Ǹjẹ́ Ìwà Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Lè Tán Láé?
JOHN ADAMS, tó di ààrẹ kejì Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wà lára àwọn tó fọwọ́ sí ìwé mánigbàgbé náà, Ìpolongo Òmìnira, èyí tó ní àwọn ọ̀rọ̀ wíwúnilórí yìí nínú: “A gbà pé òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni òtítọ́ náà pé, bá a ṣe bí ẹrú la ṣe bí ọmọ.” Síbẹ̀ náà, John Adams kò fi taratara gbà pé lóòótọ́ ni àparò kan ò ga jùkan lọ. Nítorí òun ló tún kọ̀wé pé: “Ọlọ́run Olódùmarè ló fi àìdọ́gba nínú Èrò Inú àti ní ti Ara sínú Àbùdá Ọmọ Aráyé. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kò sí ìwéwèé tàbí ìlànà èyíkéyìí tó lè sọ àwọn èèyàn di ọgbọọgba.” Àmọ́ ọ̀tọ̀ ni èrò òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, H. G. Wells. Òun ní tirẹ̀ fọkàn yàwòrán ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí gbogbo èèyàn yóò ti ní ẹ̀tọ́ ọgbọọgba, èyí tó gbé ka ohun mẹ́ta: ẹ̀sìn mímọ́ kan ṣoṣo tí kò ní àbààwọ́n kárí ayé, ẹ̀kọ́ kan náà fún gbogbo aráyé àti mímú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ogun kúrò.
Títí di bá a ti ń wí yìí, irú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí Ọ̀gbẹ́ni Wells ronú nípa rẹ̀ yìí kò tíì sí nínú ìtàn. Àwọn èèyàn ò dọ́gba rárá. Ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ sì pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ. Ǹjẹ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀ ti ṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà láǹfààní kankan? Rárá o. Ńṣe ni ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ń pín àwọn èèyàn níyà. Ó ń fa ìlara, ìkórìíra, másùnmáwo àti ọ̀pọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀. Èrò náà pé ìran aláwọ̀ funfun lọ̀gá, èyí tó gbilẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ní Áfíríkà, Ọsirélíà àti ní Àríwá Amẹ́ríkà sọ àwọn tí kì í ṣe aláwọ̀ funfun di ẹran ìyà—títí kan rírun tí wọ́n run ìran àwọn ọmọ onílẹ̀ ní erékùṣù Van Diemen’s Land (tí wọ́n ń pè ní Tasmania nísinsìnyí). Ní Yúróòpù, àìfojú èèyàn gidi wo àwọn Júù ló fa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà. Ọrọ̀ yaágbóyaájù tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú ní àti ẹ̀mí àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn tó gbèèràn láàárín àwọn kò-là-kò-ṣagbe àtàwọn mẹ̀kúnnù, wà lára ohun tó fa Ìyípadà Tegbòtigaga tó wáyé nílẹ̀ Faransé ní ọ̀rúndún kejìdínlógún. Ó tún wà lára ohun tó fa Ìyípadà Tegbòtigaga tó wáyé nílẹ̀ Rọ́ṣíà, èyí tí Bolshevik ṣagbátẹrù rẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún.
Ọkùnrin ọlọgbọ́n kan láyé àtijọ́ kọ̀wé pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Òdodo ọ̀rọ̀ lèyí o. Ì báà jẹ́ àwọn ènìyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí ní ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ló ń fọwọ́ ọlá gbáni lójú. Nígbà tí agbo àwọn èèyàn kan bá fi ara wọn jọ̀gá àwọn èèyàn mìíràn, wàhálà àti ìyà ló máa ń tìdí ẹ̀ yọ.
Gbogbo Èèyàn Dọ́gba Lójú Ọlọ́run
Ṣé a pilẹ̀ dá àwọn èèyàn kan ní ẹ̀dá tó lọ́lá ju àwọn mìíràn lọ ni? Ó tì o. Ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” (Ìṣe 17:26) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ẹlẹ́dàá “kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ aládé, . . . kì í sì í ka ọ̀tọ̀kùlú sí ju ẹni rírẹlẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn jẹ́.” (Jóòbù 34:19) Ìdílé kan ni gbogbo ẹ̀dá ènìyàn jẹ́. Ìbí kò yàtọ̀ sí ìbí lójú Ọlọ́run.
Tún rántí pé nígbà tẹ́nì kan bá kú, ibẹ̀ ni gbogbo làlà-koko-fẹ̀fẹ̀ pé òun lọ́lá ju àwọn ẹlòmíràn pin sí. Àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì kò gba èyí gbọ́. Nígbà tí Fáráò kan bá kú, wọ́n máa ń kó àwọn nǹkan olówó iyebíye sínú sàréè rẹ̀, pẹ̀lú ìrètí pé á máa lo ipò ọlá rẹ̀ nìṣó lẹ́yìn ikú. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí? Rárá o. Ọwọ́ àwọn olè tó ń jí nǹkan inú sàréè kó ni gbogbo nǹkan olówó iyebíye wọ̀nyẹn máa ń bọ́ sí. Ọ̀pọ̀ tí wọn ò sì rí jí ń bẹ nínú àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí lónìí.
