“Jèhófà Fúnra Rẹ̀ Ní Ń Fúnni Ní Ọgbọ́n”
KÍ NI ohun tí ò ń lépa, tóo ń lo àkókò àti agbára rẹ fún? Ǹjẹ́ ṣíṣe orúkọ rere fún ara rẹ tiẹ̀ jẹ ọ́ lógún? Àbí kíkó ọrọ̀ jọ lò ń lo gbogbo àkókò rẹ fún? Lílépa iṣẹ́ ìgbésí ayé kan tàbí dídi ògbógi nínú onírúurú ẹ̀ka ìmọ̀ ńkọ́? Ǹjẹ́ níní ìbátan rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tiẹ̀ jọ ẹ́ lójú? Àbí níní ìlera tó jí pépé ló jẹ ọ́ lógún?
Gbogbo àwọn nǹkan táa mẹ́nu kàn yìí ló jọ pé wọ́n ṣe pàtàkì, bó ti wù kó mọ. Ṣùgbọ́n, kí ló ṣe pàtàkì jù lọ? Bíbélì dáhùn pé: “Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ. Ní ọgbọ́n.” (Òwe 4:7) Nítorí náà, báwo la ṣe lè jèrè ọgbọ́n, kí sì ni àwọn àǹfààní rẹ̀? Èsì ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú orí kejì ìwé Òwe nínú Bíbélì.
“Dẹ Etí Rẹ Sí Ọgbọ́n”
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí baba tó fẹ́ràn ọmọ ẹ̀, Sólómọ́nì Ọba ọlọ́gbọ́n tó jẹ ní Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un sọ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:1-5.
Ǹjẹ́ o wá rí ibi tí iṣẹ́ jíjèrè ìmọ̀ wà? Nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, ọ̀rọ̀ náà “bí o bá,” fara hàn nígbà mẹ́ta. Ó ṣe kedere pé, olúkúlùkù wa ni yóò pinnu bóyá òun yóò wá ọgbọ́n àti àwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀—ìfòyemọ̀ àti òye. Ṣùgbọ́n, lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ “gba” ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n táa kọ sínú Ìwé Mímọ́ sínú ọpọlọ wa, kí a sì wá ‘fi wọ́n ṣúra.’ Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ọgbọ́n ni agbára táa fi lè lo ìmọ̀ tí Ọlọ́run fún wa dáadáa. Ohun àgbàyanu ló mà jẹ́ o, pé Bíbélì mú kí ọgbọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa! Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ló kúnnú ẹ̀, irú àwọn èyí táa kọ sínú ìwé Òwe àti Oníwàásù, ó sì ṣe pàtàkì pé ká dẹ etí wa sírú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Inú Bíbélì la tún ti rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó ń fi àǹfààní fífi ìlànà Ọlọ́run sílò hàn àti ewu tó wà nínú ṣíṣá wọn tì. (Róòmù 15:4; 1 Kọ́ríńtì 10:11) Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ìtàn Géhásì olójúkòkòrò, ìránṣẹ́ wòlíì Èlíṣà. (2 Àwọn Ọba 5:20-27) Ǹjẹ́ kò kọ́ wa ní bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó láti yẹra fún ojúkòkòrò? Kí ni ká sọ nípa àbájáde tó bani nínú jẹ́ ní ti ìbẹ̀wò tó jọ pé kò lè fa wàhálà èyí tí Dínà ọmọbìnrin Jékọ́bù ṣe sọ́dọ̀ “àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀” Kénáánì? (Jẹ́nẹ́sísì 34:1-31) Ǹjẹ́ a ò tipa èyí rí ìwà òmùgọ̀ tó wà nínú kíkẹ́gbẹ́ búburú?—Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33.
