ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 21
Má Ṣe Jẹ́ Kí “Ọgbọ́n Ayé Yìí” Nípa Lórí Rẹ
“Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 KỌ́R. 3:19.
ORIN 98 Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń kọ́ wa?
JÈHÓFÀ ni Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá, torí náà ọkàn wa balẹ̀ pé kò sí ìṣòro tá ò ní lè borí. (Àìsá. 30:20, 21) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń kọ́ wa ní gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ ká lè “kúnjú ìwọ̀n dáadáa,” ká sì “gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.” (2 Tím. 3:17) Tá a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa, a máa di ọlọgbọ́n, ìgbésí ayé wa sì máa nítumọ̀ ju tàwọn tó ń gbé “ọgbọ́n ayé” yìí lárugẹ.—1 Kọ́r. 3:19; Sm. 119:97-100.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Bá a ṣe máa rí i, kì í rọrùn láti dá yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé. Torí pé a jẹ́ aláìpé, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú tàbí ká máa hùwà bíi tàwọn tó ń fi ọgbọ́n ayé yìí ṣèwà hù. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má fi ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán mú yín lẹ́rú látinú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn.” (Kól. 2:8) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn irọ́ kàbìtì méjì tí ayé Sátánì ti pa àti bó ṣe di pé àwọn irọ́ náà gbalẹ̀ gbòde. Bá a ṣe ń gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yẹ̀ wò, a máa rí ìdí tí ọgbọ́n ayé yìí fi jẹ́ òmùgọ̀, a sì máa rí i pé gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni ọgbọ́n Ọlọ́run fi sàn ju ti ayé lọ.
OJÚ TÁWỌN ÈÈYÀN FI Ń WO ÌBÁLÒPỌ̀
3-4. Tó bá kan ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìbálòpọ̀, ìyípadà wo ló wáyé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láàárín ọdún 1900 sí 1930?
3 Láyé ìgbà kan, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn tọkọtaya nìkan ló yẹ kó máa ní ìbálòpọ̀ àti pé ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ kì í ṣohun tá à ń sọ ní gbangba. Àmọ́ láàárín ọdún 1900 sí 1930, ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìbálòpọ̀ yí pa dà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, bó ṣe di pé ìṣekúṣe gbalẹ̀ gbòde nìyẹn.
4 Ìyípadà yìí fara hàn kedere láàárín ọdún 1920 sí 1929, lásìkò yẹn ọ̀pọ̀ èèyàn ò fọwọ́ gidi mú ìwà rere àti ìwà ọmọlúàbí mọ́. Olùṣèwádìí kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn kì í gbádùn àwọn sinimá, eré orí ìtàgé, orin, ìwé àti ìpolówó ọjà tí kò bá ti ní ìṣekúṣe nínú.” Àsìkò yìí kan náà làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wọ aṣọkáṣọ, tí wọ́n sì ń jó ijókíjó tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe. Gbogbo èyí ò yani lẹ́nu torí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn máa “fẹ́ràn ìgbádùn” gan-an.—2 Tím. 3:4.
5. Ojú wo làwọn èèyàn ayé fi ń wo ìṣekúṣe látọdún 1960?
5 Bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún 1960, ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pa pọ̀ láìṣègbéyàwó, bí ọkùnrin ṣe ń fẹ́ ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ làwọn obìnrin náà ń fẹ́ obìnrin, ìkọ̀sílẹ̀ wá gbòde kan. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ eré ìnàjú ló túbọ̀ ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ lọ́nà tó burú jáì. Àkóbá wo làwọn nǹkan yìí ti ṣe? Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Báwọn èèyàn ṣe gbàgbàkugbà láyè tó bá kan ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe” ti mú kí ọ̀pọ̀ ìdílé tú ká, ó ti fa ẹ̀dùn ọkàn fáwọn míì, ó ti mú káwọn kan jingíri nínú wíwo àwòrán oníhòòhò, bẹ́ẹ̀ sì ni ìdílé olóbìí kan túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Yàtọ̀ síyẹn, báwọn àrùn ìbálòpọ̀ bí AIDS ṣe ń jà ràn-ìn jẹ́ kó hàn gbangba pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ni ọgbọ́n táyé ń gbé lárugẹ.—2 Pét. 2:19.
