Ǹjẹ́ Gbogbo Ènìyàn Lè Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé?
AMÒFIN kan ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé láti gbádùn “ìyè àìnípẹ̀kun,” a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, kí a sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa bí ara wa ni. Jésù yin amòfin náà, ó sì wí fún un pé: “Ìdáhùn rẹ tọ́; ‘máa bá a nìṣó ní ṣíṣe èyí, ìwọ yóò sì rí ìyè.’” (Lúùkù 10:25-28; Léfítíkù 19:18; Diutarónómì 6:5) Ṣùgbọ́n nítorí pé ọkùnrin náà fẹ́ fi ara rẹ̀ hàn ní olódodo, ó béèrè pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?”
Ó dájú pé amòfin náà retí kí Jésù sọ pé, “Àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ.” Àmọ́, Jésù sọ ìtàn ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere fún un, èyí tí ó fi hàn pé àwọn ènìyàn tí kì í ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú jẹ́ aládùúgbò wa. (Lúùkù 10:29-37; Jòhánù 4:7-9) Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó tẹnu mọ́ ọn pé, àṣẹ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí Ẹlẹ́dàá wa fún wa ni pé kí a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wa.—Mátíù 22:34-40.
Síbẹ̀, ǹjẹ́ àwùjọ àwọn ènìyàn kankan tíì nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wọn rí ní tòótọ́ bí? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí gbogbo ènìyàn nífẹ̀ẹ́ ara wọn ní tòótọ́?
Ìyanu Kan ní Ọ̀rúndún Kìíní
Jésù wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé a óò fi ìfẹ́ tí ó borí ààlà ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè, àti gbogbo ààlà mìíràn dá wọn mọ̀. Ó wí pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Lẹ́yìn náà, ó tún sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:34, 35; 15:12, 13.
Àwọn ohun tí Jésù ń fi kọ́ni nípa ìfẹ́, tí ó sì ń fi àpẹẹrẹ tì lẹ́yìn, ṣe ìyanu kan ní ọ̀rúndún kìíní. Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọ̀gá wọn, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn ní ọ̀nà tí ó fa àfiyèsí àti ìfẹ́ ènìyàn káàkiri mọ́ra. Tertullian, òǹkọ̀wé kan ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta Sànmánì Tiwa, fa ọ̀rọ̀ àwọn tí wọn kì í ṣe Kristẹni yọ, tí wọ́n ń yin àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé: ‘Ẹ wo bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn àti bí wọ́n ti ṣe tán láti kú fún ara wọn.’
Ní gidi, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “A wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti fi ọkàn wa lélẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa.” (1 Jòhánù 3:16) Jésù tilẹ̀ kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Mátíù 5:43-45) Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tí àwọn ènìyàn bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn dáadáa, bí Jésù ṣe kọ́ wọn?
Látàrí ẹ̀rí tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìmọ̀ ìṣèlú ní lárọ̀ọ́wọ́tó, ó ronú lórí ìbéèrè yẹn. Ìdí nìyẹn tó fi béèrè bí a ti ròyìn rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn The Christian Century pé: “Ǹjẹ́ ẹnì kan lè fí ìrònú jinlẹ̀ wòye Jésù kí ó máa ju àdó abúgbàù sí àwọn ọ̀tá rẹ̀, kí ó máa lo ìbọn arọ̀jò ọta, kí ó máa fi ohun ìjà afinásọ̀kò jà, kí ó máa rọ̀jò àwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì tàbí kí ó máa sọ̀kò bọ́ǹbù ICBM tí ó lè pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìyá àti ọmọ tàbí kí ó sọ wọ́n di arọ?”
Ọ̀jọ̀gbọ́n náà dáhùn pé: “Ìbéèrè náà kò bọ́gbọ́n mu débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má yẹ fún ìdáhùn kankan.” Ó wá béèrè pé: “Bí Jésù kò bá lè ṣe èyí, ní ìbámu pẹ̀lú àkópọ̀ ìwà rẹ̀, nígbà náà, báwo ni àwa ṣe lè ṣe èyí kí a sì jẹ́ olóòótọ́ sí i?” Nítorí náà, kò yẹ kí àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù látètèkọ́ṣe, tí ọ̀pọ̀ ìwé ìtàn ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ dáadáa, yà wá lẹ́nu. Gbé àpẹẹrẹ méjì péré yẹ̀ wò.
