Má Ba Ara Rẹ Lórúkọ Jẹ́
ỌKÙNRIN kan tó ń yàwòrán àwọn ilé mèremère ń ṣe orúkọ fún ara rẹ̀ pé òun jẹ́ ọ̀jáfáfá olùyàwòrán ìgbékalẹ̀ ilé. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó tayọ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ yóò di ẹni tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé gan-an. Kódà, ẹni tí kò ṣe nǹkan kan lè ṣe orúkọ fún ara rẹ̀ pé òun jẹ́ ọ̀lẹ afàjò. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe orúkọ rere fún ara ẹni, ó sọ pé: “Orúkọ rere sàn ju ọrọ̀ púpọ̀ lọ, níní orúkọ iyì sì sàn ju fàdákà àti wúrà.”—Òwe 22:1, An American Translation.
A lè ní orúkọ rere nípa híhùwà rere fún ìgbà pípẹ́. Ìwà òmùgọ̀ kan ṣoṣo sì ti tó láti ba gbogbo rẹ̀ jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, lílọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla kan ṣoṣo lè ba orúkọ rere téèyàn ní jẹ́. Nínú orí kẹfà ìwé Òwe inú Bíbélì, Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì fúnni ní ìkìlọ̀ nípa bí a ó ṣe yàgò fún àwọn ìwà àti ìṣe tó lè ba orúkọ rere wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Lára wọn ni ṣíṣe àdéhùn láìronú jinlẹ̀, ìwà ọ̀lẹ, ẹ̀tàn, ìwà pálapàla takọtabo—ní pàtàkì jù lọ àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. Kíkọbi ara sí ìmọ̀ràn yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dáàbò bo orúkọ rere wa.
Gba Ara Rẹ Lọ́wọ́ Ṣíṣe Àdéhùn Òmùgọ̀
Orí kẹfà ìwé Òwe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ọmọ mi, bí ìwọ bá ti lọ ṣe onídùúró fún ọmọnìkejì rẹ, bí ìwọ bá ti bá àjèjì pàápàá bọ ọwọ́, bí àwọn àsọjáde ẹnu rẹ bá ti dẹkùn mú ọ, bí àwọn àsọjáde ẹnu rẹ bá ti mú ọ, nígbà náà, gbé ìgbésẹ̀ yìí, ọmọ mi, kí o sì dá ara rẹ nídè, nítorí pé o ti bọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ ọmọnìkejì rẹ: Lọ, rẹ ara rẹ sílẹ̀, kí o sì bẹ ọmọnìkejì rẹ ní ẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dabọ̀.”—Òwe 6:1-3.
Ìmọ̀ràn tí òwe yìí ń fúnni ni pé kí a yẹra fún kíkó wọnú okòwò pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àgàgà àwọn àjèjì. Àní, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ‘pèsè fún arákùnrin wọn tó di òtòṣì, tí nǹkan kò sì rọgbọ fún ní ti ọ̀ràn ìnáwó.’ (Léfítíkù 25:35-38) Ṣùgbọ́n àwọn kan tó jẹ́ alákíkanjú láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ ń tọrùn bọ àwọn òwò tí kò dá wọn lójú, wọ́n sì ń gba owó tí wọn yóò fi ṣòwò náà nípa rírọ àwọn ẹlòmíràn láti ‘jẹ́ onídùúró’ fún wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ so gbèsè náà kọ́ àwọn wọ̀nyẹn lọ́rùn. Irú ipò kan náà lè dìde lónìí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ilé iṣẹ́ ọ̀ràn okòwò lè béèrè fún onídùúró kí wọ́n tó fọwọ́ sí yíyáni lówó kan tí wọ́n fura sí pé ó léwu. Ẹ wá wo bí yóò ṣe jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti kánjú kó wọnú irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn ẹlòmíràn! Họ́wù, ó lè sọ wá di ẹdun arinlẹ̀, kódà ó lè sọ wá dèèyàn burúkú lọ́dọ̀ àwọn báńkì àti lójú àwọn mìíràn tí ń yáni lówó!
