Ẹ̀KỌ́ 17
Irú Ẹni Wo Ni Jésù?
Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe nígbà tó wà láyé, à ń rí àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ tó jẹ́ ká sún mọ́ òun àti Jèhófà Bàbá rẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìwà àti ìṣe Jésù? Báwo la ṣe lè fára wé Jésù nígbèésí ayé wa?
1. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà jọ Bàbá rẹ̀?
Nígbà tí Jésù wà lọ́run, ó ń kíyè sí bí Bàbá rẹ̀ ṣe ń fìfẹ́ ṣe nǹkan, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ fún àìmọye ọdún. Èyí jẹ́ kó jọ Bàbá rẹ̀ ní èrò, ní ìwà àti ní ìṣe. (Ka Jòhánù 5:19.) Kódà, Jésù fìwà jọ Bàbá rẹ̀ gan-an débi tó fi sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jòhánù 14:9) Bó o bá ṣe ń mọ ìwà àti ìṣe Jésù sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa mọ Jèhófà. Bí apẹẹrẹ, bí Jésù ṣe fàánú hàn sáwọn èèyàn jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó.
2. Àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
Jésù sọ pé: “Kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, ohun tí Baba pa láṣẹ fún mi pé kí n ṣe gẹ́lẹ́ ni mò ń ṣe.” (Jòhánù 14:31) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá ẹ̀ gan-an torí ó ń ṣègbọràn sí Bàbá ẹ̀ kódà nígbà tí kò rọrùn fún un. Jésù tún fẹ́ràn kó máa sọ̀rọ̀ nípa Bàbá ẹ̀ fáwọn èèyàn, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Jòhánù 14:23.
3. Àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?
Bíbélì sọ pé Jésù “fẹ́ràn aráyé lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” (Òwe 8:31, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ìdí nìyẹn tó fi ń fún wọn níṣìírí, tó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ látọkàn wá. Ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó fi hàn pé kì í ṣe agbára nìkan ló ní àmọ́ ó tún lójú àánú. (Máàkù 1:40-42) Ó ṣoore fáwọn èèyàn, kò sì ṣojúsàájú ẹnì kankan. Ó sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn olóòótọ́ ọkàn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì mú kí wọ́n nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Jésù múra tán láti jìyà kó sì kú nítorí ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo aráyé. Àmọ́, àwọn tó ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣèwà hù ló fẹ́ràn jù.—Ka Jòhánù 15:13, 14.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìwà àti ìṣe Jésù. Kó o sì kọ́ bó o ṣe lè máa fìfẹ́ hàn, kó o sì máa ṣoore bíi ti Jésù.
4. Jésù nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀
Jésù kọ́ wa bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ka Lúùkù 6:12 àti Jòhánù 15:10; 17:26. Lẹ́yìn tó o bá ti ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, dáhùn ìbéèrè yìí:
Bíi ti Jésù, báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
5. Jésù ṣàánú àwọn aláìní
Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ká Jésù lára ju ọ̀rọ̀ tara ẹ̀ lọ. Kódà nígbà tó rẹ̀ ẹ́, ó ṣì lo àkókò àti okun rẹ̀ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ka Máàkù 6:30-44, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
6. Ọ̀làwọ́ ni Jésù
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò ní ohun ìní tó pọ̀, ó lawọ́ sáwọn èèyàn, ó sì rọ̀ wá pé káwa náà jẹ́ ọ̀làwọ́. Ka Ìṣe 20:35, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tá a bá fẹ́ láyọ̀, kí ni Jésù sọ pé ká máa ṣe?
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ṣoore fáwọn èèyàn bá ò tiẹ̀ ní ohun tó pọ̀?
Ǹjẹ́ o mọ̀?
Bíbélì kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà lórúkọ Jésù. (Ka Jòhánù 16:23, 24.) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì ohun tí Jésù ṣe fún wa ká lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà.
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ìyà tó ń jẹ wá ti pọ̀ jù, Ọlọ́run ò rí ti wa rò jàre.”
Báwo ni ìwà àti ìṣe Jésù ṣe fi hàn pé Jèhófà fẹ́ràn wa?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jésù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Jésù fìwà jọ Bàbá rẹ̀, tórí náà, bá a bá ṣe ń mọ Jésù sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa mọ Jèhófà.
Kí lo rí kọ́?
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi ti Jésù?
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bíi ti Jésù?
Èwo lo fẹ́ràn jù lára àwọn ìwà àti ìṣe Jésù?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè rí díẹ̀ lára àwọn ìwà àti ìṣe Jésù tó yẹ kí gbogbo wa ní.
“Tó O Bá Fẹ́ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù, Ó Yẹ Kó O . . . ” (Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè, ojú ìwé 317)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà lórúkọ Jésù.
“Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbọ́dọ̀ Gbàdúrà Lórúkọ Jésù?” (Ilé Ìṣọ́, February 1, 2008)
Ṣé Bíbélì sọ nǹkan kan nípa bí Jésù ṣe rí?
Kí la rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe hùwà sáwọn obìnrin?
“Wọ́n Wà Ní Ipò Ọ̀wọ̀ àti Iyì Lójú Ọlọ́run” (Ilé Ìṣọ́, September 1, 2012)