Ìwé Our World Through the Ages, tí N. Platt àti M. J. Drummond ṣe, sọ pé: “Ìwà àwọn Kristẹni yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn ará Róòmù. . . . Níwọ̀n bí Kristi ti wàásù nípa àlàáfíà, wọ́n kọ̀ láti di jagunjagun.” Ìwé The Decline and Fall of the Roman Empire, tí Edward Gibbon ṣe, sì sọ pé: “[Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀] kọ̀ láti kópa nínú ìṣèlú tàbí iṣẹ́ ológun fún ààbò ilẹ̀ ọba náà. . . . Kò ṣeé ṣe kí àwọn Kristẹni gba iṣẹ́ ológun láìgbé iṣẹ́ kan tí ó túbọ̀ jẹ́ mímọ́ jù sílẹ̀.”
Lónìí Ńkọ́?
Ẹnikẹ́ni ha ń ní ìfẹ́ bí ti Kristi lónìí bí? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia Canadiana sọ pé: “Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìmúsọjí àti ìtúngbékalẹ̀ ìsìn Kristẹni ìjímìjí tí Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe . . . Ará ni gbogbo wọn.”
Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í jẹ́ kí ohunkóhun—yálà ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè, tàbí ìran tí wọ́n ti wá—mú wọn kórìíra àwọn aládùúgbò wọn. Wọn kò sì jẹ́ pa ẹnikẹ́ni, nítorí pé, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n ti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọ́n sì ti fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe.—Aísáyà 2:4.
Abájọ tí ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé ìròyìn Sacramento Union ti California fi kà pé: “Ó tó láti sọ pé bí gbogbo ayé bá ń tẹ̀ lé ìlànà ìgbàgbọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìkórìíra yóò dópin, ìfẹ́ yóò sì jọba”!
Bákan náà, òǹkọ̀wé kan tí ń ṣiṣẹ́ fún ìwé ìròyìn Ring ti Hungary sọ pé: “Ó dá mi lójú pé bí ó bá jẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ní ń gbé orí ilẹ̀ ayé, ogun kì yóò bẹ́ sílẹ̀ mọ́, iṣẹ́ kan ṣoṣo tí àwọn ọlọ́pàá yóò sì máa ṣe ni dídarí ọkọ̀ ìrìnnà àti fífún àwọn ènìyàn ní ìwé àṣẹ ìrìnnà.”
Nínú ìwé ìròyìn ṣọ́ọ̀ṣì náà, Andare alle genti, ní Ítálì, obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan láti Ìjọ Kátólíìkì ti Róòmù pẹ̀lú kan sáárá sí Àwọn Ẹlẹ́rìí nínú ìwé tí ó kọ pé: “Wọ́n kọ irú ìwà ọ̀daràn èyíkéyìí, wọ́n sì ń fara da gbogbo ìdánwò tí a ń gbé ka iwájú wọn nítorí ìgbàgbọ́ wọn láìṣagídí . . . Ayé ì bá mà dára bí gbogbo ènìyàn bá jí lówùúrọ̀ ọjọ́ kan, tí wọ́n sì pinnu láti má ṣe gbé ohun ìjà mọ́, bí ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, láìka ohun yòówù kí ó náni tàbí nítorí ìdí èyíkéyìí sí!”
A ti mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń gbé ìgbésẹ̀ láti ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́. (Gálátíà 6:10) Nínú ìwé Women in Soviet Prisons tí obìnrin ará Latvia kan ṣe, ó wí pé, òun ṣàìsàn gan-an nígbà tí òun ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Potma ní agbedeméjì àwọn ọdún 1960. Ó wí pé: “Ní gbogbo ìgbà tí mo fi ń ṣàìsàn náà, [Àwọn Ẹlẹ́rìí] fi ìjáfáfá ṣètọ́jú mi. Kò sí ibòmíràn tí wọ́n ti lè tọ́jú mi dáadáa jù bẹ́ẹ̀ lọ, pàápàá tí ó jẹ́ àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ni.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà á sí ojúṣe wọn láti ran gbogbo ènìyàn lọ́wọ́, láìka ìsìn àti orílẹ̀-èdè sí.”
