“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
“Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 JÒHÁNÙ 4:8.
1-3. (a) Gbólóhùn wo ni Bíbélì sọ nípa ànímọ́ Jèhófà náà ìfẹ́, ọ̀nà wo sì ni gbólóhùn náà gbà jẹ́ àrà ọ̀tọ̀? (b) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́”?
GBOGBO ànímọ́ Jèhófà ló pegedé, ló jẹ́ pípé, ló sì fani mọ́ra. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló fani mọ́ra jù lọ nínú gbogbo àwọn ànímọ́ Jèhófà. Kò sí ànímọ́ mìíràn tó tún lè fà wá sún mọ́ Jèhófà bí ìfẹ́. Inú wa sì dùn pé ìfẹ́ ló tún gbawájú lára àwọn ànímọ́ rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
2 Bíbélì sọ nǹkan kan nípa ìfẹ́, èyí tí kò sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn lájorí ànímọ́ Jèhófà yòókù. Ìwé Mímọ́ ò sọ pé Ọlọ́run jẹ́ agbára tàbí pé Ọlọ́run jẹ́ ìdájọ́ òdodo, kódà kò sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ọgbọ́n. Ó ní ànímọ́ wọ̀nyẹn ni, òun sì ni orísun ànímọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Àmọ́, a sọ ohun kan tó jẹ́ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ nínú 1 Jòhánù 4:8, èyíinì ni pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Ìfẹ́ ni Jèhófà jẹ́ tinú tòde tàbí nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Lákòótán, a lè wo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà báyìí: Agbára Jèhófà ń jẹ́ kó lè ṣe ohun tó bá fẹ́. Ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n rẹ̀ ń darí ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ Jèhófà ló ń sún un láti ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe. Ìgbà gbogbo sì ni ìfẹ́ rẹ̀ yìí máa ń hàn nínú ọ̀nà tó gbà ń lo àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù.
3 A sábà máa ń sọ pé Jèhófà gan-an ni afi-gbogbo-ara-ṣe-ìfẹ́. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà ìfẹ́ Jèhófà tí ò láfiwé.
Ọ̀nà Tó Ga Jù Lọ Tó Gbà Fi Ìfẹ́ Hàn
4, 5. (a) Kí ni ọ̀nà gíga jù lọ tá a gbà fìfẹ́ hàn láyé lọ́run? (b) Èé ṣe tá a fi lè sọ pé ìdè ìfẹ́ tó lágbára jù lọ láyé lọ́run ló wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀?
4 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni Jèhófà ti gbà fi ìfẹ́ hàn, ṣùgbọ́n ọ̀nà kan wà tó ta yọ gbogbo ọ̀nà yòókù. Kí ni ọ̀nà yẹn? Òun ni rírán tó rán Ọmọ rẹ̀ láti wá jìyà kó sì kú fún wa. A tiẹ̀ lè fọwọ́ ẹ̀ sọ̀yà pé ọ̀nà tó ga jù lọ láti gbà fìfẹ́ hàn láyé lọ́run nìyẹn. Kí nìdí tá a fi lè sọ bẹ́ẹ̀?
5 Bíbélì pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Sáà rò ó wò ná, àní Ọmọ Jèhófà ti wà kí ayé òun ìsálú ọ̀run tó wà. Báwo ló wá ti pẹ́ tó tí Bàbá àti Ọmọ rẹ̀ yìí ti jọ wà? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan fojú bù ú pé á ti tó bílíọ̀nù mẹ́tàlá ọdún tí ayé òun ìsálú ọ̀run ti wà. Ká tiẹ̀ sọ pé iye tí wọ́n fojú bù yìí tọ̀nà, kò lè gùn tó ọdún gbọ́nhan tí Ọmọ Jèhófà ti wà! Iṣẹ́ wo ló ń ṣe ní gbogbo àkókò yẹn? Ńṣe ni Ọmọ ń sin Bàbá rẹ̀ tayọ̀tayọ̀ gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30; Jòhánù 1:3) Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jọ pawọ́ pọ̀ ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan yòókù. Ẹ wo àkókò alárinrin, tó kún fún ayọ̀ tí wọ́n gbádùn pa pọ̀! Nígbà náà, ta lẹni náà nínú wa, tó lè sọ bí ìdè àárín wọ́n ṣe lágbára tó ní gbogbo ọdún gbọ́nhan tí wọ́n ti jọ wà? Ní kedere, ìdè ìfẹ́ tó lágbára jù lọ láyé lọ́run ló wà láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.
6. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, kí ni Jèhófà sọ tó fi bí inú rẹ̀ ṣe dùn sí Ọmọ rẹ̀ tó hàn?
6 Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sílé ayé, kí a lè bí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọwọ́ tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ní pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ní ọ̀run du ara rẹ̀. Tọkàntara ni Ó ń wo Jésù látọ̀run, bó ṣe ń dàgbà di ọkùnrin pípé. Jésù ṣèrìbọmi nígbà tó pé ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún. Bàbá fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run lọ́jọ́ náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Ẹ sáà wo bí inú Bàbá Jésù á ti dùn tó nígbà tó rí i pé tọkàntọkàn ni Jésù ṣe gbogbo ohun tá a sọ tẹ́lẹ̀ àti gbogbo ohun tá a ní kó ṣe!—Jòhánù 5:36; 17:4.
7, 8. (a) Kí ni nǹkan tójú Jésù rí lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, báwo ló sì ṣe rí lára Baba rẹ̀ ọ̀run? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ jìyà, kí ó sì kú?
7 Àmọ́ o, báwo lọ̀ràn ṣe wá rí lára Jèhófà lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nígbà tí wọ́n da Jésù, táwọn èèyànkéèyàn sì mú un? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń fi Jésù ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń tutọ́ sí i lára, tí wọ́n ń gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń nà án lọ́rẹ́, tí ọrẹ́ náà sì dá egbò sí i lẹ́yìn yánnayànna? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń fi ìṣó kan ọwọ́ àtẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́ òpó igi, táwọn èèyàn sì ń kẹ́gàn rẹ̀ bó ṣe wà lórí igi oró? Báwo ló ṣe rí lára Bàbá nígbà tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ké lóhùn rara sí i nínú ìrora gógó? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Jésù mí èémí ìkẹyìn, tó wá di pé fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọmọ Rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣaláìsí?—Mátíù 26:14-16, 46, 47, 56, 59, 67; 27:26, 38-44, 46; Jòhánù 19:1.
8 Níwọ̀n bí Jèhófà ti máa ń mọ nǹkan lára, ìrora rẹ̀ nígbà tí Ọmọ rẹ̀ kú yóò ré kọjá ohun tí ọmọ aráyé lè fẹnu sọ. Kìkì ohun tá a lè ṣàlàyé ni ohun tó fà á tí Jèhófà fi gbà kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀. Kí nìdí tí Baba fi fi ara rẹ̀ sínú irú ipò ìrora bẹ́ẹ̀? Jèhófà ṣí ohun ìyanu kan payá fún wa nínú Jòhánù 3:16. Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn kan fi pè é ní àkópọ̀ Ìhìn Rere. Ó kà pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Nítorí náà ohun tó sún Ọlọ́run láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni: ìfẹ́. Ẹnikẹ́ni ò tíì fi ìfẹ́ tó ju ìyẹn lọ hàn rí.
Bí Jèhófà Ṣe Mú Un Dá Wa Lójú Pé Òun Nífẹ̀ẹ́ Wa
9. Èrò wo ni Sátánì fẹ́ ká ní nípa ojú tí Jèhófà fi ń wò wá, àmọ́ kí ni Jèhófà mú kó dá wa lójú?
9 Àmọ́ ìbéèrè pàtàkì kan rèé: Ǹjẹ́ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Àwọn kan lè gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ aráyé lápapọ̀, bí Jòhánù 3:16, ti wí. Àmọ́, wọ́n máa ń rò ó pé: ‘Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ èmi yìí láéláé.’ Ohun tí Sátánì kúkú ń fẹ́ nìyẹn, ká máa lérò pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bó ti wù ká lérò pé a kì í ṣe èèyàn gidi tó, pé Jèhófà ò sì lè nífẹ̀ẹ́ wa, ó fi yé wa yékéyéké pé òun ka gbogbo ìránṣẹ́ òun lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sí.