6. Kí nìdí tí ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìbálòpọ̀ fi ń múnú Sátánì dùn?
6 Irú ojú tí Sátánì fẹ́ káwọn èèyàn fi máa wo ìbálòpọ̀ gan-an lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wò ó. Inú rẹ̀ ń dùn bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń ṣèṣekúṣe, tí wọn ò sì mọyì ẹ̀bùn ìgbéyàwó àti ìbálòpọ̀ tí Jèhófà fún wa. (Éfé. 2:2) Ìṣekúṣe kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọyì ẹ̀bùn iyebíye tí Jèhófà fún wa láti máa bímọ, àwọn tó sì ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀ kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 6:9, 10.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÌBÁLÒPỌ̀
7-8. Kí nìdí tí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ fi bọ́gbọ́n mu ju ohun táyé ń gbé lárugẹ lọ?
7 Àwọn tó fara mọ́ èrò ayé máa ń bẹnu àtẹ́ lu ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀, wọ́n sì gbà pé kò bọ́gbọ́n mu. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè ronú pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run dá wa lọ́nà táá mú kó máa wù wá láti ní ìbálòpọ̀, táá tún wá fún wa lófin nípa ẹ̀?’ Ìṣòro táwọn tó nírú èrò bẹ́ẹ̀ ní ni pé, wọ́n gbà pé gbogbo ohun tó bá ti wu èèyàn ló gbọ́dọ̀ ṣe. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a lè kó ara wa níjàánu, ká sì pinnu pé a ò ní lọ́wọ́ sí ìwàkiwà. (Kól. 3:5) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti fi ẹ̀bùn ìgbéyàwó jíǹkí wa ká lè gbádùn ìbálòpọ̀ lọ́nà tó tọ́. (1 Kọ́r. 7:8, 9) Nípa bẹ́ẹ̀, tọkọtaya lè gbádùn ìbálòpọ̀ láìsí pé wọ́n ń ní ẹ̀dùn ọkàn táwọn tó ń ṣèṣekúṣe máa ń ní.
8 Kò sí àní-àní pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ bọ́gbọ́n mu, gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló sì fi sàn ju ohun táyé ń gbé lárugẹ. Bíbélì tiẹ̀ tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìbálòpọ̀ máa ń gbádùn mọ́ni. (Òwe 5:18, 19) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mọ bó ṣe máa kó ara rẹ̀ níjàánu nínú jíjẹ́ mímọ́ àti nínú iyì, kì í ṣe nínú ojúkòkòrò ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ Ọlọ́run.”—1 Tẹs. 4:4, 5.
9. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láwọn ọdún 1900 sí 1930 kí ohun táyé ń gbé lárugẹ má bàa kéèràn ràn wọ́n? (b) Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wo ló wà nínú 1 Jòhánù 2:15, 16? (d) Bó ṣe wà nínú Róòmù 1:24-27, àwọn ìwàkiwà wo ló yẹ ká sá fún?
9 Láàárín àwọn ọdún 1900 sí 1930, àwọn èèyàn Jèhófà ò jẹ́ kí ohun tí ayé ń gbé lárugẹ kéèràn ràn wọ́n, torí pé èrò àwọn èèyàn ayé ti “kọjá gbogbo òye ìwà rere.” (Éfé. 4:19) Àwọn èèyàn Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ilé Ìṣọ́ May 15, 1926 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé “kò yẹ kí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan máa ro èròkerò tàbí kó máa hùwà àìmọ́ pẹ̀lú ẹni tó jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì.” Láìka ohun táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ lákòókò yẹn sí, àwọn èèyàn Jèhófà ń tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n gíga jù lọ tó wà nínú Bíbélì. (Ka 1 Jòhánù 2:15, 16.) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí! Inú wa tún dùn pé Jèhófà ń fún wa lóúnjẹ tẹ̀mí lásìkò tó yẹ kí èròkerò táyé ní nípa ìbálòpọ̀ má bàa ràn wá.b—Ka Róòmù 1:24-27.
