Bí A Ṣe Lè Máa Bá a Lọ Ní Jíjẹ́ Aláyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
ÌMÚṢẸ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn kedere pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí. Ní mímọ èyí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ń lo gbogbo àkókò tí ó ṣeé ṣe fún wọn láti lò ní títan ìhìn rere Ìjọba rẹ̀ kálẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà tí wọ́n lé ní 600,000 ti ṣètò ìgbésí ayé wọn kí wọ́n baà lè nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àwọn kan nínú wọ́n jẹ́ àwọn olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún, tí a ń pè ní aṣáájú ọ̀nà. Àwọn mìíràn jẹ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ní Bẹ́tẹ́lì ní orílé-iṣẹ́ Watch Tower Society tàbí ní àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn mìíràn jẹ́ míṣọ́nnárì àti àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò.
Bíbélì fi hàn pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò” yóò wà. (Tímótì Kejì 3:1-5) Bíbélì Lédè Gíríìkì lo ọ̀rọ̀ kan tí a lè tú sí “àwọn àkókò rírorò tí a yàn kalẹ̀.” Nítorí náà, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni retí ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ, ní ọjọ́ wa. Fún àwọn òjíṣẹ́ Kristẹni kan, ìṣòro náà dà bí èyí tí ó nípọn débi tí wọ́n fi lè bi ara wọn léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ mo lè máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ bí, àbí kí n fi í sílẹ̀?’
Àwọn ipò wo ni ó lè mú kí aṣáájú ọ̀nà, olùyọ̀ǹda ara ẹni ní Bẹ́tẹ́lì, alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí míṣọ́nnárì kan tún ipò rẹ̀ gbé yẹ̀ wò? Ó lè jẹ́ pé àìsàn líle koko kan ń yọ ọ́ lẹ́nu. Bóyá ìbátan kan tí ó ti dàgbà tàbí tí ó jẹ́ aláìlera ń fẹ́ ìtọ́jú ìgbà gbogbo. Ó lè jẹ́ pé tọkọtaya kan fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọmọ bíbí. Kò yẹ kí ojú ti ẹnikẹ́ni tí ó bá fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀, nítorí irú àwọn ìdí bẹ́ẹ̀ àti nítorí àwọn ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ gbé léni lọ́wọ́, fún ṣíṣe ìyípadà náà.
Ṣùgbọ́n, bí ẹnì kan bá ń wéwèé láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀ nítorí àìláyọ̀ ńkọ́? Bóyá aṣáájú ọ̀nà kan kò fi bẹ́ẹ̀ rí ẹni tí ń tẹ́tí sílẹ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, tí ó sì bi ara rẹ̀ pé, ‘Èé ṣe tí n óò fi máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé onífara-ẹni-rúbọ tí mò ń gbé, nígbà tí àwọn tí ń tẹ́tí sílẹ̀ kò tó nǹkan?’ Bóyá inú olùyọ̀ǹda ara ẹni kan ní Bẹ́tẹ́lì kò dùn sí iṣẹ́ tí a yàn fún un. Ó sì lè jẹ́ pé àìsàn kan tí kì í lọ bọ̀rọ̀, bí kò tilẹ̀ ní kí a má ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ń já ayọ̀ ẹnì kan gbà mọ́ ọn lọ́wọ́. Báwo ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ aláyọ̀? Ẹ jẹ́ kí a gbé ohun tí àwọn òjíṣẹ́ onírìírí kan sọ yẹ̀ wò.
Kíkojú Ìjákulẹ̀
Anny, tí ó wá láti Switzerland, lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní 1950. Ó retí pé kí a yan òun sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà tí wọ́n dá a pa dà sẹ́nu iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì ní Europe, ìjákulẹ̀ bá Anny. Síbẹ̀síbẹ̀, ó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ ní Ẹ̀ka Ìtumọ̀, ẹnu iṣẹ́ náà ni ó sì wà títí di ìsinsìnyí. Báwo ni ó ṣe ṣẹ́pá ìjákulẹ̀ tí ó ní? Anny ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ pọ̀ gan-an láti ṣe nígbà yẹn, iṣẹ́ sì tún pọ̀ gan-an láti ṣe nísinsìnyí. Ìmọ̀lára mi àti ohun tí mo fẹ́ kò ṣe pàtàkì tó iṣẹ́ náà.”
