Ojú Wo Ni Jèhófà Fi Ń Wo Àwíjàre?
ỌKÙNRIN náà sì wí pé: “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi láti wà pẹ̀lú mi, òun ni ó fún mi ní èso láti ara igi náà, nítorí náà, mo sì jẹ.” Obìnrin náà fèsì pé: “Ejò—òun ni ó tàn mí, nítorí náà, mo sì jẹ.” Látìgbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ Ádámù àti Éfà ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Ọlọ́run ni wíwí àwíjàre ti bẹ̀rẹ̀.—Jẹ́n. 3:12, 13.
Ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fún Ádámù àti Éfà nítorí bí wọ́n ṣe mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn yìí mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò fara mọ́ àwíjàre náà. (Jẹ́n. 3:16-19) Ṣé ká wá parí èrò sí pé, gbogbo àwíjàre ni Jèhófà kì í fara mọ́ ni? Àbí, ó máa ń gbà pé àwọn àwíjàre míì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè mọ èyí tó máa ń fara mọ́ àti èyí tí kì í fara mọ́? Ká tó dáhùn, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí àwíjàre túmọ̀ sí.
Àwíjàre ni ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láti ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe ohun kan, ìdí tí kò tíì fi ṣe ohun kan tàbí ìdí tí kò fi ní ṣe ohun kan. Àwíjàre lè jẹ́ àlàyé tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ fún kíkùnà láti ṣe ohun kan, ó sì lè jẹ́ títọrọ àforíjì látọkàn wá, èyí tó lè mú kí wọ́n fi àánú hàn síni tàbí kí wọ́n tiẹ̀ dárí jini pàápàá. Àmọ́, bí ọ̀ràn ti Ádámù àti Éfà ṣe fi hàn, èèyàn tún lè wí àwíjàre láti fi tanni jẹ, ó lè jẹ́ ìdí tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ láti fi bo ohun tó jẹ́ òótọ́ lójú. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé irú àwíjàre yìí ló wọ́pọ̀, ó máa ń mú kéèyàn fura sí ẹni tó bá ń wí àwíjàre.
Nígbà téèyàn bá ń wí àwíjàre, ní pàtàkì jù lọ, tó bá jẹ́ èyí tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ‘fífi èrò èké tan ara wa jẹ.’ (Ják. 1:22) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ kan àtàwọn ìlànà kan nínú Bíbélì tó máa jẹ́ ká lè máa “bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—Éfé. 5:10.
Ohun Tí Ọlọ́run Retí Pé Ká Ṣe
A rí àwọn àṣẹ pàtó kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí àwa tá a jẹ́ èèyàn Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe ìgbọ́ràn sí. Bí àpẹẹrẹ, àṣẹ tí Kristi pa pé ‘kí a máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,’ ṣì kan gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Kristi. (Mát. 28:19, 20) Ká sòótọ́, pípa àṣẹ yẹn mọ́ ṣe pàtàkì gan-an débi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!”—1 Kọ́r. 9:16.
Síbẹ̀ náà, àwọn kan tó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wa fún àkókò pípẹ́ ṣì ń tijú láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) Àwọn kan tó ti ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tẹ́lẹ̀ kò tún wàásù mọ́. Kí ni àwọn tí kò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù máa ń sọ nígbà míì pé ó fà á tí àwọn kò fi wàásù mọ́? Kí ni Jèhófà ṣe fún àwọn tó lọ́ra láti ṣègbọràn sí àṣẹ tó pa nígbà kan rí?