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech ṣàkíyèsí ìwà Àwọn Ẹlẹ́rìí ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ìwé ìròyìn Severočeský deník sọ nípa fíìmù tí a fi ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, “The Lost Home,” tí a gbé jáde ní Brno, pé: “Ó yẹ kí a ṣàkíyèsí pé àwọn aṣeégbíyèlé tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n wọ̀nyí [àwọn Júù ará Czech àti Slovak tí wọ́n là á já] ti sọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa. Ọ̀pọ̀ sọ pé: ‘Wọ́n jẹ́ onígboyà, gbogbo ìgbà ni wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ lọ́nàkọnà tí wọ́n bá ti lè ṣe é, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fẹ̀mí wọn wewu. Wọ́n gbàdúrà fún wa bí pé a wà lára ìdílé wọn; wọ́n fún wa níṣìírí láti má ṣe bọ́hùn.’”
Àmọ́, ọ̀ràn ti nínífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n kórìíra wa ní gidi ńkọ́? Ìyẹn ha lè ṣeé ṣe bí?
Ìfẹ́ Ń Ṣẹ́gun Ìkórìíra
Ohun tí Jésù fi kọ́ni nípa nínífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òwe kan sọ nínú Bíbélì pé: “Bí ebi bá ń pa ẹni tí ó kórìíra rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.” (Òwe 25:21; Mátíù 5:44) Obìnrin adúláwọ̀ kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀wé nípa àǹfààní tó wà nínú rírí àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí a kà sí ọ̀tá nígbà kan pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, orí mi máa ń wú débi pé n óò máa sunkún ni nítorí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ funfun ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí mi, àwọn ènìyàn tó jẹ́ pé láìpẹ́ sí ìgbà tí a ń wí yẹn, n kì bá tí rò ó lẹ́ẹ̀mejì kí n tó pa wọ́n, kí n lè máa bá a lọ nínú ìlépa ìyípadà tegbòtigaga kan.”
Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé ṣàlàyé pé aládùúgbò kan fẹjọ́ ìyá rẹ̀ sun Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ọmọbìnrin náà ṣàlàyé pé: “Ó jálẹ̀ sí pé ìyá mi lo ọdún méjì ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Germany, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kú síbẹ̀. Lẹ́yìn ogun náà, àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Faransé fẹ́ kí Màmá fọwọ́ sí ìwé kan tí ń fẹ̀sùn lílẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Germany kan obìnrin náà. Àmọ́, ìyá mi kọ̀.” Nígbà tó yá, obìnrin ará àdúgbò wa náà ní àrùn jẹjẹrẹ gbẹ̀mígbẹ̀mí kan. Ọmọbìnrin náà sọ pé: “Màmá lo àkókò púpọ̀ láti mú kí obìnrin náà lè gbádùn àwọn oṣù tó lò kẹ́yìn láyé bí ó ti lè ṣeé ṣe tó. N kò jẹ́ gbàgbé ọ̀nà tí ìfẹ́ gbà ṣẹ́gun ìkórìíra yìí.”
Láìsí iyè méjì, àwọn ènìyàn lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá tẹ́lẹ̀ rí—àwọn Tutsi àti Hutu, àwọn Júù àti àwọn Lárúbáwá, àwọn ará Armenia àti àwọn ará Turkey, àwọn ará Japan àti àwọn ará Amẹ́ríkà, àwọn ará Germany àti àwọn ará Rọ́ṣíà, àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì àti àwọn Kátólíìkì—ni òtítọ́ Bíbélì ti sọ di ọ̀kan!
Níwọ̀n bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí wọ́n ti gbin oró ara wọn sínú ti wá ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn nísinsìnyí, dájúdájú, gbogbo ènìyàn àgbáyé lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, òtítọ́ ni pé a óò nílò ìyípadà kíkàmàmà kan jákèjádò ayé bí gbogbo ènìyàn yóò bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Báwo ni ìyípadà yẹn yóò ṣe ṣẹlẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn aláwọ̀ funfun àti adúláwọ̀ ní Gúúsù Áfíríkà
Àwọn Júù àti àwọn Lárúbáwá
Àwọn Hutu àti àwọn Tutsi
Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí ti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