Ayọ̀—Ó Ti Dàléèbá Pátápátá
ÌBÍNÚ, àníyàn, àti ìsoríkọ́ ti jẹ́ kókó ìwádìí sáyẹ́ǹsì tipẹ́tipẹ́. Àmọ́, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn òléwájú onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń darí àfiyèsí wọn sí ìwádìí tí ó dá lórí ìrírí rere, tí ó fani lọ́kàn mọ́ra, tí ẹ̀dá ènìyàn ń ní—ayọ̀.
Kí ni ó lè túbọ̀ mú kí àwọn ènìyàn láyọ̀? Ṣe jíjẹ́ ọ̀dọ́, níní ọrọ̀, níní ìlera jíjí pépé, jíjẹ́ ẹni gíga, tàbí jíjẹ́ ẹni tí ó tín-ínrín ni bí? Kí ni àṣírí ojúlówó ayọ̀? Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn láti dáhùn ìbéèrè yẹn, bí wọ́n bá tilẹ̀ lè dáhùn rẹ̀ rárá. Ní wíwo bí àìlèrí ayọ̀ ti tàn kálẹ̀ tó, ó lè túbọ̀ rọrùn fún àwọn kan láti rí ìdáhùn sí ohun tí kì í ṣe àṣírí ayọ̀.
Fún ìgbà pípẹ́, àwọn òléwájú afìṣemọ̀rònú ti dábàá ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá gẹ́gẹ́ bí àṣírí ayọ̀. Wọ́n rọ àwọn tí kò láyọ̀ láti darí gbogbo àfiyèsí wọn sí títẹ́ àìní ara wọn nìkan lọ́rùn. Nínú ìfìṣe-ṣèwòsàn, a ti lo àwọn gbólóhùn fífani lọ́kàn mọ́ra bíi “mọ ti ara rẹ nìkan,” “mọ ìmọ̀lára rẹ,” àti “mọ irú ẹni tí o jẹ́ gan-an.” Síbẹ̀, àwọn kan lára àwọn ògbóǹkangí náà tí wọ́n gbé èrò yí lárugẹ ti wá gbà nísinsìnyí pé irú ìṣarasíhùwà onímọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ kì í mú ayọ̀ pípẹ́ títí wá. Kò sí àní-àní pé ìgbéra-ẹni-lárugẹ yóò mú ìrora àti ìbànújẹ́ wá. Kì í ṣe ìmọtara-ẹni-nìkan ni àṣírí ayọ̀.
Àṣírí Ìbànújẹ́
Àwọn tí ń yíjú sí ìlépa adùn láti lè rí ayọ̀ ń yíjú sí ibi tí kò tọ́. Gbé àpẹẹrẹ ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì ti Ísírẹ́lì ìgbàanì yẹ̀ wò. Nínú ìwé Oníwàásù nínú Bíbélì, ó ṣàlàyé pé: “Ohunkóhun tí ojú mi fẹ́, èmi kò pa á mọ́ fún wọn; èmi kò sì du àyà mi ní ohun ayọ̀ kan; nítorí tí àyà mi yọ̀ nínú iṣẹ́ mi gbogbo; èyí sì ni ìpín mi láti inú gbogbo làálàá mi.” (Oníwàásù 2:10) Sólómọ́nì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà ọ̀gbìn, ọgbà ìtura, àti adágún odò fún ara rẹ̀. (Oníwàásù 2:4-6) Ó béèrè nígbà kan pé: “Ta ni ó ń jẹ, ta sì ni ó ń mu ohun tó dára tó tèmi?” (Oníwàásù 2:25, NW) Àwọn ọ̀gá nínú akọrin àti olórin ni ó ń forin dá a lára yá, ó sì gbádùn àjọṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó rẹwà jù lọ ní ilẹ̀ náà.—Oníwàásù 2:8.
Kókó náà ni pé, ní ti ọ̀ràn adùn, Sólómọ́nì kò fi ohunkóhun du ara rẹ̀. Ìparí èrò wo ni ó dé lẹ́yìn tí ó ti jadùn rẹpẹtẹ nínú ìgbésí ayé? Ó wí pé: “Mo wo gbogbo iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ṣe, àti làálàá tí mo ṣe làálàá láti ṣe: sì kíyè sí i, asán ni gbogbo rẹ̀ àti ìmúlẹ̀mófo, kò sì sí èrè kan lábẹ́ oòrùn.”—Oníwàásù 2:11.