Àwọn Àwíjàre Tí Ọlọ́run Kò Fara Mọ́
“Ó ti le jù.” Fún àwọn tó jẹ́ pé ojú máa ń tì gan-an, ó lè dà bíi pé iṣẹ́ ìwàásù ti le jù. Jẹ́ ká gbé ohun tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Jónà yẹ̀ wò. Jèhófà sọ fún un pé kó lọ kéde ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ìlú Nínéfè, ṣùgbọ́n ó ka iṣẹ́ náà sí èyí tó ti le jù fún òun láti ṣe. Kò ṣòro láti rí ìdí tí Jónà fi fòyà láti jẹ́ iṣẹ́ yẹn. Olú ìlú Ásíríà ni ìlú Nínéfè, àwọn ará Ásíríà sì jẹ́ òǹrorò ẹ̀dá. Jónà lè ti máa rò ó pé: ‘Ojú wo làwọn èèyàn yìí máa fi wò mí? Kí ni wọ́n máa ṣe fún mi?’ Kò pẹ́ kò jìnnà, ló bá sá lọ. Síbẹ̀, Jèhófà kò fara mọ́ àwíjàre Jónà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà tún pa dà sọ fún un pé kó lọ wàásù fún àwọn ará Nínéfè. Lọ́tẹ̀ yìí, Jónà fìgboyà ṣe iṣẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì mú kó kẹ́sẹ járí.—Jónà 1:1-3; 3:3, 4, 10.
Tó o bá ronú pé iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ ti le jù fún ẹ, máa rántí pé “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:27) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, Jèhófà á fún ẹ lókun tó o bá ń bá a nìṣó láti máa béèrè fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, yóò sì bù kún ẹ tó o bá mọ́kàn le láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.—Lúùkù 11:9-13.
“Kò wù mí ṣe.” Kí lo lè ṣe tí kò bá wù ẹ́ látọkàn wá láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni? Máa fi sọ́kàn pé, Jèhófà lè sún ẹ ṣiṣẹ́, kó sì nípa lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.” (Fílí. 2:13) Torí náà, o lè béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé kó jẹ́ kó wù ẹ́ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ohun tí Dáfídì Ọba ṣe gan-an nìyẹn. Ó bẹ Jèhófà pé: “Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ.” (Sm. 25:4, 5) O lè ṣe ohun kan náà nípa fífi taratara gbàdúrà sí Jèhófà pé kó mú kó wù ẹ́ láti ṣe ohun tó fẹ́.
Lóòótọ́, nígbà tó bá rẹ̀ wá tàbí nígbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, ó lè gba pé ká fipá mú ara wa láti lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ká lọ sóde ẹ̀rí. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé ó wá yẹ ká parí èrò sí pé a ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn? Kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìgbàanì náà sapá gidigidi kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé, òun ní láti “lu ara [òun] kíkankíkan,” kí òun bàa lè pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́. (1 Kọ́r. 9:26, 27) Torí náà, tó bá tiẹ̀ gba pé ká fipá mú ara wa láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà á bù kún wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé, a fipá mú ara wa láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nítorí ìdí tó tọ́, ìyẹn ni nítorí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè pèsè ìdáhùn fún ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé, wọ́n á sẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n bá rí àdánwò.—Jóòbù 2:4.
“Ọwọ́ mi ti dí jù.” Tó bá jẹ́ torí pé ó ń ṣe ẹ́ bíi pé ọwọ́ rẹ ti dí jù ni kò jẹ́ kó o máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o ṣàtúnyẹ̀wò ohun tó o fi sípò àkọ́kọ́. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) Láti lè tẹ̀ lé ìlànà tó ń tọ́ni sọ́nà yẹn, ó lè pọn dandan pé kó o jẹ́ kí ohun ìní tara díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn tàbí kó o dín àkókò tó o fi ń ṣeré ìnàjú kù, kó o sì máa lò ó fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lóòótọ́, kò burú láti ṣe eré ìnàjú àti àwọn nǹkan míì tó jẹ́ tara ẹni, àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ òun la máa fi ṣe àwíjàre fún pípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ tì. Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀.
