Jẹ́ Kí Ọkàn Àyà Rẹ Fà Sí Ìfòyemọ̀
“Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.”—ÒWE 2:6, NW.
1. Báwo ni a ṣe lè jẹ́ kí ọkàn àyà wa fà sí ìfòyemọ̀?
JÈHÓFÀ ni Atóbilọ́lá Olùfúnni Nítọ̀ọ́ni wa. (Aísáyà 30:20, 21) Ṣùgbọ́n, kí ni a lè ṣe láti jàǹfààní nínú “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an,” tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣí payá? Lọ́nà kan, a gbọ́dọ̀ ‘jẹ́ kí ọkàn àyà wa fà sí ìfòyemọ̀’—kí a ní ìfẹ́ àtọkànwá láti jèrè ànímọ́ yìí, kí a sì fi í hàn. Láti lè ṣe èyí, a gbọ́dọ̀ yíjú sí Ọlọ́run, nítorí ọlọgbọ́n ọkùnrin náà sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.” (Òwe 2:1-6, NW) Kí ni ìmọ̀, ọgbọ́n, àti ìfòyemọ̀?
2. (a) Kí ni ìmọ̀? (b) Báwo ni ìwọ yóò ṣe túmọ̀ ọgbọ́n? (d) Kí ni ìfòyemọ̀?
2 Ìmọ̀ jẹ́ dídi ojúlùmọ̀ àwọn òkodoro òtítọ́ tí a jèrè láti inú ìrírí, àkíyèsí, tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́. Ọgbọ́n jẹ́ agbára láti lo ìmọ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́. (Mátíù 11:19) Ọba Sólómọ́nì fi ọgbọ́n hàn nígbà tí àwọn obìnrin méjì ń jàdu ọmọ kan náà, ó sì lo ìmọ̀ tí ó ní, nípa bí ìyá ṣe ń fi ara rẹ̀ jin ọmọ inú rẹ̀, láti yanjú aáwọ̀ náà. (Àwọn Ọba Kìíní 3:16-28) Ìfòyemọ̀ jẹ́ “ṣíṣèpinnu gígún régé.” Ó jẹ́ “agbára tàbí ọgbọ́n èrò inú tí ń fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ohun kan àti òmíràn.” (Webster’s Universal Dictionary) Bí a bá jẹ́ kí ọkàn àyà wa fà sí ìfòyemọ̀, Jèhófà yóò fún wa nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀. (Tímótì Kejì 2:1, 7) Ṣùgbọ́n, báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè nípa lórí onírúurú apá ìgbésí ayé wa?
Ìfòyemọ̀ àti Ọ̀rọ̀ Ẹnu Wa
3. Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé Òwe 11:12, 13 àti ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ “ẹni tí ọkàn àyà kù fún”?
3 Ìfòyemọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé, “ìgbà dídákẹ́ àti ìgbà fífọhùn” wà. (Oníwàásù 3:7) Ànímọ́ yí tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣọ́ ohun tí a ń sọ. Òwe 11:12, 13, (NW) sọ pé: “Ẹni tí ọkàn àyà kù fún ti tẹ́ńbẹ́lú ọmọnìkejì rẹ̀, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ gbígbòòrò ni ẹni tí ó dákẹ́. Ẹni tí ń rìn káàkiri gẹ́gẹ́ bí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ a máa tú ọ̀rọ̀ àṣírí síta, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ ní ẹ̀mí a máa bo ọ̀ràn mọ́lẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, “ọkàn àyà kù fún” ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó bá ń tẹ́ńbẹ́lú ẹlòmíràn. Gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ èdè náà, Wilhelm Gesenius, ti sọ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ “aláìlóye.” Kò lè ṣèpinnu yíyè kooro, ọ̀nà tí a sì gbà lo èdè náà, “ọkàn àyà,” fi hàn pé, kò ní àwọn ànímọ́ rere ti ẹni inú lọ́hùn-ún. Bí ẹnì kan tí ó pe ara rẹ̀ ní Kristẹni bá bá bórobòro rẹ̀ dórí fífọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ tàbí kíkẹ́gàn ẹni, àwọn alàgbà tí a yàn sípò gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti fi òpin sí ipò tí kò bára dé yìí, nínú ìjọ.—Léfítíkù 19:16; Orin Dáfídì 101:5; Kọ́ríńtì Kíní 5:11.
4. Kí ni àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́, tí ó ní ìfòyemọ̀, ń ṣe nípa ìsọfúnni tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àṣírí?
4 Láìdà bí àwọn “tí ọkàn àyà kù fún,” àwọn tí ó ní “ìfòyemọ̀ gbígbòòrò” máa ń dákẹ́, nígbà tí ó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọn kì í tú ọ̀rọ̀ àṣírí síta. (Òwe 20:19) Ní mímọ̀ pé ọ̀rọ̀ bótobòto lè ṣèpalára, àwọn ẹni ìfòyemọ̀ máa ń jẹ́ “olùṣòtítọ́ ní ẹ̀mí.” Wọ́n máa ń jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn kì í sì í tú ọ̀rọ̀ àṣírí, tí ó lè fi àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn sínú ewu. Bí àwọn Kristẹni tí ó ní ìfòyemọ̀ bá gba ìsọfúnni èyíkéyìí tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àṣírí, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọ, wọ́n máa ń pa á mọ́ láṣìírí, títí di ìgbà tí ètò àjọ Jèhófà bá rí i pé ó yẹ láti sọ ọ́ di mímọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde rẹ̀ fúnra rẹ̀.
Ìfòyemọ̀ àti Ìwà Wa
5. Ojú wo ni ‘àwọn arìndìn’ fi ń wo ìwà àìníjàánu, èé sì ti ṣe?
5 Àwọn òwe inú Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti lo ìfòyemọ̀, kí a sì yẹra fún àwọn ìwà tí kò bójú mu. Fún àpẹẹrẹ, Òwe 10:23, (NW) sọ pé: “Sí arìndìn, bíbá a lọ ní híhu ìwà àìníjàánu dà bí ìdárayá, ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà fún ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀.” Ojú àwọn tí ìwà àìníjàánu ti “dà bí ìdárayá” ti fọ́ sí àìtọ́ ipa ọ̀nà wọn, wọn kò sì ka Ọlọ́run sí ẹni ti gbogbo ènìyàn yóò jíhìn fún. (Róòmù 14:12) Irú àwọn “arìndìn” bẹ́ẹ̀ di ẹlẹ́gbin nínú èrò ọkàn wọn, dórí rírò pé Ọlọ́run kò rí ìwà àìtọ́ tí wọ́n ń hù. Nípa ìgbésẹ̀ wọn, ohun tí wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ ni pé: “Ọlọ́run kò sí.” (Orin Dáfídì 14:1-3; Aísáyà 29:15, 16) Nítorí tí wọn kò jẹ́ kí ìlànà Ọlọ́run tọ́ wọn sọ́nà, wọ́n kò ní ìfòyemọ̀, wọn kò sì lè ṣèpinnu tí ó tọ́ lórí ọ̀ràn.—Òwe 28:5.
6. Èé ṣe tí ìwà àìníjàánu fi jẹ́ ìwà arìndìn, ojú wo ni a óò sì fi wò ó, bí a bá ní ìfòyemọ̀?
6 “Ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀” mọ̀ pé, ìwà àìníjàánu kì í ṣe “ìdárayá,” eré gbẹ̀fẹ́ kan. Ó mọ̀ pé kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, ó sì lè ba ipó ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà òmùgọ̀, nítorí pé ó ń fi ọ̀wọ̀ ara ẹni duni, ó máa ń run ìgbéyàwó, ó máa ń ṣèpalára fún èrò inú àti ara, ó sì máa ń yọrí sí pípàdánù ipò tẹ̀mí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ọkàn àyà wa fà sí ìfòyemọ̀, kí a sì yẹra fún ìwà àìníjàánu tàbí ìwà pálapàla irú èyíkéyìí.—Òwe 5:1-23.
Ìfòyemọ̀ àti Ẹ̀mí Wa
7. Kí ni díẹ̀ lára ipa búburú tí ìbínú ń ní lórí ara?
7 Jíjẹ́ kí ọkàn àyà wa fà sí ìfòyemọ̀ tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso ẹ̀mí wa. Òwe 14:29 (NW) sọ pé: “Ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́ aláìnísùúrù ń gbé ìwà òmùgọ̀ ga.” Ìdí kan tí ẹni tí ó ní ìfòyemọ̀ fi ń tiraka láti yẹra fún bíbínú kọjá àyè ni pé, ó ń ní ipa búburú lórí wa nípa ti ara. Ó lè ru ìwọ̀n ìfúnpá sókè, kí ó sì ṣokùnfà ìṣòro èémí. Àwọn dókítà ti sọ ọ́ gbangba gbàǹgbà pé ìbínú àti ìrunú jẹ́ èrò ìmọ̀lára tí ń fa àwọn àmódi bí ikọ́ fée, àrùn tí ń bani láwọ̀ jẹ́, ìṣòro oúnjẹ dídà, àti ọgbẹ́ inú, tàbí tí ń mú kí wọ́n burú sí i.
8. Jíjẹ́ aláìnísùúrù lè yọrí sí kí ni, ṣùgbọ́n báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn yí?
8 Kì í ṣe kìkì nítorí yíyẹra fún pípa ìlera wa lára ni ó ṣe yẹ kí a lo ìfòyemọ̀, kí a sì “lọ́ra láti bínú.” Jíjẹ́ aláìnísùúrù lè yọrí sí híhùwà òmùgọ̀ tí a óò kábàámọ̀ rẹ̀. Ìfòyemọ̀ ń mú kí a ronú lórí ohun tí ó lè tinú ọ̀rọ̀ bótobòto tàbí ìwà oníwàǹwára jáde, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí a yẹra fún ‘gbígbé ìwà òmùgọ̀ ga,’ nípa ṣíṣe ohun kan tí kò bọ́gbọ́n mu. Ìfòyemọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ ní pàtàkì láti rí i pé, ìrunú lè mú kí ọ̀nà tí a ń gbà ronú ṣiṣẹ́ gbòdì, débi tí a kò fi ní lè lo ìdájọ́ yíyèkooro. Èyí yóò fa ìfàsẹ́yìn fún agbára wa láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí a sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òdodo Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni, jíjọ̀wọ́ ara ẹni fún ìbínú tí ó kọjá àyè ń fa ìpalára nípa tẹ̀mí. Ní tòótọ́, a ka “ìrufùfù ìbínú” mọ́ “àwọn iṣẹ́ ti ẹran ara,” tí ó lè ṣèdíwọ́ fún wa láti jogún Ìjọba Ọlọ́run. (Gálátíà 5:19-21) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tí ó ní ìfòyemọ̀, ẹ jẹ́ kí a “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.”—Jákọ́bù 1:19.
9. Báwo ni ìfòyemọ̀ àti ìfẹ́ ará ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú èdèkòyedè?
9 Bí inú bá bí wa, ìfòyemọ̀ lè jẹ́ kí a rí i pé, ó yẹ kí a dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí a baà lè yẹra fún ìjà. Òwe 17:27 (NW) sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.” Ìfòyemọ̀ àti ìfẹ́ ará yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìjẹ́pàtàkì ṣíṣàkóso ìsúnniṣe láti sọ ọ̀rọ̀ tí yóò ṣèpalára jáde. Bí ìrufùfù ìbínú bá ti wáyé, ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò sún wa láti tọrọ àforíjì, kí a sì ṣàtúnṣe. Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ kí a gbà pé ẹnì kan ṣẹ̀ wá. Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a bá a sọ̀rọ̀ ní òun nìkan, ní ọ̀nà pẹ̀lẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀, kí gbígbé àlàáfíà lárugẹ sì jẹ́ olórí góńgó wa.—Mátíù 5:23, 24; 18:15-17.
Ìfòyemọ̀ àti Ìdílé Wa
10. Ipa wo ni ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ń kó nínú ìgbésí ayé ìdílé?
10 Àwọn mẹ́ńbà ìdílé ní láti fi ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ hàn, nítorí àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ń gbé agbo ilé ró. Òwe 24:3, 4 (NW) sọ pé: “Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró, nípa ìfòyemọ̀ sì ni yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Nípa ìmọ̀ sì ni àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún yóò fi kún fún gbogbo ohun oníyelórí tí ó ṣeyebíye tí ó sì wuni.” Ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ dà bíi bíríkì àtàtà tí a fi ń kọ́ ìgbésí ayé ìdílé tí yóò kẹ́sẹ járí. Ìfòyemọ̀ ń ran àwọn Kristẹni òbí lọ́wọ́ láti lè mọ bí wọn yóò ṣe mú àwọn ọmọ wọn sọ ìmọ̀lára àti àníyàn wọn jáde. Ẹni tí ó ní ìfòyemọ̀ yóò lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú alábàágbéyàwó rẹ̀, yóò lè tẹ́tí sí i, kí ó sì jèrè ìjìnlẹ̀ òye sínú ìmọ̀lára àti ìrònú rẹ̀.—Òwe 20:5.
11. Báwo ni abilékọ tí ó ní ìfòyemọ̀ ṣe lè “kọ́ ilé rẹ̀”?
11 Kò sí àníàní pé ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ṣe kókó fún ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀. Fún àpẹẹrẹ, Òwe 14:1 sọ pé: “Olúkúlùkù ọlọgbọ́n obìnrin ní í kọ́ ilé rẹ̀; ṣùgbọ́n aṣiwèrè a fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.” Abilékọ kan tí ó jẹ́ ọlọgbọ́n àti olùfòyemọ̀, tí ó ń tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀ lọ́nà yíyẹ, yóò ṣiṣẹ́ kára fún ire agbo ilé rẹ̀, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣèrànwọ́ láti gbé agbo ilé rẹ̀ ró. Ohun kan tí yóò “kọ́ ilé rẹ̀” ni pé yóò máa sọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ ní rere nígbà gbogbo, tí yóò sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fi kún ọ̀wọ̀ tí àwọn ẹlòmíràn ń fún ọkọ rẹ̀. Aya dídáńgájíá, tí ó ní ìfòyemọ̀, tí ó ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà máa ń jèrè ìyìn fún ara rẹ̀.—Òwe 12:4; 31:28, 30.
Ìfòyemọ̀ àti Ipa Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Wa
12. Ojú wo ni àwọn tí “ọkàn àyà kù fún” fi ń wo ìwà òmùgọ̀, èé sì ti ṣe?
12 Ìfòyemọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn ní ipa ọ̀nà yíyẹ nínú gbogbo àlámọ̀rí wa. A fi èyí hàn nínú Òwe 15:21 (NW), tí ó sọ pé: “Ìwà òmùgọ̀ jẹ́ ayọ̀ yíyọ̀ lójú ẹni tí ọkàn àyà kù fún, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni ẹni tí ń lọ tààrà.” Ọ̀nà wo ni ó yẹ kí a gbà lóye òwe yìí? Ipa ọ̀nà réderède, tàbí ti òmùgọ̀, jẹ́ ohun ayọ̀ fún àwọn òpònú ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọ̀dọ́. “Ọkàn àyà kù fún” wọn, wọn kò ní ète rere, wọ́n sì ponú dé bi pé wọ́n ń fi ìwà òmùgọ̀ ṣayọ̀.
13. Kí ni Sólómọ́nì fòye mọ̀ nípa ẹ̀rín àti afẹ́?
13 Ọba Sólómọ́nì ti Ísírẹ́lì, tí ó ní ìfòyemọ̀, kẹ́kọ̀ọ́ pé afẹ́ ṣíṣe kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan. Ó sọ gbangba gbàǹgbà pé: “Èmi wí nínú mi pé, wá ná! èmi óò fi iré ayọ̀ dán ọ wò, nítorí náà máa jẹ afẹ́! sì kíyè sí i, asán ni èyí pẹ̀lú! Èmi wí fún ẹ̀rín pé, Iwèrè ni ọ́: àti fún iré ayọ̀ pé kí ni o ń ṣe?” (Oníwàásù 2:1, 2) Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tí ó ní ìfòyemọ̀, Sólómọ́nì rí i pé iré ayọ̀ àti ẹ̀rín nínú ara wọn kì í mú ìtẹ́lọ́rùn wá, nítorí pé wọn kì í mú ayọ̀ tòótọ́, tí ó wà pẹ́ títí wá. Ẹ̀rín lè ṣèrànwọ́ fún wa láti gbàgbé àwọn ìṣòro wa fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn àkókò díẹ̀, àwọn ìṣòro wa lè rú yọ lọ́nà tí ó túbọ̀ ga sí i. Pẹ̀lú ẹ̀tọ́, Sólómọ́nì lè sọ nípa ẹ̀rín pé: “Iwèrè ni ọ́.” Èé ṣe? Nítorí pé, ẹ̀rín òpònú lè dènà ṣíṣe ìpinnu yíyè kooro. Ó lè mú kí a fi ojú yẹpẹrẹ wo àwọn ọ̀ràn ṣíṣe pàtàkì gan-an. A kò lè sọ pé iré ayọ̀ tí ó so pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ àti ìṣesí aláwàdà ọba ń mú ohun kan tí ó ní láárí jáde. Ríróye ìjẹ́pàtàkì dídán tí Sólómọ́nì dán ẹ̀rín àti iré ayọ̀ wò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún jíjẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—Tímótì Kejì 3:1, 4.
14. Báwo ni ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ṣe “ń lọ tààrà”?
14 Báwo ni ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ṣe “ń lọ tààrà”? Ìfòyemọ̀ tẹ̀mí àti fífi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò, máa ń sin àwọn ènìyàn sí ipa ọ̀nà ìdúróṣinṣin, tí ó ṣe tààràtà. Ìtumọ̀ Byington sọjú abẹ níkòó pé: “Ìwà òmùgọ̀ jẹ́ ìgbádùn fún ènìyàn tí kò lọ́pọlọ, ṣùgbọ́n ènìyàn onílàákàyè yóò lọ tààràtà.” “Ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀” ń ṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì lè fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, nítorí pé, ó ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀.—Hébérù 5:14; 12:12, 13.
Yíjú sí Jèhófà Nígbà Gbogbo fún Ìfòyemọ̀
15. Kí ni a rí kọ́ nínú Òwe 2:6-9?
15 Láti tọ ipa ọ̀nà adúróṣánṣán nínú ìgbésí ayé, gbogbo wa ní láti gbà pé aláìpé ni wá, kí a sì yíjú sí Jèhófà fún ìfòyemọ̀ tẹ̀mí. Òwe 2:6-9 (NW) sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá. Òun yóò sì to ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣánṣán; ó jẹ́ apata fún àwọn tí ń rìn nínú ìwà títọ́, nípa pípa àwọn ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́, yóò sì máa ṣọ́ ọ̀nà àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.”—Fi wé Jákọ́bù 4:6.
