Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tóò, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
• Báwo ni “agbára láti ronú” ṣe lè jẹ́ ohun tó ń fi ìṣọ́ ṣọ́ni? (Òwe 1:4)
Ó lè jẹ́ ká wà lójúfò sí àwọn ewu nípa tẹ̀mí, ó sì lè sún wa láti wéwèé ìgbésẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání, bíi kéèyàn yàgò fún ìdẹwò ṣíṣe ìṣekúṣe níbi iṣẹ́. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kì í ṣe ẹni pípé, ìyẹn sì lè mú ká yẹra fún títètè bínú nígbà tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá. Ó tún lè mú kó ṣeé ṣe fún wa láti yẹra fún ìdẹwò ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tó lè tì wá kúrò lójú ọ̀nà tẹ̀mí.—8/15, ojú ìwé 21-24.
• Báwo lẹnì kan ṣe lè di aládùúgbò tó ṣeyebíye?
Ọ̀nà méjì láti jẹ́ aládùúgbò rere ni pé kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́ kó sì tún jẹ́ ẹni tó máa ń moore. Ó ṣeyebíye láti jẹ́ aládùúgbò rere nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti jẹ́ aládùúgbò rere nípa kíkìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò wáyé láìpẹ́, ìyẹn ni ìgbésẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ́ gbé láti fòpin sí ìwà ibi.—9/1, ojú ìwé 4-7.
• Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì wí, àwọn wo ni ẹni mímọ́ tòótọ́, báwo ni wọ́n sì ṣe máa ran aráyé lọ́wọ́?
Gbogbo àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni ẹni mímọ́ tòótọ́, Ọlọ́run ló sì sọ wọ́n dà bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ènìyàn tàbí àwọn ètò àjọ. (Róòmù 1:7) Gbàrà táwọn ẹni mímọ́ bá ti jíǹde sí ìwàláàyè ti ọ̀run ni wọ́n á máa bá Kristi kópa nínú bíbùkún àwọn olóòótọ́ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Éfésù 1:18-21)—9/15, ojú ìwé 5-7.
• Àǹfààní wo ni mímọ ohun kan nípa àwọn eré ìdárayá ilẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì lè jẹ́ fáwọn Kristẹni?
Àwọn lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù kọ ní àwọn àpèjúwe tó pe àfiyèsí ẹni sórí àwọn eré ìdárayá ìgbàanì. (1 Kọ́ríńtì 9:26; 1 Tímótì 4:7; 2 Tímótì 2:5; 1 Pétérù 5:10) Ó ṣe pàtàkì fún eléré ìdárayá ìgbàanì láti ní olùdánilẹ́kọ̀ọ́ tó dáńgájíà, láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu, àti láti darí ìsapá rẹ̀ dáadáa. Ohun kan náà ló sì ṣe pàtàkì fún ìsapá tẹ̀mí àwọn Kristẹni òde òní.—10/1, ojú ìwé 28-31.
• Kí ni ìpèníjà àti èrè tó wà nínú títọ́ ọmọ nílẹ̀ òkèèrè?
Àwọn ọmọdé tètè máa ń gbọ́ èdè tuntun ju àwọn òbí wọn lọ, ìyẹn lè jẹ́ kó ṣòro fáwọn òbí láti lóye èrò àti ìṣe àwọn ọmọ wọn. Àwọn ọmọ sì lè má tètè lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì ní èdè àwọn òbí wọn. Síbẹ̀, ìdè àárín ìdílé lè lókun sí i báwọn òbí ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní èdè àbínibí tiwọn, àwọn ọmọ sì lè tipa bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè méjì, àṣà ìbílẹ̀ méjì á sì mọ́ wọn lára pẹ̀lú.—10/15, ojú ìwé 22-26.
• Èé ṣe tí kíkọ́ béèyàn ṣe ń tọrọ àforíjì fi ṣe pàtàkì?
