Jèhófà, ‘Odi Agbára Wa Ní Àkókò Wàhálà’
“Ọ̀dọ̀ Jèhófà sì ni ìgbàlà àwọn olódodo ti wá; òun ni odi agbára wọn ní àkókò wàhálà.”—SÁÀMÙ 37:39.
1, 2. (a) Àdúrà wo ni Jésù tìtorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà? (b) Kí ni ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀?
ALÁGBÁRA ńlá gbogbo ni Jèhófà. Ó lágbára láti dáàbò bo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nàkọnà tó bá wù ú. Ó tiẹ̀ lè kó àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn yòókù, kó sì kó wọn lọ síbi tó ní ààbò àti àlàáfíà. Àmọ́, nígbà tí Jésù ń tìtorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbàdúrà, ó sọ fún Baba rẹ̀ ọ̀run pé: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà.”—Jòhánù 17:15.
2 Jèhófà ò fẹ́ mú wa “kúrò ní ayé.” Dípò ìyẹn, ohun tó fẹ́ ni pé ká máa gbé láàárín àwọn èèyàn yòókù nínú ayé kí a lè kéde ọ̀rọ̀ ìrètí àti ọ̀rọ̀ ìtùnú rẹ̀ fún wọn. (Róòmù 10:13-15) Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù ní lọ́kàn nínú àdúrà rẹ̀ yẹn, gbígbé nínú ayé yìí lè mú ká bọ́ sọ́wọ́ “ẹni burúkú náà.” Àwọn aláìgbọràn èèyàn àtàwọn ẹ̀mí búburú ń fa ọ̀pọ̀ ìrora àti làásìgbò fáwọn èèyàn, àwọn wàhálà wọ̀nyẹn ò sì yọ àwọn Kristẹni sílẹ̀.—1 Pétérù 5:9.
3. Àwọn ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ wo ni àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Jèhófà ní láti dojú kọ́, síbẹ̀ ìtùnú wo lá rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
3 Kò sí béèyàn ò ṣe ní rẹ̀wẹ̀sì fúngbà díẹ̀ nínú irú àdánwò bẹ́ẹ̀. (Òwe 24:10) Onírúurú ìtàn ló kún inú Bíbélì nípa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n ní ìrora ọkàn. Onísáàmù sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo, ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.” (Sáàmù 34:19) Dájúdájú, àwọn ohun búburú máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn “olódodo” pàápàá. Bíi ti Dáfídì onísáàmù, ìgbà mìíràn wà tá a tiẹ̀ lè ‘kú tipiri, ká sì di ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó.’ (Sáàmù 38:8) Síbẹ̀, ìtùnú ńlá ló jẹ́ láti mọ̀ pé “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18; 94:19.
4, 5. (a) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé Òwe 18:10 sọ, kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dáàbò bò wá? (b) Kí làwọn ohun pàtó tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́?
4 Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Jésù, ó dájú pé Jèhófà ń fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wa. Òun ni “odi agbára [wa] ní àkókò wàhálà.” (Sáàmù 37:39) Ìwé Òwe náà lo gbólóhùn tó fara jọ èyí nígbà tó sọ pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” (Òwe 18:10) Ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ yìí fi òtítọ́ kan hàn kedere nípa àníyàn oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà ní fún àwọn tó dá. Ọlọ́run ń pèsè ààbò fún àwọn olódodo tó ń wá a tọkàntara, bí ẹni pé à ń sáré lọ sínú ilé gogoro kan tó lágbára ká lè rí ààbò.
5 Báwo la ṣe lè wá ààbò Jèhófà nígbà tá a bá kojú àwọn ìṣòro tó ń dorí ẹni kodò? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ohun mẹ́ta pàtàkì tá a lè ṣe ká bàa rí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Baba wa ọ̀run. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa darí wa. Ìkẹta, a gbọ́dọ̀ fara mọ́ ètò tí Jèhófà ṣe nípa bíbá àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tó lè ràn wá lọ́wọ́ lákòókò ìṣòro kẹ́gbẹ́.