Táa bá kó sínú ìṣòro gbígbé ìgbésẹ̀ kan tó dà bí èyí tó bọ́gbọ́n mu lákọ̀ọ́kọ́ ṣùgbọ́n táa wá rí i pé ìwà òmùgọ̀ ni, nígbà táa túbọ̀ wò ó dáadáa ńkọ́? Ìmọ̀ràn náà ni pé kí o gbàgbé ohun tí wọ́n ń pè ní ìgbéra–ẹni-níyì, “kí o sì bẹ ọmọnìkejì rẹ ní ẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dabọ̀”—nípa bíbẹ̀bẹ̀ léraléra. A gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun táa bá lè ṣe láti mú àwọn nǹkan tọ́. Ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ là á mọ́lẹ̀ pé: “Sá gbogbo ipá rẹ, títí dìgbà tóo bá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú elénìní rẹ, tí o sì yanjú ọ̀ràn náà, kí owó ìdúró rẹ má bàa di ohun tó máa kó ìwọ àti ìdílé rẹ sí wàhálà.” O ò sì gbọ́dọ̀ fi falẹ̀ rárá, nítorí ọba náà fi kún un pé: “Má fi oorun kankan fún ojú rẹ, tàbí ìtòògbé kankan fún ojú rẹ títàn yanran. Dá ara rẹ nídè bí àgbàlàǹgbó kúrò ní ọwọ́ náà àti bí ẹyẹ kúrò ní ọwọ́ pẹyẹpẹyẹ.” (Òwe 6:4, 5) Ó sàn láti jáwọ́ nínú àdéhùn kan tí kò mọ́gbọ́n dání nígbà tó bá ṣeé ṣe ju kí a kó sínú páńpẹ́ rẹ̀.
Jẹ́ Òṣìṣẹ́ Aláápọn Bí Eèrà
Sólómọ́nì ṣíni létí pé: “Tọ eèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ; wo àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì di ọlọ́gbọ́n.” Ọgbọ́n wo la lè kọ́ lára eèrà kékeré? Ọba náà dáhùn pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, tàbí onípò àṣẹ tàbí olùṣàkóso, ó ń pèsè oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ àní ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn; ó ti kó àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ jọ àní nígbà ìkórè.”—Òwe 6:6-8.
Àgbàyanu ni ọ̀nà tí àwọn eèrà gbà ṣètò ara wọn, wọ́n sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lọ́nà tó pẹtẹrí. Lọ́nà àdánidá, wọ́n máa ń kó oúnjẹ wọn jọ de ọjọ́ iwájú. Wọn ò ní “olùdarí, tàbí onípò àṣẹ tàbí olùṣàkóso.” Lóòótọ́, ọbabìnrin àwọn eèrà wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n ó kàn jẹ́ ọbabìnrin kìkì nítorí pé ó ń yé ẹyin, àti pé òun ni ìyá agbo náà ni. Kì í pàṣẹ kankan. Kódà láìsí ọ̀gá òṣìṣẹ́ tó ń tì wọ́n ṣiṣẹ́ tàbí alábòójútó tó ń yẹ̀ wọ́n wò, àwọn eèrà máa ń ṣiṣẹ́ láìsinmi ni.
Bíi ti eèrà, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn? Ṣíṣe iṣẹ́ ní àṣekára àti gbígbìyànjú láti jẹ́ kí iṣẹ́ wa túbọ̀ dáa sí i yóò ṣe wá láǹfààní, yálà wọ́n ń ṣọ́ wa tàbí wọn ò ṣọ́ wa. Bẹ́ẹ̀ ni o, bó jẹ́ ilé ìwé la wà ni o, tàbí níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa ni o, ì báà sì jẹ́ nígbà táa bá ń nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí pàápàá, a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Bí eèrà ṣe ń jàǹfààní nínú jíjẹ́ tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí àwa náà ‘rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára wa.’ (Oníwàásù 3:13, 22; 5:18) Ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ àti ayọ̀ àtọkànwá ni èrè iṣẹ́ àṣekára.—Oníwàásù 5:12.
Nípa lílo ìbéèrè mọ̀-ọ́n-nú méjì, Sólómọ́nì gbìyànjú láti ta onímẹ̀ẹ́lẹ́ ènìyàn jí kúrò nínú ìwà ọ̀lẹ rẹ̀, ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ, tí ìwọ yóò fi wà ní ìdùbúlẹ̀? Ìgbà wo ni ìwọ yóò dìde kúrò lójú oorun rẹ?” Ọba náà tún ń sín ọ̀lẹ jẹ, ó ní: “Oorun díẹ̀ sí i, ìtòògbé díẹ̀ sí i, kíká ọwọ́ pọ̀ díẹ̀ sí i ní ìdùbúlẹ̀, ipò òṣì rẹ yóò sì dé dájúdájú gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri kan, àti àìní rẹ bí ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra.” (Òwe 6:9-11) Ibi tí ọ̀lẹ sùn kaakà sí ni ipò òṣì yóò ti dé bá a, tí yóò sì kọlù ú bí olè, àìní yóò sì kọlù ú bí ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra. Kíá ni èpò àti èsìsì bo oko ọ̀lẹ. (Òwe 24:30, 31) Kò pẹ́ tí gbogbo òwò rẹ̀ fi pòórá. Ìgbà wo ni agbanisíṣẹ́ kan yóò máa wo ọ̀lẹ ènìyàn níran dà? Ǹjẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan tó lẹ ju isó lọ nídìí ìwé kíkà lè retí pé òun ó ṣe dáadáa nílé ìwé?
