Kí Ló Ń Mú Kí Ìbínú Máa Ru Bo Àwọn Èèyàn Lójú Tó Bẹ́ẹ̀?
WỌ́N yìnbọn pa ọ̀gbẹ́ni kan níbi tó jókòó sí nílé ọtí ní ìlú Prague, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech. Kí ló ṣe? Nítorí pé orin tó ń gbọ́ nínú rédíò rẹ̀ ń pariwo ni inú fi bí ẹni tó yìnbọn pa á. Ẹnì kan fi igi tí wọ́n fi ń gbá bọ́ọ̀lù hockey lu ọlọ́kọ̀ kan pa ní ìkòríta kan ní Cape Town, ní Gúúsù Áfíríkà. Iná ọkọ̀ tí ọlọ́kọ̀ náà tàn sí ọ̀gbẹ́ni yìí lójú ló mú kí inú rẹ̀ ru. Nọ́ọ̀sì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń gbé ní Ọsirélíà ni ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí fi ìpá já ilẹ̀kùn rẹ̀, ńṣe ni inú rẹ̀ ń ru ṣùù; ó da epo bẹntiróò sí gbogbo ara obìnrin yìí, ó sì ṣáná sí i nírètí pé kí iná jó o pa.
Ṣé pé àsọdùn làwọn ìròyìn tá à ń gbọ́ nípa àwọn tí wọ́n máa ń bínú, bí àwọn awakọ̀ tó ń bínú, ìwà ipá nínú ìdílé àtàwọn tó máa ń bínú nínú ọkọ̀ òfuurufú? Àbí ńṣe ni báwọn èèyàn ṣe ń bínú yìí dà bí ògiri tó sán, tó fi hàn pé ewu ń bẹ lóko lóńgẹ́? Ẹ̀rí fi hàn pé ewu gidi ni o.
Ní ti ojú pópó, ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí Sí Ààbò Àwọn Ọlọ́kọ̀ Lójú Pópó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Láti ọdún 1990, ìwà ipá lójú pópó ti fi ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méje nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè sí i.”
Ìbínú nínú agbo ìdílé náà ń ṣẹlẹ̀ káàkiri. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ New South Wales ní Ọsirélíà sọ pé, ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ni ẹjọ́ ìwà ipá inú ilé tí wọ́n mú wá sọ́dọ̀ wọn fi ròkè lọ́dún 1998. Ọ̀kan nínú mẹ́rin àwọn obìnrin tó ti lọ́kọ tàbí tóun àti ọkùnrin jọ ń gbé láìbófinmu ló ti fojú winá ìwà ipá látọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yẹn.
Bákan náà lọ̀rọ̀ rí béèyàn bá wọ ọkọ̀ òfuurufú. Wàhálà àwọn èrò inú ọkọ̀ òfuurufú, tí wọ́n á ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀, àwọn èrò bíi tiwọn tàbí àwọn awakọ̀ jà, ló mú káwọn ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ńláńlá kan lágbàáyé ṣe àwọn bẹ́líìtì kan sínú ọkọ̀ òfuurufú èyí tí kò ní jẹ́ káwọn èrò tó jẹ́ oníwà ipá lè kúrò lórí ìjókòó wọn.
Kí ló fà á táwọn èèyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i kì í fi í lè fọwọ́ wọ́nú bí inú bá ń bí wọn? Kí ló ń mú inú wọn ru ná? Ṣé lóòótọ́ ló ṣeé ṣe láti kápá ìbínú?
Kí Ló Fà Á Tí Àwọn Èèyàn Tí Ń Bínú Fi Ń Pọ̀ Sí I?
Pé inú ẹnì kan ru túmọ̀ sí pé inú ti bí i kọjá ààlà. Fífa ìbínú yọ máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá gbé nǹkan tó ń bí i nínú sọ́kàn títí tí ìyẹn á fi pin ín lẹ́mìí. David K. Willis, tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí Sí Ààbò Àwọn Ọlọ́kọ̀ Lójú Pópó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Kì í ṣe aáwọ̀ ẹ̀ẹ̀kan péré ló ń fa ìwà ipá àwọn ọlọ́kọ̀. Àmọ́ ó dà bí ẹni pé ìwà olúkúlùkù àwọn ọlọ́kọ̀ náà tàbí másùnmáwo tó máa ń bá wọn ló ń fà á.”
Ohun tó tún máa ń pa kún másùnmáwo yìí ni ìsọfúnni tó pọ̀ lọ jàra tá a máa ń fẹ́ kó sórí lójoojúmọ́. Ohun tó wà lẹ́yìn ìwé Information Overload, látọwọ́ David Lewis, kà pé: “Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ lóde òní ni ìsọfúnni ń rọ́ bò lọ́tùn-ún lósì . . . Bí ìsọfúnni wọ̀nyí bá sì ti pọ̀ jù, . . . másùnmáwo dé nìyẹn, wọ́n á di oníjàgídíjàgan, wọn ò sì ní lè ṣe àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe níbi tí wọ́n ti ń ronú lórí èyí tó yẹ kí wọ́n yàn nínú omilẹgbẹ ìsọfúnni ọ̀hún.” Nígbà tí ìwé ìròyìn kan ń ṣàpẹẹrẹ bí àwọn ìsọfúnni náà ti pọ̀ tó, ó sọ pé: “Ìsọfúnni tó wà nínú ìwé ìròyìn kan lọ́jọ́ kan ṣoṣo jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú gbogbo ìsọfúnni táwọn èèyàn ọ̀rúndún kẹtàdínlógún rí ní gbogbo ìgbésí ayé wọn.”