Agbára Tí Àdúrà Ní
6. Ojú wo làwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń wo àdúrà?
6 Àwọn kan tó jẹ́ ògbógi nínú ìmọ̀ ìṣègùn dábàá pé téèyàn bá ní ìrora ọkàn àti ìdààmú ọkàn, kó ṣáà máa gbàdúrà. Lóòótọ́, àkókò tá a fi dákẹ́ jẹ́ẹ́ tá à ń gbàdúrà yẹn lè mára tù wá díẹ̀, ohun kan náà ló lè ṣẹlẹ̀ nígbà tá a bá gbọ́ ìró àwọn ìṣẹ̀dá kan, tàbí tẹ́nì kan bá rọra fọwọ́ ra wá lẹ́yìn. Ní ti tòótọ́, àwọn Kristẹni kì í fojú tín-ín-rín àdúrà nípa wíwò ó gẹ́gẹ́ bí oògùn amáratuni. Ńṣe la máa ń wò ó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tá a lè gbà bá Ẹlẹ́dàá sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àdúrà ní í ṣe pẹ̀lú ìfọkànsìn wa sí Ọlọ́run àti ìgbọ́kànlé tá a ní nínú rẹ̀. Láìsí àní-àní, àdúrà jẹ́ ara ìjọsìn wa.
7. Kí ni gbígbàdúrà pẹ̀lú ìdánilójú túmọ̀ sí, báwo sì ni irú àdúrà bẹ́ẹ̀ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro?
7 Àdúrà wa gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a gbà pẹ̀lú ìdánilójú, tàbí ìgbẹ́kẹ̀lé, nínú Jèhófà. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti alágbára ńlá gbogbo, máa ń fún àdúrà àtọkànwá táwọn olùjọsìn rẹ̀ ń gbà ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Mímọ̀ tá a bá tiẹ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ ń gbọ́ wa nígbà tá a bá sọ àwọn àníyàn àtàwọn ìṣòro wa fún un máa ń tù wá nínú.—Fílípì 4:6.
8. Kí nìdí táwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í tijú tàbí kí wọ́n máa ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà sí Jèhófà?
8 Kò yẹ káwọn Kristẹni olóòótọ́ máa tijú, tàbí kí wọ́n máa ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan, tàbí kí wọ́n máa ṣiyèméjì nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà sí Jèhófà. Ká sòótọ́, a lè máà fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà nígbà tá a bá já ara wa kulẹ̀ tàbí nígbà tá a bá ní ìṣòro tó pọ̀ jù agbára wá lọ. Nígbà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká rántí pé Jèhófà “ń fi ojú àánú hàn sí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́” àti pé “ó ń tu àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ nínú.” (Aísáyà 49:13; 2 Kọ́ríńtì 7:6) Àkókò làásìgbò àti wàhálà gan-an ló yẹ ká fi ìgbọ́kànlé yíjú sí Baba wa ọ̀run tó jẹ́ odi agbára wa.
9. Ipa wo ni ìgbàgbọ́ ń kó nínú àdúrà tí à ń gbà sí Ọlọ́run?
9 Tá a bá fẹ́ jàǹfààní kíkún látinú àǹfààní tá a ní láti gba àdúrà, a gbọ́dọ̀ ní ojúlówó ìgbàgbọ́. Bíbélì sọ pé “ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ìgbàgbọ́ kì í kàn ṣe kéèyàn gbà gbọ́ pé Ọlọ́run “ń bẹ.” Ojúlówó ìgbàgbọ́ ni pé kó dá èèyàn lójú hán-únhán-ún pé Ọlọ́run ní agbára láti san èrè fún wa nítorí ìgbésí ayé onígbọràn tá a gbé àti pé ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. “Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.” (1 Pétérù 3:12) Rírí tí a rí i pé Jèhófà ní àníyàn onífẹ̀ẹ́ fún wa ń jẹ́ kí àdúrà wa nítumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan.
10. Báwo ni àdúrà wa ṣe gbọ́dọ̀ rí tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbé wa ró nípa tẹ̀mí?
10 Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà wa nígbà tá a bá gbà á pẹ̀lú ọkàn pípé pérépéré. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Mo ti fi gbogbo ọkàn-àyà mi pè. Dá mi lóhùn, Jèhófà.” (Sáàmù 119:145) Àdúrà wa kì í ṣe èyí tí kò dénú, tá a kàn ń sọ lórí ahọ́n lásán, bí àdúrà àkọ́sórí táwọn èèyàn máa ń gbà nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ẹ̀sìn. Nígbà tá a bá fi ‘gbogbo ọkàn’ wa gbàdúrà sí Jèhófà, àwọn ọ̀rọ̀ wa á nítumọ̀ á sì fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Lẹ́yìn irú àdúrà àtọkànwá bẹ́ẹ̀, a ó bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìtura tó máa ń wá látinú jíju ‘ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.’ Bíbélì sì ṣèlérí pé “òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé [wa] ró.”—Sáàmù 55:22; 1 Pétérù 5:6, 7.
Ẹ̀mí Ọlọ́run Ni Olùrànlọ́wọ́ Wa
11. Kí ni ọ̀nà kan tí Jèhófà máa ń gbà dá wa lóhùn nígbà tá a bá ń “bá a nìṣó ní bíbéèrè” fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?
11 Jèhófà kì í kàn ṣe Olùgbọ́ àdúrà nìkan, àmọ́ òun tún ni Ẹni tó máa ń dáhùn àdúrà. (Sáàmù 65:2) Dáfídì kọ̀wé pé “Ṣe ni èmi yóò ké pè ọ́ ní ọjọ́ wàhálà mi, nítorí pé ìwọ yóò dá mi lóhùn.” (Sáàmù 86:7) Abájọ tí Jésù fi gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè” fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nítorí pé “Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:9-13) Bẹ́ẹ̀ ni o, agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́, tàbí olùtùnú, fún àwọn èèyàn rẹ̀.—Jòhánù 14:16.
12. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà táwọn ìṣòro bá dà bí ohun tó kọjá agbára wa?
12 Kódà nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò, ẹ̀mí Ọlọ́run lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó fara da ọ̀pọ̀ àwọn ipò tí kò bára dé, fi ìdánilójú sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Bákan náà, ọ̀pọ̀ Kristẹni lóde òní ló ti rí i pé àwọn túbọ̀ rí okun tẹ̀mí àti okun inú gbà gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ìṣòro tó ń fa ìrora ọkàn fúnni máa ń dà bí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ le mọ́ lẹ́yìn tá a bá ti rí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run gbà. Nítorí okun tí Ọlọ́run ń fúnni yìí, àwa náà lè sọ ohun tí àpọ́sítélì náà sọ pé: “A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n a kò há wa ré kọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣùgbọ́n kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde rárá; a ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; a gbé wa ṣánlẹ̀, ṣùgbọ́n a kò pa wá run.”—2 Kọ́ríńtì 4:8, 9.
13, 14. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ odi agbára wa nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọsílẹ̀? (b) Báwo ni ìlànà Bíbélì tó o ń fi sílò ṣe ń ràn ọ́ lọ́wọ́?
13 Ẹ̀mí mímọ́ tún mí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì pa á mọ́ fún àǹfààní wa. Báwo ni Jèhófà ṣe tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ odi agbára wa láwọn àkókò wàhálà? Ọ̀nà kan ni fífún tó fún wa ní ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú. (Òwe 3:21-24) Ẹ̀kọ́ Bíbélì ń jẹ́ ká lè ronú jinlẹ̀ ó sì ń jẹ́ kí agbára ìmọnúúrò wa sunwọ̀n sí i. (Róòmù 12:1) A lè “kọ́ agbára ìwòye [wa] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́” tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, tá a sì ń fi ohun tá à ń kọ́ níbẹ̀ sílò pẹ̀lú. (Hébérù 5:14) Ìwọ fúnra rẹ̀ ti lè rí ọ̀nà tí àwọn ìlànà Bíbélì ti gbà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nígbà tó o wà nínú ìṣòro. Bíbélì ń fún wa ní ìfọgbọ́nhùwà tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ojútùú tó dára sí àwọn ìṣòro tó ń fa ìrora ọkàn fún wa.— Òwe 1:4.