Bí a bá ní ìjákulẹ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ àyànfúnni wa, bóyá a lè mú ẹ̀mí ìrònú bíi ti Anny dàgbà. Kì í ṣe ohun tí a fẹ́ ni ó yẹ kí ó ṣe pàtàkì jù lọ. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, kí a bójú tó gbogbo onírúurú ẹrù iṣẹ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú títan ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kálẹ̀ dáradára. Òwe 14:23 sọ fún wa pé, “nínú gbogbo làálàá ni èrè púpọ̀ wà.” Láìka irú iṣẹ́ àyànfúnni tí a fún wa sí, fífi ìṣòtítọ́ ṣe é ń fi kún ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ Ìjọba náà. A sì lè rí ìtẹ́lọ́rùn ńlá—àní, ayọ̀—nínú irú iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fúnni bẹ́ẹ̀.—Fi wé Kọ́ríńtì Kíní 12:18, 27, 28.
Jíjẹ́ Ẹni Tí Ó Lè Wà Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn
Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní í ṣe pẹ̀lú níní ìfararora tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn onírúurú—nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, ní Bẹ́tẹ́lì, ní ilé míṣọ́nnárì, tàbí nígbà tí a bá ń bẹ ìjọ kan wò tẹ̀lé òmíràn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Nítorí náà, dé ìwọ̀n gíga, ayọ̀ wa sinmi lórí jíjẹ́ ẹni tí ó lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n, ‘àkókò rírorò’ tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ń mú kí àjọṣepọ̀ láàárín ẹ̀dá ènìyàn ṣòro. Báwo ni òjíṣẹ́ kan ṣe lè yẹra fún pípàdánù ayọ̀ rẹ̀, àní bí ẹnì kan bá mú un bínú pàápàá? Bóyá a lè rí ohun kan kọ́ lára Wilhelm.
Wilhelm di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Europe ní ọdún 1947. Lẹ́yìn èyí, ó lo àkókò nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àti ní sísìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Wilhelm ṣàlàyé pé: “Bí èmi àti aya mi bá rí ohun tí a rò pé kò tọ́ tàbí tí ń dà wá láàmú, a máa ń sọ ìmọ̀lára wa jáde fún Jèhófà, a óò sì fa ohun gbogbo lé e lọ́wọ́ láti yanjú.”—Orin Dáfídì 37:5.
Bóyá ìwà Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ kan, tí ó lanu gbàgà sọ̀rọ̀ sí ọ, dà ọ́ láàmú. Rántí pé gbogbo wa pátá ni a máa ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú ọ̀rọ̀ ẹnu wa. (Jákọ́bù 3:2) Nítorí náà, èé ṣe tí o kò fi lo ọ̀ràn yí láti sún mọ́ “olùgbọ́ àdúrà” pẹ́kípẹ́kí? (Orin Dáfídì 65:2, NW) Sọ ọ̀ràn náà fún Jèhófà, kí o sì fà á lé e lọ́wọ́. Bí Ọlọ́run bá fẹ́ láti ṣe ìyípadà, òun yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn tí ń gbé ní ilé míṣọ́nnárì lè ní láti fi èyí sọ́kàn bí wọ́n bá ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀, nítorí èyí yóò ṣèrànwọ́ fún wọn láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ aláyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
Nígbà Tí Ìlera Kò Bá Jí Pépé
Ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ní ń gbádùn ìlera jíjí pépé fún ìgbà pípẹ́. Àwọn tí a tilẹ̀ lè sọ pé wọ́n wà ní àkókò tí ara wọ́n jí pépé jù lọ nínú ìgbésí ayé pàápàá ni ìsoríkọ́ tàbí àrùn lè kọ lù. Àìlera ń mú kí ó pọn dandan fún àwọn kan láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ títayọ lọ́lá lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba. Ṣùgbọ́n, ó máa ń ṣeé ṣe fún àwọn mìíràn láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wọn nìṣó láìka ìlera wọn tí kò jí pépé sí. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Hartmut àti Gislind yẹ̀ wò.