Àwọn ohun tó ń wọlé sẹ́nu wa tún lè mú ká máa tètè bínú. Ìwádìí gbígbòòrò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti fi hàn pé sìgá mímu, ọtí mímu àti jíjẹ oúnjẹ tí kì í ṣara lóore máa ń fa kéèyàn máa ṣe gbúngbùngbún síra wọn. Irú ìgbésí ayé báwọ̀nyí tó ti di àrùn kárí ayé máa ń tanná ran másùnmáwo àti ìjákulẹ̀. Ìjákulẹ̀ yìí ló ń mú káwọn èèyàn máa sọ ọ̀rọ̀kọ́rọ̀, kì í jẹ́ kí wọ́n lè ṣe sùúrù, wọn kì í sì í rára gba nǹkan sí.
Ipa Tí Sinimá Ń Kó Nínú Híhu Ìwàkiwà
Nígbà tí Dókítà Adam Graycar, tó jẹ́ olùdarí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Òfin Nípa Ìwà Ọ̀daràn ní Ọsirélíà, ń sọ àjọṣe tó wà láàárín àwọn àṣà tí kò dáa àti ìwà ọ̀daràn, ó sọ pé: “Níní èrò tó dára nípa bíbọ̀wọ̀ fúnni àti àwọn àṣà tó yẹ ọmọlúwàbí lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tá a máa ṣe láti dín ìwà ọ̀daràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kù.” Ilé ẹ̀kọ́ náà sọ pé ohun tó dára ni pé kéèyàn máa ní sùúrù, kó máa rí ara gba nǹkan sí, kó má sì máa bú àwọn èèyàn. Ó sọ pé láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ìwà tó kù díẹ̀ káàtó lè yọrí sí ìwà ọ̀daràn. Ó mà yani lẹ́nu o, pé ńṣe ni fàájì ṣíṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn yàn láàyò lónìí láti fi pa ìrònú àti másùnmáwo rẹ́ ń sọ wọ́n di ẹni tí kò rí ara gba nǹkan sí tí inú wọn sì tètè máa ń ru. Lọ́nà wo?
Ìròyìn kan láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Òfin Nípa Ìwà Ọ̀daràn ní Ọsirélíà sọ pé: “Gìrọ́gìrọ́ làwọn ọmọdé àtàgbà máa ń rọ́ lọ sí ilé sinimá láti wo àwọn eré táwọn èèyàn ti ń pa ara wọn tí wọ́n sì ń ba nǹkan jẹ́. Òwò àwọn fídíò oníwà ipá ti pọ̀ káàkiri ó sì ń mówó púpọ̀ wọlé. ‘Àwọn nǹkan ìṣeré tí wọ́n dà bíi tàwọn ológun’ wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn ọmọdé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí wọn kì í fìgbà gbogbo fẹ́ràn rẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́mọdé lágbà ló ń gbádùn àwọn eré oníwà ipá tí wọ́n ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n, ipa tí tẹlifíṣọ̀n sì ń kó nínú kíkọ́ àwùjọ ní àwọn ìlànà kan kò kéré.” Báwo ni èyí ṣe wá kan tàwọn tí wọ́n á kàn ṣàdédé fa ìbínú yọ lójú pópó tàbí nínú ilé? Ìròyìn náà sọ pé: “Bí àwùjọ bá ṣe fàyè gba ìwà ipá tó, bẹ́ẹ̀ náà làwọn èèyàn tó wà láwùjọ ọ̀hún á ṣe máa hùwà ipá tó.”
Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló máa sọ pé fífa ìbínú yọ jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣẹ̀dá wa láti hùwà nígbà tí ara wa kò bá lélẹ̀, pé kò sì sí ọgbọ́n tá a lè ta sí i nínú ayé oníkòókòó-jàn-ánjàn-án àti oníwà ipá yìí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé ìmọ̀ràn tó dáa ni èrò tó wọ́pọ̀ náà pé, “Bí inú bá bí ẹ, ṣáà ti ṣe ohun tó bá wù ọ́ láìwojú ẹnikẹ́ni”?
Ṣó Yẹ Kéèyàn Kápá Ìbínú Rẹ̀?
