Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Jọ Yin Jèhófà
“Ẹ yin Jáà!”—SM. 111:1.
1, 2. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “Halelúyà,” báwo ni wọ́n sì ṣe lò ó nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì?
A SÁBÀ máa ń gbọ́ táwọn èèyàn máa ń ké “Halelúyà!” nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn kan tiẹ̀ wà tí wọn ò lè sọ̀rọ̀ kí “Halelúyà” má wọ inú rẹ̀. Àmọ́, àwọn èèyàn díẹ̀ ló mọ ohun ọ̀wọ̀ tí ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí, ìgbé ayé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ké Halelúyà yìí sì ń tàbùkù sí Ọlọ́run. (Títu 1:16) Nígbà tí ìwé kan tó ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ń ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, ó ní: “Halelúyà jẹ́ ọ̀rọ̀ kan táwọn tó kọ onírúurú ìwé inú Sáàmù fi ń ké sí gbogbo èèyàn pé káwọn jọ yin Jèhófà.” Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé ìtumọ̀ “Halelúyà” ni “‘Ẹ yin Jáà,’ [ìyẹn] Jèhófà.”
2 Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, bá a ṣe túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí nínú Sáàmù 111:1 ni: “Ẹ yin Jáà!” Ọ̀rọ̀ yìí náà fara hàn lọ́nà mẹ́rin nínú Ìṣípayá 19:1-6 lọ́nà tí wọ́n gbà ń sọ ọ́ lédè Gíríìkì, ńṣe ni wọ́n sì lò ó láti fi ṣàjọyọ̀ òpin ìsìn èké. Nígbà tí òpin ìsìn èké yìí bá sì dé, àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ yóò ní ìdí pàtàkì láti fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ké “Halelúyà.”
Àwọn Iṣẹ́ Àrà Rẹ̀
3. Kí ni olórí ìdí tá a fi ń pé jọ déédéé?
3 Ẹni tó kọ Sáàmù 111 sọ ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa jọ yin Jèhófà. Ẹsẹ kìíní sọ pé: “Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé Jèhófà lárugẹ nínú àwùjọ tímọ́tímọ́ ti àwọn adúróṣánṣán àti ti àpéjọ.” Bó ṣe sọ yìí náà ló ṣe rí lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí. Olórí ìdí tá a fi ń pé jọ déédéé láwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ wa ni láti yin Jèhófà.
4. Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà ń wá iṣẹ́ Jèhófà kiri?
4 “Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tóbi, wíwá kiri ni wọ́n jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ó ní inú dídùn sí wọn.” (Sm. 111:2) Kíyè sí gbólóhùn náà “wíwá kiri.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ó lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó ń fi “tọkàntara ṣèwádìí tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lórí” iṣẹ́ Ọlọ́run ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà fi hàn pé ìdí pàtàkì wà tí Jèhófà fi dá wọn. Ó dá oòrùn, ayé àti òṣùpá sí ọ̀gangan ibi tó yẹ kí wọ́n wà kí ayé wa yìí bàa lè máa rí ooru àti ìmọ́lẹ̀ tó nílò, àti pé kí ọ̀sán àti òru lè wà, kí ìgbà àti àkókò lè máa yí pa dà, kí omi òkun lè máa wá sókè kó sì máa lọ sílẹ̀.
5. Ẹ̀rí kí làwọn èèyàn rí bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń lóye ayé àtàwọn ohun tó wà lójú sánmà?
