“Ìjìnlẹ̀ Òye Tí Ènìyàn Ní Máa Ń Dẹwọ́ Ìbínú Rẹ̀”
Níléèwé gíga kan, wọ́n lé Kóòṣì tó ń kọ́ àwọn ọmọ iléèwé ní bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá nítorí pé ó máa ń bínú lódìlódì.
Ọmọ kékeré kan ń ṣe ìjàngbọ̀n torí wọn ò fún un ní ohun tó fẹ́.
Ìyá kan jágbe mọ́ ọmọ rẹ̀ torí kò tún ilé ṣe.
A sábà máa ń rí àwọn èèyàn tó fara ya tí inú bá ń bí wọn, ó tiẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí àwa náà nígbà míì. Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tí kò bínú rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa la mọ̀ pé ìbínú ò dáa, síbẹ̀, tó bá jọ pé ẹnì kan hùwà àìdáa sí wa tá a sì bínú sí i, ńṣe la máa ń rò pé a wà lórí ẹ̀tọ́ wa. Ẹgbẹ́ Afìṣemọ̀rònú ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà tiẹ̀ sọ pé: “Ìbínú jẹ́ ara ìmọ̀lára gbogbo èèyàn, torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé èèyàn bínú, torí ìwà ẹ̀dá ni.”
Ó lè jọ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí tá a bá wò ó sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lábẹ́ ìmísí. Òun náà gbà pé àwọn ipò kan lè sún wa kan ògiri, ó wá sọ pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” (Éfésù 4:26) Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé ká fara ya tí inú bá bí wa àbí ká wá bá a ṣe máa ṣẹ́pá ìbínú náà?
ṢÉ Ó YẸ KÓ O MÁA BÍNÚ?
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ yẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí onísáàmù kan sọ ló rántí, onísáàmù yẹn sọ pé: “Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀.” (Sáàmù 4:4) Kí ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ fà yọ gan-an? Ó ń bá àlàyé rẹ̀ lọ pé: “Ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfésù 4:31) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ lérò, kódà, ńṣe ló tiẹ̀ ń gbà wá níyànjú pé ká máa ṣe sùúrù tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá. Ibi tí Ẹgbẹ́ Afìṣemọ̀rònú ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà parí ọ̀rọ̀ wọn sí náà fara jọ bẹ́ẹ̀, wọ́n ní: “Ìwádìí ti fi hàn pé téèyàn bá gbaná jẹ nítorí ìbínú, ńṣe lara á túbọ̀ máa kán sí i, èyí ò sì ní yanjú . . . ohun tó wà nílẹ̀.”
Kí la wá lè ṣe láti dẹ́kun ìbínú àti gbogbo ìwà búburú tó so mọ́ ọn? Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì àtijọ́ fún wa ní ìdáhùn, ó ní: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Báwo ni “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní” ṣe lè dẹwọ́ ìbínú rẹ̀?
BÍ ÌJÌNLẸ̀ ÒYE ṢE Ń DẸWỌ́ ÌBÍNÚ
Ohun tí ìjìnlẹ̀ òye túmọ̀ sí ni pé kéèyàn ríran kọjá igi imú, kó fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀. Ìyẹn tún gba pé kéèyàn má kàn máa mú ọ̀rọ̀ lóréfèé. Báwo wá ni ìjìnlẹ̀ òye ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní fara ya nígbà tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá?
Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó máa rí ìwà àìdáa tí inú ò ní bí i. Àmọ́ tá a bá fi tìyẹn ṣe, tá a wá gbaná jẹ, á lè kàbùkù ká sì ṣe ara wa tàbí ẹlòmíì pàápàá léṣe. Bí ilé bá ń jó téèyàn ò sì bomi pa á, ilé náà lè jó kanlẹ̀, bákan náà, bí inú bá ń bí wa tá ò sì bomi sùúrù mu, a lè tẹ́ lójú àwọn èèyàn tàbí káwọn èèyàn máa sá fún wa, ìyẹn sì lè mú ká ṣẹ Ọlọ́run. Torí náà, bí nǹkan bá bí wa nínú, á dáa ká kọ́kọ́ fara balẹ̀ yiiri ọ̀rọ̀ náà wò ká tó ṣe ohunkóhun. Ó dájú pé tá a bá lóye ọ̀rọ̀ náà dáadáa, a ò ní kù gìrì ṣe ohun tó lè mú ká kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn.
