A Ha Pinnu Ọjọ-Ọla Rẹ Nipasẹ Àyànmọ́ Bi?
BI IWỌ bá nilati yèbọ́ ninu jàm̀bá aṣekupani kan, iwọ yoo ha nimọlara pe àyànmọ́ ti ṣojurere sí ọ bi? Kaka bẹẹ iwọ yoo ha kun fun imoore pe o wulẹ wà ni ibi ti o tọ́ ni akoko ti o tọ́ ni bi?
Solomọni ọlọgbọn ọkunrin naa wi pe: “Mo pada, mo si ri i labẹ oorun, pe ire-ije kii ṣe ti ẹni ti ó yára, bẹẹ ni ogun kii ṣe ti alagbara, bẹẹ ni ounjẹ kii ṣe ti ọlọgbọn, bẹẹ ni ọrọ̀ kii ṣe ti ẹni òye, bẹẹ ni ojurere kii ṣe ti ọlọgbọn-inu; ṣugbọn ìgbà ati èèṣì nṣe sí gbogbo wọn [“akoko ati iṣẹlẹ ti a ko rí ṣaaju ṣẹlẹ si gbogbo wọn,” New World Translation].” (Oniwaasu 9:11) Ẹ wo bi ohun ti a kò reti ṣe nṣẹlẹ lemọlemọ tó! Saresare kan ti a mọ pé o ṣeeṣe julọ fun lati gbẹyẹ ni ó ṣèṣe, ti ẹni ti a reti pe yoo padanu sì gbẹyẹ. Ìjàm̀bá airotẹlẹ kan mu ipadanu ọrọ̀ aje wá fun ọkunrin oniṣowo alailabosi kan, ni yiyọọda fun alabosi abanidije rẹ̀ lati di ọlọrọ. Ṣugbọn Solomọni ha ka awọn aidọgba wọnyi sọrun kádàrá bi? Bẹẹkọ rara. Iwọnyi wulẹ jẹ iyọrisi “ìgbà ati èèṣì [“akoko ati iṣẹlẹ ti a ko rí ṣaaju,” NW].”
Jesu Kristi ṣe akiyesi ti o farajọ eyi. Ni titọka si iṣẹlẹ kan ti o ṣe kedere pe o jẹ eyi ti ọpọlọpọ laaarin awọn olugbọ rẹ̀ mọ̀, Jesu beere pe: “Tabi awọn mejidinlogun, ti ilé-ìṣọ́ ni Siloamu wólù, ti o si pa wọn, ẹyin ṣe bi wọn ṣe ẹlẹṣẹ ju gbogbo awọn eniyan ti nbẹ ni Jerusalẹmu lọ?” (Luuku 13:4) Jesu kò dẹ́bi awọn jàm̀bá iku wọnyi fun awọn kádàrá kan ti wọn ṣoro ṣalaye tabi lori àmúwá Ọlọrun, bẹẹ ni oun kò gbagbọ pe awọn ti a palara naa lọna kan ṣá jẹ́ ẹni ti o tubọ lẹtọọsi ẹbi ju awọn miiran lọ. Jàm̀bá apanilẹkun naa wulẹ jẹ apẹẹrẹ iṣẹlẹ miiran nipa akoko ati iṣẹlẹ ti a ko rí ṣaaju ni.
Kò si ibi kankan ti Bibeli ti ti ero naa lẹhin pe Ọlọrun ti pinnu akoko iku wa ṣaaju. Otitọ ni pe Oniwaasu 3:1, 2 wi pe: “Olukuluku ohun ni akoko wà fun, ati igba fun iṣẹ gbogbo labẹ ọrun. igba bíbíni, ati igba kiku, igba gbígbìn ati igba kíká ohun ti a gbìn.” Sibẹ Solomọni wulẹ njiroro bíbá a niṣo iyipo akoko iwalaaye ati iku ti ńpọ́n iran araye alaipe loju ni. A bí wa, nigba ti ó bá sì di akoko naa, nigba ti a ba dé deedee akoko ti a reti pe ki ẹnikan fi walaaye—tí ó saba maa njẹ lẹhin 70 tabi 80 ọdun tabi ju bẹẹ lọ—a ńkú. Sibẹ, Ọlọrun kò pinnu akoko iku ṣaaju gan an gẹgẹ bi agbẹ kan ko ti pinnu iṣẹju ti oun yoo pinnu ‘lati gbìn’ tabi ‘lati ká ohun ti a gbìn.’
Nitootọ, Solomọni fihan lẹhin naa pe ẹnikan le kú láìtọ́jọ́, ni wiwi pe: “Iwọ maṣe buburu aṣeleke, bẹẹ ni ki iwọ ki o ma ṣiwere; nitori ki ni iwọ yoo ṣe ku ki ọjọ rẹ ki ó tó pe?” (Oniwaasu 7:17) Ọgbọn wo ni yoo wà ninu imọran yii bi akoko iku ẹnikan ba jẹ eyi ti a ti pinnu ṣaaju lọna ti kò ṣee yipada? Bibeli tipa bayii ṣá ero naa nipa kádàrá tì. Awọn ọmọ Isirẹli apẹhinda ti wọn tẹwọgba ero abọriṣa yii ni Ọlọrun dá lẹbi lọna mimuna. Aisaya 65:11 wi pe: “Ẹyin ti ó kọ Oluwa silẹ, ti o gbagbe oke nla mímọ́ mi, ti ó pese tabili fun Gadi [“Ọlọrun Oríire,” NW], ti o sì fi ọrẹ mimu kún Meni [“ọlọrun Àyaǹmọ́,” NW].”
