KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ
2 Kíyè Sí Ohun Tó Ń Lọ Láyìíká Rẹ
O pinnu pé wàá máa jẹun gidi síkùn, ṣùgbọ́n àwọn oúnjẹ pàrùpárù ṣì kún inú ilé rẹ.
O pinnu pé o ò ní fa sìgá mọ́, síbẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣì tún ń fi sìgá lọ̀ ẹ́.
O ti pinnu pé wàá ṣe eré ìmárale lónìí, àmọ́ ojú ń ro ẹ́ láti ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá aṣọ tó o máa wọ̀!
Ǹjẹ́ o rí ohun tó jọra nínú àwọn àpẹẹrẹ yìí? Ẹ̀rí ti fi hàn pé ohun tó wà ní àyíká wa àti àwọn tá à ń bá rìn ló máa ń pinnu bóyá a máa lè ní àṣà tó dáa, ká sì jáwọ́ nínú èyí tí kò dáa.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ronú nípa àwọn ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè yẹra fún àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ àfojúsùn wa, àá sì lè máa ṣe ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́. (2 Tímótì 2:22) Ní kúkúrú, ọlọ́gbọ́n ni wá tá a bá ń kíyè sí ohun tó n lọ láyìíká wa.
Yẹra fún nǹkan tó máa jẹ́ kó o ṣe ohun tí kò dáa, mú kí ṣíṣe ohun tó tọ́ rọrùn fún ẹ
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Yẹra fún àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o ṣe ohun tí kò dáa. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, rí i dájú pé o kò tọ́jú oúnjẹ pàrùpárù sílé. Ìyẹn ló máa jẹ́ kó o lè yẹra fún irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ tó bá wù ẹ́ láti jẹ ẹ́.
Mú kí ṣíṣe ohun tó tọ́ rọrùn fún ẹ. Ká sọ pé o ti pinnu pé o máa ṣe eré ìmárale tílẹ̀ bá mọ́, ńṣe ni kó o kó àwọn aṣọ tó o máa lò sítòsí kó o tó lọ sùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa mú kó rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe láì lọ́ra.
Fara balẹ̀ yan àwọn tó o máa bá rìn. Kì í pẹ́ tá a fi máa ń mú ìwà àwọn ọ̀rẹ́ wa. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Torí náà, dín wọléwọ̀de rẹ kù pẹ̀lú àwọn tó máa mú kó o ṣì tún máa hùwà tí o kò fẹ́, kó o sì yan àwọn tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́rẹ̀ẹ́.