“Aláyọ̀ Ni Ènìyàn Tí Ó Ti Wá Ọgbọ́n Rí”
AKÉWÌ ni, ayàwòrán ilé ni, ó sì tún jẹ́ ọba. Bó ti jẹ́ pé iye tó lé ní igba mílíọ̀nù dọ́là ló ń wọlé fún un lọ́dọọdún, ó lọ́rọ̀ ju ọba èyíkéyìí lórí ilẹ̀ ayé. Ọgbọ́n tí ọkùnrin náà ní sì tún jẹ́ kí òkìkí rẹ̀ kàn. Èyí jọ ọbabìnrin kan tó ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ lójú tó fi kígbe pé: “Wò ó! a kò sọ ìdajì wọn fún mi. Ìwọ ta yọ ní ọgbọ́n àti aásìkí ré kọjá àwọn ohun tí a gbọ́ èyí tí mo fetí sí.” (1 Àwọn Ọba 10:4-9) Ipò tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì wà nìyẹn.
Sólómọ́nì ní ọrọ̀ àti ọgbọ́n. Ìyẹn gan-an ló mú kó tóótun láti pinnu èyí tó jẹ́ kòṣeémánìí nínú àwọn méjèèjì. Ó kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí, àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀, nítorí níní in gẹ́gẹ́ bí èrè sàn ju níní fàdákà gẹ́gẹ́ bí èrè, níní in gẹ́gẹ́ bí èso sì sàn ju níní wúrà pàápàá. Ó ṣe iyebíye ju iyùn, a kò sì lè mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí í ṣe inú dídùn rẹ bá a dọ́gba.”—Òwe 3:13-15.
Àmọ́, ibo la ti wá lè rí ọgbọ́n? Èé ṣe tó fi níye lórí ju ọrọ̀ lọ? Kí ló dé tí ànímọ́ yìí fi fani mọ́ra? Orí kẹjọ ìwé Òwe tí Sólómọ́nì kọ nínú Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn lọ́nà tó fani lọ́kàn mọ́ra. Ibẹ̀ la ti sọ̀rọ̀ ọgbọ́n bí ènìyàn, bí ẹni pé ó lè sọ̀rọ̀, kí ó sì dá nǹkan ṣe. Ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ènìyàn yìí fi bó ṣe fani mọ́ra àti bó ṣe níye lórí tó hàn.
‘Ó Ń Ké Tòò’
Orí kẹjọ ìwé Òwe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè onídàáhùn-un mọ̀ọ́nú kan pé: “Ọgbọ́n kò ha ń bá a nìṣó ní kíké jáde, tí ìfòyemọ̀ sì ń bá a nìṣó ní fífọ ohùn rẹ̀ jáde?”a Bẹ́ẹ̀ ni o, ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ń ké jáde, àmọ́ kì í ṣe bíi ti obìnrin oníṣekúṣe tó ń fara pa mọ́ sí àwọn ibi tó ṣókùnkùn, tó sì ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ tó fi ń tanni jẹ́ sétí ọ̀dọ́ kan tó ń dá nìkan rìn, tí kò sí nírìírí. (Òwe 7:12) “Ní orí àwọn ibi gíga, lẹ́bàá ọ̀nà, ibi ìsọdá àwọn òpópónà ni ó dúró sí. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè, ní ẹnu ìlú, ibi àtiwọ àwọn ẹnu ọ̀nà ni ó ti ń ké tòò.” (Òwe 8:1-3) Ohùn ọgbọ́n tó rinlẹ̀, tó sì ń dún kíkankíkan la ń gbọ́ ketekete ní àwọn ibi tí èrò pọ̀ sí—ní àwọn ẹnubodè, ní oríta, ní àtiwọ ìlú ńlá. Kò ṣòro fáwọn èèyàn láti gbọ́ ohùn yẹn kí wọ́n sì gbégbèésẹ̀.
Ta ló lè sẹ́ pé ọgbọ́n Ọlọ́run táa kọ sínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táa mí sí, wà lárọ̀ọ́wọ́tó olúkúlùkù tó fẹ́ ní in lórí ilẹ̀ ayé? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Bíbélì ni ìwé tí wọ́n tíì kà jù lọ nínú ìtàn.” Ó fi kún un pé: “Ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n ti pín káàkiri pọ̀ ju ti ìwé èyíkéyìí lọ. A sì ti túmọ̀ Bíbélì níye ìgbà tó pọ̀, àti sí èdè tó pọ̀ ju ti ìwé èyíkéyìí lọ.” Pẹ̀lú odindi Bíbélì tàbí àwọn apá kan níbẹ̀ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láwọn èdè àti èdè àdúgbò tó lé ní ẹgbàá lé ọgọ́rùn-ún [2,100] báyìí, ó lé ní ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn tó láǹfààní àtika ó kéré tán apá kan lára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè tiwọn.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kéde ìhìn Bíbélì fún gbogbo èèyàn níbi gbogbo. Igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ ni wọ́n ti ń fi taratara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ táa rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n gbé ka Bíbélì ni wọ́n ń tẹ̀ jáde ní ogóje [140] èdè, àti Jí!, tí wọ́n ń tẹ̀ jáde ní èdè mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] ni wọ́n ń pín èyí tó lé ní ogún mílíọ̀nù ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn káàkiri. Dájúdájú, ọgbọ́n ń ké tòò ní àwọn ibi tí èrò pọ̀ sí!