Ẹ wò bi o ti jẹ iwa omugọ tó, nigba naa, lati ka awọn jàm̀bá ati àjálù buburu si kádàrá lọ́rùn tabi, eyi ti o buruju, si amuwa Ọlọrun funraarẹ! “Ọlọrun jẹ ifẹ,” ni Bibeli wi, ati lati fẹsun jijẹ olupilẹ ibanujẹ araye kan an tako otitọ ipilẹ yii ni taarata.—1 Johanu 4:8, NW.
Awọn Ete Ọlọrun Fun Ọjọ-ọla
Nigba naa, ki ni nipa awọn ifojusọna wa fun igbala? Otitọ naa pe ko si kádàrá alaiṣeeyẹsilẹ ti ndari igbesi-aye wa ha tumọ si pe awa gbọdọ rin gbéregbère bi? Bẹẹkọ rara, nitori Ọlọrun ti pinnu ọjọ-ọla araye ni gbogbogboo. Bibeli sọ nipa iṣẹda “aye titun” ninu eyi ti “ododo ngbe.”—2 Peteru 3:13.
Lati ṣaṣepari eyi, Ọlọrun yoo dasi ọran araye ni taarata. Laimọ, iwọ ti le gbadura fun eyi lati ṣẹlẹ nipa kika adura naa lákàsórí pe: “Ki ijọba rẹ de; ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bii ti ọrun, bẹẹ ni ni aye.” (Matiu 6:10) Ijọba yii jẹ iṣakoso gidi kan ti a fidi rẹ̀ kalẹ ninu awọn ọrun. Nipa gbigbadura pe kí ó dé iwọ gbadura pe ki Ijọba yẹn gba iṣakoso ilẹ-aye lọwọ awọn oluṣakoso ode oni.—Daniẹli 2:44.
Didaabobo Ọjọ-ọla Tirẹ
Bi awọn iṣẹlẹ amunitagiri wọnyi yoo ti nipa lori ọjọ-ọla rẹ sinmi, kii ṣe lori kádàrá tabi akoko ati iṣẹlẹ ti a ko rí ṣaaju paapaa, ṣugbọn lori ipa ọna ti o yàn lati tẹle. Ranti iṣẹlẹ apanilẹkun ti ilé-ìṣọ́ Siloamu yẹn. Jesu lo iṣẹlẹ abanininujẹ yẹn lati kọnilẹkọọ jijinlẹ kan. Awọn olufarapa ilé-ìṣọ́ tí ó wó yẹn ni ko le yèbọ́ kuro lọwọ ohun ti o ṣubu lù wọn. Ni ọwọ keji ẹwẹ, awọn olufetisilẹ si Jesu le yẹra fun iparun ti o jade lati inu ibinu atọrunwa. Jesu kilọ fun wọn pe: “Bikoṣe pe ẹyin ronupiwada, gbogbo yin ni yoo ṣegbe bẹẹ gẹgẹ.” (Luuku 13:4, 5) Ni kedere, wọn le yan ọjọ-ọla tiwọn.
Anfaani kan naa ni a nà jade si wa lonii—lati pinnu igbala tiwa. (Filipi 2:12) Ọlọrun nfẹ pe ki “gbogbo eniyan . . . wá sinu imọ otitọ.” (1 Timoti 2:4) Ati bi o tilẹ jẹ pe ẹnikọọkan wa ni a nipa le lori dé iwọn kan nipasẹ ajogunba ati ipilẹ igbesi-aye, Ọlọrun ti fun wa ni ominira ifẹ-inu—agbara lati pinnu bi a ṣe fẹ lo ọna igbesi-aye wa. (Matiu 7:13, 14) A lè ṣe ohun ti o tọ tabi ohun ti kò tọ́. A lè jere iduro olojurere pẹlu Jehofa Ọlọrun ki a si jere iye, tabi a le yipada lodi si i ki a sì kú.
Ọpọlọpọ yàn lati gbe ni idaduro lominira si Ọlọrun. Wọn ya gbogbo igbesi-aye wọn sọtọ lati lépa awọn ohun ti ara, igbadun, tabi òkìkí kiri. Ṣugbọn Jesu kilọ pe: “[Ẹ] kiyesara ki ẹ sì maa ṣọra nitori ojukokoro: nitori igbesi-aye eniyan kii duro nipa ọpọ ohun ti ó ni.” (Luuku 12:15) Lori ki ni, nigba naa, ni igbesi-aye wa sinmi le? Ni 1 Johanu 2:15-17, Bibeli ṣalaye pe: “Ẹ maṣe fẹran aye, tabi ohun ti nbẹ ninu aye. . . . Nitori ohun gbogbo ti nbẹ ni aye, ifẹkufẹẹ ara, ati ifẹkufẹẹ oju, ati irera aye, kii ṣe ti Baba, bikoṣe ti aye. Aye sì nkọja lọ, ati ifẹkufẹẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹni ti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo duro laelae.”
