Ní Ìbárẹ́ Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà
ỌMỌ ẹ̀yìn nì, Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Onísáàmù náà, Dáfídì tún kọ ọ́ lórin pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Sáàmù 25:14) Ó hàn gbangba pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun. Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń jọ́sìn Ọlọ́run, tó sì ń ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀ ló sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.
Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run? Láìsí àní-àní, ó wù ọ́ láti sún mọ́ ọn. Báwo la ṣe lè ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run? Kí ni èyí yóò túmọ̀ sí fún wa? Orí kẹta ìwé Òwe inú Bíbélì fún wa ní àwọn ìdáhùn.
Fi Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ àti Òtítọ́ Hàn
Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì bẹ̀rẹ̀ orí kẹta ìwé Òwe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Ọmọ mi, má gbàgbé òfin mi, kí ọkàn-àyà rẹ sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́, nítorí ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè àti àlàáfíà ni a ó fi kún un fún ọ.” (Òwe 3:1, 2) Nígbà tó jẹ́ pé abẹ́ ìmísí àtọ̀runwá ni Sólómọ́nì ti kọ̀wé, ó fi hàn pé àmọ̀ràn bíi ti baba yìí dìídì wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni, ó sì darí rẹ̀ sí wa. Níhìn-ín la ti gbà wá nímọ̀ràn pé kí a fara mọ́ àwọn ìránnilétí Ọlọ́run—òfin rẹ̀, tàbí ẹ̀kọ́ rẹ̀, àti àwọn àṣẹ rẹ̀—tí a kọ sínú Bíbélì. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀ “ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè àti àlàáfíà ni a ó fi kún un” fún wa. Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsìnyí pàápàá, a lè gbádùn ìgbésí ayé alálàáfíà, a sì lè yẹra fún àwọn ilépa tó ń kóni sínú ewu ikú àìtọ́jọ́ tó máa ń dé bá àwọn aṣebi. Láfikún sí i, a tún lè ní ìrètí ìyè ayérayé nínú ayé tuntun alálàáfíà.—Òwe 1:24-31; 2:21, 22.
Nígbà tí Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sọ pé: “Kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ má fi ọ́ sílẹ̀. So wọ́n mọ́ ọrùn rẹ. Kọ wọ́n sára wàláà ọkàn-àyà rẹ, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ojú rere àti ìjìnlẹ̀ òye rere ní ojú Ọlọ́run àti ti ará ayé.” —Òwe 3:3, 4.
Ọ̀rọ̀ tí a lò fún “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni a tún máa ń lò fún “ìfẹ́ adúróṣinṣin,” èyí sì ní ìṣòtítọ́, ìfìmọ̀ṣọ̀kan, àti ìdúróṣinṣin nínú. Ṣé a ti pinnu láti dúró ti Jèhófà lábẹ́ ipòkípò táa bá wà? Ǹjẹ́ a máa ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa? Ǹjẹ́ à ń sakun láti sún mọ́ wọn? Nínú àjọṣe wa pẹ̀lú wọn lójoojúmọ́, ǹjẹ́ a máa ń jẹ́ kí ‘òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wà ní ahọ́n wa’ bí ipò nǹkan ò tiẹ̀ dán mọ́rán?—Òwe 31:26.
Nítorí pé Jèhófà kún fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ó “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Bí a bá ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì ti mú kí ẹsẹ̀ wa wà lójú ọ̀nà tààrà, a mú un dá wa lójú pé “àwọn àsìkò títunilára” yóò wá látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀. (Ìṣe 3:19) Ǹjẹ́ kò yẹ kí a fara wé Ọlọ́run wa nípa dídárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn jì wọ́n?—Mátíù 6:14, 15.
Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́,” ó sì ń fẹ́ “òtítọ́” látọ̀dọ̀ àwọn tó fẹ́ ní ìbárẹ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (Sáàmù 31:5) Ǹjẹ́ a lè retí pé kí Jèhófà jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa bí a bá ń gbé ìgbésí ayé méjì—tí ọ̀kan jẹ́ ọ̀nà tí a gbà ń hùwà nígbà tí a bá wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, tí òmíràn sì jẹ́ bí a ṣe ń hùwà nígbà tí wọn ò bá sí nítòsí wa—tí a bẹ̀rẹ̀ sí hùwà bíi ti “àwọn tí kì í sọ òtítọ́” tí wọ́n ń fi irú ènìyàn tí wọ́n jẹ́ pa mọ́? (Sáàmù 26: 4) Ìwà òmùgọ̀ gbáà ni ìyẹn á mà jẹ́ o, nígbà tó jẹ́ pé “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú” Jèhófà!—Hébérù 4:13.
Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́ jẹ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ gbà pé ó ṣeyebíye gẹ́gẹ́ bíi gbẹ̀dẹ̀ ‘tí a so mọ́ ọrùn wa,’ nítorí pé wọn ó ràn wá lọ́wọ́ láti rí ‘ojú rere ní ojú Ọlọ́run àti ti ará ayé.’ Kì í ṣe pé a ó máa fi ìwà yìí hàn lóde nìkan ni, àmọ́ a ó tún kọ wọ́n ‘sára wàláà ọkàn-àyà wa’ nípa fífi wọ́n ṣe apá pàtàkì nínú ànímọ́ wa.
Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Kíkún Nínú Jèhófà
Ọlọgbọ́n ọba náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
Dájúdájú, Jèhófà tóó gbẹ́kẹ̀ lé. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, ó ní “okun inú nínú agbára,” òun sì ni Orísun “okun alágbára gíga.” (Aísáyà 40:26, 29) Ó lágbára láti mú gbogbo ohun tó pète ṣẹ. Àní, ohun tí orúkọ rẹ̀ gan-an túmọ̀ sí ni “Ó Ń Mú Kí Ó Di,” èyí sì jẹ́ kí ìgbẹ́kẹ̀lé tí a ní nínú agbára tí ó ní láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ túbọ̀ pọ̀ sí i! Kókó náà pé “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́” mú kí ó jẹ́ ẹni tí àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣeé tẹ̀ lé jù lọ tó bá dọ̀ràn ká sọ òtítọ́. (Hébérù 6:18) Olórí ànímọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́. (Jòhánù 4:8) Òun jẹ́ “olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 145:17) Tí a kò bá lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ta la wá fẹ́ gbẹ́kẹ̀ lé? Àmọ́ ṣá o, ká tó lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, a ní láti ‘tọ́ ọ wò, kí a sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere’ nípa fífi ohun tí a kọ́ nínú Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé tiwa fúnra wa, kí a sì máa ronú jinlẹ̀ lórí èso rere tí èyí ń mú jáde.—Sáàmù 34:8.
Báwo la ṣe lè ‘kíyè sí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà wa’? Onísáàmù tí a mí sí náà sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.” (Sáàmù 77:12) Níwọ̀n bí a kò ti lè fojú rí Ọlọ́run, ṣíṣàṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ arabarìbì rẹ̀ àti lórí bí ó ṣe bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò ṣe pàtàkì fún wa láti ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.
Àdúrà tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti kíyè sí Jèhófà. Dáfídì Ọba ń ké pe Jèhófà “láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 86:3) Nígbà mìíràn, Dáfídì máa ń gbàdúrà ní gbogbo òru, bí irú ìgbà tó jẹ́ ìsáǹsá nínú aginjù. (Sáàmù 63:6, 7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.” (Éfésù 6:18) Báwo la ṣe máa ń gbàdúrà léraléra tó? Ǹjẹ́ a máa ń gbádùn bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ látọkànwá? Nígbà tí a bá dojú kọ àwọn ipò líle koko, ǹjẹ́ a máa ń bẹ̀ ẹ́ fún ìrànlọ́wọ́? Ǹjẹ́ a máa ń fi tàdúràtàdúrà béèrè ìdarí rẹ̀ kí a tó ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì? Àwọn àdúrà àtọkànwá táa bá gbà sí Jèhófà ń fà wá sún mọ́ ọn. A sì ní ìdánilójú pé yóò gbọ́ àdúrà wa, yóò sì ‘mú ọ̀nà wa tọ́.’
Ìwà òmùgọ̀ gbáà ló mà jẹ́ o, ká ‘máa gbára lé òye ti ara wa’ tàbí ti àwọn olókìkí nínú ayé, nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà wà ńbẹ̀ fún wa táa lè gbẹ́kẹ̀ lé ní kíkún! Sólómọ́nì sọ pé: “Má ṣe di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ.” Dípò ìyẹn, ó sọ pé: “Bẹ̀rù Jèhófà kí o sì yí padà kúrò nínú ohun búburú. Ǹjẹ́ kí ó di amúniláradá fún ìdodo rẹ àti ìtura fún egungun rẹ.” (Òwe 3:7, 8) Ojúlówó ìbẹ̀rù tí a ní pé a kò fẹ́ ṣẹ Ọlọ́run ló yẹ kó máa darí gbogbo ìṣe wa, ìrònú wa, àti ìmọ̀lára wa. Irú ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kí a ṣe ohun tí kò dára, ó sì máa ń fúnni ní ìwòsàn àti ìtura nípa tẹ̀mí.
