ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 48
Ọjọ́ Iwájú Ni Kó O Tẹjú Mọ́
“Ọ̀ọ́kán tààrà ni kí ojú rẹ máa wò, bẹ́ẹ̀ ni, iwájú rẹ gan-an ni kí o tẹjú mọ́.”—ÒWE 4:25.
ORIN 77 Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 4:25 sílò? Sọ àpẹẹrẹ kan.
Ẹ JẸ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ yìí. Arábìnrin àgbàlagbà kan ń ronú lórí ohun rere tó fi ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún un báyìí, ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe fún Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:58) Ojoojúmọ́ ló máa ń fojú inú wo ìgbà tí òun àtàwọn èèyàn ẹ̀ á jọ máa gbádùn nínú ayé tuntun. Arábìnrin míì rántí ohun tẹ́nì kan nínú ìjọ ṣe sí i tó dùn ún, àmọ́ ó pinnu pé òun máa gbọ́rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. (Kól. 3:13) Arákùnrin kan rántí àwọn àṣìṣe tó ti ṣe sẹ́yìn, àmọ́ ó wá pinnu pé òun á máa fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà láti ìsinsìnyí lọ.—Sm. 51:10.
2 Kí lohun tó jọra nínú àpẹẹrẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí? Gbogbo wọn ló rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn sẹ́yìn, àmọ́ kì í ṣèyẹn ni wọ́n ń rò ṣáá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọjọ́ iwájú ni wọ́n “tẹjú mọ́.”—Ka Òwe 4:25.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká “tẹjú mọ́” ọjọ́ iwájú?
3 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká “tẹjú mọ́” ọjọ́ iwájú? Jẹ́ ká wò ó báyìí, kí lo rò pé ó lè ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan bá ń wẹ̀yìn ṣáá dípò kó kọjú síbi tó ń lọ? Ó lè fẹsẹ̀ kọ, kó sì ṣubú. Lọ́nà kan náà, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a ti ṣe sẹ́yìn tàbí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí wa sẹ́yìn nìkan là ń rò, a ò ní lè tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—Lúùkù 9:62.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́ta tó lè mú kéèyàn máa ronú pa dà sẹ́yìn ṣáá. Àwọn ni: (1) kó máa ṣe wá bíi pé nǹkan sàn fún wa tẹ́lẹ̀ ju ti ìsinsìnyí lọ, (2) ká máa di ẹni tó ṣẹ̀ wá sínú àti (3) ká máa dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ. Bá a ṣe ń gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yẹ̀ wò, a máa jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì táá ràn wá lọ́wọ́ láti “gbàgbé àwọn ohun [tá a] fi sílẹ̀ sẹ́yìn,” ká sì “nàgà sí àwọn ohun tó wà níwájú.”—Fílí. 3:13.
EWU TÓ WÀ NÍNÚ KÉÈYÀN MÁA RONÚ PÉ NǸKAN SÀN TẸ́LẸ̀ JU TI ÌSINSÌNYÍ LỌ
5. Kí ni Oníwàásù 7:10 kìlọ̀ pé a ò gbọ́dọ̀ máa ṣe?
5 Ka Oníwàásù 7:10. Kíyè sí pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ò sọ pé ó burú tá a bá béèrè pé: “Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi dára?” Ó ṣe tán, Jèhófà dá wa ká lè máa rántí àwọn nǹkan rere tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn torí pé ìyẹn máa ń múnú wa dùn. Àmọ́, ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ ni pé: “Má sọ pé, ‘Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?’ ” Lédè míì, ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni pé kò yẹ ká máa fi bí nǹkan ṣe rí fún wa báyìí wé bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, ká wá máa ronú pé kò sóhun rere kan tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa báyìí. Ìtumọ̀ Bíbélì míì kà pé: “Má máa béèrè pé, ‘Kí ló dé tí ìgbà àtijọ́ fi dára ju ti ìsinsìnyìí lọ?’ Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́.”
6. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu ká máa ronú pé nǹkan sàn fún wa tẹ́lẹ̀ ju ti ìsinsìnyí lọ? Sọ àpẹẹrẹ kan.
6 Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu ká máa ronú pé nǹkan sàn fún wa tẹ́lẹ̀ ju ti ìsinsìnyí lọ? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ìgbà tí nǹkan dáa nìkan làá máa rántí, a ò sì ní rántí àwọn ìgbà tí nǹkan nira. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ níbẹ̀ nígbà yẹn nìkan ni wọ́n rántí, wọn ò rántí baba ńlá ìyà tó jẹ wọ́n. Wọ́n sọ pé: “A ò jẹ́ gbàgbé ẹja tí a máa ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ nílẹ̀ Íjíbítì àti kùkúńbà, bàrà olómi, ewébẹ̀ líìkì, àlùbọ́sà àti ááyù!” (Nọ́ń. 11:5) Àmọ́, ṣé ọ̀fẹ́ ni oúnjẹ yẹn lóòótọ́? Rárá o. Ojú wọn rí màbo, kódà nígbà yẹn, ẹrú ni wọ́n ní Íjíbítì, wọ́n sì jẹ palaba ìyà. (Ẹ́kís. 1:13, 14; 3:6-9) Síbẹ̀, wọn ò rántí gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ nìkan ni wọ́n rántí. Ìyẹn sì mú kí wọ́n gbàgbé àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe fún wọn. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú bí Jèhófà gan-an.—Nọ́ń. 11:10.
7. Kí ló ran arábìnrin kan lọ́wọ́ tí kò fi ronú pé nǹkan sàn fún òun tẹ́lẹ̀ ju ìsinsìnyí lọ?
7 Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa ronú pé nǹkan sàn fún wa tẹ́lẹ̀ ju ìsinsìnyí lọ? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn lọ́dún 1945. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, ó fẹ́ arákùnrin kan tóun náà ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì jọ sìn níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́ nígbà tó dọdún 1976, ọkọ rẹ̀ ṣàìsàn. Arábìnrin yẹn sọ pé nígbà tí ọkọ òun mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú, ó fún òun ní ìmọ̀ràn tó máa ran òun lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro táwọn opó máa ń ní. Ọkọ ẹ̀ sọ fún un pé: “Ìgbéyàwó wa jẹ́ aláyọ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni tiwọn ò rí bẹ́ẹ̀.” Àmọ́ ó tún sọ fún un pé: “Má máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ti kọjá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wàá ṣì máa rántí wọn. Nígbà tó bá yá, wàá mọ́kàn kúrò lára wọn. Má ṣe bọkàn jẹ́, má sì jẹ́ kí àánú ara rẹ máa ṣe ọ́. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn nítorí ayọ̀ àti ìbùkún tó o ti ní. . . . Agbára ìrántí jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa.” Ṣé ìwọ náà gbà pé ìmọ̀ràn tí arákùnrin yẹn fún ìyàwó ẹ̀ bọ́gbọ́n mu?
8. Báwo ni arábìnrin yẹn ṣe fi ìmọ̀ràn ọkọ ẹ̀ sílò?
8 Arábìnrin wa fi ìmọ̀ràn tí ọkọ ẹ̀ fún un sílò, ó sì fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà títí tó fi kú lẹ́ni ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún (92). Lọ́dún díẹ̀ kó tó kú, ó sọ pé: “Nígbà tí mo wo ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta (63) tí mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mo lè sọ pé mo ti gbé ìgbésí ayé aláyọ̀.” Kí ló mú kíyẹn ṣeé ṣe? Ó ṣàlàyé pé: “Olórí ohun tó ń mú kí ìgbésí ayé ẹni jẹ́ aláyọ̀ ni ẹgbẹ́ ará tó ṣọ̀wọ́n àti ìrètí pé a ó bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa gbé pa pọ̀ nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, tí a ó máa jìjọ sin Jèhófà Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà títí lọ gbére.”b Àpẹẹrẹ àtàtà ni arábìnrin yìí jẹ́ tó bá di pé ká máa wo ọjọ́ iwájú.
