Yọ̀ǹda Ara Rẹ Tinútinú, Kí Ìyìn Lè Jẹ́ ti Jèhófà!
“Nítorí tí àwọn ènìyàn náà fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà!”—ONÍD. 5:2.
1, 2. (a) Kí ni Élífásì àti Bílídádì sọ nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìjọsìn wa? (b) Kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa ojú tóun fi ń wo ìjọsìn wa?
ÉLÍFÁSÌ béèrè pé: “Abarapá ọkùnrin ha lè wúlò fún Ọlọ́run, pé ẹni tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò wúlò fún un? Olódùmarè ha ní inú dídùn rárá sí jíjẹ́ tí o jẹ́ olódodo, tàbí èrè èyíkéyìí nínú ṣíṣe tí o ṣe ọ̀nà rẹ ní aláìlẹ́bi?” (Jóòbù 22:1-3) Ǹjẹ́ irú àwọn ìbéèrè yìí ti wá sí ẹ lọ́kàn rí? Nígbà tí Élífásì ará Témánì bi Jóòbù láwọn ìbéèrè yẹn, Élífásì gbà pé bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn wọn. Kódà, ẹnì kejì rẹ̀ tó ń jẹ́ Bílídádì ọmọ Ṣúáhì sọ pé kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run.—Ka Jóòbù 25:4.
2 Àwọn olùtùnú èké yẹn sọ pé bí àwa èèyàn ṣe ń fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà kò nítumọ̀ sí i, àti pé lójú Ọlọ́run, a ò sàn ju òólá, ìdin tàbí kòkòrò mùkúlú. (Jóòbù 4:19; 25:6) Téèyàn bá kọ́kọ́ wò ó, ó máa dà bíi pé onírẹ̀lẹ̀ ẹ̀dá ni Élífásì àti Bílídádì. (Jóòbù 22:29) Ó ṣe tán, tẹ́nì kan bá wà lórí òkè téńté tàbí tó ń wolẹ̀ látinú ọkọ̀ òfuurufú, bóyá ló máa rí ohun táwọn èèyàn ń ṣe nílẹ̀. Àmọ́, ṣé bí gbogbo akitiyan wa nínú ìjọsìn Jèhófà ṣe rí nìyẹn bó ṣe ń wo ilẹ̀ ayé látorí ìtẹ́ rẹ̀ lọ́run? Jèhófà jẹ́ ká mọ ojú tóun fi ń wò wá nígbà tó bá Élífásì, Bílídádì àti Sófárì wí. Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé wọn ò sòótọ́ nípa òun, ó sì gbóríyìn fún Jóòbù, kódà ó pè é ní “ìránṣẹ́ mi.” (Jóòbù 42:7, 8) Èyí fi hàn pé àwa èèyàn “wúlò fún Ọlọ́run.”
‘KÍ NI ÌWỌ FÚN UN?’
3. Kí ni Élíhù sọ nípa ìjọsìn wa sí Jèhófà, kí ló sì ní lọ́kàn?
3 Jèhófà kò bá Élíhù wí nígbà tó sọ pé: ‘Bí o bá jàre ní tòótọ́, kí ni ìwọ fún Ọlọ́run, tàbí kí ni ó rí gbà láti ọwọ́ rẹ?’ (Jóòbù 35:7) Ṣé ohun tí Élíhù ń sọ ni pé ìjọsìn wa kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run? Rárá o. Ohun tó ń sọ ni pé yálà a sin Ọlọ́run tàbí a ò sìn ín, kò ní kí Jèhófà má jẹ́ Ọba Aláṣẹ. Jèhófà ò ṣaláìní ohunkóhun, torí náà, a ò lè fi kún iyì tàbí agbára rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun yòówù ká ní, ì báà jẹ́ ìwà rere, ẹ̀bùn àbínibí tàbí okun, Jèhófà ló fún wa, ó sì ń kíyè sí bá a ṣe ń lò ó.
4. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ohun rere tá à ń ṣe fáwọn míì?