Fún Jèhófà Ní Ohun Tó Dára Jù Lọ
Ọ̀nà mìíràn wo la tún lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run? Ọba náà sọ pé: “Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà àti àkọ́so gbogbo èso rẹ.” (Òwe 3:9) Láti bọlá fún Jèhófà túmọ̀ sí pé kí a kà á sí gan-an, kí a sì gbé e ga ní gbangba nípa nínípìn-ín nínú kíkéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba, kí a sì ṣe ìtìlẹ́yìn fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ohun ṣíṣeyebíye tí a fi ń bọlá fún Jèhófà ni àkókò wa, ẹ̀bùn táa ní, okun wa, àti àwọn ohun ìní wa. Ìwọ̀nyí gbọ́dọ̀ jẹ́ àkọ́so—ìyẹn ni pé kó jẹ́ ohun tí ó dára jù lọ tí a ní. Ṣé kò yẹ kí ọ̀nà tí a gbà ń lo àwọn ohun ìní wa fi hàn pé a ti pinnu láti ‘máa bá a nìṣó, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́’? —Mátíù 6:33.
Ó dájú pé a ó jèrè rẹ̀ bí a bá fi ohun ìní wa tó níye lórí bọlá fún Jèhófà. Sólómọ́nì mú un dá wa lójú pé: “Nígbà náà, àwọn ilé ìtọ́jú ẹrù rẹ yóò kún fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ; wáìnì tuntun yóò sì kún àwọn ẹkù ìfúntí rẹ ní àkúnwọ́sílẹ̀.” (Òwe 3:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aásìkí nípa tẹ̀mí fúnra rẹ̀ kọ́ ló ń mú aásìkí nípa tara wá, síbẹ̀ fífi ìwà ọ̀làwọ́ lo àwọn ohun ìní wa láti bọlá fún Jèhófà ń mú àwọn ìbùkún jìngbìnnì wá. Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni “oúnjẹ” tí ń fún Jésù lókun. (Jòhánù 4:34) Bákan náà ni kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, iṣẹ́ tó ń yin Jèhófà lógo, ń fún wa lókun. Tí a bá tẹra mọ́ iṣẹ́ yẹn, ibi tí à ń tọ́jú nǹkan pa mọ́ sí nípa tẹ̀mí yóò kún pitimu. Ayọ̀ wa—tó dúró fún ọtí tuntun—yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Ǹjẹ́ a kì í tún wo Jèhófà, kí a sì gbàdúrà sí i fún oúnjẹ tí yóò tó wa jẹ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan? (Mátíù 6:11) Ní ti tòótọ́, ọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ni gbogbo ohun tí a ní ti wá. Bí a bá ṣe lo ohun ìní wa tó níye lórí fún ìyìn Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ ni ìbùkún tó ń dà sórí wa yóò ṣe pọ̀ tó.—1 Kọ́ríńtì 4:7.
Gba Ìbáwí Jèhófà
Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì ṣàkíyèsí bí ìbáwí ti ṣe pàtàkì tó kí a tó lè ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó kìlọ̀ pé: “Ìwọ ọmọ mi, má kọ ìbáwí Jèhófà; má sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìbáwí àfitọ́nisọ́nà rẹ̀, nítorí pé ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.”—Òwe 3:11, 12.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìbáwí lè má rọrùn fún wa láti gbà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà jẹ́ apá pàtàkì nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ń mú kí a túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Jèhófà—yálà a gbà á látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa ni o, bóyá látinú ìjọ Kristẹni ni o, tàbí nípa ṣíṣàṣàrò lórí Ìwé Mímọ́ nígbà tí a bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ ni o—gbogbo rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tí ó ń gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa. Ọlọgbọ́n la jẹ́ tí a bá tẹ́wọ́ gbà á.
Di Ọgbọ́n àti Ìfòyemọ̀ Mú Ṣinṣin
Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ nínú níní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí, àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀, nítorí níní in gẹ́gẹ́ bí èrè sàn ju níní fàdákà gẹ́gẹ́ bí èrè, níní in gẹ́gẹ́ bí èso sì sàn ju níní wúrà pàápàá. . . . Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.”—Òwe 3:13-18.
Nígbà tí ọba náà ń ránni létí bí Jèhófà ṣe fi ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ hàn nínú àgbàyanu iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀, ó ní: “Ọgbọ́n ni Jèhófà fúnra rẹ̀ fi fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀. Ìfòyemọ̀ ni ó fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. . . . Ọmọ mi, kí wọ́n má ṣe lọ kúrò ní ojú rẹ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú, wọn yóò sì jẹ́ ìyè fún ọkàn rẹ àti òòfà ẹwà fún ọrùn rẹ.”—Òwe 3:19-22.