Jẹ́ Olóòótọ́
Nígbà tí Sólómọ́nì ń mẹ́nu kan ìwà mìíràn tó lè ba orúkọ ẹnì kan jẹ́ láwùjọ àti èyí tó lè ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó sọ pé: “Ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun, ènìyàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ń rìn tòun ti ọ̀rọ̀ wíwọ́, ó ń ṣẹ́jú, ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣe àmì, ó ń fi àwọn ìka rẹ̀ ṣe ìtọ́ka. Àyídáyidà ń bẹ nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Ó ń fẹ̀tàn hùmọ̀ ohun búburú ní gbogbo ìgbà. Ó ń rán kìkìdá asọ̀ jáde ṣáá.”—Òwe 6:12-14.
Àpèjúwe yìí bá ẹlẹ́tàn ènìyàn mu. Òpùrọ́ sábà máa ń wá ọ̀nà àtibo àìṣòtítọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Lọ́nà wo? Kì í ṣe nípa sísọ “ọ̀rọ̀ wíwọ́” nìkan, àmọ́ ó tún ń fi ara ṣàpèjúwe pẹ̀lú. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan là á mọ́lẹ̀ pé: “Fífara-ṣàpèjúwe, ohùn tí wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ àti ìrísí ojú pàápàá jẹ́ àwọn ọgbọ́n àdàkàdekè tí wọ́n fi ń tanni jẹ́; bí wọ́n tilẹ̀ ń ṣe bí olóòótọ́ inú, ojú ayé lásán ni, nítorí ọkàn wọn kún fún àyídáyidà àti ẹ̀mí asọ̀.” Irú ẹni tí kò dára fún ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ń fẹ̀tàn hùmọ̀ ohun búburú, ó sì ń fa asọ̀ ní gbogbo ìgbà. Báwo ni nǹkan ṣe máa rí fún un?
Ọba Ísírẹ́lì náà dáhùn pé: “Ìdí nìyẹn tí àjálù rẹ̀ yóò fi dé lójijì; ìṣẹ́jú akàn ni òun yóò ṣẹ́, kì yóò sì sí ìmúláradá.” (Òwe 6:15) Gbàrà tí àṣírí òpùrọ́ bá tú ni orúkọ rẹ̀ bà jẹ́. Ta ló tún máa fi ọkàn tán an? Òótọ́ ni pé àjálù yóò dé bá a nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, nítorí pé “gbogbo òpùrọ́” wà lára àwọn tí yóò kú ikú ayérayé. (Ìṣípayá 21:8) Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ jẹ́ kí a “máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
Kórìíra Ohun Tí Jèhófà Kórìíra
Kíkórìíra ohun búburú—ẹ ò rí i pé ìyẹn yóò mú ká yẹra fún híhu àwọn ìwà tó lè ba orúkọ rere wa jẹ́! Ǹjẹ́ kò yẹ ká kórìíra ohun tí kò dáa? Àmọ́, kí ni nǹkan tó yẹ ká kórìíra gan-an? Sólómọ́nì sọ pé: “Ohun mẹ́fà ní ń bẹ tí Jèhófà kórìíra ní tòótọ́; bẹ́ẹ̀ ni, méje ni ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún ọkàn rẹ̀: ojú gíga fíofío, ahọ́n èké, àti ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀, ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú, ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ, àti ẹnikẹ́ni tí ń dá asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.”—Òwe 6:16-19.
Ohun méje tí òwe náà mẹ́nu kàn ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan làwọn nǹkan tó ṣe kókó tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo ohun tó jẹ́ ibi ní àkótán. “Ojú gíga fíofío” àti “ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́,” jẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn máa ń dá nínú èrò. “Ahọ́n èké” àti “ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ” jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀. “Ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀” àti “ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú” jẹ́ àwọn ìṣe búburú. Ohun tí Jèhófà tún kórìíra gan-an ni kéèyàn ní inú dídùn sí dídá gbọ́nmisi-omi-ò-to sílẹ̀ láàárín àwọn tó yẹ kí wọ́n máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà. Bí iye náà ṣe lọ sókè láti orí mẹ́fà sí méje fi hàn pé kò tíì parí síbẹ̀, nítorí pé ìwà ibi àwọn ènìyàn yóò máa pọ̀ sí i ṣáá ni.
