‘A ó Fìdí Àwọn Ìwéwèé Rẹ Múlẹ̀ Gbọn-in Gbọn-in’
NÍNÚ orin kan tí onísáàmù náà Dáfídì kọ, ó gbàdúrà pé: “Àní kí o dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Mú ayọ̀ ńláǹlà ìgbàlà rẹ padà bọ̀ sípò fún mi, kí o sì fi ẹ̀mí ìmúratán pàápàá tì mí lẹ́yìn.” (Sáàmù 51:10, 12) Lẹ́yìn tí Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó bẹ Jèhófà Ọlọ́run nínú ẹsẹ Bíbélì yìí pé kó fọ ọkàn òun mọ́ kó sì fi ẹ̀mí ṣíṣe ohun tó dára sínú òun.
Ṣé Jèhófà máa ń dá ọkàn tuntun sínú wa ni, bóyá tó tiẹ̀ tún ń fi ẹ̀mí tuntun àti ẹ̀mí ìmúratán sínú wa? Àbí a ní láti sapá ká tó lè ní ọkàn mímọ́ ká má sì jẹ́ kó padà di aláìmọ́? Lóòótọ́, “Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà,” àmọ́, báwo ló ṣe ń lọ́wọ́ sí ohun tó ń lọ nínú ọkàn wa tó? (Òwe 17:3; Jeremáyà 17:10) Báwo ló sì ṣe ń darí ìgbésí ayé wa tó, àti ìwà wa àtohun tó ń mú wa ṣe àwọn nǹkan?
Ìgbà mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Òwe orí kẹrìndínlógún ẹsẹ kìíní sí kẹsàn-án mẹ́nu kan orúkọ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí ìgbésí ayé wa kí ‘àwọn ìwéwèé wa lè fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.’ (Òwe 16:3) Ẹsẹ kẹwàá sí ìkẹẹ̀ẹ́dógún ní tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ojúṣe ọba.
Ta Ló Ń ‘Ṣètò Ọkàn-Àyà’?
Apá àkọ́kọ́ nínú Òwe orí kẹrìndínlógún ẹsẹ kìíní sọ pé: “Àwọn ìṣètò ọkàn-àyà jẹ́ ti ará ayé.” Èyí fi hàn pé ojúṣe wa ni láti ‘ṣètò ọkàn’ wa. Jèhófà kì í fúnra rẹ̀ bá wa ṣètò ọkàn wa, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í gbé ẹ̀mí ìmúratán wọ̀ wá. A ní láti sapá láti ní ìmọ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà pípéye, ká ronú lórí ohun tá a bá kọ́ nínú rẹ̀, ká sì jẹ́ kí èrò wa bá ti Jèhófà mu.—Òwe 2:10, 11.
Àmọ́, bí Dáfídì ṣe ní kí Jèhófà dá “ọkàn-àyà mímọ́ gaara” sínú òun kó sì fi “ẹ̀mí tuntun” sínú òun fi hàn pé ó mọ̀ pé ẹni tó lè dẹ́ṣẹ̀ lòun, àti pé òun nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti lè fọ ọkàn òun mọ́. Níwọ̀n bá a ti jẹ́ aláìpé, a lè rí ìdẹwò tó máa fẹ́ mú wa lọ́wọ́ nínú “àwọn iṣẹ́ ti ara.” (Gálátíà 5:19-21) A nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà láti lè “sọ àwọn ẹ̀yà ara [wa] tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.” (Kólósè 3:5) Ó ṣe pàtàkì gan-an ni pé ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò ká sì lè mú àwọn ohun tó lè mú wa dẹ́ṣẹ̀ kúrò lọ́kàn wa!
Ǹjẹ́ a lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ‘ṣètò ọkàn’ wọn? Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Ìgbà wo ni ahọ́n wa máa tó lè mú àwọn míì lára dá? Ìgbà tó bá jẹ́ pé ‘láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìdáhùn ahọ́n [wa] ti wá’ nìkan ni, ìyẹn nígbà tá a bá sọ̀rọ̀ tó wà níbàámu pẹ̀lú òtítọ́ inú Bíbélì.—Òwe 16:1b.
Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà17:9) Ọkàn wa lè dá wa láre fún ohun tí kò dáa tá a ṣe, ó sì lè tàn wá jẹ. Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ kìlọ̀ nípa èyí, ó ní: “Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó mọ́ gaara ní ojú ara rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà ni ó ń díwọ̀n àwọn ẹ̀mí.”—Òwe 16:2.
Nítorí pé àwa èèyàn kì í fẹ́ kí ohunkóhun bu iyì wa kù, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwíjàre tá a bá ṣe ohun tí kò tọ́, a lè fẹ́ máa fi àwọn ànímọ́ burúkú tá a ní pa mọ́, tàbí ká máa gbójú fo àìdáa tá a bá ṣe. Àmọ́, a ò lè tan Jèhófà jẹ nítorí pé ó ń díwọ̀n ẹ̀mí. Ẹ̀mí tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni irú èrò tó sábà máa ń wà lọ́kàn èèyàn, torí ọkàn lèèyàn fi máa ń ro nǹkan. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ohun tó máa ń mú kéèyàn ní irú ẹ̀mí tó ní ni ohun tó ń lọ nínú ọkàn ẹni, irú bí ohun téèyàn ń rò lọ́kàn, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹni, àtohun tó ń mú kéèyàn ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe. Ẹ̀mí yìí ni “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà” ń díwọ̀n láti mọ bó ṣe rí gan-an, kì í sì í ṣojúsàájú. Ẹ ò rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká máa ṣọ́ ẹ̀mí wa!
“Yí Àwọn Iṣẹ́ Rẹ Lọ Sọ́dọ̀ Jèhófà”
Téèyàn bá ń wéwèé ohun kan, ó máa ń gba pé kéèyàn fọkàn rò ó. Tá a bá ti wá wéwèé nǹkan tán, ká mú un ṣe ló kù. Àmọ́ kí ló máa jẹ́ káwọn ohun tá a wéwèé láti ṣe kẹ́sẹ járí? Sólómọ́nì sọ fún wa, ó ní: “Yí àwọn iṣẹ́ rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀, a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 16:3) Ohun tó túmọ̀ sí láti yí àwọn iṣẹ́ wa lọ sọ́dọ̀ Jèhófà ni pé ká gbẹ́kẹ̀ wa lé e, ká gbójú lé e, ká jẹ́ kó máa darí wa. Ìyẹn ni pé ká gbé ẹrù ìnira kúrò léjìká wa ká sì gbé e sí èjìká tirẹ̀. Onísáàmù kan kọrin pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.”—Sáàmù 37:5.
Kí àwọn ìwéwèé wa, ìyẹn àwọn ohun tá a ronú láti ṣe, tó lè fìdí múlẹ̀ gbọn-in, wọ́n gbọ́dọ̀ wà níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, ká sì rí i pé ẹ̀mí tó dára ló mú wa ṣe àwọn nǹkan náà. Yàtọ̀ síyẹn, a ní láti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ kó sì tì wá lẹ́yìn, ká sì máa sa gbogbo ipá wa láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ‘ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà’ nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, nítorí pé ‘yóò gbé wa ró.’ Dájúdájú, “kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”—Sáàmù 55:22.
“Ohun Gbogbo Ni Jèhófà Ti Ṣe fún Ète Rẹ̀”
Kí tún lohun mìíràn tó máa jẹ́ àbájáde yíyí tá a bá yí àwọn iṣẹ́ wa lọ sọ́dọ̀ Jèhófà? Ọlọgbọ́n ọba náà sọ pé: “Ohun gbogbo ni Jèhófà ti ṣe fún ète rẹ̀.” (Òwe 16:4a) Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run jẹ́ Ọlọ́run ètò, tó ti pinnu àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe. Torí náà tá a bá yí àwọn iṣẹ́ wa lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ìgbésí ayé wa yóò nítumọ̀ ní ti pé a ó máa fi ṣe nǹkan tó ní láárí, kò ní jẹ́ ìgbésí ayé asán. Ìpinnu Jèhófà ni pé kí ilẹ̀ ayé wà títí láé kéèyàn sì máa wà nínú rẹ̀ títí lọ gbére. (Éfésù 3:11) Ńṣe ló dá ilẹ̀ ayé “kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Yàtọ̀ síyẹn, ó dájú hán-ún pé ohun tó ní lọ́kàn fáwa èèyàn lórí ilẹ̀ ayé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ máa nímùúṣẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Tẹ́nì kan bá ń fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, yóò lè máa ṣe ohun tó ní láárí títí ayérayé.
Ọlọgbọ́n ọba náà tún sọ pé Jèhófà ti ṣe “ẹni burúkú fún ọjọ́ ibi.” (Òwe 16:4b) Èyí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà dá àwọn èèyàn búburú o, torí pé “pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) Ńṣe ló fàyè gbà wọ́n kí wọ́n wà, ó sì jẹ́ kí wọ́n wà láàyè títí dìgbà tí àkókò bá tó lójú rẹ̀ láti mú ìdájọ́ wá sórí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Fáráò ọba Íjíbítì pé: “Fún ìdí yìí ni mo ṣe mú kí o máa wà nìṣó, nítorí àtifi agbára mi hàn ọ́ àti nítorí kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Ẹ́kísódù 9:16) Dájúdájú, Ìyọnu Mẹ́wàá tí Ọlọ́run mú wá sórí Íjíbítì àti pípa tó pa Fáráò tòun ti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ run ní Òkun Pupa fi hàn pé agbára Ọlọ́run ò láfiwé. Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ni.
Jèhófà tún lè mú kí ohun táwọn èèyàn búburú ń ṣe já sí ohun tó máa mú ohun tóun ní lọ́kàn ṣẹ, táwọn yẹn ò sì ní mọ̀. Onísáàmù kan sọ pé: “Àní ìhónú ènìyàn yóò gbé ọ lárugẹ; ìyókù ìhónú ni ìwọ [Jèhófà] yóò fi di ara rẹ lámùrè.” (Sáàmù 76:10) Jèhófà lè jẹ́ káwọn ọ̀tá rẹ̀ tínú ń bí jẹ àwọn ìránṣẹ́ òun níyà, àmọ́ ó máa jẹ́ ní ìwọ̀n tó fi máa kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Tó bá ti ré kọjá ìyẹn, Jèhófà yóò dá sí ọ̀rọ̀ náà.
Jèhófà máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́. Àmọ́ àwọn agbéraga ńkọ́? Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà. Ọwọ́ lè so pọ̀ mọ́ ọwọ́, síbẹ̀ ẹni náà kì yóò bọ́ lọ́wọ́ ìyà.” (Òwe 16:5) Àwọn tí ó “gbéra ga ní ọkàn-àyà” lè para pọ̀ láti dáàbò bo ara wọn, ṣùgbọ́n wọn ò ní lọ láìjìyà. Nítorí náà, bó ti wù ká ní ìmọ̀ tó, bó ti wù ká mọ nǹkan ṣe tó, tàbí irú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yòówù ká ní, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.
“Nípa Ìbẹ̀rù Jèhófà”
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wa sí, ẹni tó lè ṣàṣìṣe ni wá. (Róòmù 3:23; 5:12) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tí a kò fi ní máa gbèrò ohun tó lè mú wa dẹ́ṣẹ̀? Òwe 16:6 jẹ́ ká mọ̀ ọ́n, ó ní: “Nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ ni a ń ṣètùtù fún ìṣìnà, àti nípa ìbẹ̀rù Jèhófà, ènìyàn a yí padà kúrò nínú ohun búburú.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa ń nu ẹ̀ṣẹ̀ wa nù nítorí inú rere onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́ rẹ̀, ìbẹ̀rù Jèhófà ló máa mú ká yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ẹ ò wá rí i pé yàtọ̀ sí pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká sì mọyì inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, ó yẹ ká bẹ̀rù rẹ̀ ká má bàa ṣe ohun tí kò fẹ́!
