Ori 3
Iṣakoso “Ọmọ-Aládé Alaafia” Laaarin Awọn Ọta
1, 2. (a) Awọn ọ̀rọ̀ idagbere wo ni Jesu Kristi sọ fun awujọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ kan? (b) Eyi ha beere fun iyilọkanpada agbaye ṣaaju ki oun tó lè ṣakoso gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia” bi?
KETE ṣaaju ìgòkè re ọ̀run rẹ̀ ní eyi ti ó ju ọrundun 19 sẹhin, “Ọmọ-Aládé Alaafia” ẹhin-ọla ní ìgbà naa, Jesu Kristi, sọ awọn ọ̀rọ̀ idagbere wọnyi fun awujọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ oluṣotitọ: “Nitori naa ẹ lọ ki ẹ si sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa baptisi wọn ní orukọ Baba ati ní ti Ọmọkunrin ati ti ẹmi mímọ́ . . . Ẹ si wo o! emi wà pẹlu yin ní gbogbo ọjọ titi de ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.”—Matteu 28:19, 20, NW.
2 Awọn ọ̀rọ̀ Jesu wọnyẹn ha beere fun iyilọkanpada agbaye ṣaaju “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” ti ó bẹrẹ ní 1914 bi? O tì o. Lonii, nitosi ipari ọrundun ogun yii, ayé araye ṣi jinna si didi eyi ti a ti yilọkanpada sọdọ Jesu Kristi gẹgẹ bi Olugbala ati Ọba rẹ̀ ti ó tọna. Bi o ti wu ki o ri, eyi kò dá ṣiṣe aṣepari ohun ti Jehofa sọtẹlẹ ninu awọn asọtẹlẹ inu Bibeli duro. Kò figbakanri jẹ́ ète Ọlọrun pe ki gbogbo ayé araye di eyi ti a yilọkanpada ṣaaju ki Jesu Kristi tó bẹrẹsii ṣakoso gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia.” Ní odikeji ní taarata, a sọtẹlẹ ṣaaju nipa rẹ̀ pe yoo bẹrẹsii ṣakoso laaarin awọn ọta rẹ̀.
3. Bawo ni itọkasi ti Jesu ṣe si Orin Dafidi 110 ṣe fihan pe oun yoo jọba laaarin awọn ọta?
3 Ani nigba ti ó wà nisalẹ lori ilẹ̀-ayé nihin-in paapaa, Jesu Kristi mọ otitọ yii. Kete ṣaaju iku rẹ̀ gẹgẹ bi ajẹriiku kan, o ní ariyanjiyan kan pẹlu awọn onisin alatako rẹ̀ o si tọka si Orin Dafidi 110. A ka nipa eyi ninu Luku 20:41-44 (NW): “Ẹ̀wẹ̀ o wi fun wọn pe: ‘Bawo ni o ti jẹ́ ti wọn fi wi pe ọmọkunrin Dafidi ni Kristi? Nitori Dafidi funraarẹ wi ninu iwe Orin Dafidi pe, “Jehofa wi fun Oluwa mi, Jokoo ní ọwọ ọtun mi titi ti emi yoo fi gbe awọn ọta rẹ kalẹ gẹgẹ bi apoti itisẹ fun ẹsẹ rẹ.” Nitori naa, Dafidi pe e ní “Oluwa”; nitori naa bawo ni o ṣe lè jẹ́ ọmọkunrin rẹ̀?’”
4-6. (a) Bawo ni Orin Dafidi 2 bẹẹ gẹgẹ ṣe fihan pe Jesu ki yoo nilati duro de iyilọkanpada agbaye ṣaaju bibẹrẹ iṣakoso rẹ̀ gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia”? (b) Nigba wo ni Orin Dafidi 2:7 ní imuṣẹ?
