Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Gba Ìtọ́ni Tó Wọ̀ Wọ́n Lọ́kàn Gan-an
LỌ́JỌ́ kẹsàn-án oṣù September, ọdún 2006, ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kọkànlélọ́gọ́fà [121] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead wáyé ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fún gbogbo àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ níṣìírí gan-an.
Arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ó kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege tí wọ́n jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta àtàwọn mìíràn tó pésẹ̀ síbẹ̀ tí wọ́n wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè káàbọ̀. Iye àwọn èèyàn wọ̀nyí jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, irínwó, ó dín mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [6,366]. Ó wá sọ̀rọ̀ nípa Sáàmù 86:11, èyí tó kà pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” Arákùnrin Jackson sọ àwọn nǹkan mẹ́ta tó ṣe pàtàkì gan-an tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí tẹnu mọ́. Ó ní: “Gbólóhùn àkọ́kọ́ tẹnu mọ́ ìtọ́ni, ìkejì sọ nípa fífi ìtọ́ni náà sílò, nígbà tí ẹ̀kẹta sọ nípa fífẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin tẹ́ ẹ jẹ́ míṣọ́nnárì làwọn nǹkan mẹ́ta yìí ṣe pàtàkì fún jù lọ bẹ́ ẹ ti ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn yín.” Lẹ́yìn náà ló wá mẹ́nu kan àwọn àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó máa wáyé, àwọn kókó mẹ́ta tó mẹ́nu kàn wọ̀nyí ni wọ́n sì dá lé.
Àwọn Ìtọ́ni Tó Fún Wọn Níṣìírí
Arákùnrin William Malenfant tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń sìn ní orílé-iṣẹ́ sọ̀rọ̀ lórí àkòrí náà, “Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ.” Ó pe àfiyèsí àwọn tó wà níjòókòó sí àpẹẹrẹ Màríà, ìyẹn arábìnrin Màtá. Nígbà kan tí Jésù lọ sílé wọn, ibi ẹsẹ̀ Jésù ni Màríà jókòó sí ní tiẹ̀ tó ń tẹ́tí sóhun tí Jésù ń sọ, èyí lohun tó kà sí pàtàkì jù lọ. Jésù wá sọ fún Màtá pé: “Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 10:38-42) Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ìwọ ronú nípa ohun tí Jésù sọ yẹn ná. Títí láéláé ni Màríà yóò máa rántí pé òun jókòó níbi ẹsẹ̀ Jésù òun sì gbọ́ àwọn àgbàyanu ẹ̀kọ́ òtítọ́ látẹnu rẹ̀ ní tààràtà. Ohun tó sì mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé Màríà yan ohun tó dára.” Lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ náà ti gbóríyìn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà pé wọ́n yan ohun tẹ̀mí, tó jẹ́ ohun tó dára gan-an, ó wá sọ pé: “Àwọn ìpinnu tẹ́ ẹ ti ṣe ti jẹ́ kọ́wọ́ yín tẹ ìgbésí ayé tó dára jù lọ.”
Lẹ́yìn èyí ni arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá sọ̀rọ̀ lórí àkòrí náà, “Ẹ Gbé Olúwa Jésù Kristi Wọ̀.” Àsọyé yìí dá lórí Róòmù 13:14. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Gbígbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀ túmọ̀ sí híhùwà lọ́nà tí Olúwa gbà hùwà.” Olùbánisọ̀rọ̀ yìí sọ pé táwọn èèyàn bá wà lọ́dọ̀ Jésù, ara máa ń tù wọ́n. Ìdí ni pé Jésù nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, wọ́n sì rí èyí nínú ìṣesí rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni olùbánisọ̀rọ̀ yìí wá jíròrò báwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe gba ọ̀pọ̀ ìmọ̀ nígbà tí wọ́n wà lẹ́nu ẹ̀kọ́ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ‘kí wọ́n lè fi èrò orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn òtítọ́ jẹ́’ gẹ́gẹ́ bí Éfésù 3:18 ṣe sọ. Síbẹ̀ ó rán wọn létí ohun tó wà ní ẹsẹ 19, èyí tó sọ pé: “Àti láti mọ ìfẹ́ Kristi tí ó tayọ ré kọjá ìmọ̀.” Arákùnrin Morris wá sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Bẹ́ ẹ ti ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, ẹ máa ronú àwọn ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà fara wé ìfẹ́ àti ìyọ́nú tí Jésù fi hàn, kẹ́ ẹ sì rí i dájú pé ‘ẹ ń gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀.’”