Fáráò kò lè lo àwọn nǹkan olówó iyebíye wọ̀nyẹn nítorí pé ó ti kú. Tíkú bá dé, kò sí ọ̀tọ̀kùlú, kò sì sí gbáàtúù mọ́. Kò sí ẹgbẹ́ olówó, kò sì sí ẹgbẹ́ tálákà mọ́. Bíbélì sọ pé: “Ọlọgbọ́n ò ní ṣàì kú; òmùgọ̀ àti sùgọ́mù, gbogbo wọn ló ń ṣègbé pẹ̀lú. Nítorí pé àwọn èèyàn ò yàtọ̀ sí màlúù tí ẹ̀mí wọn kì í gùn, wọn ò yàtọ̀ sí ẹran ọ̀sìn ọlọ́jọ́ kúkúrú.” (Sáàmù 49:10, 12, The New English Bible) Yálà ọba tàbí ẹrú ni wá, ọ̀rọ̀ onímìísí tó tẹ̀ lé e yìí kò yọ ẹnikẹ́ni wa sílẹ̀, pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́ . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.”—Oníwàásù 9:5, 10.
Lójú Ọlọ́run, bá a ṣe bí ẹrú la ṣe bí ọmọ. Ìyàtọ̀ ò sì sí nínú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa nígbà tíkú bá dé. Ẹ ò wá rí i pé asán lórí asán ni àṣà gbígbé ẹ̀yà kan lékè ẹ̀yà míì láàárín àkókò kúkúrú tá à ń lò láyé!
Báwo Ni Ìwà Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Yóò Ṣe Dópin?
Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ìrètí tiẹ̀ wà pé níjọ́ ọjọ́ kan, àwùjọ kan á wà láyè yìí, tí kò ti ní sí ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni o, ìrètí wà. Ìgbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn ló ti fi ìpìlẹ̀ irú àwùjọ yẹn lélẹ̀. Jésù fẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ bí ẹbọ ìràpadà fún gbogbo ẹni tó bá gbà á gbọ́, “kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Láti fi hàn pé òun kò fẹ́ kí ìkankan lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa gbé ara rẹ̀ ga ju àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Jésù sọ pé: “Ẹ̀yin, kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi. Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ òjíṣẹ́ yín. Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.” (Mátíù 23:8-12) Lójú Ọlọ́run, ọgbọọgba ni gbogbo ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ jẹ́ nínú ìgbàgbọ́.
Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà pé ọgbọọgba làwọn jẹ́? Àwọn tí òye ọ̀rọ̀ Jésù yé gbà bẹ́ẹ̀. Ọgbọọgba ni wọ́n ka ara wọn sí nínú ẹ̀sìn tòótọ́. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ara wọn ní “arákùnrin.” (Fílémónì 1, 7, 20) Wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ka ara rẹ̀ sí ẹni tó sàn ju àwọn yòókù lọ. Fún àpẹẹrẹ, wo bí Pétérù ṣe fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ṣàpèjúwe ara rẹ̀ nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì, ó ní: “Símónì Pétérù, ẹrú àti àpọ́sítélì Jésù Kristi, sí àwọn tí ó ti gba ìgbàgbọ́, tí a dì mú nínú àǹfààní dídọ́gba pẹ̀lú tiwa.” (2 Pétérù 1:1) Jésù alára ló fún Pétérù ní ìtọ́ni, níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ àpọ́sítélì, ó ní ipò ẹrù iṣẹ́ pàtàkì. Síbẹ̀, ó ka ara rẹ̀ sí ẹrú. Ó sọ pé dọ́gbadọ́gba ni àǹfààní tóun àtàwọn Kristẹni yòókù jọ ní nínú òtítọ́.
Àwọn kan lè sọ pé ohun tí Ọlọ́run ṣe, nígbà tó fi Ísírẹ́lì ṣe àyànfẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀ kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, tako ẹ̀tọ́ ọgbọọgba. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Wọ́n lè sọ pé ẹ̀rí pé ìran kan lọ́lá ju òmíràn lọ nìyí. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Òótọ́ ni pé àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ wà láàárín Ọlọ́run àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí í ṣe àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. A sì tipasẹ̀ wọn ṣí àwọn ìsọfúnni payá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 3:1, 2) Ṣùgbọ́n ìdí tá a fi ṣe èyí kì í ṣe láti gbé wọn lékè. Kàkà bẹ́ẹ̀, èyí wáyé kí a lè “bù kún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” ni.—Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Gálátíà 3:8.