10, 11. Báwo ni àpèjúwe Jésù nípa ológoṣẹ́ ṣe fi hàn pé a níye lórí lójú Jèhófà?
10 Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 10:29-31. Nígbà tí Jésù ń ṣàpèjúwe bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe níye lórí tó, ó ní: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí létí àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò.
11 Nígbà ayé Jésù, ológoṣẹ́ ni ẹyẹ olówó pọ́ọ́kú jù lọ táwọn èèyàn ń rà fún jíjẹ. Èèyàn lè fi ẹyọ owó kan ṣoṣo tí ìníyelórí rẹ̀ kéré ra ológoṣẹ́ méjì. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Lúùkù 12:6, 7 ṣe wí, Jésù sọ lẹ́yìn náà pé béèyàn bá ní ẹyọ owó méjì lọ́wọ́ tó fẹ́ fi ra ológoṣẹ́, kì í ṣe ológoṣẹ́ mẹ́rin ni wọ́n máa tà fún un, bí kò ṣe márùn-ún. Ṣe ló dà bíi pé ọ̀kan tí wọ́n fi ṣe èènì yẹn ò níye lórí rárá. Àwọn ẹyẹ yẹn lè máà níye lórí lójú èèyàn, àmọ́ ojú wo ni Ẹlẹ́dàá fi ń wò wọ́n? Jésù sọ pé: “Kò sí ọ̀kan nínú wọn [àtèyí tí wọ́n fi ṣe èènì pàápàá] tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run.” Òye ohun tí Jésù sọ lè wá bẹ̀rẹ̀ sí yé wa wàyí. Bí ẹyẹ ológoṣẹ́ kan ṣoṣo bá níye lórí tó bẹ́ẹ̀ lójú Jèhófà, ẹ̀dá ènìyàn á mà níye lórí gan-an lójú rẹ̀ o! Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, Jèhófà mọ̀ wá látòkèdélẹ̀. Kódà, ó mọ iye irun tó wà lórí wa pàápàá!
12. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jésù mọ ohun tó ń sọ nígbà tó sọ pé Ọlọ́run mọ iye irun orí wa?
12 Àwọn kan lè máa rò pé àsọdùn ni Jésù ń sọ níbí yìí. Họ́wù, jẹ́ ká tibi ìrètí àjíǹde wò ó. Wo bí Jèhófà ṣe gbọ́dọ̀ mọ̀ wá dunjú-dunjú tó kó tó lè tún wa dá! A níye lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ lójú rẹ̀ débi pé ó rántí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa wa, títí kan àwọn èròjà tó pilẹ̀ àbùdá wa àti gbogbo ohun tó wà nínú iyè wa àti gbogbo ìrírí wa látọjọ́ tá a ti dáyé. Mímọ iye irun orí wa, tó jẹ́ pé ìpíndọ́gba tó wà lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ń jẹ́ nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000], kò lè jẹ́ nǹkan bàbàrà ní ìfiwéra pẹ̀lú iṣẹ́ ìyanu àjíǹde. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ Jésù mú un dá wa lójú kedere pé Jèhófà bìkítà nípa wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan!
13. Báwo ni ọ̀ràn Jèhóṣáfátì Ọba ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń rí iṣẹ́ rere wa bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá aláìpé ni wá?
13 Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun mìíràn tó mú un dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa: Ó ń wo àwọn ànímọ́ rere tá a ní, ojú ribiribi ló sì fi ń wò wọ́n. Gbé àpẹẹrẹ Jèhóṣáfátì Ọba rere yẹ̀ wò. Nígbà tí ọba yẹn hu ìwà òmùgọ̀ kan, wòlíì Jèhófà sọ fún un pé: “Nítorí èyí, ìkannú wà sí ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” Ọ̀ràn ńlá rèé o! Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà kò parí síbẹ̀ yẹn. Ọ̀rọ̀ náà ń bá a lọ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a rí àwọn ohun rere pẹ̀lú rẹ.” (2 Kíróníkà 19:1-3) Nítorí náà, ìbínú títọ́ tí Jèhófà fi hàn kò sọ pé kó máà rí “àwọn ohun rere” kan nínú Jèhóṣáfátì. Ǹjẹ́ kò fini lọ́kàn balẹ̀ láti mọ̀ pé rere tá a ṣe ni Ọlọ́run ń wò bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá aláìpé ni wá?
Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”
14. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ẹrù wíwọnilọ́rùn wo ni èyí lè dì rù wá, àmọ́ báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú ìdáríjì Jèhófà?
14 Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ìjákulẹ̀, ìtìjú àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tá a máa ń nímọ̀lára rẹ̀ lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé a ò lè tóótun láti jọ́sìn Jèhófà mọ́ láé. Àmọ́ o, rántí pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Dájúdájú, tá a bá ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tá a sì sapá láti má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, a lè jàǹfààní nínú ìdáríjì Jèhófà. Ṣàyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé apá fífanimọ́ra yìí nínú ìfẹ́ Jèhófà.
15. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa tó?
15 Dáfídì onísáàmù náà lo gbólóhùn kan tó fakíki láti ṣàlàyé ìdáríjì Jèhófà. Ó sọ pé: “Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; Orin Dafidi 103:12, Bibeli Mimọ) Báwo ni ìlà oòrùn ṣe jìnnà tó sí ìwọ̀ oòrùn? Ìlà oòrùn ni ibi tá a gbà pé ó jìnnà jù lọ sí ìwọ̀ oòrùn; ìhà méjèèjì ò lè bára pàdé láé. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé gbólóhùn yìí túmọ̀ sí “ibi tí nǹkan lè jìnnà dé; ibi jíjìnnà jù lọ.” Ọ̀rọ̀ onímìísí tí Dáfídì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Jèhófà bá dárí jì wá, ó máa ń kó ẹ̀ṣẹ̀ wa lọ sí ibi tó jìnnà jù lọ sí wa.
16. Èé ṣe tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà kà wá sí ẹni tó mọ́ tónítóní lẹ́yìn tó bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá?
16 Ǹjẹ́ o tíì gbìyànjú láti mú àbààwọ́n kúrò lára aṣọ aláwọ̀ títàn yòò rí? Bóyá gbogbo bó o ṣe fọ̀ ọ́ tó, àbààwọ́n náà ò parẹ́. Ẹ wá jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ṣàpèjúwe bí ìdáríjini rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì; bí wọ́n tilẹ̀ pupa bí aṣọ pípọ́ndòdò, wọn yóò dà bí irun àgùntàn gẹ́lẹ́.” (Aísáyà 1:18) Ọ̀rọ̀ náà “rírẹ̀dòdò” jẹ́ àwọ̀ tó pupa yòò.a Àwọ̀ “pípọ́ndòdò” jẹ́ ọ̀kan lára àwọ̀ pupa tí wọ́n fi ń pa aṣọ láró. Bó ṣe wù ká sapá tó, a ò lè fúnra wa mú àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Ṣùgbọ́n Jèhófà lè mú ẹ̀ṣẹ̀ tó pupa bí aṣọ rírẹ̀dòdò, tàbí èyí tó pọ́n dòdò, kí ó sọ ọ́ di funfun gbòò bí ìrì dídì tàbí bí irun àgùntàn tí a kò tíì pa láró. Nítorí náà, tí Jèhófà bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kò sídìí fún rírò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.
17. Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà ń ju ẹ̀ṣẹ̀ wa sẹ́yìn ara rẹ̀?
17 Nínú orin wíwúni lórí kan tí Hesekáyà fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lẹ́yìn tó mú kó bọ́ nínú àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí kan, ó sọ fún Jèhófà pé: “O ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.” (Aísáyà 38:17) Ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé Jèhófà mú ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan tó ti ronú pìwà dà, ó sì jù ú sẹ́yìn Rẹ̀, níbi tí Òun ò ti ní rí i tàbí kó rántí rẹ̀ mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan ti wí, èrò tí ibí yìí gbé yọ ni pé: “O ti jẹ́ kí [ẹ̀ṣẹ̀ mi] dà bí èyí tí kò tilẹ̀ wáyé rí rárá.” Ǹjẹ́ èyí kò tuni nínú?
