Ipò Òṣì Bó Ṣe Máa Dópin Títí Láé
LÁÌFI ìròyìn búburú tá à ń gbọ́ nípa ipò òṣì káàkiri àgbáyé pè, àwọn kan wà tí wọ́n ní ẹ̀mí nǹkan yóò dára tí wọ́n gbà pé ohun kan tó ṣe gúnmọ́ lè ṣeé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí àkọlé kan nínú ìwé ìròyìn Manila Bulletin sọ, Báńkì Tó Ń Rí sí Ìdàgbàsókè Ilẹ̀ Éṣíà ròyìn pé “Éṣíà lè mú ipò òṣì kúrò pátápátá láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.” Báńkì náà dábàá pé mímú kí ètò ọrọ̀ ajé gbé pẹ́ẹ́lí sí i jẹ́ ọ̀nà kan láti mú àwọn èèyàn kúrò nínú ipò òṣì paraku.
Àwọn ètò àjọ mìíràn àtàwọn alákòóso ti kọ àwọn àbá àtàwọn ìwéwèé tó gùn jàn-ànràn-jan-anran sílẹ̀ láti gbìyànjú láti yanjú ìṣòro náà. Lára wọn ni: ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìbánigbófò, ètò ẹ̀kọ́ tó túbọ̀ sunwọ̀n sí i, wíwọ́gi lé gbèsè táwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, mímú owó ibodè kúrò káwọn orílẹ̀-èdè táwọn òtòṣì pọ̀ sí lè rọ́nà ta ọjà wọn bí wọ́n ṣe fẹ́, káwọn ìjọba sì kọ́ ilé olówó pọ́ọ́kú fáwọn òtòṣì.
Ní ọdún 2000, Àpéjọ Gbogbo Gbòò ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé àwọn góńgó tí wọ́n máa lé bá lọ́dún 2015 kalẹ̀. Mímú ipò òṣì paraku àti ebi kúrò wà lára àwọn góńgó wọ̀nyí títí kan mímú àìdọ́gba owó tí ń wọlé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kúrò. Bó ti wù kírú àwọn góńgó bẹ́ẹ̀ wúni lórí tó, ọ̀pọ̀ ni ò gbà pé wọ́n lè ṣeé ṣe nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí.
Àwọn Ọ̀nà Gbígbéṣẹ́ Láti Gbógun Ti Ipò Òṣì
Níwọ̀n bí ìrètí pé nǹkan yóò dára káàkiri àgbáyé ò ti fi bẹ́ẹ̀ dáni lójú, ibo lèèyàn wá lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Gẹ́gẹ́ bá a ti mẹ́nu kàn án ṣáájú, orísun ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ kan wà tó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nísinsìnyí. Kí ni nǹkan náà? Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni.
Kí ló mú kí Bíbélì yàtọ̀ sí gbogbo orísun mìíràn téèyàn ti lè rí ìsọfúnni gbà? Ìdí ni pé àtọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ aláṣẹ gíga jù lọ ló ti wá. Ó ti fi àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣeyebíye sáwọn ojú ewé rẹ̀, ìyẹn ni àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, àwọn ìlànà tó gbéṣẹ́ tó kan gbogbo èèyàn, níbi gbogbo, àti ní gbogbo ìgbà. Títẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí lè ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀ lákòókò tá a wà yìí pàápàá. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Níní èrò tí ó tọ́ nípa owó. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:12) Kí ni kókó tá à ń sọ níhìn-ín gan-an? Ohun tá à ń wí ni pé owó ò lè ṣe ohun gbogbo. Lóòótọ́, ó lè dáàbò boni dé ààyè kan o. Ó ń jẹ́ ká lè ra àwọn ohun tá a nílò, àmọ́ ó níbi tí agbára rẹ̀ mọ. Àwọn ohun ṣíṣeyebíye kan wà tí owó kò lè rà. Mímọ kókó yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe ka àwọn ohun ìní ti ara sí bàbàrà, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún ìjákulẹ̀ táwọn tó gbé gbogbo ìgbésí ayé wọn karí kíkó owó jọ máa ń ní. Owó kò lè ra ìwàláàyè, àmọ́ fífi ọgbọ́n hùwà lè dáàbò bo ìwàláàyè wa nísinsìnyí, ó sì tún lè mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìyè ayérayé.
