‘Ètè Òtítọ́ Yóò Dúró Títí Láé’
BÍ INÁ kékeré ṣe lè jó odindi igbó kó sì pa á run yán-ányán-án ni òun náà lè ba ayé èèyàn jẹ́ pátápátá. Ó lè kún fún oró, àmọ́ ó tún lè jẹ́ “igi ìyè.” (Òwe 15:4) Ikú àti ìyè wà ní agbára rẹ̀. (Òwe 18:21) Bí agbára ẹ̀yà kékeré yìí ṣe pọ̀ tó nìyẹn o, ẹ̀yà náà ni ahọ́n wa, tó lè kó àbùkù bá gbogbo ara. (Jákọ́bù 3:5-9) Ọlọgbọ́n ni wá tá a bá lè ṣọ́ ahọ́n wa.
Ní apá kejì orí kejìlá ìwé Òwe inú Bíbélì, Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì fúnni nímọ̀ràn tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa. Ọlọgbọ́n ọba náà lo àwọn òwe ṣókí ṣùgbọ́n tí wọ́n gbéṣẹ́ gan-an láti fi hàn pé àwọn ọ̀rọ̀ tá à ń sọ ní ipa tó lágbára bẹ́ẹ̀ ló sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ púpọ̀ nípa irú èèyàn tí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà jẹ́. Ìmọ̀ràn onímìísí tí Sólómọ́nì fúnni yìí ṣe pàtàkì gan-an fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ‘yan ìṣọ́ síbi ilẹ̀kùn ètè rẹ̀.’—Sáàmù 141:3.
‘Ìrélànàkọjá Tí Ń Dẹkùn Múni’
Sólómọ́nì sọ pé: “Nípasẹ̀ ìrélànàkọjá ètè ni a ń dẹkùn mú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n olódodo yóò yọ kúrò nínú wàhálà.” (Òwe 12:13) Irọ́ pípa jẹ́ ìrélànàkọjá ètè, èyí tó ń di ìdẹkùn aṣekúpani fún òpùrọ́ náà. (Ìṣípayá 21:8) Àìṣòótọ́ lè dà bí ọ̀nà rírọrùn láti bọ́ lọ́wọ́ ìyà tàbí láti sá fún ipò kan tí kò bára dé. Àmọ́, ṣe irọ́ kan kọ́ ló máa ń súnni dórí òmíràn? Bí ẹni tó fi owó kékeré bẹ̀rẹ̀ tẹ́tẹ́ títa ṣe máa ń dẹni tó wá ń fi owó rẹpẹtẹ ta tẹ́tẹ́ níbi tó ti ń gbìyànjú àtirí owó tó ti pàdánù gbà padà. Bẹ́ẹ̀ náà ni òpùrọ́ ṣe máa ń bá ara rẹ̀ nínú ìdẹkùn fífi irọ́ kan ti òmíràn lẹ́yìn.
Ìrélànàkọjá ètè tún jẹ́ ìdẹkùn ní ti pé ẹni tó ń parọ́ fáwọn ẹlòmíì lè dẹni tó ń parọ́ fún ara rẹ̀ pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, òpùrọ́ lè máa tan ara rẹ̀ jẹ pé òun nímọ̀ gan-an, orí òun sì pé bí nǹkan míì, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò mọ dòò. Á wá bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé lọ́nà tí àṣírí irọ́ tó pa ò fi ní tú. Láìsí àní-àní, “ó ti gbé ìgbésẹ̀ fún ara rẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe féfé jù ní ojú ara rẹ̀ tí yóò fi rí ìṣìnà ara rẹ̀, kí ó bàa lè kórìíra rẹ̀.” (Sáàmù 36:2) Ẹ ò rí i pé ìdẹkùn ńlá ni irọ́ jẹ́! Àmọ́ ti olódodo èèyàn ò rí bẹ́ẹ̀, kò jẹ́ fi ara rẹ̀ sínú irú ipò búburú bẹ́ẹ̀. Kódà bó tiẹ̀ wà nínú ìṣòro pàápàá, kò jẹ́ purọ́ láé.