Hartmut àti Gislind jẹ́ tọkọtaya kan tí wọ́n ti lo 30 ọdún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, míṣọ́nnárì, àti nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Àwọn méjèèjì ti jìyà lọ́wọ́ àwọn àrùn líle koko, tí ó tán wọn lókun nípa ti ara àti ní ti ìmọ̀lára ní àwọn ìgbà míràn. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ti ṣe iṣẹ́ pípabanbarì, ó sì ti ṣeé ṣe fún wọn láti fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ń fojú gbiná irú àdánwò kan náà níṣìírí. Ìmọ̀ràn wo ni wọ́n gbà wọ́n? “Ọjọ́ iwájú ni kí o tẹjú mọ́ kì í ṣe ìgbà tí ó ti kọjá. Ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe nínú ipòkípò tí o bá bá ara rẹ. Ó lè jẹ́ àǹfààní kan ṣoṣo ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan yóò mú wá fún ọ láti yin Jèhófà. Lo àǹfààní náà, kí o sì gbádùn rẹ̀.”
Gbé ọ̀ràn Hannelore yẹ̀ wò. Àrùn tí ń lọ tí ń bọ̀ pọ́n ọn lójú láàárín 30 ọdún tí ó lò gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, míṣọ́nnárì, nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, àti nínú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Hannelore sọ pé: “Mo pọkàn pọ̀ sórí àríyànjiyàn tí Sátánì gbé dìde—pé ẹ̀dá ènìyàn ń sin Jèhófà kìkì nígbà tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá rọrùn fún wọn. Nípa fífara da àwọn àdánwò, mo lè ní ipa nínú fífẹ̀rí hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa.” Èyí lè jẹ́ ìsúnniṣe lílágbára. Rántí pé ìdúróṣinṣin rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan sí Jèhófà lábẹ́ ìdánwò ṣe pàtàkì sí i.—Jóòbù 1:8-12; Òwe 27:11.
Bí o ti ń gbìyànjú láti ṣe ìpinnu tí ó wà déédéé nípa ìlera rẹ, gbé apá méjì nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù Kristi nípa òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yẹ̀ wò. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àjàkálẹ̀ àrùn yóò wà láti ibì kan sí ibòmíràn. Ó tún sọ pé: “A óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:3, 14; Lúùkù 21:11) Jésù mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àìsàn yóò bá àwọn ọmọlẹ́yìn òun fínra. Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé kì í ṣe kìkì àwọn tí ń gbádùn ìlera jíjí pépé nìkan ni yóò ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà, ṣùgbọ́n àti àwọn tí ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn líle koko pẹ̀lú. Bí ó bá ṣeé ṣe fún wa láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wa nìṣó láìka àìlera sí, Jèhófà kì yóò gbàgbé ìfẹ́ tí a fi hàn sí orúkọ rẹ̀.—Hébérù 6:10.
Bíbá A Lọ Ní Jíjẹ́ Aláyọ̀ Láìka Ìdágunlá Àwọn Ènìyàn Sí
Bí àwọn ènìyàn ṣe dáhùn pa dà sí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba lè nípa lórí ìṣarasíhùwà wa. Òjíṣẹ́ onírìírí kan sọ pé: “Ó ń nira fún àwọn aṣáájú ọ̀nà pàápàá láti rí onílé tí wọn yóò bá jíròrò. Gbogbo wá ní láti sapá láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ aláyọ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìdágunlá àwọn ènìyàn lè dín ayọ̀ wa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá kù. Nítorí náà, báwo ni aṣáájú ọ̀nà kan tí ń bá ìdágunlá pàdé déédéé ṣe lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ aláyọ̀? Àwọn òjíṣẹ́ onírìírí dábàá àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí, tí a ti gbìyànjú, tí a sì ti dán wò.