4 Jèhófà máa ń kíyè sí ohun rere tá a bá ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì gbà pé òun la ṣe é fún. Òwe 19:17 sọ pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” Ṣé ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni pé Jèhófà ń kíyè sí gbogbo ohun rere tá à ń ṣe fáwọn ẹni rírẹlẹ̀? Ṣé a lè sọ pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé gbà pé òun jẹ èèyàn lásánlàsàn ní gbèsè torí pé onítọ̀hún ṣe rere, táá sì pọn dandan pé kóun san án lẹ́san? Bẹ́ẹ̀ ni, kódà Jésù Ọmọ Ọlọ́run náà jẹ́rìí sí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.—Ka Lúùkù 14:13, 14.
5. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò báyìí?
5 Ìgbà kan wà tí Jèhófà ní kí wòlíì Aísáyà ṣojú fún òun. Ìyẹn fi hàn pé ó dùn mọ́ Jèhófà nínú láti lo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Aísá. 6:8-10) Tayọ̀tayọ̀ ni Aísáyà fi gbà láti ṣe iṣẹ́ náà. Lọ́jọ́ tiwa yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ń sọ bíi ti wòlíì náà pé “Èmi nìyí! Rán mi!” tí wọ́n sì ń gbé ohun ribiribi ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Síbẹ̀, ẹnì kan lè ronú pé: ‘Kí lohun tí mò ń ṣe já mọ́? Mo dúpẹ́ pé Jèhófà fún mi láǹfààní pé kí n bá òun ṣiṣẹ́, àmọ́ ṣé iṣẹ́ Jèhófà kò ní di ṣíṣe yálà mo lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà àbí mi ò ṣe bẹ́ẹ̀?’ Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Dèbórà àti Bárákì ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Ẹ̀RÙ BÀ WỌ́N, ÀMỌ́ ỌLỌ́RUN FÚN WỌN LÓKUN
6. Kí ló jẹ́ kó dà bíi pé wẹ́rẹ́ làwọn ọmọ ogun Jábínì máa ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
6 Fún ogún [20] ọdún ni Jábínì tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Kénáánì fi “ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára lọ́nà lílekoko.” Ìnira náà le débi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé lábúlé kò láyà láti jáde nílé. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní nǹkan ìjà tí wọ́n lè fi gbéjà ko àwọn ọ̀tá wọn, wọn ò sì léyìí tí wọ́n á fi dáàbò bo ara wọn tógun bá dé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun onídòjé irin làwọn ọ̀tá wọn ní.—Oníd. 4:1-3, 13; 5:6-8.a
7, 8. (a) Kí ni Jèhófà sọ pé kí Bárákì ṣe? (b) Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Jábínì? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
7 Síbẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fún Bárákì nípasẹ̀ wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Dèbórà pé: “Lọ, kí o sì tan ara rẹ ká orí Òkè Ńlá Tábórì, kí o sì mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin láti inú àwọn ọmọ Náfútálì àti láti inú àwọn ọmọ Sébúlúnì pẹ̀lú rẹ. Dájúdájú, èmi yóò sì fa Sísérà olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jábínì àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ wá bá ọ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì, èmi yóò sì fi í lé ọ lọ́wọ́.”—Oníd. 4:4-7.
8 Kíá, àwọn èèyàn ti gbọ́, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún ogun náà sì kóra jọ sí Òkè Ńlá Tábórì. Bárákì ò fi nǹkan falẹ̀ rárá láti ṣe ohun tí Jèhófà sọ pé kó ṣe. (Ka Àwọn Onídàájọ́ 4:14-16.) Bí wọ́n ṣe ń jagun ní Táánákì, ọ̀wààrà òjò ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, gbogbo ilẹ̀ sì di ẹrẹ̀. Làwọn ọmọ ogun Sísérà bá fẹsẹ̀ fẹ, Bárákì sì lé wọn títí wọ́n fi dé Háróṣétì, tó wà ní nǹkan bíi máìlì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (24 km) sí Táánákì. Nígbà tí Sísérà débì kan, ó sọ̀kalẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Kẹ̀kẹ́ ogun tó ń bani lẹ́rù wá dèyí tí kò wúlò mọ́. Sísérà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sáré títí ó fi dé Sáánánímù, tó ṣeé ṣe kó wà nítòsí Kédéṣì. Ó sá wọnú àgọ́ Jáẹ́lì aya Hébà tó jẹ́ ará Kénì, kó lè forí pa mọ́, Jáẹ́lì sì gbà á sílé. Ó ti rẹ Sísérà tẹnutẹnu, torí náà kò pẹ́ tó sùn lọ fọnfọn. Ni Jáẹ́lì bá ṣọkàn akin, ó sì pa ọkùnrin náà. (Oníd. 4:17-21) Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rẹ́yìn ọ̀tá wọn nìyẹn!b