Dídẹ etí wa sí ọgbọ́n wé mọ́ níní ìfòyemọ̀ àti òye. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, Webster’s Revised Unabridged Dictionary, ti sọ, ìfòyemọ̀ ni “agbára tàbí èrò inú táa fi ń dá ohun kan mọ̀ yàtọ̀ sí òmíràn.” Ìfòyemọ̀ tí Ọlọ́run ń fúnni jẹ́ agbára láti dá ohun tó tọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́, ká sì wá yan ọ̀nà tó tọ́. Àfi táa bá ‘fi ọkàn-àyà wa’ sí ìfòyemọ̀, tàbí tí a ń hára gàgà láti ní in, àìjẹ́bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè dúró lójú “ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè”? (Mátíù 7:14; fi wé Diutarónómì 30:19, 20.) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífi í sílò ló ń fúnni ní ìfòyemọ̀.
Báwo la wá ṣe lè “ké pe òye”—ìyẹn ni agbára láti rí bí àwọn kókó ọ̀ràn kan ṣe sokọ́ kókó ọ̀ràn mìíràn? Lóòótọ́, ọjọ́ orí àti ìrírí jẹ́ ohun pàtàkì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye tó pọ̀—ṣùgbọ́n kì í ṣe ìwọ̀nyí nìkan. (Jóòbù 12:12; 32:6-12) Onísáàmù náà wí pé: “Èmi ń fi òye tí ó ju ti àwọn àgbà hùwà, nítorí pé mo ti pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ [ìyẹn, ti Jèhófà] mọ́.” Ó tún kọ ọ́ lórin pé: “Àní ìsọdimímọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ń fúnni ní ìmọ́lẹ̀, ó ń mú kí àwọn aláìní ìrírí lóye.” (Sáàmù 119:100, 130) Jèhófà ni “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” òye tirẹ̀ sì ju ti gbogbo aráyé lọ fíìfíì. (Dáníẹ́lì 7:13) Ọlọ́run lè fún ẹni tí kò nírìírí ní òye, ó sì lè ràn án lọ́wọ́ láti ní ànímọ́ yẹn ju àwọn tó jù ú lọ lọ́jọ́ orí pàápàá. Nítorí náà, ó yẹ ká jẹ́ aláápọn nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ àti fífi Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, sílò.
Àwọn ọ̀rọ̀ bíi “gbà,” “fi ṣúra,” “ké pe,” “bá a nìṣó ní wíwá,” “bá a nìṣó ní wíwá kiri” ló tẹ̀ lé gbólóhùn náà, “bí ó bá,” táa sọ ní àsọtúnsọ nínú àwọn ẹsẹ àkọ́kọ́ inú orí kejì ìwé Òwe. Èé ṣe tí òǹkọ̀wé yìí fi lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tó jẹ mọ́ ṣíṣe akitiyan níhìn-ín? Ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ wí pé: “[Níhìn-ín] amòye náà ń tẹnu mọ́ bí ṣíṣaápọn nínú lílépa ọgbọ́n ti pọndandan tó.” Bẹ́ẹ̀ ni, a gbọ́dọ̀ ṣaápọn láti lépa ọgbọ́n àti àwọn ànímọ́ mìíràn tó tan mọ́ ọn—ìyẹn ni ìfòyemọ̀ àti òye.
Ṣé Wàá Sapá?
Kókó pàtàkì nínú lílépa ọgbọ́n ni fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣùgbọ́n, ẹ̀kọ́ yìí kò ní wulẹ̀ jẹ́ kíkàwé wuuruwu lásán torí ká ṣáà lè mọ nǹkan kan. Ṣíṣàṣàrò pẹ̀lú ète kan lọ́kàn ṣe pàtàkì táa bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Jíjèrè ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ wé mọ́ ṣíṣàṣàrò lórí báa ṣe lè lo ohun táa ti kọ́ láti lè yanjú ìṣòro tàbí láti ṣèpinnu. Jíjèrè òye ń béèrè fún ríronú lórí bí ọ̀rọ̀ tuntun náà ṣe bá ohun táa ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ mu. Ta ló wá lè jiyàn pé irú ìkẹ́kọ̀ọ́ tó gbàrònú nínú Bíbélì bẹ́ẹ̀ kò béèrè àkókó àti ìsapá tó gbagbára? Lílo àkókò àti agbára wá dà bí lílo àkókò àti agbára ‘nínú wíwá ohun ìṣúra fífarasin kiri.’ Ṣé wàá sapá? Ṣé wàá ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà’ láti ṣe bẹ́ẹ̀?—Éfésù 5:15, 16.