16. Èé ṣe tí kò fi sí ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, tàbí ìmọ̀ràn èyíkéyìí ní ìlòdì sí Jèhófà?
16 Ní mímọ̀ pé a kò lè dá ohun kan ṣe láìsí Jèhófà, ẹ jẹ́ kí a lo ìrẹ̀lẹ̀ láti fòye mọ ìfẹ́ inú rẹ̀ nípa wíwalẹ̀ jìn sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó ní ọgbọ́n láìkù síbì kan, ìmọ̀ràn rẹ̀ sì máa ń ṣeni láǹfààní nígbà gbogbo. (Aísáyà 40:13; Róòmù 11:34) Ní tòótọ́, ìmọ̀ràn èyíkéyìí tí ó bá ta ko tirẹ̀ kì yóò gbéṣẹ́. Òwe 21:30 (NW) sọ pé: “Kò sí ọgbọ́n kankan, tàbí ìfòyemọ̀ èyíkéyìí, tàbí ìmọ̀ràn èyíkéyìí ní ìlòdìsí Jèhófà.” (Fi wé Òwe 19:21.) Kìkì ìfòyemọ̀ tẹ̀mí, tí a mú dàgbà nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” pèsè, ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lépa ipa ọ̀nà títọ́ nínú ìgbésí ayé. (Mátíù 24:45-47) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a darí ipa ọ̀nà ìgbésí ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Jèhófà, ní mímọ̀ pé láìka bí ìmọ̀ràn tí ó ta kò ó ti jọ bí èyí tí ó ṣeé gbára lé tó, a kò lè fi wé Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
17. Kí ní lè ṣẹlẹ̀ bí a bá fúnni ní ìmọ̀ràn òdì?
17 Àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ìfòyemọ̀, tí wọ́n ń gbani nímọ̀ràn, mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ gbé e karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pátápátá, àti pé, ó ń béèrè pé kí àwọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àṣàrò ṣáájú dídáhùn ìbéèrè kan. (Òwe 15:28) Bí a bá dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó ṣe pàtàkì lọ́nà tí kò tọ̀nà, ó lè ṣèpalára ńlá. Nítorí náà, àwọn Kristẹni alàgbà nílo ìfòyemọ̀ tẹ̀mí, kí wọ́n sì gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jèhófà, nígbà tí wọ́n bá ń gbìyànjú láti ṣèrànwọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nípa tẹ̀mí.
Kún fún Ìfòyemọ̀ Tẹ̀mí
18. Bí ìṣòro kan bá dìde nínú ìjọ, báwo ni ìfòyemọ̀ yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìwàdéédéé wa nípa tẹ̀mí mọ́?
18 Láti mú inú Jèhófà dùn, a nílò ‘ìfòyemọ̀ nínú ohun gbogbo.’ (Tímótì Kejì 2:7) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ojú méjèèjì, àti títẹ̀lé ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run àti ètò àjọ rẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí a fòye mọ ohun tí ó yẹ kí a ṣe nígbà tí a bá dojú kọ àwọn ipò tí ó lè sìn wá lọ sínú ipa ọ̀nà tí kò tọ́. Fún àpẹẹrẹ, kí a sọ pé a kò bójú tó ọ̀ràn kan nínú ìjọ lọ́nà tí a rò pé ó yẹ kí a gbà bójú tó o. Ìfòyemọ̀ tẹ̀mí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé, èyí kì í ṣe ìdí fún wa láti ṣíwọ́ kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Jèhófà, kí a sì ṣíwọ́ ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run. Ronú nípa àǹfààní tí a ní láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, nípa òmìnira tẹ̀mí tí a ń gbádùn, nípa ìdùnnú tí a lè rí nínú ṣíṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba. Ìfòyemọ̀ tẹ̀mí ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti rí nǹkan lọ́nà títọ́, kí a sì mọ̀ pé, a ti ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ó sì yẹ kí a ṣìkẹ́ ipò ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀, láìka ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń ṣe sí. Bí kò bá sí ohun tí a lè ṣe lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run láti yanjú ìṣòro kan, a ní láti fi sùúrù dúró de Jèhófà láti yanjú ìṣòro náà. Dípò jíjáwọ́ tàbí bíbọ́hùn, ẹ jẹ́ kí a “dúró de Ọlọ́run.”—Orin Dáfídì 42:5, 11, NW.
19. (a) Kí ni lájorí àdúrà Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Fílípì? (b) Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́, bí a kò bá lóye ohun kan dáradára?
19 Ìfòyemọ̀ tẹ̀mí ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin sí Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ní Fílípì pé: “Èyí ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún; pé kí ẹ lè máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, kí ẹ lè jẹ́ aláìlábààwọ́n ẹ̀gbin kí ẹ má sì ṣe máa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀ títí di ọjọ́ Kristi.” (Fílípì 1:9, 10) Láti lè ronú lọ́nà yíyẹ, a nílò “ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “ìfòyemọ̀” níhìn-ín túmọ̀ sí “agbára títètè mòye ìwà rere.” Nígbà tí a bá kọ́ ohun kan, a fẹ́ mòye ìsopọ̀ tí ó ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti Kristi, kí a sì ṣàṣàrò lórí bí ó ṣe gbé àkópọ̀ ìwà Jèhófà àti àwọn ìpèsè rẹ̀ ga. Èyí ń fi kún ìfòyemọ̀ àti ìmọrírì tí a ní fún ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ti ṣe fún wa. Bí a kò bá lóye ohun kan dáradára, ìfòyemọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé, a kò gbọ́dọ̀ pa ìgbàgbọ́ wa nínú gbogbo ohun pàtàkì tí a ti kọ́ nípa Ọlọ́run, Kristi, àti ète àtọ̀runwá, tì.
20. Báwo ni a ṣe lè kún fún ìfòyemọ̀ tẹ̀mí?
20 A óò kún fún ìfòyemọ̀ tẹ̀mí bí a bá mú èrò wa àti ìwà wa ṣe déédéé pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. (Kọ́ríńtì Kejì 13:5) Ṣíṣe èyí ní ọ̀nà tí ń mú nǹkan sunwọ̀n, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí a má ṣe jẹ́ ẹni tí èrò tirẹ̀ nìkan ń jọ lójú, kí a má sì ṣe jẹ ẹni tí ń ṣe lámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn. Ìfòyemọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú àwọn ìtọ́sọ́nà tí a fún wa, kí a sì máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù. (Òwe 3:7) Nítorí náà, pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn láti mú inú Jèhófà dùn, ẹ jẹ́ kí a máa wá ọ̀nà láti kún fún ìmọ̀ pípéye Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èyí yóò mú kí a lè fòye mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, láti pinnu àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì ní tòótọ́, kí a sì fi ìdúróṣinṣin rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ipò ìbátan ṣíṣeyebíye tí a ní pẹ̀lú Jèhófà. Gbogbo ìwọ̀nyí yóò ṣeé ṣe bí a bá jẹ́ kí ọkàn àyà wa fà sí ìfòyemọ̀. Síbẹ̀, a ṣì nílò ohun kan. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfòyemọ̀ dáàbò bò wá.
Báwo ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?
◻ Èé ṣe tí a fi ní láti jẹ́ kí ọkàn àyà wa fà sí ìfòyemọ̀?
◻ Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè nípa lórí ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa?
◻ Ipa wo ni ìfòyemọ̀ lè ní lórí ẹ̀mí wa?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a yíjú sí Jèhófà fún ìfòyemọ̀ nígbà gbogbo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìfòyemọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso ẹ̀mí wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọba Sólómọ́nì, tí ó ní ìfòyemọ̀, mọ̀ pé afẹ́ kì í mú ìtẹ́lọ́rùn wá ní tòótọ́