4 O ṣe kedere, nigba naa pe, Jesu Kristi, gẹgẹ bi Ọmọkunrin Dafidi, ni ki yoo bẹrẹ iṣakoso rẹ̀ lẹhin iyilọkanpada agbaye. Kakabẹẹ, oun yoo bẹrẹsii ṣakoso laaarin awọn ọta rẹ̀ awọn ẹni ti Jehofa Ọlọrun nipasẹ ogun jija yoo sọ di apoti itisẹ ní asẹhinwa-asẹhinbọ fun ẹsẹ Ọmọkunrin rẹ̀ ti a ti gbeka ori itẹ. Bẹẹ gẹgẹ Orin Dafidi 2 (NW), ninu awọn ọ̀rọ̀ ti wọn tẹ̀lé e wọnyi, fi ibẹrẹ iṣakoso rẹ̀ gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia” laaarin awọn ọta han:
5 “Eeṣe ti awọn orilẹ-ede fi wà ninu ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ti awọn awujọ orilẹ-ede funraawọn si ń baa lọ́ ní sisọrọ nǹkan ofifo ní kẹlẹkẹlẹ? Awọn ọba ilẹ̀-ayé mu iduro wọn awọn ijoye oṣiṣẹ giga funraawọn si ti kojọpọ gẹgẹ bi ọkanṣoṣo lodisi Jehofa ati lodisi ẹni ami-ororo rẹ̀ [Kristi rẹ̀], ní wiwi pe: ‘Ẹ jẹ́ ki a já awọn ìdè wọn sọtọọtọ ki a si ju awọn okun wọn nù kuro lọdọ wa!’ Ẹni naa gan-an ti ó jokoo ninu awọn ọ̀run yoo rẹrin-in; Jehofa fúnraarẹ̀ yoo fi wọn ṣẹsin. Ní akoko naa oun yoo sọrọ si wọn ninu ibinu rẹ̀ oun yoo si yọ wọn lẹnu ninu ibinu rẹ̀, ní wiwi pe: ‘Emi, ani emi, ti fi ọba mi sori oyè lori Sioni, oke-nla mímọ́ mi.’
6 “Jẹ ki emi tọkasi aṣẹ Jehofa; o ti sọ fun mi [Kristi] pe: ‘Iwọ ni ọmọkunrin mi; lonii ni mo di baba rẹ. [Orin Dafidi 2:7 ní a muṣẹ nigba ti Jehofa ji Ọmọkunrin rẹ̀ dide kuro ninu oku, ti ó si tipa bẹẹ di Baba ayeraye fun Jesu. (Romu 1:4)] Beere lọwọ mi, ki emi baa lè fi awọn orilẹ-ede fun ọ gẹgẹ bi ogún ati awọn opin ilẹ̀-ayé gẹgẹ bi nǹkan ìní tirẹ. Iwọ yoo fi ọpa-alade irin fọ́ wọn tuutuu, iwọ yoo si fọ́ wọn yanga si wẹ́wẹ́ bi ẹni pe wọn jẹ́ ohun-eelo amọkoko.’ Ati nisinsinyi, oo ẹyin ọba, ẹ lo ijinlẹ-oye; ẹ jẹ́ ki a tọ́ yin sọna, oo ẹyin onidaajọ ilẹ̀-ayé. Ẹ ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu ibẹru ki ẹ si fi ìwárìrì kun fun ayọ̀. Ẹ fi ẹnu ko ọmọkunrin naa lẹnu, ki ẹ ma baa ru ibinu Rẹ̀ soke ki ẹ ma si ṣe ṣegbe kuro ní oju ọna, nitori ibinu rẹ̀ maa ń fi tirọrun-tirọrun faru. Alayọ ni gbogbo awọn wọnni ti wọn ń wá isadi lọdọ rẹ̀.”
7. Itọka wo si Orin Dafidi 2 ni awọn aposteli Jesu Kristi ṣe lẹhin ọjọ Pentekosti?
7 Gẹgẹ bi Iṣe 4:24-27 (NW) ti wi, awọn aposteli Jesu Kristi tọkasi Orin Dafidi 2 yii lẹhin ọjọ Pentekosti, 33 C.E.: “Pẹlu iṣọkan wọn gbe ohun wọn soke si Ọlọrun wọn si wi pe: ‘Oluwa Ọba-alaṣẹ, iwọ ni Ẹni naa ti ó ṣẹ̀dá ọ̀run ati ilẹ̀-ayé ati okun ati gbogbo ohun ti ń bẹ ninu wọn, ati ẹni ti o tipasẹ ẹmi mímọ́ wi lati ẹnu Dafidi babanla wa, iranṣẹ rẹ pe, “Eeṣe ti awọn orilẹ-ede fi ń rọ́kẹ̀kẹ̀ ti awọn eniyan si ń ṣàṣàrò lori awọn ohun asan? Awọn ọba ilẹ̀-ayé mu iduro wọn awọn oluṣakoso si kojọpọ gẹgẹ bi ọkan lodisi Jehofa ati ẹni ami-ororo rẹ̀.” Ani bẹẹ gẹgẹ, ati Herodu ati Pontiu Pilatu pẹlu awọn eniyan awọn orilẹ-ede ati pẹlu awọn eniyan Israeli ni wọn kojọpọ nitootọ ninu ilu-nla yii lodisi Jesu iranṣẹ mímọ́ rẹ, ẹni ti iwọ fororo yàn.’”