OJÚ TÁWỌN ÈÈYÀN AYÉ FI Ń WO ARA WỌN
10-11. Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
10 Bíbélì sọ pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn èèyàn máa “nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan.” (2 Tím. 3:1, 2) Torí náà, kò yani lẹ́nu pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan layé ń gbé lárugẹ. Ìwé ìwádìí kan sọ pé láwọn ọdún 1970, “àwọn ìwé tó dá lórí béèyàn ṣe lè yọrí ọlá ló kún ìgboro.” Àwọn ìwé kan tiẹ̀ “gba àwọn tó ń kà á níyànjú pé kò yẹ kí wọ́n yí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ pa dà bíi pé ìwà wọn ò dáa, pé àfi káwọn èèyàn gbà wọ́n bí wọ́n ṣe rí.” Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn ìwé yẹn sọ pé: “Nífẹ̀ẹ́ ara ẹ, torí pé kò sí ẹlòmíì tó rẹwà tó sì dáa tó ẹ.” Ohun tí ìwé náà ń gbé lárugẹ ni pé “ohunkóhun tó bá wù ẹ́, tó tọ́ lójú ẹ, tó sì bá ẹ lára mu ni kó o máa ṣe.”
11 Ṣé o rántí pé ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ni Sátánì sọ fún Éfà lọ́jọ́ kìíní àná. Ó sọ fún un pé, ó lè ‘dà bí Ọlọ́run, ó sì máa mọ rere àti búburú.’ (Jẹ́n. 3:5) Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ro ara wọn ju bó ti yẹ lọ, wọ́n gbà pé kò sẹ́ni tó lè pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fáwọn, kódà wọn ò ka ìlànà Ọlọ́run sí rárá. Irú èrò yìí hàn kedere nínú ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìgbéyàwó.
12. Èrò wo làwọn èèyàn ayé ní nípa ìgbéyàwó?
12 Bíbélì sọ pé káwọn tọkọtaya máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, kí wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn. Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, kí wọ́n má sì jẹ́ kí ohunkóhun yà wọ́n. Ó sọ pé: ‘Ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.’ (Jẹ́n. 2:24) Àmọ́ ojú táwọn èèyàn ayé fi ń wo ìgbéyàwó yàtọ̀ síyẹn. Wọ́n gbà pé ohun tó bá wu kálukú ni kó ṣe láìfi ti ẹnì kejì pè. Bí àpẹẹrẹ, ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀ sọ pé: “Níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, àwọn tọkọtaya sábà máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á wà pa pọ̀ ‘níwọ̀n ìgbà táwọn bá fi jọ wà láàyè.’ Àmọ́ àwọn kan ti sọ ẹ̀jẹ́ náà di nǹkan míì, wọ́n máa ń sọ pé àwọn á wà pa pọ̀ ‘níwọ̀n ìgbà táwọn bá fi jọ nífẹ̀ẹ́ ara àwọn.’” Irú èrò yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ ìdílé tú ká, ó sì ti fa ọgbẹ́ ọkàn tí kì í jinná bọ̀rọ̀ fáwọn míì. Kò sí àní-àní pé, ohun tí ọgbọ́n ayé fi ń kọ́ni nípa ìgbéyàwó kò bọ́gbọ́n mu rárá àti rárá.
13. Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra àwọn agbéraga?
13 Bíbélì sọ pé: “Jèhófà kórìíra gbogbo ẹni tó ń gbéra ga.” (Òwe 16:5) Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra àwọn agbéraga? Ìdí kan ni pé Sátánì làwọn agbéraga fìwà jọ. Àbí kí ni ká ti gbọ́, pé kí Sátánì máa sọ fún Jésù pé kó forí balẹ̀ fún òun kó sì jọ́sìn òun, tó sì mọ̀ pé Jésù ni Jèhófà lò láti dá gbogbo nǹkan. Ẹ ò rí i pé àrífín gbáà nìyẹn, ìkọjá-àyè sì ni! (Mát. 4:8, 9; Kól. 1:15, 16) Irú ojú táwọn agbéraga fi ń wo ara wọn yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé lójú Ọlọ́run, ìwà òmùgọ̀ lohun tí ayé ń gbé lárugẹ.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA OJÚ TÓ YẸ KÁ FI MÁA WO ARA WA
14. Báwo ni ohun tó wà nínú Róòmù 12:3 ṣe lè jẹ́ ká ní èrò tó tọ́ nípa ara wa?
14 Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn táá jẹ́ ká lè máa fojú tó tọ́ wo ara wa. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa déwọ̀n àyè kan. Jésù sọ pé ká ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa bí ara wa,’ tó fi hàn pé ó yẹ ká máa tọ́jú ara wa. (Mát. 19:19) Àmọ́ Bíbélì ò sọ pé ká máa ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìbínú tàbí ìgbéraga mú yín ṣe ohunkóhun, àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.”—Fílí. 2:3; ka Róòmù 12:3.