‘Èso Tó Ń Tẹ́ni Lọ́rùn’
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Ó dájú pé ìlànà yìí kan ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣe wa. Sólómọ́nì sọ pé: “Láti inú èso ẹnu ènìyàn ni a ti ń fi ohun rere tẹ́ ẹ lọ́rùn, àní ìgbòkègbodò iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn yóò padà wá sọ́dọ̀ rẹ̀.”—Òwe 12:14.
Ẹnu tó bá “sọ ọgbọ́n jáde” ló ń so èso tó ń tẹ́ni lọ́rùn. (Sáàmù 37:30) Ọgbọ́n béèrè pé kéèyàn ní ìmọ̀, kò sì sẹ́ni tó mọ gbogbo nǹkan tán. Olúkúlùkù gbọ́dọ̀ fetí sílẹ̀ sí ìmọ̀ràn rere kó sì kọbi ara sí i. Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Ọ̀nà òmùgọ̀ tọ̀nà ní ojú ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fetí sí ìmọ̀ràn ni ọlọ́gbọ́n.”—Òwe 12:15.
Jèhófà ń fún wa láwọn ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, ó ń lo àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ń pèsè. (Mátíù 24:45; 2 Tímótì 3:16) Ẹ ò rí i bó ṣe jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti kọ ìmọ̀ràn rere sílẹ̀ ká wá rin kinkin mọ́ ohun tó dára lójú tiwa! A gbọ́dọ̀ “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́” nígbà tí Jèhófà, “Ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀,” bá ń fún wa nímọ̀ràn nípasẹ̀ ètò tó fi ń báni sọ̀rọ̀.—Jákọ́bù 1:19; Sáàmù 94:10.
Báwo ni ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ṣe máa ń hùwà nígbà táwọn èèyàn bá fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n tàbí tí wọ́n bá ṣe àríwísí wọn? Sólómọ́nì fèsì pé: “Òmùgọ̀ ni ó máa ń sọ ìbínú rẹ̀ di mímọ̀ ní ọjọ́ kan náà, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà a máa bo àbùkù mọ́lẹ̀.”—Òwe 12:16.
Nígbà tí wọ́n bá fi ìwọ̀sí lọ òmùgọ̀ èèyàn, ńṣe ló máa tutọ́ sókè tá fojú gbà á lójú ẹsẹ̀—“ní ọjọ́ kan náà.” Àmọ́ ọlọ́gbọ́n èèyàn ní tiẹ̀ á gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun ni ẹ̀mí rẹ̀ kí òun lè lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Ó máa ń fara balẹ̀ ṣàṣàrò lórí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì máa ń fi ìmọrírì ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí èkejì sí i pẹ̀lú.” (Mátíù 5:39) Ẹni tó jẹ́ afọgbọ́nhùwà máa ń pa ètè rẹ̀ mọ́ láti má ṣe sọ̀rọ̀ lọ́nà àìgbatẹnirò kí ó má bàá “fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” (Róòmù 12:17) Nígbà táwa náà bá bo àbùkù èyíkéyìí táwọn èèyàn lè fi kàn wá mọ́lẹ̀, a ó yẹra fún gbọ́nmi-si omi-ò-tó tó lè tibẹ̀ jáde.
‘Ahọ́n Tí Ń Múni Lára Dá’
Ìrélànàkọjá ètè lè fa ọ̀pọ̀ aburú níbi ìgbẹ́jọ́. Ọba Ísírẹ́lì náà sọ pé: “Ẹni tí ń gbé ìṣòtítọ́ yọ a máa sọ ohun tí í ṣe òdodo, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké, a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” (Òwe 12:17) Ẹni tó jẹ́ ẹlẹ́rìí tòótọ́ a máa gbé ìṣòtítọ́ yọ nítorí pé ẹ̀rí rẹ̀ ṣeé fọkàn tán, ó sì ṣeé gbíyè lé. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ máa ń jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣeé ṣe. Ti ẹni tó jẹ́ ẹlẹ́rìí èké ò rí bẹ́ẹ̀ o, ẹ̀tàn ló kún ẹnu rẹ̀ ó sì máa ń dá kún àìṣèdájọ́ òdodo.