18. Báwo ni wòlíì Míkà ṣe fi hàn pé nígbà tí Jèhófà bá dárí jì wá, ńṣe ni Ó máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá?
18 Nínú ìlérí kan tó jẹ́ ìlérí ìmúbọ̀sípò, wòlíì Míkà sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó dá a lójú pé Jèhófà yóò dárí ji àwọn èèyàn rẹ̀ tó ronú pìwà dà, ó ní: “Ta ni Ọlọ́run bí ìwọ, . . . tí ó . . . ń ré ìṣìnà àṣẹ́kù ogún rẹ̀ kọjá? . . . Ìwọ yóò sì sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sínú ibú òkun.” (Míkà 7:18, 19) Sáà ronú ohun tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn máa túmọ̀ sí létí àwọn tó ń gbé ayé nígbà tá a kọ Bíbélì. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti rí ohun tá a sọ “sínú ibú òkun” yọ? Fún ìdí yìí, ọ̀rọ̀ Míkà fi hàn pé nígbà tí Jèhófà bá dárí jì wá, ńṣe ló máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá.
“Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run Wa”
19, 20. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù tá a túmọ̀ sí “fi àánú hàn sí” tàbí “ṣe ojú àánú sí”? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe lo ìyọ́nú tí ìyá máa ń ní sí ọmọ rẹ̀ jòjòló láti jẹ́ ká lóye ìyọ́nú Jèhófà?
19 Ìyọ́nú tún jẹ́ apá mìíràn nínú ìfẹ́ Jèhófà. Kí ni ìyọ́nú? Nínú Bíbélì, ìyọ́nú àti àánú kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Àwọn ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan ni wọ́n ń lò láti ṣàlàyé ìyọ́nú lédè Hébérù àti Gíríìkì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sábà máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà ra·chamʹ, sí “fi àánú hàn sí” tàbí “ṣe ojú àánú sí.” Ọ̀rọ̀ Hébérù yìí, tí Jèhófà lò fún ara rẹ̀, tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ilé ọlẹ̀.” A sì tún lè pè é ní “ìyọ́nú tí ìyá ní.”
20 Bíbélì lo ìyọ́nú tí ìyá máa ń ní fún ọmọ rẹ̀ jòjòló láti jẹ́ ká lóye ìyọ́nú Jèhófà. Aísáyà 49:15 kà pé: “Obirin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu [ra·chamʹ] si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ.” (Bibeli Mimọ) Kò ṣeé gbọ́ sétí pé abiyamọ kan sọ pé òun gbàgbé àtifún ọmọ òun lóúnjẹ àti ìtọ́jú. Ó ṣe tán, ìkókó kò lè dá nǹkan kan ṣe; tọ̀sántòru ni ọmọ ọwọ́ ń fẹ́ ìtọ́jú ìyá rẹ̀. Ó kàn ṣeni láàánú ni, pé àwọn ìyá kan ti ń pa ọmọ inú wọn tì, àgàgà ní “àwọn àkókò lílekoko” yìí. (2 Tímótì 3:1, 3) Àmọ́ Jèhófà sọ pé, “ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ.” Ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà ní fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀ gidigidi ju ìkẹ́ àti ìgẹ̀ jíjinlẹ̀ lọ tá a lè ronú kàn, ìyẹn ìyọ́nú tí abiyamọ máa ń ní sí ọmọ rẹ̀ jòjòló.
21, 22. Kí ni ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ní Íjíbítì ìgbàanì, kí sì ni Jèhófà ṣe nípa igbe ẹkún wọn?
21 Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi ìyọ́nú hàn, bíi ti òbí onífẹ̀ẹ́? Ànímọ́ yìí hàn kedere nínú ọwọ́ tó fi mú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì. Nígbà tó fi máa di apá ìparí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà lóko ẹrú ní Íjíbítì, níbi tí wọ́n ti ń fìyà pá wọn lórí. (Ẹ́kísódù 1:11, 14) Nígbà tí ìyà ọ̀hún wá pọ̀ jù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà. Kí ni Ọlọ́run oníyọ̀ọ́nú wá ṣe?