Títọrọ àforíjì látọkànwá sábà máa ń jẹ́ ọ̀nà láti tún àjọṣe tó ti bà jẹ́ ṣe. Bíbélì fúnni láwọn àpẹẹrẹ tó fi agbára tí títọrọ àforíjì lè ní hàn. (1 Sámúẹ́lì 25:2-35; Ìṣe 23:1-5) Lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà tí ẹni méjì bá ní aáwọ̀, àwọn méjèèjì ló máa ń ní ibi tí wọ́n ti jẹ̀bi. Nítorí náà yíyanjú ọ̀ràn ní ìtùnbí ìnùbí àti títọrọ àforíjì ṣe pàtàkì.—11/1, ojú ìwé 4-7.
• Èé ṣe tí tẹ́tẹ́ títa fi lòdì bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tá a ó fi ta á kò ju táṣẹ́rẹ́ lọ?
Tẹ́tẹ́ títa lè mú kéèyàn di ẹni tí ń gbé ara rẹ̀ lárugẹ, tó ní ẹ̀mí ìdíje, àti ìwọra, èyí tí Bíbélì kórìíra. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún ló jẹ́ pé orí kíkọ́ iyàn kéékèèké nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀.—11/1, ojú ìwé 31.
• Nígbà tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé inú Bíbélì la fi èdè Gíríìkì kọ níbẹ̀rẹ̀, èé ṣe tá a tún wá ń túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gíríìkì, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
Èdè Gíríìkì òde òní yàtọ̀ pátápátá sí èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ ìtumọ̀ Septuagint ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó sì yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n fi kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Láwọn ọ̀rúndún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti sapá gidi gan-an láti tẹ apá kan lára Bíbélì tàbí gbogbo rẹ̀ jáde ní èdè Gíríìkì táwọn èèyàn ń sọ. Lónìí, wọ́n ti tẹ nǹkan bí ọgbọ̀n ìtumọ̀ Bíbélì táwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì lè kà kí wọ́n sì lóye rẹ̀ jáde yálà lódindi tàbí lápá kan. Èyí tó múná dóko jù lọ nínú wọn ni ẹ̀dà ti Gíríìkì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tá a tẹ̀ jáde ní 1997.—11/15, ojú ìwé 26-29.
• Èé ṣe tá ò fi béèrè pé káwọn Kristẹni máa san ìdá mẹ́wàá?
Lábẹ́ Òfin tá a fún Ísírẹ́lì ìgbàanì, ìdá mẹ́wàá ni wọ́n fi ń ṣètìlẹyìn fún ẹ̀yà Léfì, òun ni wọ́n sì fi ń gbọ́ bùkátà àwọn aláìní. (Léfítíkù 27:30; Diutarónómì 14:28, 29) Ikú ìrúbọ Jésù ti fòpin sí Òfin náà àti ìdá mẹ́wàá tó béèrè fún. (Éfésù 2:13-15) Nínú àwọn ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń rówó ná ni pé kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan ṣètọrẹ bí agbára rẹ̀ bá ṣe mọ àti bí ó bá ṣe pinnu nínú ọkàn rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 9:5, 7)—12/1, ojú ìwé 4-6.
• Ṣé ohun tí Ìṣípayá 20:8 túmọ̀ sí ni pé àwọn tó pọ̀ rẹpẹtẹ ni Sátánì máa ṣì lọ́nà nígbà ìdánwò ìkẹyìn?
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà sọ pé àwọn tó ṣì lọ́nà yóò “rí bi iyanrìn òkun.” Nínú Bíbélì, gbólóhùn náà sábà máa ń túmọ̀ sí iye tí a kò mọ̀, láìfi hàn pé ó jẹ́ iye tó pọ̀ lọ́nà kíkàmàmà. Irú ọmọ Ábúráhámù tá a sọ pé yóò rí “bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun,” wá jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì láìka Jésù Kristi mọ́ ọn. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17; Ìṣípayá 14:1-4)—12/1, ojú ìwé 29.