15. Kí lo rò nípa ohun tí Bíbélì sọ tó bá kan ojú tó yẹ ká fi máa wo ara wa?
15 Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn táwọn èèyàn kà sí ọlọ́gbọ́n nínú ayé máa ń bẹnu àtẹ́ lu ohun tí Bíbélì sọ nípa ojú tó yẹ ká fi máa wo ara wa. Wọ́n gbà pé sùẹ̀gbẹ̀ lẹni tó bá ń ronú pé àwọn míì sàn ju òun lọ àti pé wọ́n máa rẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ. Àmọ́, báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn tó ń gbéra ga? Kí lo ti kíyè sí? Ṣé àwọn onímọtara-ẹni-nìkan máa ń láyọ̀? Ṣé ayọ̀ máa ń wà nínú ìdílé wọn? Ṣé wọ́n láwọn ọ̀rẹ́ gidi? Ṣé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run? Látinú ohun tíwọ fúnra rẹ ti rí, èwo lo gbà pé ó sàn jù, ṣé ọgbọ́n táyé ń gbé lárugẹ ni àbí ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì?
16-17. Kí ló yẹ ká máa dúpẹ́ fún, kí sì nìdí?
16 Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táyé ń gbé lárugẹ dà bí ẹni tí kò mọ̀nà tó wá ń béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹni tó ti sọnù, àfàìmọ̀ káwọn méjèèjì má bára wọn nínú igbó. Jésù sọ nípa àwọn tí wọ́n kà sí “ọlọ́gbọ́n” nígbà yẹn lọ́hùn-ún pé: “Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.” (Mát. 15:14) Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni ọgbọ́n ayé yìí!
17 Ìgbà gbogbo ni ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì máa ń “wúlò fún kíkọ́ni, fún bíbáni wí, fún títún nǹkan ṣe, fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo.” (2 Tím. 3:16, àlàyé ìsàlẹ̀) A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà o, bó ṣe ń lo ètò rẹ̀ láti tọ́ wa sọ́nà, tó sì ń dáàbò bò wá ká má bàa dẹni tí ọgbọ́n ayé yìí ṣì lọ́nà! (Éfé. 4:14) Oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa lóríṣiríṣi ń mú ká túbọ̀ máa fìgboyà tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní pé ọgbọ́n Ọlọ́run tí kò láfiwé tó wà nínú Bíbélì ló ń darí wa!
ORIN 54 “Èyí Ni Ọ̀nà”
a Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé kò sí ẹlòmíì tá a lè gbára lé fún ìtọ́sọ́nà bí kò ṣe Jèhófà. A tún máa rí i pé àwọn tó ń tẹ̀ lé ọgbọ́n ayé sábà máa ń kàgbákò, àmọ́ ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì máa ń ṣe wá láǹfààní.
b Bí àpẹẹrẹ, wo ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, orí 24 sí 26 àti Apá Kejì, orí 4 àti 5.
c ÀWÒRÁN: A rí bí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan ṣe gbé ìgbé ayé wọn látìgbà ọ̀dọ́ títí dìgbà tí wọ́n di àgbàlagbà. Láwọn ọdún 1960, àwọn méjèèjì ń wàásù fún ẹnì kan.
d ÀWÒRÁN: Láwọn ọdún 1980, ọkọ náà ń tọ́jú ìyàwó rẹ̀ tó ń ṣàìsàn, ọmọbìnrin wọn sì wà níbẹ̀ tó ń wò wọ́n.
e ÀWÒRÁN:Ní báyìí tí wọ́n ti di àgbàlagbà, tọkọtaya náà ń wo àwọn fọ́tò wọn, wọ́n sì ń rántí bí wọ́n ṣe lo ìgbésí ayé wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọmọbìnrin wọn, ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ náà wà pẹ̀lú wọn, inú wọn sì ń dùn bí wọ́n ṣe ń wo àwọn fọ́tò náà.