Yiyan Ìyè
Bawo ni ó ṣe lè dá ọ loju pe iwọ nṣe ifẹ inu Ọlọrun nitootọ? Jesu polongo pe: “Iye ainipẹkun naa sì ni eyi, ki wọn ki o le mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ rán.” (Johanu 17:3) Imọ pipeye lati inu Bibeli pese ipilẹ fun igbagbọ. “Ṣugbọn laisi igbagbọ ko ṣeeṣe lati wù ú; nitori ẹni ti ó ba ntọ Ọlọrun wá ko lè ṣai gbagbọ pe ó nbẹ, ati pe oun ni oluṣẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wa a.” (Heberu 11:6) Imọ ti o nilati gbà wà larọọwọto ni sẹpẹ. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ran araadọta ọkẹ lọwọ lati jere rẹ̀ nipasẹ ikẹkọọ Bibeli deedee kan.a
Ki o baa le wu Ọlọrun, iwọ nilati ṣe awọn iyipada kan. Awọn iwa baraku diẹ lè wà ti o nilati ṣẹ́pá tabi awọn aṣa oniwa palapala paapaa ti o nilati fopin si. Maṣe jọ̀gọ̀nù, gẹgẹ bi ẹni pe ko ni le ṣeeṣe fun ọ lati yipada. Ironu naa pe awọn nǹkan ni a ko le yipada wulẹ jẹ ero miiran kan ti a mujade lati inu ẹkọ eke nipa kádàrá. Pẹlu iranlọwọ Jehofa, o ṣeeṣe fun ẹnikẹni lati ‘yi ero inu rẹ̀ pada’ ati lati gba “akopọ animọ iwa titun naa.” (Roomu 12:2; Efesu 4:22-24, NW) Awọn isapa rẹ lati wu Ọlọrun ni a ko ni ṣalai kiyesi. Oun duro ni sẹpẹ lati bukun awọn wọnni ti wọn nṣe ifẹ inu rẹ̀.
A gbà pe, kikẹkọọ Bibeli ki yoo yanju gbogbo iṣoro rẹ. Awọn ojulowo iranṣẹ Ọlọrun ni wọn wà labẹ jàm̀bá ati awọn ipo ti ó lekoko, gẹgẹ bii ti awọn miiran. Bi o ti wu ki o ri, Ọlọrun le fun wa ni ọgbọn lati koju ìjábá. (Jakọbu 1:5) Ayọ mimọ pe ẹnikan ni ipo ibatan rere pẹlu Ọlọrun tún wà nibẹ. “Ẹni ti ó sì gbẹkẹle Oluwa [“Jehofa,” NW], ayọ ni fun un,” ni Owe 16:20 wi.
Ninu Paradise ti a mú padabọsipo labẹ Ijọba Ọlọrun, a ki yoo halẹ mọ́ wa mọ́ nipasẹ akoko ati iṣẹlẹ ti a ko ri ṣaaju. Nitootọ, Ọlọrun yoo mu gbogbo awọn nǹkan ti nba ayọ eniyan jẹ nisinsinyi kuro. “Ọlọrun yoo sì nu omije gbogbo nù kuro ni oju [wa]; ki yoo sì sí iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ,” ni Bibeli ṣeleri. (Iṣipaya 21:4) Ailonka awọn olufarapa jàm̀bá yoo niriiri ajinde.—Johanu 5:28, 29.
Iwọ yoo ha jogun ọjọ-ọla ologo yii bi? Nigba ti o kù diẹ ki awọn ọmọ Isirẹli wọnu Ilẹ Ileri, Mose sọ fun wọn pe: “Emi pe ọrun ati ilẹ jẹrii tì yin ni oni pe, emi fi ìyè ati iku, ibukun ati ègún siwaju rẹ: nitori naa yan ìyè, ki iwọ ki ó lè yè, iwọ ati iru-ọmọ rẹ: ki iwọ ki o lè maa fẹ Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ, ati ki iwọ ki o le maa gba ohùn rẹ̀ gbọ́, ati ki iwọ ki ó lè maa faramọ́ ọn: nitori pe oun ni ìyè rẹ, ati gigun ọjọ rẹ.”—Deutaronomi 30:19, 20.
Rárá, awa kii ṣe ẹru alainiranlọwọ labẹ idari kádàrá alailaanu kan. Ayọ ọjọ-ọla rẹ, nitootọ ọjọ-ọla ayeraye rẹ, wà ni ọwọ rẹ. A rọ̀ ọ́ lati yan ìyè.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Iru ikẹkọọ kan bẹẹ ni o lè ṣeto fun nipa kikọwe si awọn ti o tẹ iwe irohin yii.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Awọn ọmọ Isirẹli apẹhinda ti wọn tẹwọgba ero abọriṣa ti kádàrá ni Ọlọrun dá lẹbi lọna mimuna