Díẹ̀ ló kù kí Dáfídì Ọba tó jẹ́ bàbá Sólómọ́nì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nígbà tí inú bí i sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nábálì. Ọpẹ́lọpẹ́ pé ó rẹ́ni ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún un, tó sì pe orí rẹ̀ wálé. Ó ṣẹlẹ̀ pé Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dáàbò bò àwọn àgùntàn Nábálì nínú aginjù Jùdíà. Nígbà tí Nábálì bẹ̀rẹ̀ sí i rẹ́ irun àwọn àgùntàn náà, Dáfídì béèrè pé kó fún òun ní oúnjẹ díẹ̀. Ni Nábálì bá sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, ó ní: “Mo ha sì ní láti mú oúnjẹ mi àti omi mi àti ẹran mi tí mo pa, tí mo ti kun fún àwọn olùrẹ́run mi, kí n sì fi í fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò tilẹ̀ mọ ibi tí wọ́n ti wá?” Bí Dáfídì ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, orí ẹ̀ gbóná, òun àti irínwó [400] nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí dìde láti lọ pa gbogbo ìdílé Nábálì run.—1 Sámúẹ́lì 25:4-13.
Bí Ábígẹ́lì ìyàwó Nábálì ṣe gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, kíá ló gbéra lọ sọ́dọ̀ Dáfídì. Nígbà tó pàdé Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Dáfídì, ó sì sọ pé: “Jẹ́ kí ẹrúbìnrin rẹ sọ̀rọ̀ ní etí rẹ, sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹrúbìnrin rẹ.” Lẹ́yìn ìyẹn, obìnrin náà ṣàlàyé irú ẹni tí Nábálì jẹ́ àti bó ṣe máa ń hùwà òpònú, ó sì jẹ́ kó yé Dáfídì pé tó bá gbẹ̀san lára Nábálì tó sì pa ìdílé rẹ̀ run, àbámọ̀ lọ̀rọ̀ náà máa yọrí sí.—1 Sámúẹ́lì 25:24-31.
Òye wo ni Dáfídì rí nínú ọ̀rọ̀ tí Ábígẹ́lì bá a sọ tó mú kí ara rẹ̀ wálẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, ó rí i pé bí Nábálì ṣe máa ń hùwà òpònú nìyẹn, àti pé òun máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tóun bá gbẹ̀san lára rẹ̀. Lónìí, tí ẹnì kan bá múnú bí ẹ, kí ló yẹ kó o ṣe? Àpilẹ̀kọ kan látọwọ́ Mayo Clinic sọ bí èèyàn ṣe lè ṣàkóso ìbínú rẹ̀, ó ní: “Kọ́kọ́ mí kanlẹ̀, kó o sì ka oókan sí ẹẹ́wàá.” Kó o tó kà á délẹ̀, inú rẹ tó ń ru á ti rọlẹ̀, èyí á jẹ́ kó o lè fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó fa ìbínú náà, wàá sì mọ ibi tí ìbínú náà lè já sí. Ó dájú pé tó o bá lo ìjìnlẹ̀ òye lọ́nà yìí, wàá lè dẹwọ́ ìbínú rẹ, ọ̀rọ̀ náà á sì tán lọ́kàn rẹ pátápátá.—1 Sámúẹ́lì 25:32-35.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni Bíbélì ti ràn lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìbínú wọn. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sebastian tó jẹ́ onínúfùfù nígbà tó wà lẹ́wọ̀n nílùú Poland lọ́mọ ọdún mẹ́tàlélógún [23]. Ó sọ bí Bíbélì ṣe ran òun lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá inú fùfù rẹ̀, ó ní: “Lákọ̀ọ́kọ́, màá ronú nípa ìṣòro náà, màá wá sapá láti fi ìlànà Bíbélì sílò. Mo wá rí i pé kò sí ìwé mí ì tó lè tọ́ni sọ́nà bíi Bíbélì.”
Ohun tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Setsuo náà ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo máa ń pariwo mọ́ àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tí ara bá kan mí. Àmọ́, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa ronú jinlẹ̀, dípò kí n máa kanra, mo máa ń bí ara mi pé: ‘Ta ló jẹ̀bi gan-an? Ṣé kì í ṣe àìfara balẹ̀ mi ló ń dà mí láàmú?’” Ríronú lórí àwọn ìbéèrè yìí ti mú kó lè ṣàkóso ìbínú rẹ̀.
Ká sòótọ́, kì í rọrùn láti pa ìbínú mọ́ra, síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso rẹ̀. Tá a bá ń fi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò, tá a sì ń gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó dájú pé òye tó jinlẹ̀ máa dẹwọ́ ìbínú wa, àá sì lè ṣẹ́pá rẹ̀ pátápátá.