-
Àwọn Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Láti ṢàfarawéIlé-Ìṣọ́nà—1993 | December 1
-
-
4. Àwọn ẹsẹ ìwé-mímọ́ wo ni ó fihàn pé Jehofa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?
4 Jehofa Ọlọrun—Ẹni Gíga Jùlọ, Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé, Ọba ayérayé—jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. (Genesisi 14:22) Ó ha ṣeéṣe pé kí ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ni, nítòótọ́! Ọba Dafidi sọ, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Orin Dafidi 18:35 (NW) pé: “Ìwọ yóò fún mi ní apata ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì mú mi dúró, ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rẹ yóò sì sọ mi di ńlá.” Lọ́nà tí ó ṣe kedere, Ọba Dafidi kà á sí pé ìrẹ̀lẹ̀-ọ̀kan Jehofa ni ó sọ òun, Dafidi, di ńlá. Lẹ́yìn náà, a tún kà nínú Orin Dafidi 113:6 pé Jehofa “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wo ohun tí ó wà ní ọ̀run àti ní ayé.” Àwọn ìtumọ̀ mìíràn kà pé, “bẹ̀rẹ̀mọ́lẹ̀ láti wò,” (New International Version) “tẹ araarẹ̀ wálẹ̀ láti wo ìsàlẹ̀ rẹlẹ̀-rẹlẹ̀ gan-an.”—The New English Bible.
5. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó jẹ́rìí sí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Jehofa?
5 Dájúdájú Jehofa Ọlọrun rẹ araarẹ̀ wálẹ̀ ní ọ̀nà tí ó gbà bá Abrahamu lò, ní fífàyègba Abrahamu láti gbé ìbéèrè dìde sí ìwà-òdodo Rẹ̀ níti pípète láti pa àwọn ìlú-ńlá Sodomu àti Gomora bíburúbàlùmọ̀ run.a (Genesisi 18:23-32) Nígbà tí Jehofa sì sọ ìtẹ̀sí rẹ̀ jáde láti pa orílẹ̀-èdè Israeli run—ní ìgbà kan nítorí ìbọ̀rìṣà, nígbà mìíràn nítorí ọ̀tẹ̀—Mose bá Jehofa ronú pọ̀ ní àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan bí ẹni pé ó ń bá ènìyàn mìíràn kan sọ̀rọ̀. Ní ìgbà kọ̀ọ̀kan Jehofa fi ojúrere dáhùnpadà. Fún Un láti gba ẹ̀bẹ̀ Mose nípa àwọn ènìyàn Rẹ̀ Israeli fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn hàn. (Eksodu 32:9-14; Numeri 14:11-20) Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn nípa fífi tí Jehofa fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn bá àwọn ènìyàn lò lórí ìpìlẹ̀ ti ẹnìkan sí ẹnìkan, bí a ṣe lè sọ pé ó jẹ́, ní a lè rí nínú àjọsepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Gideoni àti Jona, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Awọn Onidajọ 6:36-40 àti Jona 4:9-11.
-
-
Àwọn Àpẹẹrẹ Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Láti ṢàfarawéIlé-Ìṣọ́nà—1993 | December 1
-
-
a “Rẹrawálẹ̀” ní a sábà máa ń lò pẹ̀lú ìtumọ̀ náà “láti fira sípò ìlọ́lájù.” Ṣùgbọ́n ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an—àti ìtumọ̀ rẹ̀ nínú New World Translation—ni “mú dẹjú,” “yẹ àwọn àǹfààní ipò jù sílẹ̀.”—Wo Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary.
-