14 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún fún wa ní orísun mìíràn tá a ti lè gba okun, ìyẹn ni ìrètí pé a ó gbà wá là. (Róòmù 15:4) Bíbélì sọ fún wa pé àwọn ohun búburú kò ní máa wáyé títí láé. Ìpọ́njú èyíkéyìí tá a bá ní jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:16-18) A ní “ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́.” (Títù 1:2) Tá a bá ń yọ̀ nínú ìrètí yẹn, tá a sì ń rántí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tí Jèhófà ṣèlérí, a ó lè fara da ìpọ́njú.—Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 1:3.
Ìjọ Jẹ́ Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Gbà Ń Fi Ìfẹ́ Rẹ̀ Hàn
15. Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn?
15 Ohun mìíràn tí Jèhófà pèsè tó lè ràn wá lọ́wọ́ lákòókò wàhálà ni ìbákẹ́gbẹ́ tá à ń gbádùn nínú ìjọ Kristẹni. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún gbogbo ẹni tó wà nínú ìjọ níṣìírí pé kí wọ́n máa bọlá fún ara wọn, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn pẹ̀lú. (Róòmù 12:10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Níní irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa ronú nípa ohun tí àwọn ẹlòmíràn nílò dípò tí a ó fi máa ronú nípa àwọn àdánwò tiwa. Nígbà tá a bá lo ara wa fún àwọn ẹlòmíràn, kì í ṣe pé a ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nìkan ni, àmọ́ àwa fúnra wá tún ń rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó ń sọ ìṣòro wa di èyí tó ṣeé fara dà.—Ìṣe 20:35.
16. Báwo ni Kristẹni kọ̀ọ̀kan ṣe lè jẹ́ ẹni tí ń fúnni níṣìírí?
16 Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí lè kó ipa pàtàkì nínú fífún àwọn ẹlòmíràn lókun. Kí wọ́n lè ṣe èyí, wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ téèyàn sì máa ń rí bá sọ̀rọ̀. (2 Kọ́ríńtì 6:11-13) Ìjọ máa ń jàǹfààní gan-an nígbà tí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ bá ń wá àkókò láti yin àwọn ọ̀dọ́, láti gbé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ró, àti láti fún àwọn tó sorí kọ́ níṣìírí. (Róòmù 15:7) Ìfẹ́ ará yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe máa fura sí ara wa. Kò yẹ ká máa tètè sọ pé àìlera nípa tẹ̀mí ló fa ìṣòro tẹ́nì kan ní. Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú pé ká “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Bíbélì fi hàn pé àwọn Kristẹni tòótọ́ pàápàá máa ń bára wọn nínú wàhálà.—Ìṣe 14:15.
17. Àwọn àǹfààní wo la ní láti mú kí ìdè ẹgbẹ́ ara Kristẹni túbọ̀ lágbára sí i?
17 Àwọn ìpàdé Kristẹni tún jẹ́ ibi tá a ti láǹfààní títayọ láti tu ara wa nínú àti láti fún ara wa níṣìírí. (Hébérù 10:24, 25) Àjọṣepọ̀ onífẹ̀ẹ́ yìí kò mọ sí àwọn ìpàdé ìjọ nìkan o. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn Ọlọ́run tún máa ń wá àǹfààní láti ní ìbákẹ́gbẹ́ tó gbámúṣé láwọn àkókò mìíràn. Nígbà tí wàhálà bá dé, yóò rọrùn láti ran ara wa lọ́wọ́ nítorí pé ìdè ọ̀rẹ́ tó nípọn ti wà láàárín wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ó má . . . sí ìpínyà kankan nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara . . . lè ní aájò kan náà fún ara wọn. Bí ẹ̀yà ara kan bá sì ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà; tàbí bí a bá ṣe ẹ̀yà ara kan lógo, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a yọ̀.”—1 Kọ́ríńtì 12:25, 26.