Imuṣẹ Titobiju Ti Orin Dafidi 2
8. (a) Nigba wo ni imuṣẹ akọkọ ti Orin Dafidi 2:1, 2 ṣẹlẹ? (b) Lati igba wo ni imuṣẹ titobiju ti Orin Dafidi 2 ti ń ṣẹlẹ?
8 Ni ọdun 33 ti ọrundun kìn-ín-ní ni awọn ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ wọnyẹn ti Orin Dafidi 2:1, 2 kọ́kọ́ ní imuṣẹ. Eyi jẹ́ ní isopọ pẹlu ọkunrin naa Jesu Kristi lori ilẹ̀-ayé. Oun ni a ti fororo yàn pẹlu ẹmi mímọ́ Jehofa ní akoko baptisi rẹ̀ nipasẹ Johannu Arinibọmi. Ṣugbọn imuṣẹ titobiju ti Orin Dafidi 2 ti ń ṣẹlẹ lati igba opin Akoko Awọn Keferi ní ọdun 1914. (Luku 21:24) A ti jẹrii sii lẹkun-unrẹrẹ pe “akoko awọn Keferi,” eyi ti ó bẹrẹ nigba iparun akọkọ ti ilu Jerusalemu ní 607 B.C.E., dopin ní ọdun 1914.a Nigba naa ni agogo iku ró fun awọn orilẹ-ede agbaye, titikan awọn ti Kristẹndọm.
9. Ki ni ṣẹlẹ nigba iparun akọkọ Jerusalemu ní isopọ pẹlu Ijọba Ọlọrun eyi ti ìlà ọlọba ti Ọba Dafidi ṣoju fun?
9 Nigba iparun akọkọ Jerusalemu, lati ọwọ́ awọn ara Babiloni, Ijọba Jehofa Ọlọrun lori orilẹ-ede Israeli, eyi ti ìlà ọlọba ti Ọba Dafidi ń ṣoju fun, wá sí ipari. Lati igba naa wa, awọn Ju abinibi kò tii ní ọba kankan lori wọn lati ìlà ile ọlọba ti Dafidi. Ṣugbọn Ijọba Ọlọrun Ọga Ogo ní ọwọ́ atọmọdọmọ Dafidi kan, ẹni ti Jehofa bá dá majẹmu kan fun Ijọba ainipẹkun ní ìlà rẹ̀, kì yoo wà bẹẹ laigberi mọ́ lori ilẹ̀-ayé titi lae.
10, 11. (a) Ki ni Ọlọrun sọ nipasẹ wolii rẹ̀ Esekieli ní isopọ pẹlu itẹ Dafidi? (b) Ta ni ó wá sori itẹ Dafidi pẹlu “ẹ̀tọ́ ofin”? (c) Ki ni ogunlọgọ awọn Ju sọ nigba ti o fi araarẹ̀ han gẹgẹ bi ajogun lọna ofin?
10 Kete ṣaaju iparun rẹ̀ akọkọ, Jehofa mu ki wolii rẹ̀ Esekieli dari awọn ọ̀rọ̀ wọnyi si ọba Jerusalemu igbaani pe: “Ati iwọ, aláìlọwọ̀ ẹni buburu ọmọ-alade Israeli, ẹni ti ọjọ rẹ̀ de, nigba aiṣedeede ikẹhin. Bayii ni Oluwa Ọlọrun wi; Mu fìlà ọba kuro, sì ṣí ade kuro: eyi kò ni jẹ́ ọkan naa; gbe ẹni ti ó rẹlẹ ga, sì rẹ ẹni ti ó ga silẹ. Emi o bì ṣubu, emi o bì ṣubu, emi o bì í ṣubu, ki yoo sì sí mọ́, titi igba ti ẹni ti ó [ni ẹ̀tọ́ ofin si i, NW] bá de; emi o si fi fun un.”—Esekieli 21:25-27.
11 Ẹni naa ti ó ní “ẹ̀tọ́ ofin si i” wá oun sì ni Jesu Kristi, ìlà atirandiran rẹ̀ lati ọdọ Dafidi ni a sì kọ silẹ ninu Matteu 1:1-16 ati Luku 3:23-31. Oun ni a saba maa ń pe ní “Ọmọ Dafidi.” Ní ọjọ igun kẹtẹkẹtẹ alayọ iṣẹgun rẹ̀ wọnu Jerusalemu, ti ó gun ori kẹtẹkẹtẹ ní imuṣẹ asọtẹlẹ, ogunlọgọ awọn Ju ti wọn ń yọ ayọ̀ aṣeyọri ti wọn ń bá oun ati awọn aposteli rẹ̀ rin lọ́ kejade pẹlu ìhó ayọ̀ pe: “Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun ni ẹni ti o ń bọ̀ wá ní orukọ Oluwa; Hosanna loke ọ̀run.”—Matteu 21:9.