“Mi ò kúnjú ìwọ̀n tó.” Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o kò tóótun láti jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìn rere. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì nímọ̀lára pé àwọn kò kúnjú ìwọ̀n tó láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wọn. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Mósè yẹ̀ wò. Nígbà tí Jèhófà gbé iṣẹ́ kan lé Mósè lọ́wọ́, ohun tó sọ ni pé: “Dákun, Jèhófà, ṣùgbọ́n èmi kì í ṣe ẹni tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó já geere, kì í ṣe láti àná, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ṣáájú ìgbà yẹn tàbí láti ìgbà tí o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, nítorí ẹnu mi wúwo, ahọ́n mi sì wúwo.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fọkàn rẹ̀ balẹ̀, Mósè fèsì pé: “Dákun, Jèhófà, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́, ránṣẹ́ nípa ọwọ́ ẹni tí ìwọ yóò rán.” (Ẹ́kís. 4:10-13) Kí ni Jèhófà wá ṣe?
Jèhófà kò gba iṣẹ́ yẹn lọ́wọ́ Mósè. Àmọ́, Jèhófà yan Áárónì láti ran Mósè lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. (Ẹ́kís. 4:14-17) Síwájú sí i, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà dúró ti Mósè, ó sì ń pèsè ohunkóhun tó bá nílò fún un kó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ tó gbé lé e lọ́wọ́. Lóde òní, ó yẹ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà máa lo àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Lékè gbogbo rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé Jèhófà máa mú ká kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ tó pa láṣẹ fún wa pé ká ṣe.—2 Kọ́r. 3:5; wo àpótí náà “Ọdún Tí Mo Láyọ̀ Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Mi.”
“Ẹnì kan ṣe ohun tó dùn mí.” Àwọn kan ṣíwọ́ lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí lílọ sí ìpàdé ìjọ torí pé ẹnì kan ṣẹ̀ wọ́n, wọ́n ronú pé Jèhófà á tẹ́wọ́ gba àwíjàre yìí fún pípa iṣẹ́ ìsìn Kristẹni tì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń dùn wá gan-an tí ẹnì kan bá ṣe ohun tó múnú bí wa, ṣé ó wá yẹ ká torí ìyẹn ṣíwọ́ lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni? Ó ṣeé ṣe kí èdèkòyédè tó wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ mú kí àwọn méjèèjì bínú síra, ó sì yọrí sí “ìbújáde ìbínú mímúná.” (Ìṣe 15:39) Àmọ́, ṣé a rí èyí tó torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣíwọ́ lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? Rárá o!
Bákan náà, bí ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá ṣe ohun tó dùn ẹ́, máa fi sọ́kàn pé kì í ṣe ẹni tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni, tó sì jẹ́ aláìpé yẹn ni ọ̀tá rẹ, bí kò ṣe Sátánì, tó fẹ́ pa ẹ́ jẹ. Èṣù kò ní ṣàṣeyọrí, tó o bá ‘mú ìdúró rẹ lòdì sí i, tó o sì dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.’ (1 Pét. 5:8, 9; Gál. 5:15) Tó o bá ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, o kò ní “wá sí ìjákulẹ̀” lọ́nàkọnà.—Róòmù 9:33.
Tí A Kò Bá Lè Ṣe Tó Bó Ṣe Yẹ
Látinú àpẹẹrẹ àwọn àwíjàre tá a ti rí yìí, ó ti wá ṣe kedere pé kò sí àwíjàre kankan tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti má ṣe ṣe àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún wa, tó fi mọ́ àṣẹ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, a lè ní ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún ṣíṣàì ṣe tó bó ṣe yẹ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Àwọn ojúṣe kan tó bá Ìwé Mímọ́ mu lè mú ká má lè lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó lè rẹ̀ wá tẹnutẹnu tàbí ká ṣàìsàn gan-an débi tí a ò fi ní lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé Jèhófà mọ bó ṣe ń wù wá lọ́kàn tó, ó sì mọ̀ pé ó ní ibi tí agbára wa mọ.—Sm. 103:14; 2 Kọ́r. 8:12.
Torí náà, a ní láti ṣọ́ra ká má ṣe máa dá ara wa tàbí àwọn míì lẹ́jọ́ lórí ọ̀ràn yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ta ni ìwọ láti ṣèdájọ́ ìránṣẹ́ ilé ẹlòmíràn? Lọ́dọ̀ ọ̀gá òun fúnra rẹ̀ ni ó dúró tàbí ṣubú.” (Róòmù 14:4) Dípò tí a ó fi máa fi ipò tiwa wé tàwọn ẹlòmíì, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé “olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12; Gál. 6:4, 5) Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, tá a sì sọ àwọn àwíjàre wa fún un, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa á fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú “ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí.”—Héb. 13:18.