Ronú nípa ohun ìṣúra ńláǹlà tí a óò rí báa bá fòótọ́ inú ṣèwádìí jinlẹ̀ nínú Bíbélì. Họ́wù, a óò rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an”—ìmọ̀ tó yè kooro, tó fìdí múlẹ̀, ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè, nípa Ẹlẹ́dàá wa! (Jòhánù 17:3) “Ìbẹ̀rù Jèhófà” tún jẹ́ ìṣúra táa lè jèrè. Ẹ ò rí i bí níní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún un ṣe ṣeyebíye tó! Ìbẹ̀rù tó gbámúṣé tí kì í jẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà kò fẹ́ gbọ́dọ̀ máa darí gbogbo apá ìgbésí ayé wa, kó máa fi ìjẹ́pàtàkì tẹ̀mí kún gbogbo ohun tí a bá ń ṣe.—Oníwàásù 12:13.
Ìfẹ́ fún ṣíṣèwádìí àti wíwá ohun ìṣúra nípa tẹ̀mí yẹ kó ká wa lára. Kí ìwádìí táa fẹ́ ṣe lè rọrùn, Jèhófà ti pèsè ohun èlò tó gbámúṣé—àwọn ìwé ìròyìn tó bá àkókò mu, tó ń la òdodo ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀, Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àti àwọn ìwé mìíràn táa gbé karí Bíbélì. (Mátíù 24:45-47) Nítorí àtilè kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì lè mọ ọ̀nà rẹ̀, Jèhófà tún ti pèsè àwọn ìpàdé Kristẹni. A gbọ́dọ̀ máa lọ sáwọn ìpàdé wọ̀nyí déédéé, ká máa tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń sọ, ká sapá gidigidi láti fiyè sí kókó tí wọ́n ń jíròrò, ká sì fi wọ́n sọ́kàn, ká sì wá ronú jinlẹ̀ nípa ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà.—Hébérù 10:24, 25.
Oò Ní Ṣe É Tì
Lọ́pọ̀ ìgbà, béèyàn bá ń wá ohun ìṣúra tó wà nínú ilẹ̀, wúrà, tàbí fàdákà kiri, kì í rí wọn. Ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ tó bá di ti wíwá ohun ìṣúra tẹ̀mí. Èé ṣe? Sólómọ́nì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.”—Owe 2:6.
Kò sẹ́ni tí ò mọ Sólómọ́nì Ọba pé ọgbọ́n rẹ̀ pọ̀ jọjọ. (1 Àwọn Ọba 4:30-32) Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ó ní ìmọ̀ nínú onírúurú ẹ̀kọ́, títí kan irúgbìn, ẹranko, ènìyàn, àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Òye tó fi hàn nígbà tó wà lórí oyè, tí kò sì tíì dàgbà púpọ̀, nígbà tó parí ìjà láàárín àwọn obìnrin méjì, táwọn ìyá méjèèjì ń jà lórí ọmọ kan ṣoṣo, ló jẹ́ kó wá di ẹni tí gbogbo ayé mọ̀. (1 Àwọn Ọba 3:16-28) Kí ni orísun ìmọ̀ ńlá tó ní yìí? Sólómọ́nì gbàdúrà sí Jèhófà fún “ọgbọ́n àti ìmọ̀” àti agbára “láti fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú.” Gbogbo rẹ̀ sì ni Jèhófà fún un.—2 Kíróníkà 1:10-12; 1 Àwọn Ọba 3:9.
Ó yẹ kí àwa pẹ̀lú gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà báa ti ń fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Onísáàmù gbàdúrà pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” (Sáàmù 86:11) Jèhófà gbọ́ àdúrà yẹn, nítorí ó mú ká kọ ọ́ sínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò gbọ́ àdúrà àtọkànwá tí à ń gbà nígbà gbogbo, pé kó jọ̀wọ́ ràn wá lọ́wọ́ láti rí ohun ìṣúra tẹ̀mí tó wà nínú Bíbélì.—Lúùkù 18:1-8.