Ṣe bó o ti mọ. Kì í ṣe gbogbo ohun tó máa ń wù wá láti rà ló máa ń jẹ́ ohun tá a dìídì nílò. Ohun tá a nílò gan-an la gbọ́dọ̀ fi ṣáájú. A lè máa sọ lọ́kàn wa pé a nílò ohun kan, nígbà tó sì jẹ́ pé ńṣe ni nǹkan náà kàn wù wá tí kì í ṣe pé a nílò rẹ̀ ní ti gidi. Ọlọgbọ́n èèyàn á kọ́kọ́ ṣètò owó tó ń wọlé fún un sórí àwọn ohun tó nílò gidigidi—bí oúnjẹ, aṣọ, ilé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn ìyẹn, kó tó náwó lé ohunkóhun mìíràn lórí, á kọ́kọ́ wò ó bóyá owó tó kù sóun lọ́wọ́ lè tóó ra àwọn nǹkan mìíràn. Nínú ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe Jésù, ó dámọ̀ràn pé kí ẹnì kan “kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó.”—Lúùkù 14:28.
Ní ilẹ̀ Philippines, Eufrosina, tó jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ tó ní ọmọ mẹ́ta ti kojú ìṣòro nípa gbígbọ́ bùkátà, ó sì di pé kó máa ṣún owó tó bá wà lọ́wọ́ rẹ̀ ná látìgbà tí ọkọ rẹ̀ ti fi í sílẹ̀ lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láti mọ àwọn ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi owó tó bá wà lọ́wọ́ wọn rà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ rẹ̀ lè rí ohun kan tó wù wọ́n láti rà. Dípò tó fi máa sọ pé rárá, ńṣe ló máa ń bá wọn fèrò wérò, nípa sísọ pé: “Kò burú, o lè rà á tó bá wù ẹ́, àmọ́ ó ní láti pinnu. Ohun kan ṣoṣo ni owó tá a ní lè tóó rà. A lè ra nǹkan tó wù ọ́ yìí, tàbí ká ra ẹran díẹ̀ tàbí ẹ̀fọ́ tá a máa fi jẹ ìrẹsì wa lọ́sẹ̀ yìí. Èwo lo wá fẹ́ ká rà níbẹ̀ báyìí? Mú ìkan.” Ojú ẹsẹ̀ làwọn ọmọ náà máa ń rí kókó náà lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n sì máa ń yàn láti ra oúnjẹ dípò nǹkan mìíràn.
Ní ìtẹ́lọ́rùn. Ìlànà Bíbélì mìíràn sọ pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:8) Owó fúnra rẹ̀ kì í fúnni láyọ̀. Àìmọye àwọn ọlọ́rọ̀ ni kò láyọ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn tálákà sì ń yọ̀ ṣìnkìn. Àwọn tálákà wọ̀nyí ti kọ́ béèyàn ṣe ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun díẹ̀ tí wọ́n nílò nínú ìgbésí ayé wọn. Jésù sọ̀rọ̀ nípa níní ‘ojú tí ó mú ọ̀nà kan’ èyí tó ń wo kìkì àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. (Mátíù 6:22) Èyí máa ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn. Ọ̀pọ̀ àwọn tálákà lọkàn wọn balẹ̀ bíi ti tòlótòló nítorí pé wọ́n ti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, ìgbésí ayé ìdílé wọn sì jẹ́ aláyọ̀—àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í ṣe ohun téèyàn ń fowó rà.
Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tí Bíbélì fúnni, èyí tó lè ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́ láti kojú ipò wọn. Àwọn tó kù ṣì pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, yẹra fún àwọn ìwà abèṣe bíi sìgá mímu àti tẹ́tẹ́ títa, tó máa ń jẹ́ kéèyàn fowó ṣòfò; mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé, àgàgà àwọn ohun tó jẹ́ góńgó tẹ̀mí; níbi tí iṣẹ́ bá ti wọ́n, gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ ọwọ́ tàbí kó o máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó tètè ń mówó wọlé. (Òwe 22:29; 23:21; Fílípì 1:9-11) Bíbélì dámọ̀ràn lílo irú “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú” bẹ́ẹ̀ nítorí pé “wọn yóò . . . jẹ́ ìyè fún ọkàn rẹ.”—Òwe 3:21, 22.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì lè ran àwọn tó wà nínú ipò òṣì lọ́wọ́, síbẹ̀ àwọn ìbéèrè kan nípa ohun tí ọjọ́ iwájú yóò mú wá ṣì wà níbẹ̀. Ṣé inú ipò òṣì làwọn tálákà máa wà títí láé? Ǹjẹ́ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn olówó rẹpẹtẹ àtàwọn òtòṣì parakú á ṣeé mú kúrò títí láé? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ojútùú kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ̀ nípa rẹ̀.
Bíbélì Fúnni Láwọn Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Nírètí
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ìwé rere ni Bíbélì. Àmọ́, wọn ò mọ̀ pé ó ń fúnni láwọn ìsọfúnni pàtó kan tó ń tọ́ka sí àwọn ìyípadà ńláǹlà tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.