A Gbé “Ọmọ Dafidi” Ka Ori Itẹ Ní Ọrun
12. Nigba ti Akoko Awọn Keferi dopin ní 1914, nibo ni a ti gbé Jesu Kristi ka ori itẹ, gẹgẹ bi ajogun Dafidi wíwà titilọ?
12 Ọdun 2,520 naa fun awọn Keferi lati maa tẹ Ijọba Ọlọrun ti ó wa ní ọwọ́ idile Dafidi mọlẹ labẹ atẹlẹsẹ wọn dopin ní 1914. Nigba naa ní akoko dé fun Jesu Kristi, “Ọmọ Dafidi,” lati di ẹni ti a gbé ka ori itẹ, kii ṣe nisalẹ nihin-in lori itẹ ti ilẹ̀-ayé, ṣugbọn ninu awọn ọ̀run gigajulọ ní ọwọ́ ọtun Jehofa Ọlọrun!—Danieli 7:9, 10, 13, 14.
13. (a) Lati ọdun wo ni a ti tọka ṣaaju si ọdun 1914 gẹgẹ bi opin Akoko Awọn Keferi, nipasẹ ta sì ni? (b) Ki ni iṣarasihuwa awọn orilẹ-ede ilẹ̀-ayé si “Ọmọ Dafidi” ti a ṣẹṣẹ gbeka ori itẹ yii?
13 Ọdun manigbagbe yẹn ni awọn wọnni ti wọn di alabaakẹgbẹpọ Watch Tower Bible and Tract Society ti tọkasi ṣaaju lati 1876 wá. Ṣugbọn awọn orilẹ-ede ilẹ̀-ayé, ati awọn wọnni ti wọn jẹ́ ti Kristẹndọm paapaa, kọ̀ lati gba a gẹgẹ bi akoko fun wọn lati fi awọn ipo ọba-alaṣẹ wọn ti ilẹ̀-ayé fun “Ọmọ Dafidi” ti a ṣẹṣẹ gbeka ori itẹ. Wọn kò gbà pe oun ní ẹtọ ti Ọlọrun fifun un si ipo ọba-alaṣẹ lori gbogbo ilẹ̀-ayé, eyi ti ó jẹ́ apoti itisẹ Jehofa Ọlọrun. (Matteu 5:35) Wọn fami sọ fífi ti wọn fi ọdaju pa Ọba titọna naa tì nipa kikowọnu ogun agbaye kìn-ín-ní.
14. (a) Pẹlu ibẹsilẹ Ogun Agbaye I, iṣarasihuwa wo ni awọn orilẹ-ede fihan si awọn Kristian ti wọn jẹ alabaakẹgbẹpọ Watch Tower Society? (b) Loju-iwoye eyi, ki ni ipo kárí-ayé tumọsi?
14 Ninu gbogbo awọn orilẹ-ede ti wọn ń jagun naa, awọn Kristian oluṣeyasimimọ ti wọn jẹ alabaakẹgbẹpọ Watch Tower Society wá sabẹ ikimọlẹ pipabambari lati pa igberopinnu wọn lati takete kuro ninu ẹbi-ẹjẹ tì. Ohun ti a beere fun aidasitọtuntosi Kristian ni wọn kò tii loye de iwọn kikunrẹrẹ julọ nigba naa. Asọtẹlẹ “Ọmọ Dafidi,” Jesu Kristi, fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nipa “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” jasi otitọ ní ọna ti ó kun fun irora pe: “A o si koriira yin lọdọ gbogbo orilẹ-ede nitori orukọ mi.” (Matteu 24:9) Ikoriira naa kò tii rọlẹ lati igba Ogun Agbaye I. Loju-iwoye awọn otitọ ti ó kun fun itumọ wọnyi ti itan ode-oni, ki ni ipo kárí-ayé tumọsi? Eyi: “Ọmọ-Aládé Alaafia” ń ṣakoso laaarin awọn ọta ti wọn wà nihin-in gan-an lori ilẹ̀-ayé!
15. Ki ni o ṣẹlẹ si Satani Eṣu ati agbo ẹgbaagbeje ẹmi eṣu rẹ̀ nigba ti ogun jija bẹsilẹ ní ọ̀run, ní ọdun wo si ní o nilati jẹ pe a ti ṣe abajade naa ní aṣepari?