Tá a bá ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún agbára ńláǹlà tí Ọlọ́run ní, àá dẹni tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn. Tiẹ̀ ronú ná nípa agbára ńláǹlà tí àwọn nǹkan tó dá fi hàn pé ó ní! Nígbà tí Ọlọ́run rán Jóòbù létí agbára tóun fi ṣẹ̀dá, Jóòbù yí èrò tó ní padà. (Jóòbù 42:1-6) Nígbà táwa náà bá ṣí Bíbélì tá a sì kà nípa bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò láyé ọjọ́un, tá a wá ronú jinlẹ̀ nípa rẹ̀, ǹjẹ́ kì í mú ká tún èrò wa ṣe? Onísáàmù kan kọrin pé: “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Ọlọ́run. Ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ènìyàn múni kún fún ẹ̀rù.” (Sáàmù 66:5) Kò yẹ ká gbà pé ńṣe ni Jèhófà á máa fi àánú hàn sí wa ṣáá láìka bá a ṣe ń ṣe sí. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ‘ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tí wọ́n sì ba ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́, Jèhófà yí padà di ọ̀tá wọn; òun fúnra rẹ̀ sì bá wọn jagun.’ (Aísáyà 63:10) Àmọ́, “nígbà tí Jèhófà bá ní ìdùnnú nínú àwọn ọ̀nà ènìyàn, ó máa ń mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀.” (Òwe 16:7) Ẹ ò rí i pé ààbò ńlá ni ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́!
Ọlọgbọ́n ọba náà ní: “Díẹ̀ tòun ti òdodo, sàn ju ọ̀pọ̀ yanturu àmújáde láìsí ìdájọ́ òdodo.” (Òwe 16:8) Bákan náà, Òwe 15:16 sọ pé: “Díẹ̀ ní inú ìbẹ̀rù Jèhófà sàn ju ọ̀pọ̀ ìpèsè yanturu tòun ti ìdàrúdàpọ̀.” Dájúdájú, kòṣeémáàní ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run téèyàn ò bá fẹ́ kúrò lójú ọ̀nà òdodo.
“Ọkàn-Àyà Ará Ayé Lè Gbìrò Ọ̀nà Ara Rẹ̀”
Ọlọ́run dá àwa èèyàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tó lómìnira láti yan èyí tó wù ú nínú ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Diutarónómì 30:19, 20) Ọkàn wa lágbára láti gbé ọ̀pọ̀ nǹkan yẹ̀ wò kó sì yan ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára wọn. Sólómọ́nì fi hàn pé ojúṣe wa ni láti máa ṣèpinnu, ó ní: “Ọkàn-àyà ará ayé lè gbìrò ọ̀nà ara rẹ̀.” Téèyàn bá ti lè ṣèyẹn, ‘Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa darí àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀.’ (Òwe 16:9) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà lè darí ìṣísẹ̀ wa, ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ tá a bá ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti ‘fìdí àwọn ìwéwèé wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.’
Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò, ọkàn máa ń ṣe àdàkadekè, èrò tó ń tanni jẹ sì lè wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá dẹ́ṣẹ̀, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn ro bó ṣe máa dá ara rẹ̀ láre. Kàkà kó kiwọ́ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ bọlẹ̀, ó lè máa rò pé Ọlọ́run jẹ́ onífẹ̀ẹ́, onínúure, aláàánú, àtẹni tó máa ń dárí jini. Ohun tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń sọ nínú ọkàn rẹ̀ ni pé: “Ọlọ́run ti gbàgbé. Ó ti fi ojú rẹ̀ pa mọ́. Dájúdájú, òun kì yóò rí i láé.” (Sáàmù 10:11) Bẹ́ẹ̀, kò tọ̀nà láti gbà pé ńṣe ni Ọlọ́run á máa fi àánú hàn sí wa ṣáá láìka bá a ṣe ń ṣe sí, irú èrò bẹ́ẹ̀ sì léwu.
“Àwọn Atọ́ka-Ìwọ̀n àti Òṣùwọ̀n Títọ́ Jẹ́ Ti Jèhófà”
Sólómọ́nì mẹ́nu kúrò lórí ọ̀rọ̀ ọkàn àti ìwà ọmọ aráyé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa ọkàn àti ìwà ọba. Ó ní: “Ìpinnu onímìísí ni ó yẹ kí ó wà ní ètè ọba; kò yẹ kí ẹnu rẹ̀ jẹ́ aláìṣòótọ́ nínú ìdájọ́.” (Òwe 16:10) Ó dájú pé Jésù Kristi, Ọba tí Jèhófà ti fi jẹ, máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa ṣàkóso ayé lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́.
