orin Dafidi 42 àti 43. Fún àwọn ìdí kan, ọmọ Lefi kan wà ní ìgbèkùn. Ó pàdánù ìjọsìn ní ibùjọsìn Ọlọrun tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi nímọ̀lára bíi àgbọ̀nrín tí òùngbẹ ń gbẹ, tàbí bí abo ìgalà, tí ń yánhànhàn fún omi ní ẹkùn ilẹ̀ gbígbẹ háúháú tí ó jẹ́ aṣálẹ̀. “Òùngbẹ” gbẹ ẹ́ ní èdè mìíràn ó yánhànhàn, fún Jehofa àti fún àǹfààní jíjọ́sìn Ọlọrun ní ibùjọ́sìn Rẹ̀. (Orin Dafidi 42:1, 2) Ìrírí ẹni tí a kó ní ìgbèkùn yìí níláti sún wa láti fi ìmọrírì hàn fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí a ń gbádùn pẹ̀lú àwọn ènìyàn Jehofa. Bí irú àwọn ipò bíi wíwà ní àhámọ́ nítorí inúnibíni bá dí wa lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn, ẹ jẹ́ kí a ronú nípa ìdùnnú-ayọ̀ wa tí a ti ní pẹ̀lú wọn rí nínú iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ kí a sì gbàdúrà fún ìfaradà bí a ṣe ń “ṣe ìrètí níti Ọlọrun” láti mú wa padà sínú ìgbòkègbodò déédéé pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn rẹ̀.—Orin Dafidi 42:4, 5, 11; 43:3-5.
“Ẹ Fi Ayọ̀ Inúdídùn Sin Jehofa”
13. Báwo ni Orin Dafidi 100:1, 2 ṣe fihàn pé ìdùnnú-ayọ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ apá ẹ̀ka kan nínú iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun?
13 Ìdùnnú-ayọ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ apá ẹ̀ka kan nínú iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun. Èyí ni a fihàn nínú orin ọpẹ́ amáratuni nínú èyí tí onipsalmu náà ti kọrin pé: “Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Jehofa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn orí ilẹ̀-ayé. Ẹ fi ayọ̀ inúdídùn sin Jehofa. Ẹ wọlé wa sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú igbe ìdùnnú-ayọ̀.” (Orin Dafidi 100:1, 2, NW) Jehofa jẹ́ “Ọlọrun aláyọ̀” ó sì fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ òun rí ìdùnnú-ayọ̀ nínú mímú ojúṣe ìyàsímímọ́ wọn sí òun ṣẹ. (1 Timoteu 1:11, NW) Gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè níláti yọ̀ nínú Jehofa, àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn wa sì gbọ́dọ̀ lágbára, gẹ́gẹ́ bí “ìhó ayọ̀” ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó ṣẹ́gunborí. Níwọ̀n bí iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun ti ń tunilára, ayọ̀ inúdídùn níláti máa bá a rìn. Nípa bẹ́ẹ̀, onipsalmu náà rọ àwọn ènìyàn láti wá sí iwájú Ọlọrun “pẹ̀lú igbe ìdùnnú-ayọ̀.”
14, 15. Báwo ni Orin Dafidi 100:3-5 ṣe bá àwọn onídùnnú-ayọ̀ ènìyàn Jehofa mu lónìí?
14 Onipsalmu náà fikún un pé: “Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ [mọ̀ dájú ṣáká, mọ̀ ní àmọ̀jẹ́wọ́] pé Oluwa, òun ni Ọlọrun: òun ni ó dá wa, tirẹ̀ ni àwa; àwa ni ènìyàn rẹ̀, àti àgùtàn pápá rẹ̀.” (Orin Dafidi 100:3) Níwọ̀n bí Jehofa ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa, òun ni ó ni wá gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn ti í ni àwọn àgùtàn rẹ̀. Lọ́nà kan náà ni Ọlọrun gbà ń bójútó wa kí a lè fi pẹ̀lú ọpẹ́ kókìkí yìn ín. (Orin Dafidi 23) Onipsalmu náà tún kọrin nípa Jehofa pé: “Ẹ lọ si ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ọpẹ́, àti sí àgbàlá rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ìyìn: ẹ máa dúpẹ́ fún un, kí ẹ sì máa fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀. Nítorí tí Oluwa pọ̀ ní oore; àánú rẹ̀ kò nípẹ̀kun; àti òtítọ́ rẹ láti ìrandíran.”—Orin Dafidi 100:4, 5.
15 Lónìí, àwọn ènìyàn onídùnnú-ayọ̀ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè ń wọnú àgbàlá ibùjọsìn Jehofa láti fi ọpẹ́ àti ìyìn fún un. A ń fi tìdùnnú-ayọ̀ tìdùnnú-ayọ̀ yin orúkọ Ọlọrun nípa sísọ̀rọ̀ rere nípa Jehofa nígbà gbogbo, àwọn ànímọ́ rẹ̀ títayọ sì ń sún wa láti yìn ín. Òun jẹ́ rere látòkèdélẹ̀, ìṣeun-ìfẹ́ tàbí ìkàsí oníyọ̀ọ́nú tí ó ní fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ohun tí wọ́n lè máa gbáralé nígbà gbogbo, nítorí tí ó ń bá a nìṣó títí ayérayé. Láti “ìrandíran,” Jehofa jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Romu 8:38, 39) Nígbà náà, ó dájú pé a ní ìdí rere láti “fi ayọ̀ inúdídùn sin Jehofa.”
Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí Yín
16. Nínú ìrètí àti ìfojúsọ́nà wo ni àwọn Kristian ti lè máa yọ̀?
16 Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máa yọ̀ ninu ìrètí.” (Romu 12:12, NW) Àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi yọ̀ nínú ìrètí ológo ti ìwàláàyè àìleèkú lókè ọ̀run tí Ọlọrun ti ṣí sílẹ̀ fún wọn nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀. (Romu 8:16, 17; Filippi 3:20, 21) Àwọn Kristian tí wọ́n ní ìrètí ìyè ayérayé nínú Paradise orí ilẹ̀-ayé ní ìdí ìpìlẹ̀ fún yíyọ̀ pẹ̀lú. (Luku 23:43) Gbogbo àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jehofa ní ìdí láti yọ̀ nínú ìrètí Ìjọba náà, nítorí pé wọn yóò jẹ́ yálà apákan àkóso ti ọ̀run yẹn tàbí kí wọ́n gbé nínú pápá àkóso rẹ̀ ti orí ilẹ̀-ayé. Ẹ wo ìbùkún onídùnnú-ayọ̀ tí èyí jẹ́!—Matteu 6:9, 10; Romu 8:18-21.
17, 18. (a) Kí ni a sọtẹ́lẹ̀ ní Isaiah 25:6-8? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah ṣe ń ní ìmúṣẹ nísinsìnyí, kí sì ni nípa ti ìmúṣẹ rẹ̀ ní ọjọ́-ọ̀la?
17 Isaiah pẹ̀lú sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la onídùnnú-ayọ̀ fún aráyé onígbọràn. Ó kọ̀wé pé: “Àti ní òkè-ńlá yìí ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun yóò se àsè ohun àbọ́pa fún gbogbo orílẹ̀-èdè, àsè ọtí-wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti ohun àbọ́pa tí ó kún [fún] ọ̀rá, àti ọtí-wáìnì tí ó tòrò lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀. Ní òkè-ńlá yìí òun ó sì pa ìbòjú tí ó bo gbogbo ènìyàn lójú run, àti ìbòjú tí a nà bo gbogbo orílẹ̀-èdè, òun ó gbé ikú mì láéláé; Oluwa Jehofa yóò nu omijé nù kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn; yóò sì mú ẹ̀gàn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ayé: nítorí tí Oluwa ti wí i.”—Isaiah 25:6-8.
18 Níti gidi àsè tẹ̀mí tí a ń nípìn-ín nínú rẹ̀ lónìí gẹ́gẹ́ bí olùjọ́sìn Jehofa jẹ́ àsè-ńlá onídùnnú-ayọ̀. Níti tòótọ́, ìdùnnú-ayọ̀ wa ń kún àkúnwọ́sílẹ̀ bí a ṣe ń fi tìtara-tìtara ṣiṣẹ́sin Ọlọrun ní ìfojúsọ́nà fún àsè-ńlá ti àwọn ohun rere tí wọ́n jẹ́ gidi tí óun ti ṣèlérí fún ayé titun náà. (2 Peteru 3:13) Lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jesu, Jehofa yóò ká “ìbòjú” tí ń bo aráyé lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Adamu kúrò. Ẹ wo irú ìdùnnú-ayọ̀ tí yóò jẹ́ nígbà tí a bá rí i pé ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni a ti mú kúrò! Ẹ wo irú ìdùnnú tí yóò jẹ́ láti kí àwọn olólùfẹ́ wa tí a jíǹde káàbọ̀, láti kíyèsíi pé omijé ti pòórá, àti láti gbé nínú paradise orí ilẹ̀-ayé, níbi tí a kì yóò ti gan àwọn ènìyàn Jehofa ṣùgbọ́n tí wọn yóò ti pèsè ìdáhùn tí Ọlọrun yóò fún olùganni ńlá náà, Satani Èṣù!—Owe 27:11.
19. Báwo ni a ṣe níláti hùwàpadà sí ìfojúsọ́nà tí Jehofa ti gbékalẹ̀ sí iwájú wa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀?
19 Inú rẹ kò ha kún fún ìdùnnú-ayọ̀ àti ìmoore láti mọ ohun tí Jehofa yóò ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? Níti gidi, irú ìfojúsọ́nà títóbilọ́lá bẹ́ẹ̀ ń fikún ìdùnnú-ayọ̀ wa! Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìrètí wa tí ń pèsè ìtẹ́lọ́rùn ń mú kí a máa wo Ọlọrun wa aláyọ̀, onífẹ̀ẹ́, ọlọ́làwọ́ pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára bí ìwọ̀nyí: “Wò ó, Ọlọrun wa ni èyí; àwa ti dúró dè é, òun ó sì gbà wá là: Oluwa ni èyí: àwa ti dúró dé é, àwa ó máa yọ̀, inú wa ó sì máa dùn nínú ìgbàlà rẹ.” (Isaiah 25:9) Pẹ̀lú jíjẹ́ kí ìrètí gbígbámúṣé wa fẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin nínú ọkàn wa, ẹ jẹ́ kí a fi tokunratokunra darí gbogbo ìsapá síhà ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?
◻ Báwo ni a ṣe lè ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú “ìdùnnú-ayọ̀ ọkàn-àyà”?
◻ Kí ni a lè ṣe bí kò bá sí ìdùnnú-ayọ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun?
◻ Èéṣe tí àwọn ènìyàn Jehofa fi lè ní ìdùnnú-ayọ̀ láìka inúnibíni sí?
◻ Àwọn ìdí wo ni a ní láti máa yọ̀ nínú ìrètí wa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Nínípìn-ín nínú gbogbo apá ẹ̀ka ìgbésí-ayé Kristian yóò mú kí ìdùnnú-ayọ̀ wa pọ̀ síi