Láìsí àní-àní, a gbọ́dọ̀ kórìíra ohun tí Ọlọ́run kórìíra. Fún àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ yàgò fún “ojú gíga fíofío” tàbí ohunkóhun mìíràn tó jẹ mọ́ ìgbéraga. A sì gbọ́dọ̀ yẹra fún òfófó tí ń pani lára, nítorí ó lè tètè dá “asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.” Bí a bá ń tan àhesọ tí kò dára ká, tí a ń ṣe lámèyítọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tàbí ká máa parọ́, a lè máà “ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀,” àmọ́ ó dájú pé a lè tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ rere ẹlòmíràn jẹ́.
“Má Ṣe Fẹ́ Ẹwà Ojú Rẹ̀”
Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ abala kejì ìmọ̀ràn rẹ̀ nípa sísọ pé: “Ìwọ ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́, má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì. So wọ́n mọ́ ọkàn-àyà rẹ nígbà gbogbo; dè wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.” Torí kí ni? “Nígbà tí ìwọ bá ń rìn káàkiri, yóò máa ṣamọ̀nà rẹ; nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, yóò máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí rẹ; nígbà tí o bá sì jí, yóò máa fi ọ́ ṣe ìdàníyàn rẹ̀.”—Òwe 6:20-22.
Ǹjẹ́ fífi Ìwé Mímọ́ tọ́ni dàgbà lè dáàbò bò wá kúrò nínú ìdẹkùn ìwà pálapàla takọtabo? Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè dáàbò bò wá. A mú un dá wa lójú pé: “Àṣẹ jẹ́ fìtílà, òfin sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àwọn ìtọ́sọ́nà inú ìbáwí sì ni ọ̀nà ìyè, láti máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ obìnrin búburú, lọ́wọ́ dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ahọ́n obìnrin ilẹ̀ òkèèrè.” (Òwe 6:23, 24) Rírántí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a sì máa lò ó bí ‘fìtílà fún ẹsẹ̀ wa àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wa’ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìkésíni dídùn mọràn-ìn mọran-in látọ̀dọ̀ obìnrin burúkú, tàbí ọkùnrin burúkú pàápàá.—Sáàmù 119:105.
Ọlọ́gbọ́n ọba náà ṣí ni létí pé: “Má ṣe fẹ́ ẹwà ojú rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ, ǹjẹ́ kí ó má sì fi ojú rẹ̀ dídán gbinrin mú ọ.” Èé ṣe? “Nítorí pé, ní tìtorí kárùwà obìnrin, ènìyàn a di ẹni tí kò ní ju ìṣù búrẹ́dì ribiti kan ṣoṣo; ṣùgbọ́n ní ti aya ọkùnrin mìíràn, ó ń ṣọdẹ ọkàn tí ó ṣe iyebíye pàápàá.”— Òwe 6:25, 26.
Ṣé Sólómọ́nì tọ́ka sí aya oníṣekúṣe gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó ni? Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó sì tún lè jẹ́ pé ṣe ló fi ìyàtọ̀ sáàárín àbájáde lílọ bá aṣẹ́wó ṣèṣekúṣe àti lílọ bá aya ẹlòmíràn ṣe panṣágà. Ẹni tó ń lọ bá aṣẹ́wó ṣèṣekúṣe lè di “ẹni tí kò ní ju ìṣù búrẹ́dì ribiti kan ṣoṣo”—kí ó di tálákà paraku. Ó tiẹ̀ lè kó àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta àtaré rẹ̀, àwọn àrùn tí ń roni lára gógó tó sì ń sọni di olókùnrùn, títí kan àrùn aṣekúpani tí a ń pè ní éèdì. Ní ọ̀wọ́ kejì, kò ní pẹ́ tí ẹni tó ń ṣèṣekúṣe pẹ̀lú ọkọ tàbí aya ẹlòmíràn yóò kó ara rẹ̀ sínú ewu ńlá lábẹ́ Òfin. Aya tó jẹ́ panṣágà ń fi “ọkàn” tí ó ṣe iyebíye,” èyíinì ni ọkàn àlè rẹ̀, sínú ewu. Ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Kì í ṣe kìkì pé ìṣekúṣe tó ń ṣe lè ké ìgbésí ayé rẹ̀ kúrú . . . lohun tí à ń sọ níhìn-ín. Ìyà ikú ló tọ́ sí irú ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀.” (Léfítíkù 20:10; Diutarónómì 22:22) Lọ́rọ̀ kan ṣá, bó ti wù kí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ lẹ́wà tó, a ò gbọ́dọ̀ fojú sí i lára.