Ìdí tí Sísin Jèhófà Fi Ń Fún Wa Láyọ̀
Gbogbo wa la lè sin Jèhófà pẹ̀lú ayọ̀ tó tọkàn wá torí pé gbogbo ìgbà ni àwọn ohun tó fẹ́ ká máa ṣe ń bọ́gbọ́n mu, tó sì jẹ́ ohun tágbára wa gbé láìka ipò wa nígbèésí ayé sí. Kí nìdí tá a fi lè sọ bẹ́ẹ̀?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Òwe 3:27) Kí lo kíyè sí nínú òwe yìí nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ń retí pé ká ṣe? Jèhófà kò pàṣẹ fún ẹ pé kó o sapá láti ní ìwọ̀n agbára tó ṣeé ṣe kó wà ní ọwọ́ arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ, àmọ́ ó ní kó o sin Òun pẹ̀lú ohun “tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè sin Jèhófà tọkàntọkàn, láìka ti bá a ṣe jẹ́ aláìlera tàbí bí agbára ọwọ́ wa ṣe pọ̀ tó sí.—Lúùkù 10:27; Kól. 3:23.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
“Ọdún Tí Mo Láyọ̀ Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Mi”
Kódà tá a bá ní àìlera tó le gan-an tàbí tí agbára ìrònú wa kò já gaara, a kò gbọ́dọ̀ yára parí èrò sí pé èyí kò ní jẹ́ ká lè kópa kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Láti ṣàpèjúwe èyí, gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Ernest, lórílẹ̀-èdè Kánádà yẹ̀ wò.
Ernest kò lè sọ̀rọ̀ já geere ojú sì máa ń tì í gan-an. Ó ní láti fi iṣẹ́ kọ́lékọ́lé tó ń ṣe sílẹ̀ nígbà tí ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í dùn ún nítorí jàǹbá kan tó burú jáì tó ṣẹlẹ̀ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán, ipò tó wà yìí mú kó lè lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìṣírí tí wọ́n fún àwọn ará ní ìpàdé ìjọ pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ mú kó wù ú látọkàn wá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó wò ó pé òun kò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.
Kó lè túbọ̀ dá a lójú pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kọjá agbára òun, ó fọwọ́ sí ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan. Ó yà á lẹ́nu pé, ó ṣeé ṣe fún òun láti dójú ìlà ohun tí wọ́n béèrè fún. Lẹ́yìn náà ó wá sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Mo mọ̀ pé mi ò lè ṣe é mọ́ láé.’ Kó lè dá a lójú pé èrò òun tọ̀nà, ó tún gbà á lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún ṣàṣeyọrí.
Ernest ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ọdún kan gbáko, àmọ́ ó sọ pé, “Ó dá mi lójú pé mi ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé láéláé.” Torí náà, kó tún lè mú un dá ara rẹ̀ lójú pé òun kò lè ṣe é, ó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ó yà á lẹ́nu pé òun lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé fún odindi ọdún kan gbáko. Ó wá pinnu láti máa bá iṣẹ́ náà lọ, Ọlọ́run sì bù kún un torí pé ó fàyọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún méjì, kó tó di pé ẹ̀yìn tó ń dùn ún burú sí i, tó sì gbabẹ̀ kú. Àmọ́, kó tó kú, ó sábà máa ń sọ fún àwọn tó bá wá kí i pẹ̀lú omijé lójú pé, “Àwọn ọdún tí mo fi sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà ni àwọn ọdún tí mo láyọ̀ jù lọ ní ìgbésí ayé mi.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
A lè borí ohun ìdènà èyíkéyìí tó lè fẹ́ dí wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá sìn ín tọkàntọkàn nípa ṣíṣe gbogbo ohun tí ipò wa bá gbà wá láyè láti ṣe