Ara ànímọ́ Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀. Kì í ṣe pé a ní láti ní wọn nìkan ni, àmọ́ a ní láti dì wọ́n mú ṣinṣin nípa ṣíṣàì fà sẹ́yìn láé nínú fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àti fífi ohun tí a ń kọ́ sílò. Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò máa rìn nínú ààbò ní ọ̀nà rẹ, ẹsẹ̀ rẹ pàápàá kì yóò sì gbún ohunkóhun.” Ó wá fi kún un pé: “Nígbàkigbà tí o bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò ní ìbẹ̀rùbojo; dájúdájú, ìwọ yóò dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò sì dùn mọ́ ọ.”—Òwe 3:23, 24.
Dájúdájú, a lè rìn nínú ààbò, kí a sì sùn pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn bí a ti ń dúró de ọjọ́ “ìparun òjijì” lórí ayé burúkú ti Sátánì yìí, èyí tí yóò dé bí olè. (1 Tẹsalóníkà 5:2, 3; 1 Jòhánù 5:19) Kódà lákòókò ìpọ́njú ńlá tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ yìí pàápàá, a lè ní ìdánilójú yìí pé: “Kì yóò sí ìdí fún ọ láti fòyà ohun òjijì èyíkéyìí tí ó jẹ́ akún-fún-ìbẹ̀rùbojo, tàbí ìjì lórí àwọn ẹni burúkú, nítorí pé ó ń bọ̀. Nítorí, ní ti tòótọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò jẹ́ ìgbọ́kànlé rẹ, dájúdájú, kì yóò jẹ́ kí a gbá ẹsẹ̀ rẹ mú.”—Òwe 3:25, 26; Mátíù 24:21.
Máa Hùwà Rere
Ìmọ̀ràn Sólómọ́nì ni pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Òwe 3:27) Híhùwà rere sí àwọn ẹlòmíràn ní í ṣe pẹ̀lú fífi ìwà ọ̀làwọ́ lo àwọn ohun ìní wa fún àǹfààní tiwọn, èyí sì pín sí ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Àmọ́, ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run òtítọ́ ha kọ́ ni ohun tó dára jù lọ tí a lè ṣe fún wọn láàárín “àkókò òpin” yìí? (Dáníẹ́lì 12:4) Nítorí náà, àkókò táa wà yìí ló yẹ ká máa fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 28:19, 20.
Ọlọgbọ́n ọba náà tún to àwọn ìwà kan tí a ní láti sá fún lẹ́sẹẹsẹ, ó sọ pé: “Má sọ fún ọmọnìkejì rẹ pé: ‘Máa lọ, kí o sì padà wá lọ́la, èmi yóò sì fi fún ọ,’ nígbà tí nǹkan kan wà lọ́wọ́ rẹ. Má fẹ̀tàn hùmọ̀ ohunkóhun tí ó burú sí ọmọnìkejì rẹ, nígbà tí ó ń gbé pẹ̀lú rẹ nínú ìmọ̀lára ààbò. Má ṣe bá ènìyàn ṣe aáwọ̀ láìnídìí, bí òun kò bá ṣe ọ́ ní búburú. Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni kí o má yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀.”—Òwe 3:28-31.
Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ ìdí tí ó fi fúnni ní àwọn àmọ̀ràn rẹ̀, ó ní: “Nítorí oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán. Ègún Jèhófà wà lórí ilé ẹni burúkú, ṣùgbọ́n ibi gbígbé àwọn olódodo ni ó ń bù kún. Bí ó bá jẹ mọ́ ti àwọn olùyọṣùtì, òun fúnra rẹ̀ yóò fi wọ́n ṣẹ̀sín; ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò fi ojú rere hàn sí. Ọlá ni àwọn ọlọ́gbọ́n yóò wá ní, ṣùgbọ́n àwọn arìndìn ń gbé àbùkù ga.”—Òwe 3:32-35.
Bí a bá fẹ́ gbádùn ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, a ò gbọ́dọ̀ báni gbìmọ̀ ohun békebèke tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́. (Òwe 6:16-19) Àyàfi tí a bá ṣe ohun tó tọ́ ní ojú Ọlọ́run la fi lè rí ojú rere àti ìbùkún rẹ̀. A sì tún lè rí ọ̀wọ̀ tí a kò retí gbà, nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá kíyè sí i pé a ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n àtọ̀runwá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yẹra fún ọ̀nà békebèke ti ayé burúkú oníwà ipá yìí. Àní, ẹ jẹ́ kí a máa tọ ipa ọ̀nà tí ó tọ́, kí a sì ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
“Fi àwọn ohun ìní rẹ̀ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà”