“Gbòǹgbò tí Kò Ṣeé Fàtu”
AWỌN igi sequoia ti California jẹ́ ọ̀kan lára awọn ohun alààyè títóbi jùlọ tí ó sì tún lọ́jọ́ lórí jùlọ lágbàáyé. Awọn ohun ìyanu àwòṣífìlà wọnyi ga tó nǹkan bíi 90 mítà bí wọn bá ti dàgbà tán wọn sì lè wàláàyè fún èyí tí ó tó 3,000 ọdún.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrísí sequoia jẹ́ amúnikúnfún-ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀, ètò-ìgbékalẹ̀ gbòǹgbò rẹ̀ tí a kò rí tún fanimọ́ra lọ́nà kan naa. Igi sequoia ní gbòǹgbò títẹ́rẹrẹ tí ó lè tàn ká agbègbè kan tí ó fẹ̀ tó 1.2 sí 1.6 hectare. Ètò-ìgbékalẹ̀ gbòǹgbò fàkìà-fakia yii pèsè ìfìdímúlẹ̀ gbọnyin nígbà tí ìkún-omi tabi ìjì líle bá wáyé. Ó tilẹ̀ lè ṣeéṣe fún sequoia lati rí ara gba ìmìtìtì ilẹ̀ sí!
Ọba Solomoni yan ètò-ìgbékalẹ̀ gbòǹgbò lílágbára ti igi kan gẹ́gẹ́ bí àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ninu ọ̀kan lára awọn òwe rẹ̀. “Ènìyàn kan kò lè fi ìdí araarẹ̀ múlẹ̀ nípa ìwà ibi,” ni oun wí, “ṣugbọn awọn ènìyàn rere ní gbòǹgbò tí kò ṣeé fàtu.” (Owe 12:3, The New English Bible) Bẹ́ẹ̀ni, ilẹ̀ ń mì mọ́ awọn ẹni ibi lẹ́sẹ̀. Àṣeyọrí èyíkéyìí tí ó bá dàbí ẹni pé wọn ní jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, nitori Jehofa ṣèlérí pé “ìrètí ènìyàn búburú ni yoo ṣègbé.”—Owe 10:28.
Ìkìlọ̀ kan ni èyí jẹ́ fún awọn wọnnì tí wọn jẹ́wọ́ pé awọn jẹ́ Kristian, nitori tí Jesu wí pé awọn kan ‘kì yoo ní gbòǹgbò’ ninu araawọn wọn yoo sì kọsẹ̀. (Matteu 13:21) Síwájú síi, aposteli Paulu kọ̀wé nipa awọn ènìyàn kan tí a óò máa “bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ awọn ìgbì òkun tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ [èké].” (Efesu 4:14, NW) Bawo ni a ṣe lè dènà èyí?
Gan-an gẹ́gẹ́ bí gbòǹgbò igi sequoia kan ṣe ń tẹ́ rẹrẹ ninu ilẹ̀ ọlọ́ràá lọ́nà gbígbòòrò, bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí èrò-inú ati ọkàn-àyà wa máa walẹ̀jìn lọ́nà gbígbòòrò ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí ó sì máa fa omi rẹ̀ tí ń fúnni ní ìyè mu. Èyí yoo ṣèrànwọ́ fún wa lati mú ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin dàgbà. Àmọ́ ṣáá o, a óò nímọ̀lára ipa-ìdarí awọn àdánwò lílekoko. A tilẹ̀ lè wárìrì, gẹ́gẹ́ bí igi kan, lójú awọn ipò onítúláàsì. Ṣugbọn bí ìgbàgbọ́ wa bá fìdímúlẹ̀ gbọnyin-gbọnyin, awa yoo lè fihàn pé a ní “gbòǹgbò tí kò ṣeé fàtu.”—Fiwé Heberu 6:19.