22 Àánú ṣe Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn . . . mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.” (Ẹ́kísódù 3:7) Jèhófà kò lè rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ tàbí kí ó gbọ́ igbe ẹkún wọn láìmọ̀ ọ́n lára. Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Gẹ́gẹ́ bá a sì ti mọ̀, ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ni mímọ ẹ̀dùn ọkàn àwọn ẹlòmíràn lára, tí í ṣe ànímọ́ tó tan mọ́ ìyọ́nú. Àmọ́ kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe pé Jèhófà mọ ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ lára nìkan ni; ó gbé ìgbésẹ̀ fún ire wọn. Aísáyà 63:9 sọ pé: “Nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti nínú ìyọ́nú rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ tún wọn rà.” Ó wá fi “ọwọ́ líle” dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì. (Diutarónómì 4:34) Lẹ́yìn ìyẹn ló pèsè oúnjẹ fún wọn lọ́nà ìyanu, tó sì mú wọn dé ilẹ̀ wọn ọlọ́ràá.
23. (a) Báwo làwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù ṣe mú un dá wa lójú pé Jèhófà kò fi ọ̀ràn kálukú wa ṣeré rárá? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ràn wá lọ́wọ́?
23 Kì í kàn án ṣe pé Jèhófà ń fi ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ nìkan ni. Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ kò fi ọ̀ràn kálukú wa ṣeré rárá. Ó ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ wá. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́. Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:15, 18) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran olúkúlùkù wa lọ́wọ́? Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń mú ohun tó ń fa ìjìyà wa kúrò. Ṣùgbọ́n ó ti ṣètò ohun púpọ̀ fáwọn tó ń ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń fún wa ní ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó lè ṣèrànwọ́. Nínú ìjọ, ó fún wa ní àwọn alábòójútó tó tóótun nípa tẹ̀mí, tí ń sapá láti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú bíi tirẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. (Jákọ́bù 5:14, 15) Gẹ́gẹ́ bí “Olùgbọ́ àdúrà,” Jèhófà ń “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 65:2; Lúùkù 11:13) Gbogbo irú ìpèsè wọ̀nyí jẹ́ ara ẹ̀rí “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run wa.”—Lúùkù 1:78.
24. Kí lo máa ṣe nípa ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí ọ?
24 Ǹjẹ́ kò múni lọ́kàn yọ̀ láti ronú nípa ìfẹ́ Bàbá wa ọ̀run? Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a rán wa létí pé Jèhófà ti lo agbára, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n rẹ̀ lọ́nà onífẹ̀ẹ́ tó máa ṣe wá láǹfààní. A sì ti rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí pé Jèhófà ti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí ẹ̀dá èèyàn lápapọ̀—àti sí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan—láwọn ọ̀nà tó ga lọ́lá. Ní báyìí, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa béèrè pé, ‘Kí ni mo máa ṣe nípa ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí mi yìí?’ Ǹjẹ́ kí ìwọ náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ, pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ. (Máàkù 12:29, 30) Ǹjẹ́ kí ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ lójoojúmọ́ fi hàn pé ó wù ẹ́ tọkàntọkàn láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ǹjẹ́ kí Jèhófà, tí í ṣe Ọlọ́run ìfẹ́, máa sún mọ́ ọ títí ayé!—Jákọ́bù 4:8.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé àwọ̀ rírẹ̀dòdò “jẹ́ àwọ̀ tí kì í ṣí tàbí tí kì í bó. Ìrì tàbí òjò tàbí fífọ̀ tàbí lílò pàápàá kò lè mú un kúrò.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo la ṣe mọ̀ pé ìfẹ́ ló gbawájú nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà?
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé rírán tí Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti jìyà kí ó sì kú nítorí wa jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ tó ga jù lọ láyé lọ́run?
• Báwo ni Jèhófà ṣe mú un dá wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìdáríjì Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
“Ọlọ́run . . . fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
“Ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ”
[Credit Line]
© J. Heidecker/VIREO
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọ̀nà tí ìyá máa ń gbà tọ́jú ọmọ rẹ̀ jòjòló lè jẹ́ ká lóye ìyọ́nú Jèhófà