Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dárí Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Jáì Jini?
ÀÁNÚ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ pàtàkì tí Ọlọ́run ní. (Sáàmù 86:15) Báwo ni àánú Ọlọ́run ṣe rìn jìnnà tó? Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù ròyìn pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.” (Sáàmù 130:3, 4) Apá ibòmíì nínú Sáàmù tún kà pé: “Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa. Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.”—Sáàmù 103:12-14.
Ìwọ̀nyí mú kó ṣe kedere pé àánú Jèhófà máa ń mú kó dárí jini pátápátá láìkù síbì kan, torí pé ó mọ ibi tí agbára wá mọ, ó mọ̀ pé aláìpé ni wá, “ekuru” lásán. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò látinú Bíbélì tó jẹ́ ká rí bí àánú Ọlọ́run ṣe rìn jìnnà tó.
Ìgbà mẹ́ta ni àpọ́sítélì Pétérù sẹ́ Kristi. (Máàkù 14:66-72) Kó tó di pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù di onígbàgbọ́, ó ṣenúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Nígbà tí wọ́n sì fẹ́ pa àwọn kan lára wọn, Pọ́ọ̀lù ò róhun tó burú níbẹ̀. Kódà, ó fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa ọ̀kan lára wọn. (Ìṣe 8:1, 3; 9:1, 2, 11; 26:10, 11; Gálátíà 1:13) Kí àwọn kan tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì tó di Kristẹni, wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀mùtípara, alọ́nilọ́wọ́gbà àti olè. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Síbẹ̀, gbogbo wọn padà wá rí ojú rere Ọlọ́run. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dárí jì wọ́n?
Ọ̀nà Mẹ́ta Téèyàn Fi Lè Rí Àánú Ọlọ́run Gbà
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A fi àánú hàn sí mi, nítorí tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan, tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ nínú àìnígbàgbọ́.” (1 Tímótì 1:13) Bí kò ṣe fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa ara rẹ̀ yìí ló mú wa dórí ọ̀nà àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run fi lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ìyẹn ni pé ká dẹ́kun jíjẹ́ aláìmọ̀kan nípa àwọn ọ̀nà Ọlọ́run, ká sì gba ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. (2 Tímótì 3:16, 17) Ó ṣe tán, kò sí bá a ṣe lè ṣe ohun tó dùn mọ́ Ẹlẹ́dàá wa bá ò bá mọ̀ ọ́n dáadáa. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Báwọn olóòótọ́ ọkàn bá gba ìmọ̀ yẹn, wọ́n máa ń kábàámọ̀ àwọn ohun búburú tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, wọ́n sì máa ń ronú pìwà dà látọkàn wá. Ìyẹn ni ọ̀nà kejì tá a lè gbà rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìṣe 3:19 sọ pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.”
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn tún mẹ́nu kan ọ̀nà kẹta, ìyẹn sì ni pé ká yí padà. Kéèyàn yí padà túmọ̀ sí pé kó kọ ọ̀nà tó ti ń gbà gbé ìgbé ayé ẹ̀ àti ìwà tó ti ń hù tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run, kó sì máa fojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan wò wọ́n. (Ìṣe 26:20) Ní kúkúrú ṣá, ó gbọ́dọ̀ hàn nínú ọ̀nà téèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbà gbé ìgbé ayé ẹ̀ pé, kì í ṣe orí ahọ́n lásán lòún fi ń sọ pé, “Mo tọrọ àforíjì.”
Ọlọ́run Kì Í Dárí Gbogbo Ẹ̀ṣẹ̀ Jini
Àwọn èèyàn kan wà tí Ọlọ́run kì í dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, bí kò ṣe ìfojúsọ́nà fún ìdájọ́ [ẹ̀bi].” (Hébérù 10:26, 27) Gbólóhùn náà, “mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà” mú kó dà bíi pé ẹnì kan ti di ajìhànrín tí kò fẹ́ fi ẹ̀ṣẹ̀ dídá sílẹ̀, èyí tó já sí pé ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ burú jáì.
Irú ọkàn tí Júdásì Ísíkáríótù ní gan-an nìyẹn. Jésù sọ pé: “Ì bá ti sàn fún un ká ní a kò bí ọkùnrin yẹn.” (Mátíù 26:24, 25) Nígbà tí Jésù sì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn olórí ìsìn kan nígbà tó wà láyé, ó sọ pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá . . . Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Bíi ti Sátánì, àwọn èèyàn wọ̀nyẹn burú débi gẹ́ẹ́. Wọn ò kábàámọ̀ rárá, ṣe ni wọ́n wulẹ̀ ń jingíri sínú ìwà búburú wọn.a Òótọ́ ni pé nítorí àìpé àti àìlera ẹ̀dá, àwọn tó jẹ́ ojúlówó Kristẹni pàápàá lè dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nígbà míì. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ìwà ibi ti jọba sí wọn lọ́kàn.—Gálátíà 6:1.
Ó Jẹ́ Aláàánú Títí Dójú Ikú
Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan bá dá nìkan ni Jèhófà máa ń kíyè sí, ó tún máa ń kíyè sí ìṣarasíhùwà ẹni tó dẹ́ṣẹ̀. (Aísáyà 1:16-19) Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn aṣebi méjì tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì Jésù. Ó dájú pé àwọn méjèèjì ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, torí ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Ohun tí ó tọ́ sí wa ni àwa ń gbà ní kíkún nítorí àwọn ohun tí a ṣe; ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí [Jésù] kò ṣe ohun kan tí kò tọ̀nà.” Ọ̀rọ̀ tí aṣebi yẹn sọ fi hàn pé ó mọ ohun kan nípa Jésù. Ó sì ṣeé ṣe kí ohun tó mọ̀ yẹn wà lára ohun tó ràn án lọ́wọ́ tí ọ̀nà tó gbà sọ̀rọ̀ nípa Jésù fi yàtọ̀. Ìyẹn sì fara hàn nínú ẹ̀bẹ̀ tó bẹ Jésù pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Kí ni Kristi sọ sí ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá tí aṣebi náà bẹ̀ ẹ́? Ó dáhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:41-43.
Ẹ ò rí i pé ohun tó kọyọyọ gbáà ni pé lára ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ gbẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn ni pé òun á fi àánú hàn sí ọkùnrin kan tó gbà pé ikú tọ́ sí òun. Ìṣírí ńlá gbáà mà nìyẹn jẹ́ o! Ó yẹ kó dá wa lójú nígbà náà pé Jésù Kristi àti Baba rẹ̀, Jèhófà, máa fi àánú hàn sí gbogbo àwọn tó bá ronú pìwà dà látọkàn wá láìka ohun yòówù tí wọn ì báà ti ṣe nígbà kan rí sí.—Róòmù 4:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ǹjẹ́ O Rò Pé O Ti Ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́?” tó wà lójú ìwé 16 sí 20 nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2007.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Àlàyé wo lo lè ṣe nípa àánú Ọlọ́run?—Sáàmù 103:12-14; 130:3, 4.
◼ Àwọn ọ̀nà wo lèèyàn lè gbà rí ojúure Ọlọ́run?—Jòhánù 17:3; Ìṣe 3:19.
◼ Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún ọ̀kan lára àwọn aṣebi tí wọ́n kàn mọ́ ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀?—Lúùkù 23:43.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jésù fi hàn pé Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì jini