ÀWỌN TÍ KÒ ṢE TÁN LÁTI YỌ̀ǸDA ARA WỌN
9. Kí ni Àwọn Onídàájọ́ 5:20, 21 sọ nípa ogun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá Sísérà jà?
9 Téèyàn bá máa lóye ìtàn tó wà nínú Àwọn Onídàájọ́ orí 4 dáadáa, ó gbọ́dọ̀ ka orí 5 náà. Bí àpẹẹrẹ, Àwọn Onídàájọ́ 5:20, 21 sọ pé: “Àwọn ìràwọ̀ jà láti ọ̀run, láti àwọn ipa ọ̀nà ìyípo wọn ni wọ́n ti bá Sísérà jà. Ọ̀gbàrá Kíṣónì gbá wọn lọ.” Ṣé ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ ni pé àwọn áńgẹ́lì ló ran Bárákì lọ́wọ́, àbí ńṣe làwọn nǹkan kan jábọ́ látọ̀run? Ìtàn náà kò ṣàlàyé. Àmọ́, rò ó wò ná, bí kì í bá ṣe ọwọ́ Ọlọ́run, kí lo rò pé ó mú kí ọ̀wààrà òjò rọ̀ nígbà tó rọ̀ yẹn àti níbi tó ti rọ̀ yẹn, tó sì mú kó nira fáwọn kẹ̀kẹ́ ogun ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] láti rìn? Kódà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìwé Àwọn Onídàájọ́ 4:14, 15, sọ pé Jèhófà ló ṣẹ́gun fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, kò sí èyíkéyìí lára àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ọmọ Ísírẹ́lì tó yọ̀ǹda ara wọn tó lè fọ́nnu pé ọpẹ́lọpẹ́ òun làwọn fi ṣẹ́gun.
10, 11. Kí ló ṣeé ṣe kí “Mérósì” jẹ́, kí sì nìdí tí wọ́n fi gégùn-ún fún un?
10 Àmọ́ ohun kan yani lẹ́nu nínú orin ìṣẹ́gun tí Dèbórà àti Bárákì kọ láti yin Jèhófà bó ṣe ṣẹ́gun fún wọn, wọ́n sọ pé: “ ‘Ẹ gégùn-ún fún Mérósì,’ ni áńgẹ́lì Jèhófà wí, ‘ẹ gégùn-ún fún àwọn olùgbé rẹ̀ láìdábọ̀, nítorí tí wọn kò wá sí ìrànwọ́ Jèhófà, sí ìrànwọ́ Jèhófà pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá.’ ”—Oníd. 5:23.
11 Kí ni Mérósì jẹ́ gan-an? A ò lè sọ. Àmọ́ ègún tí wọ́n gé fún un ṣẹ sí i lára débi pé ó ṣòro láti mọ ohun tó jẹ́ gan-an. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìlú kan táwọn èèyàn rẹ̀ kọ̀ láti yọ̀ǹda ara wọn nígbà tí wọ́n kéde pé káwọn èèyàn jáde wá jagun. Ṣé wọn ò gbọ́ pé Jèhófà nílò àwọn tó máa yọ̀ǹda ara wọn fún ogun ni? Tó sì jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ló yọ̀ǹda ara wọn láti àgbègbè tó yí wọn ká. Ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí Sísérà gbà nígbà tó ń sá lọ. Ṣé àwọn ará ìlú náà rí i àmọ́ tí wọ́n kọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ? Ṣé wọ́n ń wo Sísérà bó ṣe ń sáré lọ lójú pópó wọn, lóun nìkan tó sì ń mí hẹlẹhẹlẹ? Àǹfààní lèyí ò bá jẹ́ fún wọn láti gbèjà àwọn èèyàn Jèhófà, kí wọ́n sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n láǹfààní láti ṣe ohun kan fún Jèhófà, wọ́n kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ gbáà ló wà láàárín àwọn ará ìlú yẹn àti Jáẹ́lì tó fìgboyà gbé ìgbésẹ̀ bá a ṣe rí i nínú àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e!—Oníd. 5:24-27.
12. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn èèyàn tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú Àwọn Onídàájọ́ 5:9, 10, kí ló yẹ kó mú káwa náà ṣe?
12 Nínú Àwọn Onídàájọ́ 5:9, 10, a tún rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sójú ogun pẹ̀lú Bárákì àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Dèbórà àti Bárákì gbóríyìn fún “àwọn ọ̀gágun Ísírẹ́lì, tí wọ́n fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láàárín àwọn ènìyàn náà.” Wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn “olùgun abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláwọ̀ pupa àdàpọ̀-mọ́-yẹ́lò,” tí ìgbéraga ò jẹ́ kí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn! Àwọn yìí náà ni Bíbélì sọ pé wọ́n “jókòó sórí àwọn kápẹ́ẹ̀tì tí ó gbówó lórí,” tí wọ́n ń jayé orí wọn. Bí wọ́n á ṣe gbádùn ara wọn ló jẹ wọ́n lọ́kàn. Wọn ò dà bí àwọn “tí ń rìn lójú ọ̀nà,” ìyẹn àwọn tó lọ jagun pẹ̀lú Bárákì ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Tábórì àti ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì. Wọ́n wá rọ àwọn tí ò mọ̀ ju ìgbádùn lọ pé kí wọ́n “gbà á rò!” Ọ̀rọ̀ yẹn gbàrònú lóòótọ́, wọ́n láǹfààní láti ti iṣẹ́ Jèhófà lẹ́yìn, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, ó yẹ kẹ́ni tó bá ń lọ́ tìkọ̀ láti yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ Ọlọ́run ronú dáadáa nípa ọ̀rọ̀ yìí.
13. Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú ohun táwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Dánì àti Áṣérì ṣe àti ohun táwọn ẹ̀yà Sébúlúnì àti Náfútálì ṣe?
13 Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fojú ara wọn rí bí Jèhófà ṣe fi ara rẹ̀ hàn ní ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Mánigbàgbé lohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ fún wọn, wọ́n á sì máa “ròyìn àwọn ìṣe òdodo Jèhófà lẹ́sẹẹsẹ” fáwọn míì. (Oníd. 5:11) Àmọ́ nínú Àwọn Onídàájọ́ 5:15-17, a rí i pé ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Dánì àti Áṣérì jẹ́ kí àwọn nǹkan tara gbà wọ́n lọ́kàn jù. Àwọn agbo ẹran wọn, àwọn ọkọ̀ òkun àti ibi tí ọkọ̀ òkun máa ń gúnlẹ̀ sí ní etíkun ni wọ́n gbájú mọ́ dípò iṣẹ́ Jèhófà tó ń lọ lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ohun tí ẹ̀yà Sébúlúnì àti Náfútálì ṣe yàtọ̀ pátápátá síyẹn, ṣe ni wọ́n fẹ̀mí ara wọn wewu “títí dé ojú ikú” kí wọ́n lè ti Dèbórà àti Bárákì lẹ́yìn. (Oníd. 5:18) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wà tá a lè rí kọ́ látinú ohun táwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Dánì àti Áṣérì ṣe àti ohun táwọn ẹ̀yà Sébúlúnì àti Náfútálì ṣe.
“Ẹ FI ÌBÙKÚN FÚN JÈHÓFÀ!”
14. Báwo la ṣe ń fi hàn pé à ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ Ọlọ́run lónìí?
14 Lónìí, a kò pè wá fún ogun èyíkéyìí, àmọ́ a láǹfààní láti fi ìgboyà tá a ní hàn bá a ṣe ń fìtara wàásù. Ìgbà tiwa yìí gan-an ni ètò Jèhófà túbọ̀ nílò àwọn tó lè yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Àìmọye ló sì ń yọ̀ǹda ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbàágbèje àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì làwọn kan, àwọn míì yọ̀ǹda láti máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, nígbà táwọn míì sì ń yọ̀ǹda ara wọn láwọn àpéjọ àyíká àti ti àgbègbè. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà kan tún ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn, àwọn míì sì wà lára àwọn tó ń ṣètò àpéjọ àgbègbè. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni tó o ní, kò sì ní gbàgbé rẹ̀ láé.—Héb. 6:10.