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Ọ̀rọ̀ lè gúnni bí idà, ó ń ba àárín ọ̀rẹ́ jẹ́, ó sì ń dá wàhálà sílẹ̀. Ó tún lè múnú ẹni dùn, kó sì jẹ́ kí àárín ọ̀rẹ́ túbọ̀ gún régé. Àbí kí ni àwọn orúkọkórúkọ tí wọ́n ń peni, ṣíṣe àríwísí ẹni ní gbogbo ìgbà, àti àwọn ọ̀rọ̀ àbùkù jẹ́ bí kò ṣe ìgúnni idà tí ń fa ọgbẹ́ jíjinnú síni lọ́kàn? Ì bá mà dára ò, tá a bá lè fi ọ̀rọ̀ ìmúniláradá tọrọ àforíjì látọkànwá láti wá àtúnṣe sí àṣìṣe èyíkéyìí tá a bá ti ṣe nípa èyí!
Ní àkókò líle koko tá à ń gbé yìí, kì í ṣe ohun àjèjì rárá láti rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà,” tí a sì “wó ẹ̀mí wọn palẹ̀.” (Sáàmù 34:18) Nígbà tá a bá “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,” tá a sì “ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera,” ǹjẹ́ kì í ṣe agbára ìmúniláradá inú ọ̀rọ̀ sísọ là ń mú lò yẹn? (1 Tẹsalóníkà 5:14) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀rọ̀ tó fi ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn hàn lè fún àwọn ọ̀dọ́langba, tí wọ́n ń kojú ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe níṣìírí. Ahọ́n tó sọ̀rọ̀ ìgbatẹnirò lè fi àwọn arúgbó lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n wúlò, àti pé a ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ onínúure lè jẹ́ kí inú àwọn tó ń ṣàìsàn dùn lọ́jọ́ náà. Kódà, ó máa ń rọrùn láti gba ìbáwí nígbà tá a bá fúnni “nínú ẹ̀mí ìwà tútù.” (Gálátíà 6:1) Ìmúniláradá gidi mà ni ahọ́n ẹni tó ń fi tirẹ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn tó fẹ́ gbọ́!
‘Ètè Tí Ń Wà Títí Láé’
Nígbà tí Sólómọ́nì ń lo ọ̀rọ̀ náà “ètè” gẹ́gẹ́ bí èyí tí òun àti “ahọ́n” jọ ní ìtumọ̀ kan náà, ó sọ pé: “Ètè òtítọ́ ni a ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in títí láé, ṣùgbọ́n ahọ́n èké yóò wà fún kìkì ìwọ̀nba ìṣẹ́jú kan.” (Òwe 12:19) Gbólóhùn náà, “ètè òtítọ́” jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń tọ́ka sí ohun kan ṣoṣo ní èdè Hébérù, ó sì ní ìtumọ̀ kan tó gbòòrò ju ọ̀rọ̀ òtítọ́ lásán lọ. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ànímọ́ bíi lílálòpẹ́, wíwàpẹ́títí, àti ṣìṣeégbáralé. Ọ̀rọ̀ tó ní irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí yóò wà pẹ́ . . . títí láé nítorí pé á ṣeé gbára lé èyí sì yàtọ̀ pátápátá sí ahọ́n èké . . . tó lè tanni jẹ fún ìgbà díẹ̀ àmọ́ tí kò lè dúró nígbà tá a bá dán an wò.”
Ọlọgbọ́n ọba náà sọ pé: “Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn-àyà àwọn tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ ibi, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbani nímọ̀ràn àlàáfíà ń yọ̀. Ó fi kún un pé: “Kò sí ohun aṣenilọ́ṣẹ́ tí yóò ṣẹlẹ̀ sí olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú ni àwọn tí yóò kún fún ìyọnu àjálù dájúdájú.”—Òwe 12:20, 21.
Kìkì ìrora àti ìjìyà ni ẹni tó ń hùmọ̀ ibi lè fà. Ní ìyàtọ̀ síyẹn, àwọn tí ń gbani nímọ̀ràn àlàáfíà yóò jèrè ìtẹ́lọ́rùn nítorí pé wọ́n ń ṣe ohun tí ó tọ́. Wọ́n tún ń ní ayọ̀ rírí àwọn àbájáde tó dáa. Ní pàtàkì ju lọ, wọ́n ń rí ojú rere Ọlọ́run nítorí pé “ètè èké jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn tí ń fi ìṣòtítọ́ hùwà jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”—Òwe 12:22.