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kò ní irú ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù baba ńlá wọn ní. Wọ́n di aláìṣòótọ́, wọn ò gba pé Jésù ni Mèsáyà náà. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi kọ àwọn náà. (Mátíù 21:43) Àmọ́, àwọn ìbùkún tá a ṣèlérí kò fo àwọn ọlọ́kàn tútù ayé dá. Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa la dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Ètò àjọ àwọn Kristẹni yìí, tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, ni a pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” Ipasẹ̀ ìṣètò yìí sì ni ìbùkún wọ̀nyẹn yóò gbà wá.—Gálátíà 6:16.
Ó yẹ kí àwọn kan lára mẹ́ńbà ìjọ yẹn kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ sí i nípa ọ̀ràn ẹ̀tọ́ ọgbọọgba. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù gba àwọn tí ń bọlá fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju àwọn tó jẹ́ òtòṣì nímọ̀ràn. (Jákọ́bù 2:1-4) Ìwà yẹn lòdì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé àwọn Kristẹni tí í ṣe Kèfèrí kò rẹlẹ̀ rárá sáwọn Kristẹni tí í ṣe Júù. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ obìnrin kò sì rẹlẹ̀ rárá sáwọn ọkùnrin. Ó kọ̀wé pé: “Ní ti tòótọ́, ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú Kristi Jésù. Nítorí gbogbo ẹ̀yin tí a ti batisí sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀. Kò sí Júù tàbí Gíríìkì, kò sí ẹrú tàbí òmìnira, kò sí akọ tàbí abo; nítorí ẹnì kan ṣoṣo ni gbogbo yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.”—Gálátíà 3:26-28.
Àwọn Èèyàn Tí Kò sí Ìwà Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Láàárín Wọn Lónìí
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbìyànjú lóde òní láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Wọ́n mọ̀ pé ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kò dáa lójú Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí kò fi sí ẹgbẹ́ àlùfáà àti ti ọmọ ìjọ láàárín wọn. Wọn kì í sì í ya ara wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nítorí àwọ̀ tàbí ọrọ̀. Bí àwọn kan nínú wọn tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀, wọn kì í lọ́wọ́ sí “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” Torí wọ́n mọ̀ pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ò láyọ̀lé. (1 Jòhánù 2:15-17) Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run, Ọba Aláṣẹ Ọ̀run òun Ayé.
Gbogbo wọn ló gbà pé ojúṣe àwọn ni láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún ọmọnìkejì wọn. Bíi ti Jésù, wọ́n ń buyì fún àwọn tí ìpọ́njú dé bá àtàwọn tí kò ní alábàárò, nípa lílọ tí wọ́n ń lọ fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wọn nínú ilé wọn. Àwọn tó wà ní ipò rírẹlẹ̀ ń jùmọ̀ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn táwọn kan kà sí èèyàn pàtàkì. Àwọn ànímọ́ tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe ipò téèyàn wà láwùjọ. Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní, arákùnrin àti arábìnrin ni gbogbo wọn nínú ìgbàgbọ́.
Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba Kò Ní Kí Ìyàtọ̀ Máà Sí
Àmọ́ o, níní ẹ̀tọ́ ọgbọọgba kò wá sọ pé kí ìyàtọ̀ máà sí rárá. Tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà, ló wà nínú ètò àjọ Kristẹni yìí. Wọ́n sì wá látinú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran, èdè, orílẹ̀-èdè, wọ́n sì jẹ́ olówó tàbí tálákà. Agbára àti òye kálukú wọn kò dọ́gba. Ṣùgbọ́n ìyẹn ò wá sọ àwọn kan di ọ̀gá, kí àwọn yòókù sì jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, irú ìyàtọ̀ wọ̀nyẹn ń jẹ́ ká rí ọ̀kan-kò-jọ̀kan ànímọ́ tó kọyọyọ. Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn mọ̀ pé ẹ̀bùn àbínibí yòówù kí àwọn ní jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, kò sídìí fún gbígbà pé àwọn lọ́lá ju àwọn ẹlòmíràn lọ.
Ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ń wáyé nítorí pé ènìyàn ń gbìyànjú láti ṣàkóso ara rẹ̀, dípò títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gbogbo ayé yìí. Yóò fòpin sí gbogbo ọ̀ràn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àti gbogbo nǹkan yòókù tó ti fa ìjìyà jálẹ̀ ìtàn ìran ènìyàn. Nígbà yẹn gan-an ni ‘àwọn ọlọ́kàn tútù yóò wá jogún ilẹ̀ ayé.’ (Sáàmù 37:11) Kò ní sídìí fún fífẹlá mọ́. Ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kò ní lè paná ìfẹ́ ará tí yóò wà kárí ayé mọ́ láé.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ẹlẹ́dàá “kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ aládé, . . . kì í sì í ka ọ̀tọ̀kùlú sí ju ẹni rírẹlẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn jẹ́.”—Jóòbù 34:19.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bọlá fún àwọn aládùúgbò wọn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ànímọ́ tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́