15. Báwo la ṣe máa mọ̀ bóyá a ṣì ń fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ Jèhófà?
15 Ó yẹ kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé mo máa ń dọ́gbọ́n yẹṣẹ́ sílẹ̀ nínú ìjọ? Ṣé bí màá ṣe kó nǹkan jọ ló gbà mí lọ́kàn àbí bí màá ṣe yọ̀ǹda ara mi fún iṣẹ́ Ọlọ́run? Bíi ti Bárákì, Dèbórà, Jáẹ́lì àtàwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tó yọ̀ǹda ara wọn, ṣé èmi náà ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà táá jẹ́ kí n ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà? Bí mo bá ń ronú láti ṣí lọ sílùú tàbí orílẹ̀-èdè míì kí n lè rí tajé ṣe, ṣé mo ti ro ọ̀rọ̀ náà tàdúràtàdúrà? Ṣé mo ti ronú ìpalára tó máa ṣe fún ìdílé mi àti ìjọ?’c
16. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tí Jèhófà kò ní, síbẹ̀ kí la lè fún un?
16 Jèhófà pọ́n àwa èèyàn lé ní ti pé ó fún wa láǹfààní láti kọ́wọ́ ti ìṣàkóso rẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀, torí náà tó o bá fara rẹ sábẹ́ àkóso Jèhófà, ṣe lò ń jẹ́ kí Sátánì mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà lo wà. Ìgbàgbọ́ tó o ní àti bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin ló mú kó o yọ̀ǹda ara rẹ, èyí sì ń múnú Jèhófà dùn. (Òwe 23:15, 16) Bó o ṣe ń kọ́wọ́ ti ìṣàkóso Jèhófà ń jẹ́ kó lè máa fún Sátánì lésì. (Òwe 27:11) Torí náà, bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin, tó o sì ń ṣègbọràn, Jèhófà gbà pé ẹ̀bùn iyebíye lò ń fún òun, ìyẹn sì ń múnú rẹ̀ dùn gan-an.
17. Kí ni Àwọn Onídàájọ́ 5:31 sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
17 Láìpẹ́, àwọn tó fara wọn sábẹ́ àkóso Jèhófà nìkan ló máa wà láyé. Ṣe ló ń ṣe wá bíi pé kọ́jọ́ náà ti dé! Bíi ti Dèbórà àti Bárákì, àwa náà ń panu pọ̀ sọ pé: “Kí gbogbo ọ̀tá rẹ ṣègbé, Jèhófà, kí àwọn olùfẹ́ rẹ sì rí bí ìgbà tí oòrùn bá jáde lọ nínú agbára ńlá rẹ̀.” (Oníd. 5:31) Jèhófà máa dáhùn àdúrà yìí nígbà tó bá pa Sátánì àti ayé búburú yìí run! Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, kò ní sí pé à ń yọ̀ǹda ara wa láti bá àwọn ọ̀tá Jèhófà jà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la máa ṣe ohun tí Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín.” (2 Kíró. 20:17) Àmọ́ ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká lo gbogbo àǹfààní tá a ní láti máa fìtara àti ìgboyà ṣe iṣẹ́ Jèhófà.
18. Kí làwọn míì máa ṣe bá a ṣe ń yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ Jèhófà?
18 Nígbà tí Dèbórà àti Bárákì ń kọrin ìṣẹ́gun láti yin Jèhófà, wọ́n sọ pé: “Nítorí tí àwọn ènìyàn náà fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.” Ó ṣe kedere pé Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ ni wọ́n gbógo fún, kì í ṣe ẹ̀dá èyíkéyìí. (Oníd. 5:1, 2) Torí náà, ẹ jẹ́ káwa náà máa bá a lọ láti yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ Jèhófà káwọn míì lè máa yin Jèhófà!
a Irin gígùn tí ẹnu rẹ̀ mú bérébéré ni dòjé irin tí ẹsẹ yìí ń sọ, nígbà míì ó máa ń dà bí akọ́rọ́, ó sì máa ń yọ síta látinú àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Ta ló máa gbójúgbóyà sún mọ́ irú kẹ̀kẹ́ ogun tó ń bani lẹ́rù bẹ́ẹ̀?
b Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìtàn alárinrin yìí, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní ‘Mo Dìde Gẹ́gẹ́ Bí Ìyá ní Ísírẹ́lì’.” nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2015,
c Wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní ““Àníyàn Nípa Owó”” nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2015.