Ọba ọlọgbọ́n náà sọ ẹni tó jẹ́ orísun òdodo àti ìdájọ́ òdodo, ó ní: “Àwọn atọ́ka-ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n títọ́ jẹ́ ti Jèhófà; gbogbo àwọn òkúta àfiwọn-ìwúwo tí ń bẹ nínú àpò jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀.” (Òwe 16:11) Jèhófà ló lè pèsè àwọn atọ́ka ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n tó tọ́. Kò sí ọba èyíkéyìí tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé ìlànà tó tọ́ lójú ara rẹ̀ kálẹ̀. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé: “Èmi kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara mi; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ń gbọ́ ni mo ń ṣèdájọ́; òdodo sì ni ìdájọ́ tí mo ń ṣe, nítorí pé kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mo ń wá, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” Ó yẹ ká nígbàgbọ́ pé Ọmọ tí Bàbá ‘ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé lọ́wọ́’ yóò fòdodo ṣèdájọ́.—Jòhánù 5:22, 30.
Kí tún lohun míì tá a lè retí látọ̀dọ̀ ọba tó ń ṣojú fún Jèhófà? Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Híhu ìwà burúkú jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún àwọn ọba, nítorí nípasẹ̀ òdodo ni ìtẹ́ fi ń fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 16:12) Ìlànà òdodo Ọlọ́run ni Ìjọba Mèsáyà fi ń ṣàkóso. Ìjọba náà ò bá “ìtẹ́ tí ń fa àgbákò” dá nǹkan kan pọ̀.—Sáàmù 94:20; Jòhánù 18:36; 1 Jòhánù 5:19.
Bá A Ṣe Lè Rí Ojú Rere Ọba Náà
Kí ló yẹ kí àwọn tí ọba ọlọ́lá ńlá ń ṣàkóso lé lórí ṣe? Sólómọ́nì sọ pé: “Ètè òdodo jẹ́ ìdùnnú atóbilọ́lá ọba; ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun adúróṣánṣán. Ìhónú ọba túmọ̀ sí àwọn ońṣẹ́ ikú, ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni ẹni tí ń yẹ̀ ẹ́.” (Òwe 16:13, 14) Àwọn olùjọsìn Jèhófà lóde òní fi ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn, wọ́n ń bá iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn lọ ní pẹrẹu. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Wọ́n mọ̀ pé lílò táwọn ń lo ètè àwọn lọ́nà yẹn ń mú inú Mèsáyà Ọba náà, Jésù Kristi, dùn. Kò sí àní-àní pé ó jẹ́ ìwà ọgbọ́n láti máa wá ojú rere ọba tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn, kéèyàn má sì ṣe ohun tó máa múnú bí i. Mélòómélòó wa ni Mèsáyà Ọba! Dájúdájú, ó yẹ kéèyàn wá ojú rere rẹ̀.
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Inú ìmọ́lẹ̀ ojú ọba ni ìyè, ìfẹ́ rere rẹ̀ sì dà bí àwọsánmà òjò ìgbà ìrúwé.” (Òwe 16:15) “Ìmọ́lẹ̀ ojú ọba” túmọ̀ sí ojú rere rẹ̀, àní bí ‘ìmọ́lẹ̀ ojú Jèhófà’ ṣe túmọ̀ sí ojú rere rẹ̀. (Sáàmù 44:3; 89:15) Bí òjò tó ṣú ṣe máa ń jẹ́ kó dáni lójú pé òjò á rọ̀ láti mú kí ohun ọ̀gbìn ṣe dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere ọba ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé ó ń bọ̀ wá ṣe nǹkan rere fúnni. Lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà, ńṣe ni inú aráyé á máa dùn wọ́n á sì láásìkí, bí ìdùnnú àti aásìkí ṣe wà nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. Àmọ́ kékeré ni ti ìgbà ìṣàkóso Sólómọ́nì máa jẹ́ tá a bá fi wé èyí tó máa wà nígbà Ìjọba Mèsáyà.—Sáàmù 72:1-17.
Bá a ṣe ń retí pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé láti gbàkóso ohun gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, ẹ jẹ́ ká máa wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá a ṣe ń sapá láti wẹ ọkàn wa mọ́. Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ wa lé Jèhófà ká sì ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á lè dá wa lójú pé ‘àwọn ìwéwèé wa yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.’—Òwe 16:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ṣe “ẹni burúkú fún ọjọ́ ibi”?