Ṣé Òótọ́ ni?
Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro
Ohun tó sábà máa ń jẹ́ káwọn kan kórìíra àwọn míì ni ohun tí kì í ṣòótọ́ tí wọ́n gbọ́ nípa wọn. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí:
Àwọn agbanisíṣẹ́ kan gbà pé àwọn obìnrin ò lè ṣiṣẹ́ tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì, iṣẹ́ agbára tàbí iṣẹ́ tó gba àròjinlẹ̀.
Nígbà àtijọ́ nílẹ̀ Yúróòpù, wọ́n fẹ̀sùn èké kan àwọn Júù pé wọ́n ń da májèlé sínú àwọn kànga, wọ́n sì ń mú kí àrùn tàn káàkiri. Bákan náà, nígbà ìjọba Násì, wọ́n tún fẹ̀sùn èké kan àwọn Júù. Lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n sọ pé àwọn ló jẹ́ kí ètò ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Jámánì. Láwọn ìgbà méjèèjì yìí, ìyà ńlá ni wọ́n fi jẹ́ àwọn Júù. Kódà, àwọn kan ṣì ń fojú burúkú wò wọ́n títí dòní.
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé gbogbo àwọn aláàbọ̀ ara ni kì í láyọ̀, ọkàn wọn sì máa ń bà jẹ́.
Àwọn ẹlẹ́tanú tó gba irú ọ̀rọ̀ yìí gbọ́ máa ń tọ́ka sí àwọn àpẹẹrẹ tàbí ẹ̀rí tó jọ pé ó bá èrò wọn mu. Wọ́n sì gbà pé aláìmọ̀kan lẹ́ni tó bá ta ko èrò wọn.
Ìlànà Bíbélì
“Kò dára kí èèyàn wà láìní ìmọ̀.”—ÒWE 19:2.
Kí la rí kọ́? Téèyàn ò bá mọ òótọ́ ọ̀rọ̀, ìpinnu tí kò dáa lèèyàn máa ṣe. Téèyàn bá fòótọ́ sílẹ̀ tó wá gba ìtàn àròsọ gbọ́, ńṣe lá kàn máa fojú burúkú wo àwọn èèyàn.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Mọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀
Tá a bá mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa àwọn èèyàn, a ò ní tètè máa gba ọ̀rọ̀ tí kò dáa táwọn èèyàn ń sọ nípa wọn gbọ́. Nígbà tá a bá sì ti mọ pé wọn ò sọ òótọ́ nípa àwọn èèyàn kan fún wa, a máa fẹ́ mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa wọn.
Ohun To O Lè Ṣe
Tí wọ́n bá sọ pé ẹ̀yà kan burú, rántí pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó wá látinú ẹ̀yà náà ló burú.
Rántí pé o ò lè mọ gbogbo nǹkan nípa àwọn èèyàn.
Sapá láti gbọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu ẹni tó ṣeé fọkàn tán.