15 Ọlọrun Olodumare mu ki a bí Ijọba Messia naa ti a ṣeleri ní akoko ti oun yankalẹ laika gbogbo awọn ọta ti wọn wà larọọwọto ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé sí. Ìfihàn 12:1-9 fihan pe lẹhin ibi Ijọba ‘akọ ọmọ’ yii ninu awọn ọ̀run lati inu ilé-ọlẹ̀ ètò-àjọ Jehofa ti ó dabi aya fun un, gẹgẹ bi a ti lè sọ pe o jẹ́, ogun jija bẹsilẹ ní kánmọ́ ní ọ̀run fúnraarẹ̀. Awọn ọ̀run mímọ́ naa kii tun ṣe ibi àyè mọ́ fun dragoni iṣapẹẹrẹ naa, Satani Eṣu, ati awọn angẹli ẹmi eṣu rẹ̀. Ninu ogun jija yii, ti oju eniyan ko rí, “Ọmọ Dafidi” naa ti a ti fi agbara ọba fun, ja ajaṣẹgun o si lé Satani Eṣu ati agbo ẹgbaagbeje ẹmi eṣu rẹ̀ jade kuro ninu awọn ọ̀run o si se wọn mọ́ sàkáání obirikiti ilẹ̀-ayé wa. Irẹniposilẹ agbo ọmọ-ogun Satani yii ni o han gbangba pe a ti ṣaṣepari rẹ̀ ní ẹkunrẹrẹ ní 1918, ọdun naa ti Ogun Agbaye I wá sí opin.
Ní Rírẹ̀ Ẹ́ Nipo Silẹ, Eṣu Gbogun Dide
16, 17. (a) Ta ni Satani Eṣu ti a rẹ̀ nipo silẹ naa gbé ogun jija dide si? (b) Ta ni oun ń lò lati maa ba ogun jija yii niṣo?
16 Satani Eṣu ti a rẹ̀ nipo silẹ naa, dragoni iṣapẹẹrẹ naa, ń binu niti gidi nisinsinyi si ètò-àjọ ti ó dabi aya fun Jehofa Ọlọrun. (Ìfihàn 12:17) Nipa bayii oun ń fi tìkorò-tìkorò gbé ogun jija dide si àṣẹ́kù awọn Kristian oluṣeyasimimọ ti a fi ẹmi bi ti wọn ní ẹri pe o jẹ́ iya wọn nipa tẹmi.—Galatia 4:26.
17 Satani tun ń gbogun dide si “awọn agutan miiran” naa, ti wọn ń fi tigbọran-tigbọran ṣiṣẹ pẹlu àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo ní jijẹ ẹri si ìbí Ijọba naa. (Johannu 10:16) Kii ṣe kiki agbo ọmọ-ogun ẹmi eṣu rẹ̀ ti a rẹ̀ nipo silẹ, ti wọn ń bẹ ní sàkáání ilẹ̀-ayé nisinsinyi, ni oun ń lò, ṣugbọn o tun ń lo apa ti ó ṣee fojuri ninu ètò-àjọ rẹ̀ lati maa bá ogun jija yii niṣo lodisi àṣẹ́kù naa ati “awọn agutan miiran.”
18. (a) Bi o tilẹ jẹ pe Eṣu ń fi tìkorò-tìkorò gbé ogun dide si àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo ati awọn alabaakẹgbẹpọ wọn, agbo oludaaboboni wo ni wọn ní? (b) Apa wo ninu iṣakoso “Ọmọ-Aládé Alaafia” ní ń sunmọ opin rẹ̀?
18 Iṣakoso “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa laaarin awọn ọta rẹ̀ nisalẹ nihin-in lori ilẹ̀-ayé ń sunmọ opin rẹ̀. Oun ti bojuto ipo naa lọna titayọlọla. Tọ̀sántòru ni awọn angẹli rẹ̀ aduroṣinṣin wà ní sẹpẹ́, wọn muratan lati gba aṣẹ ọba lati ọdọ rẹ̀ ki wọn si ṣiṣẹ lé wọn lori pẹlu iyarakankan. Wọn ṣiṣẹsin gẹgẹ bi agbo oludaaboboni fun àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo naa ati awọn alabaakẹgbẹpọ wọn, “ogunlọgọ nla” naa ti “awọn agutan miiran,” bi awọn wọnyi ti ń baa lọ lati ṣiṣẹsin fun awọn ire Ijọba naa nigba akoko ti ń yara dinku yii ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ń ṣakoso laaarin awọn ọta rẹ̀.—Ìfihàn 7:9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun kulẹkulẹ, wo iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, oju-iwe 138 si 141, ti a tẹ̀ jade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.