Sólómọ́nì tọ́ka sí i pé: “Òun yóò sì to ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣánṣán; ó jẹ́ apata fún àwọn tí ń rìn nínú ìwà títọ́, nípa pípa àwọn ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́, yóò sì máa ṣọ́ ọ̀nà àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.” (Òwe 2:7-9) Èyí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Kì í ṣe kìkì pé Jèhófà ń fún àwọn tó bá fi tọkàntọkàn béèrè fún ọgbọ́n tòótọ́ nírú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ nìkan, àmọ́, ó tún máa ń jẹ́ asà tó lè dáàbò bo àwọn adúróṣánṣán nítorí pé wọ́n fi ọgbọ́n tòótọ́ hàn, wọ́n sì ń rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ǹjẹ́ ká lè wà lára àwọn tí Jèhófà ń ràn lọ́wọ́ láti lóye “gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.”
Ìgbà Tí “Ìmọ̀ [Bá] Dùn Mọ́ Ọkàn Rẹ”
Ìdákẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì—ohun pàtàkì láti lè ní ọgbọ́n—kì í rọ ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́rùn. Fún àpẹẹrẹ, Lawrence ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta sọ pé: “Iṣẹ́ ọwọ́ ni mò ń ṣe. Kíkẹ́kọ̀ọ́ nira fún mi.” Michael ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún, tí ìwé kíkà ni lára nígbà tó wà ní ilé ẹ̀kọ́, sọ pé: “Túláàsì ni mo fi máa ń jókòó kàwé.” Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe láti mú ẹ̀mí kíkẹ́kọ̀ọ́ dàgbà.
Ronú nípa ohun tí Michael ṣe. Ó wí pé: “Mo sọ ọ́ di kàráǹgídá láti rí i pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lójoojúmọ́. Kò pẹ́ púpọ̀, èmi náà ti rí ìyàtọ̀ rẹ̀ lórí ìwà mi, ìdáhùn mi nípàdé Kristẹni, àti ìjíròrò mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Wàyí o, ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ mi ti tó, n kì í fẹ́ kí ohunkóhun pa á lára.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìdákẹ́kọ̀ọ́ máa ń di ohun tó ń dùn mọ́ni nígbà tí a bá ń rí bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú. Lawrence pẹ̀lú tẹra mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó yá, ó di alàgbà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Láti lè sọ ìdákẹ́kọ̀ọ́ di ohun tí à ń gbádùn, ó ń béèrè pé ká túbọ̀ tẹra mọ́ ọn. Ṣùgbọ́n, àǹfààní rẹ̀ pọ̀ jọjọ. Sólómọ́nì sọ pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.”—Òwe 2:10, 11.
“Láti Dá Ọ Nídè Kúrò Ní Ọ̀nà Búburú”
Lọ́nà wo ni ọgbọ́n, ìmọ̀, agbára ìrònú, àti ìfòyemọ̀ yóò fi máa ṣọ́ni? Sólómọ́nì wí pé: “Láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun àyídáyidà, kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń fi àwọn ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán sílẹ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà òkùnkùn, kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń yọ̀ nínú ṣíṣe búburú, àwọn tí ń kún fún ìdùnnú nínú àwọn ohun àyídáyidà ìwà búburú; àwọn tí ipa ọ̀nà wọn jẹ́ wíwọ́, tí wọ́n sì ń ṣe békebèke ní gbogbo ipa ọ̀nà wọn.”—Òwe 2:12-15.
Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tó mọyì ọgbọ́n tòótọ́ máa ń yẹra fún kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tó bá ń lọ́wọ́ nínú “àwọn ohun àyídáyidà,” ìyẹn ni, àwọn ohun tó lòdì sí ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ. Agbára ìrònú àti ìfòyemọ̀ ń gbani lọ́wọ́ àwọn tó kọ òtítọ́ sílẹ̀, tó jẹ́ pé ọ̀nà òkùnkùn ni wọ́n ń rìn, ó sì tún ń gbani lọ́wọ́ àwọn aláyìídáyidà àtàwọn tí ń fi ìwà burúkú ṣayọ̀.—Òwe 3:32.
Ẹ wo báa ti ṣe lè kún fún ìmoore tó pé ọgbọ́n tòótọ́ àti àwọn ànímọ́ tó tan mọ́ ọn tún ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin oníṣekúṣe! Sólómọ́nì fi kún un pé àwọn ànímọ́ wọ̀nyí wà “láti dá ọ nídè kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin, kúrò lọ́wọ́ obìnrin ilẹ̀ òkèèrè tí ó ti mú kí àwọn àsọjáde rẹ̀ dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in, ẹni tí ń fi ọ̀rẹ́ àfinúhàn ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì ti gbàgbé májẹ̀mú Ọlọ́run rẹ̀. Nítorí inú ikú nísàlẹ̀ ni ilé rẹ̀ rì sí àti sí ìsàlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú ni àwọn òpó ọ̀nà rẹ̀. Kò sí ìkankan lára àwọn tí ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ tí yóò padà wá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò tún padà rí ipa ọ̀nà àwọn alààyè.”—Òwe 2:16-19.
“Àjèjì obìnrin,” ìyẹn ni aṣẹ́wó, la sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fi “ọ̀rẹ́ àfinúhàn ìgbà èwe rẹ̀” sílẹ̀—ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọkọ tó fẹ́ ẹ́ lọ́lọ́mọge.a (Fi wé Málákì 2:14.) Ó ti gbàgbé pé májẹ̀mú Òfin ka panṣágà léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:14) Ọ̀nà ikú lọ́nà rẹ̀. Àwọn tó bá sì ń bá a ṣe wọléwọ̀de kò ní “padà rí ipa ọ̀nà àwọn alààyè” láé, torí pé bó pẹ́ bó yá wọ́n lè kàndin nínú iyọ̀ nípa rírìn débi tí iwájú ò ti ní ṣeé lọ, tí ẹ̀yìn ò ti ní ṣeé padà sí, kí wọ́n sì tibẹ̀ ríkú he. Ọkùnrin tó lóye, tí agbára ìrònú rẹ̀ sì jí pépé yóò tètè fura, kò ní kó sínú àwọn ọ̀fìn ìṣekúṣe, yóò sì fọgbọ́n yẹra fún ríré sínú wọn.
‘Àwọn Adúróṣánṣán Ni Yóò Máa Gbé Ilẹ̀ Ayé’
Nígbà tó ń ṣàkópọ̀ ète ìmọ̀ràn rẹ̀ nípa ọgbọ́n, Sólómọ́nì wí pé: “Ète rẹ̀ ni pé kí ìwọ lè máa rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere, kí o sì lè pa ipa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.” (Òwe 2:20) Ète àgbàyanu mà ni ọgbọ́n wà fún o! Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé aláyọ̀, tó mú ìtẹ́lọ́rùn wá, ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́.
Tún ronú nípa àwọn ìbùkún ńláǹlà tó wà ní ìpamọ́ fún àwọn tó bá ń “rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere.” Sólómọ́nì ń bá a nìṣó pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” (Òwe 2:21, 22) Ǹjẹ́ kí o lè wà lára àwọn aláìlẹ́bi tí yóò máa gbé nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run títí láé.—2 Pétérù 3:13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà “àjèjì” la lò fún àwọn tí kò rìn ní ìbámu pẹ̀lú Òfin mọ́, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọra wọn dọ̀tá Jèhófà. Nítorí náà, aṣẹ́wó náà—tó lè máà jẹ́ àjèjì ní ti gidi—la pè ní “àjèjì obìnrin.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Sólómọ́nì gbàdúrà fún ọgbọ́n. Ó yẹ káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