Ọ̀rọ̀ Ìdágbére Látẹnu Àwọn Olùkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
Arákùnrin Wallace Liverance tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló sọ ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e, Òwe 4:7 ló sì gbé àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà. Ó sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ló ṣe pàtàkì jù, a tún gbọ́dọ̀ “ní òye,” ìyẹn ni pé ká lè pa àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ kan pọ̀, ká sì wá rí bí wọ́n ṣe sọ pọ̀ mọ́ ara wọn, èyí tá á wá jẹ́ ká mọ ohun tí ọ̀ràn kan túmọ̀ sí. Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé níní òye máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Nehemáyà, àwọn ọmọ Léfì “ń ṣàlàyé òfin” wọ́n sì ń mú kó “yéni.” Lẹ́yìn èyí, àwọn èèyàn náà wá “ń bá a lọ nínú ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà, nítorí wọ́n lóye ọ̀rọ̀ tí a ti sọ di mímọ̀ fún wọn.” (Nehemáyà 8:7, 8, 12) Arákùnrin Liverance kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Ayọ̀ ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ téèyàn bá lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó fi ẹ̀mí mímọ́ darí kíkọ rẹ̀.”
Àkòrí tí Arákùnrin Mark Noumair tòun náà jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ̀rọ̀ lé lórí ni, “Ta Ni Ọ̀tá Rẹ Gan-an? Tí ogun bá ń lọ lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ sójà ló jẹ́ pé ọta ìbọn tiwọn fúnra wọn tàbí tàwọn tí wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan náà ló máa ń pa wọ́n. Ó wá béèrè pé: “Ogun tẹ̀mí tí à ń jà ńkọ́? Bá ò bá ṣọ́ra, a lè má mọ ẹni tó jẹ́ ọ̀tá wa gan-an, ká sì wá máa ṣe àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tiwa fúnra wa léṣe.” Ìlara lè mú kó ṣòro fáwọn kan láti mọ ẹni tó jẹ́ ọ̀tá wọn gan-an. Òun ló mú kí Sọ́ọ̀lù Ọba gbìyànjú láti pa Dáfídì tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà bíi tiẹ̀, nígbà tó sì jẹ́ pé àwọn Filísínì ni ọ̀tá rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 18:7-9; 23:27, 28) Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ká ní ìwọ àti míṣọ́nnárì kan tó ta ọ́ yọ lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà lẹ jọ ń sìn níbì kan náà ńkọ́? Ṣé wàá máa ṣe ẹni tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan náà yìí léṣe nípa sísọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa, àbí wàá mú kí àlàáfíà jọba nípa gbígbà pé ó di dandan káwọn kan ta ọ́ yọ lónírúurú ọ̀nà? Ńṣe ni gbígbájúmọ́ àìpé àwọn mìíràn á wúlẹ̀ mú ká máa rò pé àwọn gan-an ni ọ̀tá wa. Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá rẹ gan-an ni kó o máa bá jà.”
Àwọn Ìrírí Tó Dùn Mọ́ni Àtàwọn Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Tó Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
Arákùnrin Lawrence Bowen tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló bójú tó apá tó tẹ̀ lé e nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ṣe Iṣẹ́ Ajíhìnrere.” Apá yìí sì ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti ìrírí nínú. Olórí iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ni pé kí wọ́n wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn, kíláàsì yìí sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ibi tí wọ́n bá ti ráwọn èèyàn. Wọ́n ṣàṣefihàn díẹ̀ lára àwọn ìrírí tó dùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Ohun tó tẹ̀ lé e nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni apá méjì tí Arákùnrin Michael Burnett àti Arákùnrin Scott Shoffner, táwọn méjèèjì jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì, bójú tó. Wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn arákùnrin kan tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, Barbados, Kòríà, àti Uganda. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ jẹ́ ká mọ bí ipa tí wọ́n ń sà ti pọ̀ tó kí wọ́n tó lè pèsè ohun táwọn míṣọ́nnárì nílò, títí kan pípèsè ilé tó bójú mu fún wọn àti bíbójútó ìlera wọn. Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ ẹ̀ka wọ̀nyí tẹnu mọ́ ọn pé àwọn míṣọ́nnárì tó ṣàṣeyọrí kì í lọ́ra láti mú ara wọn bá ipò àgbègbè tí wọ́n bá ara wọn mu.