Àwárí ọlọgbọ́n ọba náà ṣì péye títí di òní olónìí. Fún àpẹẹrẹ, gbé orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ kan bí United States yẹ̀ wò. Ní 30 ọdún tí ó kọjá, àwọn ará Amẹ́ríkà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ dúkìá wọn, bí ọkọ̀ àti tẹlifíṣọ̀n, di ìlọ́po méjì. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ògbóǹkangí nínú ìlera ọpọlọ ti sọ, àwọn ará Amẹ́ríkà kò láyọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni kan ti sọ, “ní àkókò kan náà, iye ìsoríkọ́ ti ròkè lálá. Ìṣekúpara-ẹni ti àwọn ọ̀dọ́langba ti di ìlọ́po mẹ́ta. Iye ìkọ̀sílẹ̀ ti di ìlọ́po méjì.” Ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, àwọn aṣèwádìí ti dórí ìparí èrò kan náà lẹ́yìn tí wọ́n ṣàyẹ̀wò ìbátan tí ó wà láàárín owó àti ayọ̀ láàárín àwọn olùgbé 50 orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ní ṣókí, ayọ̀ kò ṣeé fowó rà.
Ní òdì kejì pátápátá, lọ́nà tí ó tọ́, a lè pe ìlépa ọrọ̀ ní àṣírí ìbànújẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Àwọn wọnnì tí wọ́n [pinnu] láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ àwọn ìfẹ́ ọkàn òpònú àti aṣenilọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ìrunbàjẹ́. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọn sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—Tímótì Kíní 6:9, 10.
Ọrọ̀, ìlera, jíjẹ́ ọ̀dọ́, ẹwà, agbára, tàbí àpapọ̀ ìwọ̀nyí kò lè mú ayọ̀ pípẹ́ títí dáni lójú. Èé ṣe? Nítorí a kò ní agbára láti dènà ìṣẹ̀lẹ̀ búburú. Ọba Sólómọ́nì sọ ọ́ lọ́nà ṣíṣe wẹ́kú pé: “Ènìyàn pẹ̀lú kò mọ ìgbà tirẹ̀; bí ẹja tí a mú nínú àwọ̀n búburú, àti bí ẹyẹ tí a mú nínú òkun; bẹ́ẹ̀ ni a ń dẹ àwọn ọmọ ènìyàn ni ìgbà búburú, nígbà tí ó ṣubú lù wọ́n lójijì.”—Oníwàásù 9:12.
Góńgó Àléèbá
Kò sí ìwádìí sáyẹ́ǹsì tí a lè ṣe tí ó lè mú ìlànà tàbí ìwéwèé ẹ̀dá ènìyàn láti rí ayọ̀ jáde. Sólómọ́nì tún sọ pé: “Mo pa dà láti rí i lábẹ́ oòrùn pé eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ìjà ogun kì í ṣe ti àwọn alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kì í ṣe ti àwọn ọlọ́gbọ́n pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti àwọn olóye pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá; nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11, NW.
Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yí ti parí èrò sí pé ríretí ìgbésí ayé aláyọ̀ tòótọ́ kò lè ṣẹ. Ìlúmọ̀ọ́ká ọ̀mọ̀wé kan sọ pé “ayọ̀ jẹ́ ipò kan tí a finú rò lásán.” Àwọn mìíràn gbà gbọ́ pé àdììtú pátápátá ni àṣírí ayọ̀, pé ó lè jẹ́ pé ìwọ̀nba kéréje àwọn amòye tí ó ní ẹ̀bùn ìmọ̀ awo ni ó ní agbára láti mọ àṣírí náà.
Síbẹ̀, nínú bí wọ́n ṣe ń wá ayọ̀ kiri, àwọn ènìyàn kò dẹ́kun dídán onírúurú ọ̀nà ìgbésí ayé wò. Láìka ìjákulẹ̀ tí àwọn aṣáájú wọn ti ní sí, ọ̀pọ̀ lónìí ṣì ń lépa ọrọ̀, agbára, ìlera, tàbí adùn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó lè mú ìbànújẹ́ wọn kúrò. Ìwákiri náà ń bá a lọ, nítorí nínú lọ́hùn-ún, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn gbà gbọ́ pé ayọ̀ pípẹ́ títí kì í ṣe ipò tí a ń finú rò lásán. Wọ́n ní ìrètí pé ayọ̀ kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ. Nígbà náà, o lè béèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè rí i?’