“Ìgbà Dídákẹ́”
ÀWỌN èèyàn máa ń sọ pé “ẹyin lohùn tó bá bọ́ kì í ṣeé kó,” ìyẹn ni pé, àwọn àkókò kan wà tó sàn kéèyàn dákẹ́ ju kó sọ̀rọ̀ lọ. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì ti ìlú Ísírẹ́lì ìgbàanì pẹ̀lú kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.”—Oníw. 3:1, 7.
Ìgbà wo gan-an ló yẹ kéèyàn dákẹ́ jẹ́ẹ́ dípò kó sọ̀rọ̀? Ó fẹ́ẹ̀ tó ogóje [140] ìgbà táwọn ọ̀rọ̀ náà “dákẹ́,” “dákẹ́ jẹ́ẹ́” àti “dídákẹ́” fara hàn nínú Bíbélì. Ó kéré tán, àwọn apá ibi tá a ti lo ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ ọ̀nà mẹ́ta tó ti ṣe pàtàkì pé kéèyàn wà ní dídákẹ́ jẹ́ẹ́ nígbèésí ayé. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ ṣe jẹ́ àmì ọ̀wọ̀, bó ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé èèyàn gbọ́n àti ọ̀nà láti ṣàṣàrò.
Àmì Ọ̀wọ̀
Béèyàn bá dákẹ́, ó jẹ́ àmì ọ̀wọ̀ tàbí bíbu ọlá fúnni. Wòlíì Hábákúkù sọ pé: “Jèhófà ń bẹ nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú rẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé!” (Háb. 2:20) Àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti “dúró, àní ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, de ìgbàlà Jèhófà.” (Ìdárò 3:26) Ọ̀kan lára àwọn onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà kí o sì fi ìyánhànhàn dúró dè é. Má ṣe gbaná jẹ mọ́ ẹnikẹ́ni tí ń mú kí ọ̀nà rẹ̀ kẹ́sẹ járí, sí ènìyàn tí ń mú èrò-ọkàn rẹ̀ ṣẹ.”—Sm. 37:7.
Ǹjẹ́ a lè yin Jèhófà láìsọ̀rọ̀? Ó dáa, ǹjẹ́ kì í yà wá lẹ́nu débi tá ò fi ní lè sọ̀rọ̀ nígbà míì tá a bá ń wo àwọn nǹkan ẹlẹ́wà tí Ọlọ́run dá? Kò sí àní-àní pé ríronú lórí àwọn ohun àgbàyanu tí Ẹlẹ́dàá ṣe jẹ́ ọ̀nà kan láti yìn ín nínú ọkàn wa! Onísáàmù náà Dáfídì bẹ̀rẹ̀ ọ̀kan lára àwọn orin atunilára tó kọ báyìí pé: “Ìyìn ń bẹ fún ọ ìdákẹ́jẹ́ẹ́, Ọlọ́run, ní Síónì; Ìwọ ni a ó sì san ẹ̀jẹ́ fún.”—Sm. 65:1.
Bí Jèhófà ti yẹ lẹ́ni tá à ń bọ̀wọ̀ fún náà ló ṣe yẹ ká bọ̀wọ̀ fáwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Mósè wòlíì Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ ìdágbére fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, òun àtàwọn àlùfáà gba àwọn tó wà níbẹ̀ níyànjú pé: “Dákẹ́ jẹ́ẹ́ . . . , kí ìwọ sì fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Àwọn ọmọdé wà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí wọ́n bá pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ láti ka Òfin Ọlọ́run fún wọn. Mósè sọ pé: “Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké . . . kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́.”—Diu. 27:9, 10; 31:11, 12.
Lákòókò wa yìí, ẹ ò rí i pé ó yẹ káwọn olùjọ́sìn Jèhófà máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fetí sílẹ̀ sáwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń rí gbà láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ! Ẹ gbọ́ ná, ṣó fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ètò Ọlọ́run bó bá jẹ́ pé ńṣe là ń tàkúrọ̀sọ nígbà tí wọ́n bá ń ṣàlàyé àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì látinú Bíbélì látorí pèpéle? Àkókò tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́ jẹ́ àkókò tó yẹ ká dákẹ́ jẹ́ẹ́ ká sì fetí sílẹ̀.
Kódà, bí àwa àtẹnì kan bá ń sọ̀rọ̀, ó máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ẹni náà tá a bá fetí sí ohun tó fẹ́ sọ. Bí àpẹẹrẹ, baba ńlá náà Jóòbù sọ fáwọn tó ń ta kò ó pé: “Ẹ fún mi ní ìtọ́ni, àní èmi, ní tèmi, yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́.” Jóòbù gbà láti dákẹ́ kó sì fetí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Nígbà tó sì tákòókò fún un láti sọ̀rọ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ dákẹ́ níwájú mi, kí èmi alára lè sọ̀rọ̀.”—Jóòbù 6:24; 13:13.
Ẹ̀rí Pé Èèyàn Gbọ́n
Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” “Ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ gbígbòòrò ni ẹni tí ó dákẹ́.” (Òwe 10:19; 11:12) Wo ọ̀nà tó dára tí Jésù gbà fi ọgbọ́n hàn nípa dídákẹ́ jẹ́ẹ́. Nígbà tí Jésù fòye mọ̀ pé kò ní bọ́gbọ́n mu kóun sọ̀rọ̀ láàárín àwọn ọ̀tá òun tí inú ń bí, ńṣe ni “Jésù dákẹ́.” (Mát. 26:63) Nígbà tó yá, tí wọ́n ń fẹ̀sùn kàn án níwájú Pílátù, Jésù “kò dáhùn.” Ńṣe ló fọgbọ́n ṣe é, ó yàn pé kí àwọn ohun tí òun ti ṣe jẹ́rìí.—Mát. 27:11-14.
Ìwà ọgbọ́n ló máa jẹ́ tá a bá dákẹ́, ní pàtàkì, nígbà tí inú bá ń bí wa. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́ aláìnísùúrù ń gbé ìwà òmùgọ̀ ga.” (Òwe 14:29) Tá a bá fi ìwàǹwára sọ̀rọ̀ nígbà tínú ṣì ń bí wa, a lè ṣọ̀rọ̀ sọ, tá a sì lè wá kábàámọ̀ rẹ̀ nígbà tó bá yá. Nírú àkókò yìí, a lè sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èyí á sì bà ayọ̀ wa jẹ́.
Ó máa fi hàn pé a gbọ́n tá a bá kíyè sí ohun tá a máa sọ nígbà tá a bá ń bá àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ ìlànà Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Nígbà tá a bá pàdé àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó lè jẹ́ dídákẹ́ lohun tó máa dáa jù. Nígbà táwọn ọmọ iléèwé tàbí ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bá dá àpárá tí kò dáa tàbí tí wọ́n ń sọ̀rọ̀kọ́rọ̀, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká dákẹ́, kí ọ̀rọ̀ tàbí ìṣesí wa máa bàa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ sóhun tí wọ́n sọ? (Éfé. 5:3) Ọ̀kan lára àwọn onísáàmù sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò fi ìdínu tí ó rí bí ẹ̀ṣọ́ dí ẹnu mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹni burúkú bá ti wà ní iwájú mi.”—Sm. 39:1.
Ẹni tó ní “ìfòyemọ̀ gbígbòòrò” ò ní tú ọ̀rọ̀ àṣírí. (Òwe 11:12) Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń rí i dájú pé àwọn ò tú ọ̀rọ̀ àṣírí. Ní pàtàkì, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra lápá yìí káwọn ará ìjọ bàa lè máa fọkàn tán wọn.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé dídákẹ́ gba pé kéèyàn má sọ̀rọ̀, síbẹ̀ ó máa ń ní ipa tó lágbára. Nígbà tí òǹkọ̀wé èdè Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́, Sydney Smith, tó gbáyé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń sọ nípa alájọgbáyé ẹ̀ kan, ó ní: “Bó ṣe máa ń dákẹ́ lẹ́kọ̀ọ̀kan máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó bá sọ nítumọ̀ kó sì tu èèyàn lára.” Bí ọ̀rẹ́ méjì bá ń sọ̀rọ̀, àwọn méjèèjì ló gbọ́dọ̀ máa sọ̀rọ̀ kì í ṣe ẹnì kan. Ẹni tó mọ bá a ti ń fọ̀rọ̀wérọ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń fetí sílẹ̀ dáadáa.
Sólómọ́nì kìlọ̀ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” (Òwe 10:19) Torí náà, béèyàn ò bá sọ̀rọ̀ jù, àṣìṣe téèyàn máa ṣe ò ní pọ̀. Bíbélì pàápàá tiẹ̀ sọ pé: “Ẹni tí ó tilẹ̀ ya òmùgọ̀, nígbà tí ó bá dákẹ́, ni a ó kà sí ọlọ́gbọ́n; ẹni tí ó pa ètè ara rẹ̀ dé, ni a ó kà sí ẹni tí ó ní òye.” (Òwe 17:28) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bẹ Jèhófà pé kó ‘yan ìṣọ́ síbi ilẹ̀kùn ètè wa.’—Sm. 141:3.
Ọ̀nà Láti Ṣàṣàrò
Nígbà tí Ìwé Mímọ́ ń sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń rìn lọ́nà òtítọ́, ó ní, “ó . . . ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.” (Sm. 1:2) Nínú Bibeli Mimọ gbólóhùn yẹn kà pé: “Ninu ofin rẹ̀ . . . o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru.” Ibo ló ti yẹ kéèyàn ṣe irú àṣàrò bẹ́ẹ̀?
Ísákì tó jẹ́ ọmọ baba ńlá náà Ábúráhámù, “ń rìn níta kí ó lè ṣe àṣàrò nínú pápá nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ ní ìrọ̀lẹ́.” (Jẹ́n. 24:63) Ó yan àkókò tí kò sáriwo àti ibi tó pa rọ́rọ́ láti ṣàṣàrò. Ní ti Dáfídì Ọba, ọ̀gànjọ́ òru tí kò sáriwo ló máa ń ṣàṣàrò. (Sm. 63:6) Bí Jésù tiẹ̀ jẹ́ ẹni pípé, síbẹ̀ ó sapá láti wá ibi àdádó kó bàa lè ṣàṣàrò, ibi tóun nìkan máa wà lórí òkè àti aṣálẹ̀ tí ariwo àwọn èèyàn ò ti ní dí i lọ́wọ́.—Mát. 14:23; Lúùkù 4:42; 5:16.
Ara máa ń tuni téèyàn bá wà níbi tó pa rọ́rọ́. Àyíká tó dákẹ́ rọ́rọ́ lè jẹ́ kéèyàn láǹfààní láti ṣàyẹ̀wò ara ẹni lọ́nà tó nítumọ̀, èyí sì ṣe pàtàkì béèyàn bá fẹ́ tẹ̀síwájú. Àyíká tó pa rọ́rọ́ lè jẹ́ kéèyàn ní àlàáfíà ọkàn. Àṣàrò téèyàn ṣe níbi tí kò sáriwo lè mú kéèyàn jẹ́ ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, kó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó tún lè jẹ́ kéèyàn mọyì àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dáa kéèyàn dákẹ́, síbẹ̀ “ìgbà sísọ̀rọ̀” tún wà. (Oníw. 3:7) Lónìí, ọwọ́ àwọn olùjọsìn tòótọ́ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i, à ń gbọ́ bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń fìdùnnú hó ìhó ayọ̀. (Míkà 2:12) Ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti wà lára àwọn tó ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa sọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀. Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí, ǹjẹ́ kí gbogbo ohun tá a bá ń ṣe fi hàn pé a mọyì pé ìgbà kan wà tó yẹ kéèyàn dákẹ́ jẹ́ẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ó yẹ ká máa fetí sílẹ̀ ká sì kẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó lè jẹ́ pé ohun tó máa dáa jù ni pé ká dákẹ́ jẹ́ẹ́ nígbà táwọn kan bá ń bú wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ibi tó pa rọ́rọ́ ló dáa jù lọ láti ṣàṣàrò