EWU TÓ WÀ NÍNÚ KÁ MÁA DI ÈÈYÀN SÍNÚ
9. Bó ṣe wà nínú Léfítíkù 19:18, àwọn ìgbà wo ló lè ṣòro láti dárí ji ẹnì kan tó ṣẹ̀ wá?
9 Ka Léfítíkù 19:18. Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti dárí ji ẹnì kan tó bá ṣẹ̀ wá, pàápàá tí onítọ̀hún bá jẹ́ Kristẹni bíi tiwa, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí mọ̀lẹ́bí. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan fẹ̀sùn kan arábìnrin míì pé ó jí owó òun. Nígbà tó yá, arábìnrin tówó ẹ̀ sọnù wá bẹ arábìnrin kejì pé kó má bínú, pé òun ti wá mọ̀ pé òun kọ́ ló jí owó náà. Àmọ́ ó ṣòro fún arábìnrin tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà láti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Ǹjẹ́ ìgbà kan wà tó ṣòro fún ìwọ náà láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́? Ká tiẹ̀ ní wọn ò fẹ̀sùn olè kàn wá rí, ó ṣeé ṣe káwọn kan ti ṣẹ̀ wá tó sì ṣòro fún wa láti dárí jì wọ́n.
10. Kí ló lè mú ká dárí ji ẹnì kan tó ṣẹ̀ wá?
10 Kí ló lè mú ká dárí ji ẹnì kan tó ṣẹ̀ wá ká má sì dì í sínú? Ká máa rántí pé Jèhófà rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ó mọ àwọn nǹkan tá à ń kojú àti ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù sí wa. (Héb. 4:13) Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń mọ̀ ọ́n lára tá a bá ń jìyà. (Àìsá. 63:9) Ó sì ṣèlérí pé òun máa dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìyà tó ń jẹ wá.—Ìfi. 21:3, 4.
11. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá?
11 Ó yẹ ká tún fi sọ́kàn pé tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, à ń ṣe ara wa láǹfààní. Ohun tí arábìnrin tí wọ́n fẹ̀sùn olè kàn náà wá pa dà mọ̀ nìyẹn. Nígbà tó yá, ó dárí ji ẹni náà, ó sì gbọ́rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Ó wá yé e pé tá a bá ń dárí ji àwọn míì, Jèhófà náà máa dárí jì wá. (Mát. 6:14) Ó mọ̀ pé ohun tẹ́ni yẹn ṣe ò dáa àti pé ọ̀rọ̀ náà dun òun, àmọ́ ó yàn láti dárí ji arábìnrin yẹn, ó sì gbàgbé ọ̀rọ̀ náà. Bí arábìnrin yẹn ṣe dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ mú kó túbọ̀ láyọ̀, ìyẹn sì mú kó lè gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
EWU TÓ WÀ NÍNÚ KÉÈYÀN MÁA DÁ ARA RẸ̀ LẸ́BI JU BÓ ṢE YẸ LỌ
12. Kí la rí kọ́ nínú 1 Jòhánù 3:19, 20?
12 Ka 1 Jòhánù 3:19, 20. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo wa la máa ń dá ara wa lẹ́bi. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè máa dá ara wọn lẹ́bi nítorí àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn míì sì máa ń dá ara wọn lẹ́bi nítorí àṣìṣe tí wọ́n ṣe lẹ́yìn ìrìbọmi. (Róòmù 3:23) Òótọ́ ni pé a máa ń fẹ́ ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jém. 3:2; Róòmù 7:21-23) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa kì í dùn tá a bá ń dára wa lẹ́bi, ó láǹfààní tiẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi, ó lè mú ká ṣàtúnṣe sí ìwà kan tá a hù, á sì mú ká pinnu pé a ò ní ṣe irú ẹ̀ mọ́.—Héb. 12:12, 13.
13. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ?
13 Lọ́wọ́ kejì, ẹnì kan lè máa dára ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, lédè míì kó máa dára ẹ̀ lẹ́bi lẹ́yìn tó ti ronú pìwà dà, tí Jèhófà sì ti jẹ́ kó dá a lójú pé òun dárí jì í. Irú èrò bẹ́ẹ̀ léwu gan-an. (Sm. 31:10; 38:3, 4) Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń dára ẹ̀ lẹ́bi ṣáá nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Mo ronú pé kò sídìí tó fi yẹ kí n máa lo ara mi dé góńgó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó ṣe tán, kò sí bí mo ṣe ṣe tó, tí màá rí ojúure Jèhófà.” Ọ̀pọ̀ wa náà ti lè ronú bẹ́ẹ̀ rí. Àmọ́ kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé inú Sátánì máa dùn tá a bá rẹ̀wẹ̀sì tá a sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ti dárí jì wá!—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 2:5-7, 11.
14. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà lè dárí jì wá?
14 Síbẹ̀, a lè máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé Jèhófà lè dárí jì mí?’ Ti pé o béèrè ìbéèrè yẹn fi hàn pé Jèhófà lè dárí jì ẹ́. Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: “A lè máa ṣàṣìṣe kan náà lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè jẹ́ ìwà kan tó ti mọ́ wa lára ká tó rí òtítọ́, tá a sì gbà pé a ti borí ẹ̀. . . . Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má sọ̀rètí nù, má ṣe ronú pé Jèhófà ò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì ẹ́ láé àti láéláé. Fi sọ́kàn pé bí Sátánì ṣe fẹ́ kó o máa ronú nìyẹn. Ti pé ọ̀rọ̀ náà ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́, tó sì ń mú kó o máa bínú sí ara ẹ fi hàn pé o kì í ṣe èèyàn burúkú àti pé Jèhófà máa dárí jì ẹ́. Máa tọ Jèhófà lọ nígbà gbogbo, má jẹ́ kó sú ẹ. Yíjú sí i tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, kó o sì bẹ̀ ẹ́ taratara pé kó dárí jì ẹ́, kó wẹ̀ ẹ́ mọ́, kó sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Máa lọ sọ́dọ̀ Jèhófà bí ìgbà tí ọmọdé kan ń lọ sọ́dọ̀ bàbá ẹ̀ nígbà ìṣòro. Má jẹ́ kó sú ẹ láìka iye ìgbà tó o ṣe àṣìṣe kan náà. Sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa fi ojú àánú hàn sí ẹ nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.”c
15-16. Báwo ló ṣe rí lára àwọn kan nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà lè dárí jì wọ́n?
15 Ọkàn ọ̀pọ̀ lára àwa èèyàn Jèhófà ló balẹ̀ nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà lè dárí jì wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, arákùnrin kan ka ọ̀kan lára àwọn ìrírí tó máa ń jáde nínú àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà,” ìyẹn sì ràn án lọ́wọ́ gan-an. Nínú àpilẹ̀kọ yẹn, arábìnrin kan sọ pé òun ò gbà pé Jèhófà lè nífẹ̀ẹ́ òun nítorí àwọn nǹkan tóun ti ṣe sẹ́yìn. Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tó ti ṣèrìbọmi, ó ṣì ń ronú bẹ́ẹ̀. Àmọ́, lẹ́yìn tó ronú lórí ẹ̀bùn ìràpadà, ó tún èrò ẹ̀ ṣe, ó sì gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun.d
16 Báwo ni ìrírí yìí ṣe ran arákùnrin náà lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì kéré, mo sapá gidigidi kí n tó lè bọ́ lọ́wọ́ wíwo àwòrán ìṣekúṣe tó ti di bárakú fún mi. Láìpẹ́ yìí, mo tún pa dà jìn sí ọ̀fìn yẹn kan náà. Mo ti lọ bá àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni, wọ́n ti ràn mí lọ́wọ́, mo sì ti ń borí ìṣòro náà. Àwọn alàgbà fi dá mi lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi, pé yóò sì ṣíjú àánú wò mí. Síbẹ̀, mo ṣì máa ń ka ara mi sí ẹni tí kò wúlò bíi pé kò sí bí Jèhófà ṣe lè fẹ́ràn mi. Ìrírí arábìnrin tí mo kà ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Mo ti wá rí i pé tí mo bá ti ń rò ó pé bóyá ni Ọlọ́run lè dárí jì mí, ṣe ló dà bí ìgbà tí mò ń sọ pé ẹbọ ìràpadà ọmọ Rẹ̀ kò lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù. Ṣe ni mo gé àpilẹ̀kọ náà dání kí n lè máa kà á, kí n sì máa ṣàṣàrò lé e lórí nígbàkigbà tí ìrònú pé mi ò wúlò bá tún fẹ́ gbà mí lọ́kàn.”
17. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe kó má bàa máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ?
17 Irú àwọn ìrírí yìí rán wa létí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Kó tó di Kristẹni, ó ti hu àwọn ìwà burúkú sẹ́yìn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù rántí àwọn nǹkan tó ṣe, kì í jẹ́ káwọn nǹkan yẹn gbà á lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. (1 Tím. 1:12-15) Ó gbà pé torí òun ni Kristi ṣe kú. (Gál. 2:20) Torí náà, Pọ́ọ̀lù ò dá ara ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà látìgbà yẹn lọ.
MÁA RONÚ NÍPA AYÉ TUNTUN!
18. Kí la ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
18 Kí làwọn nǹkan tá a ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí? (1) Jèhófà dá wa ká lè máa rántí àwọn nǹkan rere tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn torí pé ìyẹn máa ń múnú wa dùn. Àmọ́ bó ti wù kí nǹkan dáa tó fún wa tẹ́lẹ̀, ayé tuntun máa sàn jù ú lọ fíìfíì. (2) Àwọn èèyàn lè ṣẹ̀ wá, àmọ́ tá a bá dárí jì wọ́n, àá lè pọkàn pọ̀ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (3) Tá a bá ń dára wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, a ò ní lè fayọ̀ sin Jèhófà. Torí náà, bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ti dárí jì wá.
19. Báwo la ṣe mọ̀ pé a ò ní máa kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá tá a bá dénú ayé tuntun?
19 Nínú ayé tuntun, a ò ní kú mọ́, àá wà láàyè títí láé, a ò sì ní máa kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Bíbélì sọ nípa ìgbà yẹn pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí.” (Àìsá. 65:17) Rò ó wò ná: Àwọn kan lára wa ti dàgbà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ nínú ayé tuntun, gbogbo wa máa pa dà di ọ̀dọ́. (Jóòbù 33:25) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní máa ronú pa dà sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa wo ayé tuntun lọ́ọ̀ọ́kán, ká sì máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè wà níbẹ̀!
ORIN 142 Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára
a Ó dáa ká máa rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa rí nígbèésí ayé. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ìyẹn nìkan là ń rò ṣáá, ó lè mú ká dẹwọ́ nínú ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà báyìí, ó sì lè má jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sí ìrètí ọjọ́ iwájú mọ́. Téèyàn bá ń ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ẹ̀, ṣe ló dà bí ìgbà tó ń wakọ̀ sẹ́yìn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́ta tó lè mú kéèyàn máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àá sì jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì àtàwọn àpẹẹrẹ òde òní tí kò ní jẹ́ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀.
c Wo Ilé Ìṣọ́ November 1954, ojú ìwé 167.
e ÀWÒRÁN: Ohun ìnira ni téèyàn bá ń ronú pé nǹkan sàn fún òun tẹ́lẹ̀ ju ti ìsinsìnyí lọ, tó ń di àwọn míì sínú, tó sì ń dá ara ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kó ṣòro láti máa rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.
f ÀWÒRÁN: Tá a bá já ara wa gbà lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó ń fà wá sẹ́yìn yìí, ọkàn wa á balẹ̀, àá láyọ̀, àá sì tún lókun. Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè tẹjú mọ́ ọjọ́ iwájú.