‘Ọ̀rọ̀ Tó Ń Bo Ìmọ̀’
Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì náà tún ń sọ ìyàtọ̀ mìíràn tó wà láàárín ẹni tó ronú dáadáa kó tó sọ̀rọ̀ àti ẹni tí kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Afọgbọ́nhùwà ń bo ìmọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà àwọn arìndìn ni èyí tí ń pòkìkí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.”—Òwe 12:23.
Ẹni tó jẹ́ afọgbọ́nhùwà mọ ìgbà tó yẹ kí òun sọ̀rọ̀ àti ìgbà tó yẹ kí òun dákẹ́. Ó ń bo ìmọ̀ nípa yíyẹra fún fífi ohun tó mọ̀ ṣe fọ́rífọ́rí. Èyí ò túmọ̀ sí pé ó máa ń fi ìmọ̀ rẹ̀ pa mọ́ ní gbogbo ìgbà o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń fi ọgbọ́n lò ó. Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, ojú ẹsẹ̀ ni arìndìn máa ń sọ̀rọ̀, á sì wá jẹ́ káwọn èèyàn rí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa mọ níwọ̀nba, kí a má sì fi ahọ́n wa fọ́nnu.
Sólómọ́nì ń bá a lọ láti fi ìyàtọ̀ náà hàn nípa mímẹ́nu kan kókó pípabanbarì kan nípa jíjẹ́ aláápọn àti jíjẹ́ ọ̀lẹ. Ó ní: “Ọwọ́ àwọn ẹni aláápọn ni yóò ṣàkóso, ṣùgbọ́n ọwọ́ dẹngbẹrẹ yóò wá wà fún òpò àfipámúniṣe.” (Òwe 12:24) Iṣẹ́ àṣekára lè jẹ́ kéèyàn ní ìlọsíwájú kó sì lówó lọ́wọ́, àmọ́ jíjẹ́ ọ̀lẹ lè mú kéèyàn bá ara rẹ̀ nínú òpò àfipámúniṣe àti ìsìnrú. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Bópẹ́ bóyá, ọ̀lẹ a di ẹrú ẹni tó jẹ́ aláápọn.”
‘Ọ̀rọ̀ Tó Ń Múni Lọ́kàn Yọ̀’
Sólómọ́nì Ọba tún padà sórí ọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu nípa ṣíṣàkíyèsí irú ẹ̀dá tí ọmọ èèyàn jẹ́ gan-an. Ó ní: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.”—Òwe 12:25.
Ọ̀pọ̀ àníyàn àti hílàhílo ló wà tó lè mú kí ìbànújẹ́ tẹ ọkàn èèyàn ba. Ohun tá a nílò láti mú kí ẹrù ìnira náà dín kù àti láti mú ọkàn wa yọ̀ ni ọ̀rọ̀ rere tó ń fúnni níṣìírí látẹnu ẹni kan tó jẹ́ olóye. Àmọ́, báwo làwọn ẹlòmíràn ṣe lè mọ bí àníyàn ọkàn wa ṣe pọ̀ tó láìjẹ́ pé a lahùn, ká sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, nígbà tá a bá wà nínú ìdààmú tàbí tí ọkàn wa bá gbọgbẹ́, a ní láti finú han ẹnì kan tó ń gba tẹni rò tó sì lè ràn wá lọ́wọ́. Ìyẹn nìkan kọ́ o, sísọ bí nǹkan ṣe rí lára wa jáde tún lè dín ẹ̀dùn ọkàn wa kù. Nítorí náà, ó dára ká finú hàn ọkọ tàbí aya wa, òbí wa, tàbí ọ̀rẹ́ kan tó jẹ́ oníyọ̀ọ́nú tó sì tóótun nípa tẹ̀mí.
Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ló tún lè dára ju èyí tó wà nínú Bíbélì? Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run nípa fífi ìmọrírì ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ onímìísí rẹ̀. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ lè fún ọkàn tí ìdààmú bá láyọ̀ ó sì lè fún ojú tó kún fún ìbìnújẹ́ ní ìmọ́lẹ̀. Onísáàmù náà jẹ́rìí sí èyí nípa sísọ pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá. Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n. Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.”—Sáàmù 19:7, 8.
Ipa Ọ̀nà Tó Ń Mérè Wá
Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì náà ń sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹni tó jẹ́ adúróṣánṣán àti ẹni burúkú, ó ní: “Olódodo ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò pápá ìjẹko tirẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ẹni burúkú ń mú kí wọ́n rìn gbéregbère.” (Òwe 12:26) Olódodo máa ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò pápá ìjẹko tirẹ̀—ìyẹn ni irú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ àti ọ̀rẹ́ tó yàn. Ó máa ń fi ọgbọ́n yàn wọ́n, á sapá láti yẹra fún àjọṣe tó jẹ́ eléwu. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹni burúkú ò rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọn kì í gba ìmọ̀ràn, wọ́n sì máa ń rin kinkin mọ́ ọ̀nà tó tọ́ lójú ara wọn. Wọ́n ṣìnà, wọ́n sì ń rìn gbéregbère kiri.
Ẹ̀yìn ìyẹn ni Sólómọ́nì Ọba tún fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹni tó ń dẹwọ́ dẹngbẹrẹ àti ẹni tó jẹ́ aláápọn hàn lọ́nà mìíràn. Ó ní: “Ìṣọwọ́dẹngbẹrẹ kì yóò mú àwọn ẹran tí ènìyàn ń ṣọdẹ rẹ̀ bẹ́ gìjà, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ aláápọn ni ọlà iyebíye ènìyàn.” (Òwe 12:27) Ẹni tó ń dẹwọ́ dẹngbẹrẹ—“ìyẹn ọ̀lẹ èèyàn”—kò ní mú kí àwọn ẹran ọdẹ rẹ̀ “bẹ́ gìjà” bẹ́ẹ̀ ni kò ní “yan” wọ́n. (New International Version) Ìyẹn ni pé kò lè parí ohun tó bá bẹ̀rẹ̀ láé. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ńṣe ni jíjẹ́ aláápọn àti ọrọ̀ jọ ń rìn.
Jíjẹ́ ọ̀lẹ burú débi pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé ó pọn dandan kóun kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ òun tó wà ní Tẹsalóníkà, kó sì tọ́ àwọn kan tó “ń rìn ségesège” níbẹ̀ sọ́nà—ìyẹn àwọn tí kì í ṣiṣẹ́ rárá àmọ́ tí wọ́n ń tojú bọ ohun tí ò kàn wọ́n. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń di ẹrù ìnira ńláǹlà ka àwọn tó kù lọ́rùn. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi bá wọn wí ní gbangba, tó gbà wọ́n níyànjú láti ‘ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.’ Tí wọn ò bá sì kọbi ara sí ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ yìí, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tó kù nínú ìjọ pé kí wọ́n “yẹra” fún wọn—ìyẹn ni pé kí wọ́n yàgò fún wọn pátápátá, ìyẹn sì ní láti jẹ́ nínú ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.—2 Tẹsalóníkà 3:6-12.
Kì í ṣe ìmọ̀ràn Sólómọ́nì nípa jíjẹ́ aláápọn nìkan la ó fi sílò, àmọ́ a tún ní láti fi ìmọ̀ràn tó fún wa nípa bá a ṣe ní láti lo ahọ́n wà lọ́nà yíyẹ sílò pẹ̀lú. Ẹ jẹ́ ká sapá láti lo ẹ̀yà kékeré yẹn lọ́nà ti yóò fi jẹ́ ìmúniláradá àti ìdùnnú bá a ṣe ń yẹra fún ìrélànàkọjá ètè tá a sì ń lépa ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán. Sólómọ́nì mú un dá wa lójú pé: “Ìyè wà ní ipa ọ̀nà òdodo, ìrìn àjò ní òpópó ọ̀nà rẹ̀ kò sì túmọ̀ sí ikú.”—Òwe 12:28.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
“Ẹni tí ń fetí sí ìmọ̀ràn ni ọlọ́gbọ́n”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
“Ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Fífinú han ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán lè mú ìtùnú wá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Fífi ìmọrírì ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń mú ọkàn yọ̀