5 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí ohun tó pọ̀ gan-an nípa ọ̀gangan ibi tí ayé wà láàárín àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó yí oòrùn ká. Wọ́n sì tún rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nípa òṣùpá, ìyẹn bó ṣe ń lọ yí po ayé, bó ṣe tóbi níwọ̀n tó yẹ tí kò sì wúwo ju bó ṣe yẹ lọ. Bí oòrùn, òṣùpá àtàwọn nǹkan yòókù ṣe tò sójú ọ̀run àti bí gbogbo wọn ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ló ń jẹ́ kí ìgbà àti àkókò máa yí pa dà déédéé ní ayé. A tún ti rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe ṣètò agbára òòfà àtàwọn agbára míì tó gbé ilé ayé àtàwọn nǹkan tó wà lójú sánmà ró, tí wọ́n fi gún régé tí gbogbo nǹkan sì fi ń lọ déédéé. Ìdí nìyẹn tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ẹ̀rọ fi sọ ohun tó sọ nínú àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa ayé àtọ̀run tá a gbé kalẹ̀ lọ́nà tó gún régé, ó ní: “Kò ṣòro láti rí ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fi ń yí èrò wọn pa dà láti bí ọgbọ̀n ọdún báyìí, tí wọ́n wá ń gbà pé kìkì àwọn tó bá ń gba èrò èèyàn gbọ́ láìrí ẹ̀rí, ló máa fara mọ́ ọn pé ńṣe ni ayé àtọ̀run kàn dédé wà láìsí ẹni tó dá wọn. Bá a ṣe túbọ̀ ń lóye ayé wa tí a dìídì ṣètò tá a sì gbé kalẹ̀ lọ́nà tó fi ṣeé gbé fún ẹ̀dá alààyè, la túbọ̀ ń rí ẹ̀rí púpọ̀ sí i pé afinúṣọgbọ́n oníṣẹ́ àrà kan wà tó ṣe gbogbo nǹkan.”
6. Kí lèrò rẹ nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá èèyàn?
6 Nǹkan àrà míì lára iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Ọlọ́run ni ọ̀nà tó gbà dá wa. (Sm. 139:14) Nígbà tó ń dá àwa èèyàn, ó dá ọpọlọ tá a ó fi lè máa ronú mọ́ wa, ó dá gbogbo ẹ̀yà ara tá a nílò sínú ara wa, ó sì fún wa ní agbára tá ó máa fi ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ ìyanu ni ohùn tí Ọlọ́run fún wa tá a fi ń lè sọ̀rọ̀, etí tó fún wa tá a fi ń lè gbọ́ràn, ọwọ́ tó fún wa tá a fi lè kọ̀wé àti ojú tó fún wa tá a fi lè kà á. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì máa ń ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí. Àgbàyanu tún ni bó ṣe dá ọ ní ẹ̀dá tó lè dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ. Àní sẹ́, ìyanu gbáà ni bó o ṣe ń dìde dúró, tó ò ń rìn lórí ẹsẹ̀ méjì tó o tún ń ṣiṣẹ́ síbẹ̀ náà tó ò ṣubú, àti ọ̀nà tí àwọn èròjà inú ara rẹ gbà ń ṣiṣẹ́ tí oúnjẹ fi ń dà tó sì ń fún ọ ní agbára. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀nà àrà ni Ọlọ́run gbà to àwọn fọ́nrán àti iṣan inú ara rẹ, tí wọ́n fi so kọ́ra lọ́nà tó ń jẹ́ kó o lè máa fi ọpọlọ rẹ ronú, kó o sì máa mọ nǹkan lára. Gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ lèyí fi ju gbogbo ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tíì gbé ṣe lọ. Kódà, ohun tó ń jẹ́ káwọn èèyàn lè ṣe ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ń gbé ṣe ni pé Ẹlẹ́dàá dá wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tó lè fi ọpọlọ ronú, tó sì lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Kódà onímọ̀ ẹ̀rọ tó kẹ́kọ̀ọ́ jù lọ tó sì mọṣẹ́ jù lọ kò lè ṣe ohun tó rẹwà tó sì máa wúlò tó irin iṣẹ́ tí Ẹlẹ́dàá ti dá mọ́ ọ láti máa fi ṣiṣẹ́, ìyẹn ìka ọwọ́ rẹ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá, pàápàá àwọn àtàǹpàkò rẹ. Wá bi ara rẹ ní ìbéèrè yìí: ‘Tí kì í bá ṣe tàwọn ìka ọwọ́ tí Ọlọ́run dá fún wa, ǹjẹ́ àwa ọmọ èèyàn á lè máa ṣe àwọn iṣẹ́ ọnà aláràbarà, ṣé a ó sì lè máa ṣe àwọn ẹ̀rọ ńláńlá ká sì máa kọ́ ilé aláràbarà?’
Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run Àtàwọn Iṣẹ́ Àrà Rẹ̀ Míì
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká ka Bíbélì sí ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run?
7 Àwọn nǹkan àgbàyanu míì wà tí Jèhófà ṣe fún aráyé, tí Bíbélì fi hàn pé ó wà lára àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀. Iṣẹ́ àrà gan-an tiẹ̀ ni Bíbélì fúnra rẹ̀ torí kò sí ìwé míì tó dà bíi rẹ̀, pàápàá bó ṣe jẹ́ ìwé tó ṣọ̀kan látòkèdélẹ̀. Ká sòótọ́, òun nìkan ni ìwé tí “Ọlọ́run mí sí,” tó sì “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni.” (2 Tím. 3:16) Bí àpẹẹrẹ, ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ìyẹn Jẹ́nẹ́sísì, sọ bí Ọlọ́run ṣe mú ìwà ibi kúrò láyé nígbà ayé Nóà. Ẹ́kísódù, ìwé kejì sọ bí Jèhófà ṣe fi ẹ̀rí hàn pé òun nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́, nípa bó ṣe kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú àwọn ará Íjíbítì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ni onísáàmù náà rántí tó mú kó sọ pé: “Ìgbòkègbodò [Jèhófà] jẹ́ iyì àti ọlá ńlá pàápàá, òdodo rẹ̀ sì dúró títí láé. Ó ti ṣe ìrántí fún àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀. Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú.” (Sm. 111:3, 4) Ṣé ìwọ náà ò gbà pé gbogbo iṣẹ́ Jèhófà tó o ti gbọ́ ìtàn wọn àtàwọn èyí tó ti ṣe látìgbà tí wọ́n ti bí ọ jẹ́ ohun tó ń ránni létí “iyì àti ọlá ńlá” rẹ̀?
8, 9. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni iṣẹ́ Ọlọ́run gbà yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ èèyàn? (b) Mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tó wù ọ́.
8 Kíyè sí i pé onísáàmù náà tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó fani mọ́ra, irú bí òdodo, oore ọ̀fẹ́ àti àánú. Ìwọ náà mọ̀ pé ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì í sábà fi òdodo ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Wọ̀bìà, owú àti ìgbéraga ló sábà máa ń wà nídìí ohun tí wọ́n ń ṣe. Ẹ̀rí èyí hàn nínú àwọn ohun ìjà olóró táwọn èèyàn ń ṣe láti fi ja àwọn ogun tí wọ́n ń dá sílẹ̀ àti láti fi pawó. Èyí sì ń kó ọ̀kẹ́ àìmọye ẹni ẹlẹ́ni sínú ìyà òun ìṣẹ́ àti ìbẹ̀rùbojo. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ohun táwọn èèyàn ti gbé ṣe ló jẹ́ pé àwọn aláìní tí wọ́n ń tẹ̀ lórí ba ni wọ́n ń lò nílòkulò láti fi ṣe wọ́n. Àpẹẹrẹ irú rẹ̀ kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa ni àwọn ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ táwọn ará Íjíbítì àtijọ́ máa ń lo àwọn ẹrú wọn láti kọ́. Kò sí nǹkan gidi kan tí wọ́n sì fàwọn ilé ọ̀hún ṣe ju ibojì àwọn Fáráò agbéraga lọ. Yàtọ̀ sí pé ohun táwọn èèyàn ń gbé ṣe lóde òní ń mú ìnira bá àwọn ẹni ẹlẹ́ni, wọ́n tún ń fi àwọn iṣẹ́ náà “run ilẹ̀ ayé.”—Ka Ìṣípayá 11:18.
9 Iṣẹ́ Jèhófà, tó máa ń dá lórí ohun tó tọ́, mà yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo ìwọ̀nyẹn o! Ara iṣẹ́ rẹ̀ ni bó ṣe ṣàánú àwa aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ tó sì ṣètò ìgbàlà fún wa. Pípèsè tí Ọlọ́run sì pèsè ẹbọ ìràpadà tó ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wa yìí, ń ‘fi òdodo rẹ̀ hàn.’ (Róòmù 3:25, 26) Láìsí àní-àní, ‘òdodo rẹ̀ dúró títí láé’! Oore ọ̀fẹ́ rẹ̀ sì hàn nínú bó ṣe ń fi sùúrù bá àwọn èèyàn ẹlẹ́sẹ̀ lò. Àní nígbà míì, ó máa ń lo gbólóhùn náà “jọ̀wọ́” nígbà tó bá ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò lọ́nà ibi tó máa kó wọn sí wàhálà, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó tọ́.—Ka Ìsíkíẹ́lì 18:25.
Jèhófà Máa Ń Pa Ìlérí Rẹ̀ Mọ́
10. Báwo ni ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀ràn májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá ṣe fi hàn pé ó máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
10 “Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni òun yóò máa rántí májẹ̀mú rẹ̀.” (Sm. 111:5) Ó dà bíi pé májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá ni onísáàmù náà ń tọ́ka sí níbí yìí. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún irú ọmọ Ábúráhámù, ó sì sọ pé wọn yóò gba ẹnubodè àwọn ọ̀tá wọn. (Jẹ́n. 22:17, 18; Sm. 105:8, 9) Nígbà tí ìlérí yìí kọ́kọ́ ṣẹ, àwọn irú ọmọ Ábúráhámù yìí di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sìnrú nílẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ nígbà tó yá, “Ọlọ́run . . . rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù,” ó sì dá wọn nídè. (Ẹ́kís. 2:24) Ọ̀nà tí Jèhófà sì gbà bá wọn lò lẹ́yìn ìgbà náà fi hàn pé ó jẹ́ oníbú ọrẹ. Ó ń pèsè oúnjẹ tara fún wọn kí wọ́n lè máa wà láàyè, bákan náà ló tún ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wọn kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. (Diu. 6:1-3; 8:4; Neh. 9:21) Láwọn ọgọ́rùn-ún ọdún tó tẹ̀ lé e, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yẹn ṣàìgbọràn sí Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń rán àwọn wòlíì sí wọn pé kí wọ́n yí pa dà. Ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì, ó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sáyé. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù ló kọ Jésù, wọ́n sì gbà káwọn ọ̀tá pa á. Ni Jèhófà bá dá orílẹ̀-èdè míì tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí sílẹ̀, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” Orílẹ̀-èdè tuntun yìí ló wá pa pọ̀ mọ́ Kristi láti di irú ọmọ Ábúráhámù nípa tẹ̀mí, èyí tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé òun máa lò láti bù kún aráyé.—Gál. 3:16, 29; 6:16.
11. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ṣì ń “rántí májẹ̀mú” tó bá Ábúráhámù dá?
11 Jèhófà ṣì ń “rántí májẹ̀mú rẹ̀” àtàwọn ìbùkún tó ṣèlérí nípasẹ̀ májẹ̀mú yẹn. Ìdí ni pé, lónìí, ó ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí ní ohun tó ju irínwó [400] èdè lọ. Bákan náà, ó tún ń pèsè àtijẹ àtimu fún wa bá a ṣe ń gbàdúrà sí i níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí, pé: “Fún wa ní oúnjẹ wa fún òòjọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òòjọ́ ń béèrè.”—Lúùkù 11:3; Sm. 72:16, 17; Aísá. 25:6-8.
Agbára Àgbàyanu Tí Jèhófà Ní
12. Báwo ni Jèhófà ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un ní “ogún àwọn orílẹ̀-èdè”?
12 “Ó ti sọ agbára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ní fífún wọn ní ogún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Sm. 111:6) Ohun àrà ọ̀tọ̀ kan tó wáyé nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣeé ṣe kí onísáàmù yìí ní lọ́kàn ni ọ̀nà àrà tí Jèhófà gbà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò ní Íjíbítì. Nígbà tí Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ó mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba tó wà níhà ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn Odò Jọ́dánì. (Ka Nehemáyà 9:22-25.) Bí Jèhófà ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní “ogún àwọn orílẹ̀-èdè” nìyẹn o. Ẹ ò rí bí agbára Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó!
13, 14. (a) Èwo ló ṣeé ṣe kí onísáàmù náà ní lọ́kàn lára ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fi agbára rẹ̀ hàn lórí Bábílónì? (b) Àwọn ọ̀nà mìíràn wo ni Jèhófà tún gbà lo agbára ńlá rẹ̀ láti dá àwọn èèyàn nídè?
13 Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a mọ̀ pé wọn ò ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àtàwọn babańlá wọn bí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Ńṣe ni wọ́n ń ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ṣáá títí tó fi lo àwọn ará Bábílónì láti kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ tó fún wọn, lọ sí ìgbèkùn. (2 Kíró. 36:15-17; Neh. 9:28-30) Tó bá jẹ́ pé ẹ̀yìn ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ìgbèkùn Bábílónì dé lẹni tó kọ Sáàmù 111 kọ ọ́ gẹ́gẹ́ báwọn ọ̀mọ̀wé kan ṣe sọ, a jẹ́ pé ìdáǹdè yẹn tún jẹ́ ìdí míì tó fi yin Jèhófà fún ìdúróṣinṣin àti agbára rẹ̀. Ọlọ́run fi ìdúróṣinṣin àti agbára rẹ̀ hàn nípa bó ṣe dá àwọn Júù sílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì, nítorí pé àwọn ará Bábílónì kì í dá àwọn tí wọ́n bá kó ní ìgbèkùn sílẹ̀ kí wọ́n pa dà sílé.—Aísá. 14:4, 17.
14 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó tún ju ìyẹn lọ, ó pèsè ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú fáwọn èèyàn tó bá ronú pìwà dà. (Róòmù 5:12) Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tó tinú èyí wá ni pé ó ṣeé ṣe fún ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn láti lè di ọmọlẹ́yìn Kristi tí Ọlọ́run fẹ̀mí mímọ́ yàn. Lọ́dún 1919, Jèhófà lo agbára rẹ̀ láti dá àwọn kéréje tó jẹ́ àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró yìí nídè kúrò nínú ìsìn èké. Àwọn ohun tí wọ́n sì ń gbé ṣe lákòókò òpin yìí kì bá tí ṣeé ṣe tí kì í bá ṣe ti agbára Ọlọ́run. Tí wọ́n bá dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ títí dójú ikú, wọ́n máa bá Jésù Kristi ṣàkóso ayé látọ̀runwá, láti lè ṣe àwọn èèyàn tó bá ronú pìwà dà láǹfààní. (Ìṣí. 2:26, 27; 5:9, 10) Wọ́n á jogún gbogbo ilẹ̀ ayé, èyí tó ju ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ jogún lọ.—Mát. 5:5.
Àwọn Ìlànà Tó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé, Tó sì Wúlò Títí Ayé
15, 16. (a) Kí ló tún jẹ́ ara iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run? (b) Àwọn òfin wo ni Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
15 “Òtítọ́ àti ìdájọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀; aṣeégbẹ́kẹ̀lé ni gbogbo àṣẹ ìtọ́ni tí ó ń fi fúnni, èyí tí a tì lẹ́yìn dáadáa títí láé, fún àkókò tí ó lọ kánrin, tí a ṣe nínú òtítọ́ àti ìdúróṣánṣán.” (Sm. 111:7, 8) Ara “àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀” ni wàláà òkúta méjì tí Jèhófà fi ìka ọwọ́ rẹ̀ fín òfin pàtàkì mẹ́wàá sí lára fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kís. 31:18) Àwọn òfin yìí àtàwọn ìtọ́ni míì ló para pọ̀ di májẹ̀mú Òfin Mósè tó dá lórí àwọn ìlànà tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó sì wúlò títí ayé.
16 Bí àpẹẹrẹ, a rí i lára òfin tó wà nínú wàláà òkúta yẹn pé: “Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” Ó tún sọ síwájú sí i pé Jèhófà máa “ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ìran ẹgbẹ̀rún ní ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ [rẹ̀], tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ [rẹ̀] mọ́.” Lára àwọn ìlànà tó wúlò títí ayé tó wà nínú wàláà òkúta yẹn ni “bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ,” àti “ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.” Ara rẹ̀ náà sì ni òfin kan tó fi ìjìnlẹ̀ òye hàn, èyí tó sọ pé ká má ṣe jẹ́ kí ojú wa wọ nǹkan oníǹkan.—Ẹ́kís. 20:5, 6, 12, 15, 17.
Olùràpadà Wa, Ẹni Mímọ́, Amúnikún-fún-Ẹ̀rù
17. Àwọn ìdí wo ló fi yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì fọwọ́ mímọ́ mú orúkọ Ọlọ́run?
17 “Ìtúnràpadà ni òun ti fi ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin. Mímọ́ àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ni orúkọ rẹ̀.” (Sm. 111:9) Ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jèhófà ṣe ń mú májẹ̀mú rẹ̀ tó bá Ábúráhámù dá ṣẹ ni onísáàmù náà ní lọ́kàn níbí yìí. Nítorí májẹ̀mú yẹn, Jèhófà kò pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì nígbà tí wọ́n ń sìnrú ní Íjíbítì àtijọ́ àti nígbà tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì. Lẹ́ẹ̀méjèèjì yìí, Ọlọ́run ra àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà. Nǹkan méjì péré yìí lára àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tiẹ̀ ti tó láti mú kí wọ́n fọwọ́ mímọ́ mú orúkọ rẹ̀.—Ka Ẹ́kísódù 20:7; Róòmù 2:23, 24.
18. Kí nìdí tó o fi kà á sí àǹfààní láti jẹ́ ẹni tá à ń fi orúkọ Ọlọ́run pè?
18 Bó ṣe rí fáwọn Kristẹni òde òní, tí Jèhófà ti rà pa dà kúrò nínú oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọn ì bá wà títí gbére, náà nìyẹn. Ó yẹ ká máa sa gbogbo ipá wa láti máa ṣe ohun tó bá ẹ̀bẹ̀ àkọ́kọ́ nínú àdúrà Olúwa mu, pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí orúkọ ńlá yẹn, a óò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Ẹni tó kọ Sáàmù 111 mọ ohun tí ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ gan-an, torí ó sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n. Gbogbo àwọn tí ń pa wọ́n mọ́ ní ìjìnlẹ̀ òye rere.”—Sm. 111:10.
19. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
19 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run yóò mú ká kórìíra ohun tó burú. Ó tún máa jẹ́ ká ní irú àwọn ànímọ́ àtàtà tí Ọlọ́run ní, èyí tí Sáàmù 112 fi hàn, tá a sì máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí. Sáàmù 112 yìí yóò jẹ́ ká rí bá a ṣe lè wà lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí yóò fayọ̀ yin Ọlọ́run títí ayé. Ó sì yẹ ká máa fayọ̀ yin Jèhófà títí ayé lóòótọ́, nítorí pé: “Ìyìn rẹ̀ dúró títí láé.”—Sm. 111:10.
Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò
• Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa jọ yin Jèhófà?
• Àwọn ànímọ́ Jèhófà wo làwọn iṣẹ́ rẹ̀ fi hàn?
• Ojú wo lo fi ń wo àǹfààní tó o ní láti jẹ́ ẹni tá à ń fi orúkọ Ọlọ́run pè?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Olórí ìdí tá a fi ń pé jọ déédéé ni láti yin Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Gbogbo òfin Jèhófà ló dá lórí àwọn ìlànà tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó sì wúlò títí láé