‘Má Ṣe Wa Iná Jọ sí Oókan Àyà Rẹ’
Sólómọ́nì tún tẹnu mọ́ ewu tó wà nínú ṣíṣe panṣágà, nípa bíbéèrè pé: “Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná? Tàbí kẹ̀, ṣé ọkùnrin kan lè rìn lórí ẹyín iná, kí ẹsẹ̀ rẹ̀ pàápàá má sì jó?” Ó wá sọ ìtumọ̀ àpèjúwe rẹ̀, ó ní: “Bákan náà ni pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya ọmọnìkejì rẹ̀, kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí kò ní yẹ fún ìyà.” (Òwe 6:27-29) Ó dájú pé irú ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò jìyà.
A rán wa létí pé: “Àwọn ènìyàn kì í tẹ́ńbẹ́lú olè kìkì nítorí pé ó jalè láti fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn nígbà tí ebi ń pa á.” Bí ebi tilẹ̀ ń pa á, “nígbà tí a bá rí i, òun yóò san án padà ní ìlọ́po méje; gbogbo àwọn ohun tí ó níye lórí nínú ilé rẹ̀ ni yóò fi lélẹ̀.” (Òwe 6:30, 31) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, olè kan ní láti san ohun tó jí padà, kódà bí gbogbo ohun tó ní tiẹ̀ máa bá ọ̀ràn náà rìn.a Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ìyà tó tọ́ sí panṣágà ọkùnrin kan, tí kò ní àwíjàre kankan fún ohun tó ṣe!
Sólómọ́nì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá obìnrin kan ṣe panṣágà jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún.” Ọkùnrin tí ọkàn-àyà kù fún jẹ́ ẹni tí kò ní òye, nítorí pé ó “ń run ọkàn ara rẹ̀.” (Òwe 6:32) Ní ìrísí, ó lè dà bí ẹni iyì, ẹni ẹ̀yẹ lójú àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n adàgbà-má-danú ni.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wé mọ́ èso tí onípanṣágà ń ká. “Yóò rí ìyọnu àti àbùkù, a kì yóò sì nu ẹ̀gàn rẹ̀ nù. Nítorí owú ni ìhónú abarapá ọkùnrin, kì yóò sì fi ìyọ́nú hàn ní ọjọ́ ẹ̀san. Kì yóò fi ìgbatẹnirò kankan hàn fún ìràpadà èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ẹ̀mí ìmúratán hàn, láìka bí o ti mú kí ẹ̀bùn náà pọ̀ tó.”—Òwe 6:33-35.
Olè lè san ohun tó jí padà, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí panṣágà lè rí san padà. Kí ló fẹ́ san padà fún ọkọ tí inú ń bí? Kò sí ẹ̀bẹ̀ tó lè bẹ̀ tó fi lè rí ìyọ́nú gbà. Kò sì sí ọ̀nà tí onípanṣágà náà lè gbà san ohunkóhun padà fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀gàn àti àbùkù tó ti kó bá orúkọ ara rẹ̀ kò lè kúrò láé. Láfikún sí i, kò sí bí ó ṣe lè ra ara rẹ̀ padà tàbí kí o gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìyà tí ó tọ́ sí i.
Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti sá fún panṣágà àti àwọn ìwà àti ìṣe mìíràn tó lè ba orúkọ rere wa jẹ́, tó sì lè mú ẹ̀gàn bá Ọlọ́run! Ǹjẹ́ kí a ṣọ́ra láti má ṣe àdéhùn òmùgọ̀. Ẹ jẹ́ kí jíjẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn àti jíjẹ́ olóòótọ́ ṣe orúkọ rere wa lọ́ṣọ̀ọ́. Bí a sì tí ń gbìyànjú láti kórìíra ohun tí Jèhófà kórìíra, ǹjẹ́ kí a máa ṣe orúkọ rere lọ́dọ̀ rẹ̀ àti lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Mósè, olè kan gbọ́dọ̀ san ohun tó jí padà ní ìlọ́po méjì, ìlọ́po mẹ́rin, tàbí ìlọ́po márùn-ún. (Ẹ́kísódù 22:1-4) Ọ̀rọ̀ náà “ìgbà méje” ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí ìyà tó kún rẹ́rẹ́, tó lè mú kó san ohun tó jí padà ní ọ̀pọ̀ ìlọ́po.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ṣọ́ra nípa bíbáni fọwọ́ sí owó yíyá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn bí eèrà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Yẹra fún òfófó tí ń pani lára