Gẹ́gẹ́ bí òkè ayọnáyèéfín tó bú gbàù ṣe máa ń ṣe àwọn tó ń gbé lágbègbè rẹ̀ bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojú, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnì kan tí kì í wẹ̀yìn wò bó bá ń bínú ṣe máa ń ṣèpalára fáwọn tó ń gbé ládùúgbò rẹ̀. Bákan náà ló tún ń ṣe ara rẹ̀ léṣe gidi gan-an. Lọ́nà wo? Ìwé The Journal of the American Medical Association (JAMA), sọ pé: “Bíbínú rangbandan máa ń mú kéèyàn túbọ̀ fínràn sí i ni.” Ìwádìí sì fi hàn pé àwọn ọkùnrin tó máa ń bínú rangbandan “ló ṣeé ṣe kí wọ́n yára di olóògbé tí wọ́n bá fi máa pé ẹni àádọ́ta ọdún ju àwọn tí kì í bínú rangbandan lọ.”
Bákan náà, Ẹgbẹ́ Ìtọ́jú Àrùn Ọkàn Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó ṣeé ṣe ní ìlọ́po méjì kí àwọn ọkùnrin tí wọ́n máa ń bínú rangbandan ní àrùn ẹ̀gbà ju àwọn tí kì í bínú rangbandan.” Àtọkùnrin àtobìnrin ni ìkìlọ̀ yìí wà fún o.
Àmọ̀ràn wo ló wá gbéṣẹ́? Ìwọ wo bí ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn ìwé téèyàn kọ ṣe jọra pẹ̀lú èyí tó wà nínú ìwé kan tó jẹ́ ọba ìwé lórí àjọṣe ẹ̀dá, tá a tíì pín kiri jù lọ, ìyẹn Bíbélì.
Kápá Ìbínú Rẹ, Yéé Bínú Rangbandan
Dókítà Redford B. Williams sọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn JAMA pé: “Ìmọ̀ràn tó rọrùn náà pé ‘tí ìbínú bá dé, ṣáà ṣe ohun tó bá wù ọ́ láìwojú ẹnikẹ́ni,’ kò dà bí èyí . . . tó máa ṣèrànwọ́ gidi kan o. Ohun tó ṣe pàtàkì gan-an ni pé kó o kíyè sí bí inú ṣe máa ń bí ọ kó o sì kọ́ láti kápá rẹ̀.” Ó dábàá pé kó o béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: “(1) Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ bàbàrà sí mí? (2) Ṣé èrò mi àti ìmọ̀lára mi bá òótọ́ tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà mu? (3) Ṣé ọgbọ́n wà tí mo lè ta sí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, tí kò fi ní pọn dandan pé kí n bínú?”
Òwe 14:29; 29:11 “Ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́ aláìnísùúrù ń gbé ìwà òmùgọ̀ ga. Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.”
Éfésù 4:26 “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.”
Frank Donovan, dámọ̀ràn nínú ìwé rẹ̀, Dealing With Anger—Self-Help Solutions for Men, pé: “Ṣíṣàìbínú rangbandan, tàbí ká kúkú là á mọ́lẹ̀, kíkúrò níbi tí ọ̀rọ̀ tó lè fa ìbínú náà ti ṣẹlẹ̀ àti kíkúrò ní sàkáání gbogbo èèyàn tọ́rọ̀ náà kàn jẹ́ ọgbọ́n kan tó gbéṣẹ́ gan-an nígbà tí ìbínú bá dójú ẹ̀.”
Òwe 17:14 “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde; nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.”
Ohun tí Bertram Rothschild kọ nínú ìwé àtìgbàdégbà náà, The Humanist, ni pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa bójú tó ọ̀ràn ìbínú. Àwọn nǹkan tó sì ń mú ká bínú wà ní agbárí wa. . . . Tó o bá fi ìwọ̀nba ìgbà tí ìbínú ti ṣe ohun tó o fẹ́ kó ṣe wéra pẹ̀lú àìmọye ìgbà tó ti dojú ọ̀rọ̀ rú, wàá rí i pé kò tó nǹkan rárá. Kó o máà bínú rárá dára gan-an ju pé kó o bínú kó sì wá ṣe ọ́ ní jàǹbá.”
Sáàmù 37:8 “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.”
Òwe 15:1 “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.”
Òwe 29:22 “Ènìyàn tí ó fi ara fún ìbínú ń ru asọ̀ sókè, ẹnikẹ́ni tí ó sì fi ara fún ìhónú ní ọ̀pọ̀ ìrélànàkọjá.”
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ni wọ́n ń fi ìmọ̀ràn tó wà lókè yìí sílò. A ké sí ọ láti lọ sáwọn ìpàdé wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níbi tó ò ń gbé kó o sì fojú ara rẹ rí i pé fífi àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì sílò dára gan-an ni, láìka ìrunú tó gbòde kan láyé tá a wà yìí sí.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Gẹ́gẹ́ bí òkè ayọnáyèéfín tó bú gbàù ni ẹni kan tí kì í wẹ̀yìn wò bó bá ń bínú ṣe máa ń ṣèpalára
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àmọ̀ràn Bíbélì gbéṣẹ́ gan-an ni