Ìdágunlá jẹ́ ìpèníjà kan, ṣùgbọ́n kò yẹ kí ó fa ìjákulẹ̀. Nínú ara rẹ̀, ìdágunlá tí ó gbòde kan kì í ṣe ìdí láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀. A lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ aláyọ̀ lójú ìdágunlá bí a bá ya àkókò tí ó tó sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ aláápọn nínú Ìwé Mímọ́. Wọ́n ‘ń mú wa gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo,’ ìyẹn sì kan bíbá àwọn tí wọ́n kọ etí ikún sí ìhìn rere náà sọ̀rọ̀. (Tímótì Kejì 3:16, 17) Bí àwọn ènìyàn kò tilẹ̀ fẹ́ tẹ́tí sí wòlíì Jeremáyà, ìyẹn kò dá a dúró. (Jeremáyà 7:27) Bí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni, a lè jàǹfààní gidigidi bí a bá kíyè sí àwọn èrò tí ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, tí ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìdágunlá.
Ní gbígbà pé ìdágunlá jẹ́ ìpèníjà kan, ẹ jẹ́ kí a gbé ìṣarasíhùwà wa sí àwọn tí a ń wàásù fún yẹ̀ wò. Èé ṣe tí wọ́n fi ní ẹ̀mí ìdágunlá? Fún àpẹẹrẹ, àwọn àkọsílẹ̀ burúkú tí ìsìn èké ti ṣe fún ara rẹ̀ jẹ́ ọkàn lára àwọn ìdí fún ìtànkálẹ̀ ìdágunlá ní àwọn apá ibì kan ní Europe. Àwọn ènìyàn kò ronú mọ́ pè ìsìn ní àyè tirẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn, wọn kò sì fẹ́ ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú rẹ̀. A ní láti jẹ́ ẹni tí ó lè tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, ní bíbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ọ̀ràn tí ó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n, irú bí àìríṣẹ́ṣe, àìlera, ìwà ọ̀daràn, àìráragba-nǹkan-sí, àyíká, àti ogun tí ń fẹjú mọ́ni.
Nínú ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa pẹ̀lú onílé, a lè mẹ́nu kan ọ̀ràn kan tí àwọn ènìyàn ládùúgbò nífẹ̀ẹ́ sí. Ohun tí Dietmar gbìyànjú láti ṣe nìyẹn, nígbà tí ó ń wàásù ní abúlé kan níbi tí kò ti ṣàṣeyọrí púpọ̀. Ọ̀kan lára àwọn ará abúlé sọ fún un pé ọ̀fọ̀ ńlá kan ṣẹ̀ ní abúlé náà ní ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ yẹn. Gbogbo ilé tí Dietmar lọ lẹ́yìn ìgbà náà ni ó ti ń kí àwọn ènìyàn kú ọ̀fọ̀. Ó sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kan náà, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi sọ̀rọ̀. Ọ̀fọ̀ ńlá náà ni ó wà ní ọkàn gbogbo ènìyàn. Mo ni ìjíròrò tí ó gbámúṣé pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní ọjọ́ yẹn, nítorí tí mo lọ́kàn ìfẹ́ sí ìgbésí ayé wọn.”
Ó ṣe pàtàkì pé kí a jẹ́rìí Ìjọba náà fún àwọn ènìyàn níbikíbi tí a bá ti rí wọn. Ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà lè méso wá, a sì lè fi ìgbòkègbodò yí kọ́ ara wa nípa lílo àwọn ìmọ̀ràn tí a pèsè nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì. Bíbá onílé sọ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ ráńpẹ́ tàbí fífún un ní àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lè múni láyọ̀. Bí a bá ti ṣe ìpadàbẹ̀wò, tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú olùfìfẹ́hàn kan, a lè gba ìtọ́ka nípa bíbéèrè pé: “Ìwọ ha mọ ẹnì kan tí yóò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Èyí lè ṣamọ̀nà sí fífìdí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé mìíràn múlẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ olùfojúsọ́nà fún rere, kí a gbára lé Jèhófà nínú àdúrà, kí a má ṣe jẹ́ kí ìdágunlá kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa.
Ìṣírí Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlòmíràn
Jürgen àti Christiane ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, wọ́n sì ti wà nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò fún èyí tí ó lé ní 30 ọdún. Nígbà kan, iṣẹ́ àyànfúnni wọ́n jẹ́ láti wàásù ní àgbègbè kan tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ti jẹ́ adágunlá àti olórí kunkun. Ẹ wo bí Jürgen àti aya rẹ̀ ti ń fẹ́ ìṣírí lójú méjèèjì tó! Ṣùgbọ́n, fún àwọn ìdí kan, àwọn yòó kù nínú ìjọ kò dáhùn pa dà sí àìní wọn.
Nítorí náà, Jürgen mọ̀ láti inú ìrírí pé “nǹkan kì í fara rọ fún àwọn aṣáájú ọ̀nà kan. Wọ́n nílò ìṣírí síwájú sí i láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti àwọn akéde yòó kù.” Ọlọ́run sọ fún Mósè pé kí ó fún Jóṣúà ní ìṣírí àti okun. (Diutarónómì 3:26-28) Ó sì yẹ kí àwọn Kristẹni jẹ́ orísun ìṣírí fún ara wọn lẹ́nì kíní kejì. (Róòmù 1:11, 12) Àwọn akéde Ìjọba lè fún àwọn tí ó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún níṣìírí nípa bíbá wọn sọ ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró, àti nípa lílọ pẹ̀lú wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Ìdùnnú Jèhófà—Odi Agbára Wa
Àwọn Kristẹni tí ó ti lo èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà tàbí míṣọ́nnárì, sísìn ní Bẹ́tẹ́lì, tàbí bíbẹ àwọn ìjọ wò nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò, ti rí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ ìṣòro jẹ́ fún ìgbà kúkúrú, ṣùgbọ́n àwọn kan máa ń wà pẹ́ títí. Àní àwọn ìṣòro díẹ̀ tí ó jọ bíi pé wọn kò fẹ́ lọ kò yẹ kí ó fi ayọ̀ wa dù wá. Ramon, tí ó ti sìn ní ilẹ̀ òkèèrè fún èyí tí ó lé ní 45 ọdún, dábàá pé nígbàkigbà tí ìṣòro bá kó ìbànújẹ́ bá wa, “ó yẹ kí a ronú nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tí a ní, àti nípa ẹgbẹẹgbẹ̀rún mìíràn tí ń jìyà àwọn ìnira tí ó ju tiwa lọ.” Ní tòótọ́, àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kárí ayé ń jìyà, Jèhófà sì bìkítà nípa gbogbo wa ní ti gidi.—Pétérù Kíní 5:6-9.
Nítorí náà, nígbà náà, bí àyíká ipò wa bá yọ̀ǹda fún wa láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, kí a sì máa bá a lọ, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní jíjẹ́ aláyọ̀ nípa gbígbára lé Bàbá wa ọ̀run. Ó ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun, ó sì yẹ kí gbogbo wá rántí pé ‘ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára wa.’—Nehemáyà 8:10, NW.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
“Ìmọ̀lára mi àti ohun tí mo fẹ́ kò ṣe pàtàkì tó iṣẹ́ náà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
“A máa ń sọ ìmọ̀lára wa jáde fún Jèhófà, a óò sì fa ohun gbogbo lé e lọ́wọ́”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe nínú ipòkípò tí o bá bá ara rẹ. Ó lè jẹ́ àǹfààní kan ṣoṣo ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan yóò mú wá fún ọ láti yin Jèhófà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Nípa fífara da àwọn àdánwò, mo lè ní ipa nínú fífẹ̀rí hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
“Nǹkan kì í fara rọ fún àwọn aṣáájú ọ̀nà kan. Wọ́n nílò ìṣírí síwájú sí i láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti àwọn akéde yòó kù”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
“Ó yẹ kí a ronú nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tí a ní”