18. Èrò wo ló yẹ ká yẹra fún nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn?
18 Nígbà míì, a lè rò pé ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tá a ní ti pọ̀ kọjá ohun tá a fi lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Ó yẹ ká dènà irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ká má bàa fi àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú táwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa lè fún wa àti ìrànlọ́wọ́ tá a lè rí gbà lọ́dọ̀ wọn du ara wa. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ni Ọlọ́run ń lò láti fi bójú tó wa. Tá a bá mọyì ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí, a ó rí ìtura ní àkókò wàhálà.
Ní Ẹ̀mí Nǹkan Yóò Dára
19, 20. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún èrò òdì?
19 A máa ń tètè ní èrò òdì nígbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìpọ́njú bá dé, àwọn kan máa ń ṣiyèméjì nípa ipò tí wọ́n wà nípa tẹ̀mí, wọ́n á máa ronú pé torí pé Ọlọ́run ti kọ àwọn sílẹ̀ làwọn ṣe níṣòro. Àmọ́ o, rántí pé Jèhófà kì í fi “àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi” dán ẹnikẹ́ni wò. (Jákọ́bù 1:13) Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe láti inú ọkàn-àyà òun fúnra rẹ̀ ni [Ọlọ́run] ti ṣẹ́ni níṣẹ̀ẹ́ tàbí ni ó ti kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ọmọ ènìyàn.” (Ìdárò 3:33) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni inú Jèhófà máa ń bà jẹ́ gan-an nígbà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ń jìyà.—Aísáyà 63:8, 9; Sekaráyà 2:8.
20 Jèhófà jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3) Ó bìkítà fún wa, yóò sì gbé wa ga nígbà tí àkókò bá tó lójú rẹ̀. (1 Pétérù 5:6, 7) Tá a bá ń rántí nígbà gbogbo pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí tó dára, kódà yóò máa múnú wa dùn pẹ̀lú. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé.” (Jákọ́bù 1:2) Kí nìdí? Ó dáhùn pé: “Nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè, èyí tí Jèhófà ṣèlérí fún àwọn tí ń bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—Jákọ́bù 1:12.
21. Láìfi àwọn ìṣòro tá a dojú kọ pè, ẹ̀rí ìdánilójú wo ni Ọlọ́run fún àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí i?
21 Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe kìlọ̀ fún wa pé nínú ayé, a óò máa ní ìpọ́njú. (Jòhánù 16:33) Àmọ́ Bíbélì ṣèlérí pé kò sí “ìpọ́njú . . . tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ebi tàbí ìhòòhò tàbí ewu” tó lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Jèhófà àti ìfẹ́ Ọmọ rẹ̀. (Róòmù 8:35, 39) Ẹ ò rí i bó ṣe tù wá nínú tó pé wàhálà èyíkéyìí tó bá bá wa jẹ́ fúngbà díẹ̀! Ní báyìí ná, bá a ṣe ń dúró de ìgbà tí ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá ènìyàn máa dópin, Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́ ń fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wa. Tá a bá sa lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún ààbò, yóò jẹ́ “ibi gíga ààbò fún ẹni tí a ni lára, ibi gíga ààbò ní àwọn àkókò wàhálà.”—Sáàmù 9:9.
Ẹ̀kọ́ Wo La Rí Kọ́?
• Kí ló yẹ káwọn Kristẹni máa retí bí wọ́n ṣe ń gbé nínú ayé búburú yìí?
• Báwo ni àdúrà àtọkànwá tá à ń gbà ṣe lè fún wa lókun nígbà tí àdánwò bá dé?
• Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe jẹ́ olùrànlọ́wọ́?
• Kí la lè ṣe láti ran ara wa lọ́wọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
A gbọ́dọ̀ máa wá Jèhófà bí ìgbà táa bá ń sáré lọ sínú ilé gogoro kan tó lágbára
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí máa ń lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti yin àwọn ẹlòmíràn àti láti fún wọn níṣìírí