Ọlọ́run ti ní i lọ́kàn láti yanjú àwọn ìṣòro ọmọ aráyé, títí kan ipò òṣì. Níwọ̀n bí ìjọba ènìyàn ò ti lágbára àtiṣe é tàbí tí wọn ò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ fi ìjọba mìíràn rọ́pò wọn. Lọ́nà wo? Bíbélì là á mọ́lẹ̀ kedere nínú ìwé Dáníẹ́lì 2:44 pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”
Lẹ́yìn tó bá mú “àwọn ìjọba” wọ̀nyí kúrò, Alákòóso tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yàn yóò wá ṣe ohun tó yẹ. Alákòóso yẹn kì í ṣe ènìyàn bí kò ṣe ẹ̀dá alágbára kan tó dà bí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ní ọ̀run, tó ní agbára láti ṣe àwọn ìyípadà tá a nílò láti mú àwọn àìdọ́gba tó wà nísinsìnyí kúrò. Ọlọ́run ti yan Ọmọ tiẹ̀ fúnra rẹ̀ láti ṣe èyí. (Ìṣe 17:31) Sáàmù 72:12-14 ṣàpèjúwe ohun tí Alákòóso yìí yóò ṣe, nípa sísọ pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.” Ìfojúsọ́nà àgbàyanu mà lèyí o! Òmìnira dé nígbẹ̀yìngbẹ́yín! Alákòóso tí Ọlọ́run yàn yóò gba ti àwọn òtòṣì àti ẹni rírẹlẹ̀ rò.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro tó so mọ́ ipò òṣì yóò yanjú lákòókò yẹn. Ẹsẹ kẹrìndínlógún Sáàmù 72 sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” Kò tún ní sí àìtó oúnjẹ nítorí ìyàn, àìsí owó, tàbí àìṣàkóso lọ́nà tó yẹ mọ́.
Àwọn ìṣòro mìíràn yóò yanjú pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó pọ̀ ju lọ láyé òde òní ni kò nílé tó jẹ́ tiwọn. Àmọ́ Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Aísáyà 65:21, 22) Olúkúlùkù ni yóò ní ilé ti ara rẹ̀, ti yóò sì gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ̀. Ìyẹn ni pé Ọlọ́run ń ṣèlérí láti fòpin sí ìṣòro ipò òṣì. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín olówó àti tálákà báyìí kò ní sí mọ́, kò ní sí pé àwọn kan wà láyé bí ẹni tí kò sí mọ́.
Nígbà tẹ́nì kan bá kọ́kọ́ gbọ́ nípa àwọn ìlérí Bíbélì wọ̀nyí, ó lè rò pé àlá tí ò lè ṣẹ ni. Àmọ́, nígbà téèyàn bá túbọ̀ ṣàyẹ̀wò Bíbélì, á rí i pé gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nígbà àtijọ́ ló mú ṣẹ pátá. (Aísáyà 55:11) Nítorí náà, kì í ṣe ọ̀ràn pé bóyá ó máa ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìbéèrè tó yẹ kó o máa béèrè ni pé, Kí lo lè ṣe láti jàǹfààní rẹ̀ nígbà tó bá ṣẹlẹ̀?
Ṣé Wàá Wà Níbẹ̀?
Níwọ̀n bí ìjọba yẹn ti jẹ́ ti Ọlọ́run, ó yẹ ká jẹ́ irú èèyàn tí Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà sábẹ́ ìṣàkóso yẹn. Kò fi wá sínú òkùnkùn nípa ohun tá a ó ṣe láti tóótun. Àwọn ìlànà náà wà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé nínú Bíbélì.
Alákòóso tá a yàn náà, ìyẹn Ọmọ Ọlọ́run, jẹ́ olódodo. (Aísáyà 11:3-5) Nítorí ìdí èyí, a rétí pé káwọn tó máa gbé lábẹ́ ìjọba yìí jẹ́ olódodo. Òwe 2:21, 22 sọ pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”
Ǹjẹ́ ọ̀nà èyíkéyìí wà láti kọ́ béèyàn ṣe ń kún ojú ìwọ̀n ohun tó yẹ ní ṣíṣe? Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀nà wà. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti fífi àwọn ìtọ́ni rẹ̀ sílò yóò jẹ́ kó o lè gbádùn ọjọ́ ọlà aláìlẹ́gbẹ́ yìí. (Jòhánù 17:3) Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè kọ́ ẹ̀kọ́ náà. A ké sí ọ láti lo àǹfààní ọ̀nà tá a là sílẹ̀ yìí kó o lè wà lára ẹgbẹ́ kan tí kò ní í nírìírí ipò òṣì àti ìwà ìrẹ́jẹ láé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Eufrosina: “Wíwéwèé ìṣúnná owó lọ́nà tó dáa ran ìdílé mi lọ́wọ́ láti ní ohun tí wọ́n nílò”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àjọṣe rere pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ kò ṣeé fowó rà