‘Ohùn Mi Ń Kọ sí Àwọn Ọmọ Ènìyàn’
Ọgbọ́n táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ̀yin ènìyàn ni mo ń pè, ohùn mi sì ń kọ sí àwọn ọmọ ènìyàn. Ẹ̀yin aláìní ìrírí, ẹ lóye ìfọgbọ́nhùwà; àti ẹ̀yin arìndìn, ẹ lóye ọkàn-àyà.”—Òwe 8:4, 5.
Ibi gbogbo ni ohùn ọgbọ́n dé. Gbogbo ènìyàn ló ń pè. Kódà ó ń pe àwọn aláìní ìrírí láti ní ìfọgbọ́nhùwà tàbí òye, ó sì ń pe àwọn arìndìn láti wá jèrè ìmọ̀. Ní ti tòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Bíbélì jẹ́ ìwé kan fún gbogbo ènìyàn, wọ́n sì ń sapá láìṣe ojúsàájú láti gba ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá bá pàdé níyànjú láti yẹ̀ ẹ́ wò kí wọ́n sì rí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú rẹ̀.
“Òkè Ẹnu Mi Ń Sọ Òtítọ́ Jáde”
Ọgbọ́n ń bá ọ̀rọ̀ ìkésíni rẹ̀ lọ, ó ní: “Ẹ fetí sílẹ̀, nítorí àwọn ohun àkọ́kọ́ ni mo ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ṣíṣí ètè mi sì jẹ́ nípa ìdúróṣánṣán. Nítorí òkè ẹnu mi ń sọ òtítọ́ jáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́; ìwà burúkú sì jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún ètè mi. Nínú òdodo ni gbogbo àsọjáde ẹnu mi. Kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ màgòmágó tàbí wíwọ́ nínú wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀kọ́ tí ọgbọ́n fi ń kọ́ni tayọ lọ́lá, ó dúró ṣánṣán, òtítọ́ àti òdodo sì ni. Kò sí ohun békebèke tàbí ohun wíwọ́ nínú wọn. “Gbogbo wọn jẹ́ títọ́ lójú ẹni tí ó ní ìfòyemọ̀, àti adúróṣánṣán lójú àwọn tí ó rí ìmọ̀.”—Òwe 8:6-9.
Lọ́nà tí ó bá a mu gẹ́ẹ́, ọgbọ́n rọ̀ wá pé “Ẹ gba ìbáwí mi kì í sì í ṣe fàdákà, àti ìmọ̀ dípò ààyò wúrà.” Ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí mọ́gbọ́n dání, “nítorí ọgbọ́n sàn ju iyùn, a kò sì lè mú gbogbo ohun mìíràn tí ń fúnni ní inú dídùn bá a dọ́gba.” (Òwe 8:10, 11) Àmọ́, kí ló fà á? Kí ló mú kí ọgbọ́n níye lórí ju ọrọ̀ lọ?
“Èso Mi Sàn Ju Wúrà”
Ẹ̀bùn tí ọgbọ́n ń fún àwọn tó fetí sí i níye lórí ju wúrà, fàdákà, tàbí iyùn. Nígbà tí ọgbọ́n ń to àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí lẹ́sẹẹsẹ, ó ní: “Èmi, ọgbọ́n, mo ń bá ìfọgbọ́nhùwà gbé, mo sì ti wá ìmọ̀ agbára láti ronú pàápàá rí. Ìbẹ̀rù Jèhófà túmọ̀ sí kíkórìíra ohun búburú. Mo kórìíra ìgbéra-ẹni-ga àti ìyangàn àti ọ̀nà búburú àti ẹnu tí ń ṣàyídáyidà.”—Òwe 8:12, 13.
Ọgbọ́n ń fi ìfọgbọ́nhùwà àti agbára láti ronú fún ẹni tó bá ní in. Ẹni tó ní ọgbọ́n Ọlọ́run tún ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run, nítorí pé “ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.” (Òwe 9:10) Nípa bẹ́ẹ̀, ó kórìíra ohun tí Jèhófà kórìíra. Ìjọra-ẹni-lójú, ìrera, ìwà pálapàla, àti ọ̀rọ̀ àyídáyidà jìnnà sí i. Ìkórìíra tó ní fún ohun tó burú ń dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ dídi ẹni tí agbára ń gùn. Ó mà kúkú ṣe pàtàkì o, pé kí àwọn tó ní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni àtàwọn olórí ìdílé máa wá ọgbọ́n!
Ọgbọ́n ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Mo ní ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n gbígbéṣẹ́. Èmi-òye; mo ní agbára ńlá. Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba ń jọba, tí àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì ń gbé àṣẹ òdodo kalẹ̀. Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọmọ aládé ń ṣàkóso bí ọmọ aládé, tí gbogbo àwọn ọ̀tọ̀kùlú sì ń ṣèdájọ́ ní òdodo.” (Òwe 8:14-16) Ìjìnlẹ̀ òye, ìmọ̀, àti agbára ńlá wà lára èso tí ọgbọ́n ní—ànímọ́ wọ̀nyí sì wúlò gan-an fún àwọn alákòóso, àwọn aláṣẹ onípò gíga, àtàwọn ọ̀tọ̀kùlú. Kòṣeémánìí ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tó wà ní ipò agbára àtàwọn tó máa ń fún àwọn ẹlòmíràn nímọ̀ràn.
Ọgbọ́n tòótọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo èèyàn, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń wá a rí. Àwọn mìíràn ò náání rẹ̀ àní wọ́n tiẹ̀ ń yẹra fún un, kódà nígbà tó wà ní igi imú wọn pàápàá. Ọgbọ́n sọ pe: “Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni èmi alára nífẹ̀ẹ́, àwọn tí ń wá mi sì ni àwọn tí ń rí mi.” (Òwe 8:17) Kìkì àwọn tó ń fi tọkàntọkàn wá ọgbọ́n ló ń ní ọgbọ́n.
Àwọn ọ̀nà ọgbọ́n dúró ṣánṣán, wọ́n sì jẹ́ òdodo. Ó ń san èrè fún àwọn tó ń wá a. Ọgbọ́n sọ pé: “Ọrọ̀ àti ògo ń bẹ lọ́dọ̀ mi, àwọn ohun àjogúnbá oníyelórí àti òdodo. Èso mi sàn ju wúrà, àní ju wúrà tí a yọ́ mọ́, àmújáde mi sì sàn ju ààyò fàdákà. Ipa ọ̀nà òdodo ni mo ń rìn, ní àárín àwọn òpópónà ìdájọ́, láti mú kí àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ní ohun ìní ti ara; mo sì mú kí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ wọn kí ó kún.”—Òwe 8:18-21.
Yàtọ̀ sí àwọn ànímọ́ títayọ bíi òye, agbára ìrònú, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ìjìnlẹ̀ òye, ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́, àti ìmọ̀, ọrọ̀ àti ọlá tún wà lára ẹ̀bùn tí ọgbọ́n ń fúnni. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn lè ní ọrọ̀ lọ́nà òdodo, yóò sì láásìkí nípa tẹ̀mí. (3 Jòhánù 2) Ọgbọ́n tún máa ń fi ọlá fún ènìyàn. Síwájú sí i, àwọn ohun tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn, yóò sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ẹ̀rí ọkàn rere níwájú Ọlọ́run. Dájúdájú, aláyọ̀ ni ènìyàn náà tí ó ti wá ọgbọ́n rí. Èso ọgbọ́n dára ju wúrà tí a yọ́ mọ́ àti ààyò fàdákà ní ti tòótọ́.
Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn yìí bá a mu wẹ́kú fún wa, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì là ń gbé, tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa di ọlọ́rọ̀ lọ́nàkọnà ni wọ́n ń tẹnu mọ́ ṣáá! Ǹjẹ́ kí a má ṣe gbàgbé bí ọgbọ́n ṣe níye lórí tó tàbí kí a má fi àìṣòdodo kó ọrọ̀ jọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a torí àtidi ọlọ́rọ̀ kí a wá ṣàìnáání àwọn ìpèsè tó ń fúnni lọ́gbọ́n—ìyẹn àwọn ìpàdé Kristẹni wa, ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè.—Mátíù 24:45-47.
“Láti Àkókò Tí Ó Lọ Kánrin Ní A Ti Gbé Mi Kalẹ̀”
Ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ènìyàn nínú orí kẹjọ ìwé Òwe kì í kàn-án ṣe ohun táa fi ń ṣàlàyé ànímọ́ kan tó fara sìn. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó tún ń tọ́ka sí ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìṣẹ̀dá Jèhófà. Ọgbọ́n ń bá a lọ ní sísọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ó ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà rẹ̀, ìbẹ̀rẹ̀pàá àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Láti àkókò tí ó lọ kánrin ni a ti gbé mi kalẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀, láti àwọn àkókò tí ó wà ṣáájú ilẹ̀ ayé. Nígbà tí kò sí àwọn ibú omi, a ti bí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí, nígbà tí kò sí àwọn ìsun tí omi kún dẹ́múdẹ́mú. Kí a tó fìdí àwọn òkè ńláńlá kalẹ̀, ṣáájú àwọn òkè kéékèèké, a ti bí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí, nígbà tí kò tíì ṣe ilẹ̀ ayé àti àwọn àyè gbayawu àti apá àkọ́kọ́ lára àwọn ìwọ́jọpọ̀ ekuru ilẹ̀ eléso.”—Òwe 8:22-26.
Ẹ ò rí i bí àpèjúwe tí a ṣe nípá ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ènìyàn ṣe bá ohun táa sọ nípa “Ọ̀rọ̀ náà” nínú Ìwé Mímọ́ mu wẹ́kú! Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ náà wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan.” (Jòhánù 1:1) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tọ́ka sí Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí kò tíì di ènìyàn.b
Jésù Kristi ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá; nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí.” (Kólósè 1:15, 16) Ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ g̣ẹ́gẹ́ bí ènìyàn ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nígbà tí ó [ Jèhófà] pèsè ọ̀run, mo wà níbẹ̀; nígbà tí ó fàṣẹ gbé òbìrìkìtì kalẹ̀ sí ojú ibú omi, nígbà tí ó mú àwọn ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ti òkè le gírígírí, nígbà tí ó mú kí àwọn ìsun ibú omi lágbára, nígbà tí ó fi àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ fún òkun pé kí omi rẹ̀ má ṣe ré àṣẹ ìtọ́ni òun kọjá, nígbà tí ó fàṣẹ gbé àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé kalẹ̀, nígbà náà ni mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ sí ilẹ̀ eléso ilẹ̀ ayé rẹ̀, àwọn ohun tí mo sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” (Òwe 8:27-31) Àkọ́bí Jèhófà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀, tó ń ṣiṣẹ́ àṣekára pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa aláìlẹ́gbẹ́, tó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé. Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run dá ènìyàn àkọ́kọ́, Ọmọ Rẹ̀ bá a lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Àgbà Òṣìṣẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Abájọ tí Ọmọ Ọlọ́run fi ní ire àwọn ènìyàn lọ́kàn gan-an, tó sì fẹ́ràn wọn!
“Aláyọ̀ Ni Ènìyàn Tí Ń Fetí sí Mi”
Gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ènìyàn, Ọmọ Ọlọ́run sọ pé: “Wàyí o, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi; bẹ́ẹ̀ ni, àní aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ọ̀nà mi mọ́. Ẹ fetí sí ìbáwí kí ẹ sì di ọlọ́gbọ́n, ẹ má sì fi ìwà àìnáání èyíkéyìí hàn. Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ń fetí sí mi nípa wíwà lójúfò lẹ́nu àwọn ilẹ̀kùn mi lójoojúmọ́, nípa ṣíṣọ́ arópòódògiri àwọn ẹnu ọ̀nà mi. Nítorí ẹni tí ó bá rí mi yóò rí ìyè dájúdájú, yóò sì rí ìfẹ́ rere gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá tàsé mi ń ṣe ọkàn ara rẹ̀ léṣe; gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan ni àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ ikú.”—Òwe 8:32-36.
Jésù Kristi gan-an ni ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. “Inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.” (Kólósè 2:3) Ẹ jẹ́ kí a fetí sí i dáadáa nígbà náà, kí a sì máa tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. (1 Pétérù 2:21) Kíkọ̀ ọ́ sílẹ̀ túmọ̀ sí ṣíṣe ọkàn wa léṣe àti nínífẹ̀ẹ́ ikú nítorí pé “kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn.” (Ìṣe 4:12) Àní, ẹ jẹ́ kí a tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run ti pèsè fún ìgbàlà wa. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Nípa bẹ́ẹ̀, a óò gbádùn ayọ̀ tó ń wá látinú ‘rírí ìyè àti rírí ìfẹ́ rere gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà.’
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “ọgbọ́n” jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún obìnrin. Ìdí nìyẹn táwọn ìtumọ̀ kan fi lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún obìnrin nígbà tí wọ́n ń tọ́ka sí ọgbọ́n.
b Kókó náà pé ọ̀rọ̀ Hébérù fún “ọgbọ́n” sábà máa ń jẹ́ ọ̀rọ̀ táa ń lò fún obìnrin kò tako bí a ṣe lo ọgbọ́n láti dúró fún Ọmọ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ táa ń lò fún obìnrin ni a tún lò fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà “ìfẹ́” nínú gbólóhùn tó sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Síbẹ̀ a lò ó láti tọ́ka sí Ọlọ́run.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kòṣeémánìí ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tó wà nípò àṣẹ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Má ṣàìnáání àwọn ìpèsè tó ń fúnni lọ́gbọ́n