Ọ̀rọ̀ Ìkádìí Tó Wọni Lọ́kàn Tó sì Fúnni Níṣìírí Gan-an
Àsọyé tí àkòrí rẹ̀ sọ pé “Ẹ Bẹ̀rù Ọlọ́run Kí Ẹ sì Fi Ògo Fún Un” ni èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó wáyé nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, Arákùnrin John E. Barr tó ti jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí látọjọ́ pípẹ́ ló sì sọ ọ́. Ó jíròrò Ìṣípayá 14:6, 7, èyí tó kà pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.’”
Arákùnrin Barr rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n fi àwọn ohun mẹ́ta kan nípa áńgẹ́lì náà sọ́kàn. Èkíní, ó polongo ìhìn rere àìnípẹ̀kun pé Kristi tí n ṣàkóso báyìí, gbogbo agbára Ìjọba náà ló sì wà lọ́wọ́ rẹ̀. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ó dá wa lójú gan-an pé ọdún 1914 ló gorí ìtẹ́. Nítorí náà, a ní láti polongo ìhìn aláyọ̀ yìí ní gbogbo ayé pátá.” Èkejì, áńgẹ́lì náà sọ pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege yìí ní láti ran àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè dẹni tó ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an fún Ọlọ́run, kí wọ́n má bàa ṣe ohunkóhun tí kò ní dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Ẹ̀kẹta, áńgẹ́lì náà pàṣẹ pé: ‘Ẹ fi ògo fún Ọlọ́run.’ Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Ẹ má ṣe gbàgbé láé pé sísìn tá à ń sìn, fún ògo Ọlọ́run ni, kì í ṣe fún ògo ara wa.” Nígbà tí Arákùnrin Barr wá ń jíròrò “wákàtí ìdájọ́,” ó ní: “Àkókò díẹ̀ péré ló ṣẹ́ kù láti kéde ìdájọ́ ìkẹyìn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ní àwọn ìpínlẹ̀ wa ṣì ní láti gbọ́ ìhìn rere náà kó tó pẹ́ jù.”
Bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ń dún gbọnmọgbọnmọ lọ́kàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege mẹ́rìndínlọ́gọ́ta yìí ni wọ́n gba ìwé ẹ̀rí wọn, tí wọ́n sì rán wọn lọ sí ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Ìmọ̀ràn tó ń fúnni níṣìírí táwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà àti gbogbo àwọn tó wà níjòókòó gbọ́ lọ́jọ́ tó lárinrin yẹn, wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an ni.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ
Iye orílẹ̀ èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 6
Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 25
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 56
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 35.1
Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 18.3
Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún: 13.9
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kíláàsì Kọkànlélọ́gọ́fà [121] Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead
Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Fox, Y.; Kunicki, D.; Wilkinson, S.; Kawamoto, S.; Consolandi, G.; Mayen, C. (2) Santiago, N.; Clancy, R.; Fischer, M.; de Abreu, L.; Davis, E. (3) Hwang, J.; Hoffman, D.; Wridgway, L.; Ibrahim, J.; Dabelstein, A.; Bakabak, M. (4) Peters, M.; Jones, C.; Ford, S.; Parra, S.; Rothrock, D.; Tatlot, M.; Perez, E. (5) de Abreu, F.; Kawamoto, S.; Ives, S.; Burdo, J.; Hwang, J.; Wilkinson, D. (6) Fox, A.; Bakabak, J.; Cichowski, P.; Forier, C.; Mayen, S.; Consolandi, E.; Wridgway, W. (7) Parra, B.; Perez, B.; Tatlot, P.; Santiago, M.; Ibrahim, Y.; Kunicki, C. (8) Burdo, C.; Cichowski, B.; Ives, K.; Ford, A.; Rothrock, J.; Hoffman, D.; Davis, M. (9) Peters, C.; Dabelstein, C.; Jones, K.; Clancy, S.; Fischer, J.; Forier, S.