Àwọn Olólùfẹ́ Rẹ tí Wọ́n Ti Kú—Ìwọ Yóò Ha Tún Rí Wọn Bí?
ỌMỌ ọdún mẹ́sàn-án péré ní John nígbà tí ìyá rẹ̀ kú. Lẹ́yìn ìgbà náà, ó rántí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí: “Mo ya àwòrán kan fún un mo sì kọ àkọsílẹ̀ kékeré kan sórí rẹ̀ láti sọ fún un pé kí ó dúró de gbogbo wa lọ́run. Mo fún Dádì pé kí ó fi sínú pósí rẹ̀, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kú, ó wù mí láti máa ronú pé ó rí ìhìn-iṣẹ́ tí ó kẹ́yìn yẹn gbà láti ọ̀dọ̀ mi.”—How It Feels When a Parent Dies, láti ọwọ́ Jill Krementz.
Kò lè sí iyèméjì kankan pé John fẹ́ràn ìyá rẹ̀ gidigidi. Lẹ́yìn ṣíṣàpèjúwe àwọn ànímọ́ rere rẹ̀, ó wí pé: “Bóyá ó wulẹ̀ jẹ́ pé n kò fẹ́ láti rántí àwọn ohun tí ó burú ni, ṣùgbọ́n n kò lè ronú ohunkóhun tí ó burú nípa rẹ̀. Òun ni obìnrin dídára jùlọ tí mo tíì rí rí ní gbogbo ìgbésí-ayé mi.”
Bíi ti John, ọ̀pọ̀ máa ń fi pẹ̀lú ìfẹ́ rántí àwọn olólùfẹ́ wọn tí ó ti kú wọ́n sì gbà pé àwọn ní àìní ti èrò-ìmọ̀lára láti tún rí wọn. Edith, tí ọmọkùnrin rẹ̀ ẹni ọdún 26 kú ikú àrùn jẹjẹrẹ, wí pé: “Mo ni àìní náà láti gbàgbọ́ pé ọmọkùnrin mi wàláàyè níbìkan ṣùgbọ́n emi kò mọ ibi tí ó jẹ́. Èmi yóò ha tún rí i bí? Èmi kò mọ̀ ṣùgbọ́n mo nírètí pé èmi yóò rí i.”
Dájúdájú, Ẹlẹ́dàá ènìyàn onífẹ̀ẹ́ kìí ṣe aláìnímọ̀lára nípa ìfẹ́-ọkàn yíyẹ tí ènìyàn ní. Ìdí nìyẹn tí ó fi ṣèlérí pé àkókò náà yóò dé nígbà tí a óò tún àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ènìyàn sopọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wọn tí ó ti kú. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìtọ́ka wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun èyí tí ó sọ nípa àjíǹde àwọn òkú tí ń bọ̀wá yìí.—Isaiah 26:19; Danieli 12:2, 13; Hosea 13:14; Johannu 5:28, 29; Ìfihàn 20:12, 13.
Àwọn Wo Ni A Jí Dìde Sí Ọ̀run?
Ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò ìrètí John pé ìyá òun àyànfẹ́ ń dúró de òun ní ọ̀run. Ọ̀pọ̀ àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì ní ìrètí tàbí ìgbàgbọ́ yìí. Nínú ìgbìdánwò láti ṣètìlẹ́yìn fún irú ojú-ìwòye bẹ́ẹ̀, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan ṣi àwọn ẹsẹ inú Bibeli lò.
Fún àpẹẹrẹ, ògbógi kan nínú ríran àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lọ́wọ́, Dókítà Elisabeth Kübler-Ross, sọ nínú ìwé rẹ̀ On Children and Death pé: “Kìkì ohun tí kíkú túmọ̀sí ni pé a gbé ara wa jùnù ní ọ̀nà kan náà tí a lè gbà gbé ẹ̀wù àwọ̀lékè kan tí ó ti gbó jù sẹ́gbẹ̀ẹ́kan, tàbí kí a ti inú iyàrá kan bọ́ sínú òmíràn. Nínú Oniwasu 12:7, a kà pé: ‘Nígbà náà ni erùpẹ̀ yóò padà sí ilẹ̀ bí ó ti wà rí; ẹ̀mí yóò sì padà tọ Ọlọrun tí ó fi í fúnni.’ Jesu wí pé: ‘Èmi ń lọ pèsè àyè sílẹ̀ fún yín pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú.’ Àti fún olè tí ó wà lórí àgbélébùú pé: ‘Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní paradise.’”
Àwọn ẹsẹ tí ó wà lókè wọ̀nyí níti gidi ha túmọ̀sí pé àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú wàláàyè nísinsìnyí tí wọ́n sì ń dúró dè wá ní ọ̀run bí? Ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ farabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹsẹ náà, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Oniwasu 12:7. Ó ṣe kedere pé, ọlọgbọ́n ọkùnrin náà tí ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì kò ní in lọ́kàn láti tako ohun tí ó ti sọ ṣáájú nínú ìwé Bibeli kan náà pé: “Alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan.” (Oniwasu 9:5) Ó ń jíròrò ikú aráyé ní gbogbogbòò. Ó ha lọ́gbọ́n nínú láti gbàgbọ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n kéde jíjẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun àti àwọn ọ̀daràn tí ó ti yigbì padà tọ Ọlọrun lọ lẹ́yìn ikú wọn bí? Àgbẹdọ̀. Nítòótọ́, a kò lè sọ ìyẹn nípa ẹnikẹ́ni nínú wa, ìbáà tilẹ̀ jẹ́ pé a ka araawa sí ẹni búburú tàbí ẹni rere. Níwọ̀n bí kò ti sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí ó tíì wà pẹ̀lú Ọlọrun rí ní ọ̀run, báwo ni a ṣe lè sọ pé a óò padà tọ̀ ọ́ lọ?
Nígbà náà, kí ni òǹkọ̀wé Bibeli náà ní lọ́kàn nípa sísọ pé lẹ́yìn ikú, ‘ẹ̀mí padà tọ Ọlọrun tí ó fi í fúnni’? Ní lílo ọ̀rọ̀ Heberu náà tí a túmọ̀sí “ẹ̀mí,” òun kò tọ́kasí ohun aláìlẹ́gbẹ́ kan tí ó fi ènìyàn kan hàn yàtọ̀ sí òmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ní Oniwasu 3:19, òǹkọ̀wé Bibeli kan náà tí a mísí ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn àti ẹranko ‘ni gbogbo wọn ní ẹ̀mí kan náà.’ Ẹ̀rí fihàn pé òun ní in lọ́kàn pé “ẹ̀mí” ni agbára ìwàláàyè náà tí ń bẹ nínú àwọn ohun tín-ín-tìn-ìn-tín inú ara tí wọ́n parapọ̀ di ara ìyára ènìyàn àti ti ẹranko. Àwa kò gba ẹ̀mí yìí ní tààràtà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A ta àtaré rẹ̀ sí wa nípasẹ̀ àwọn òbí wa tí wọ́n jẹ́ ènìyàn nígbà tí a lóyún wa tí a sì bí wa lẹ́yìn náà. Síwájú síi, ẹ̀mí yìí kìí rìnrìn-àjò ní tààràtà gba inú òfuurufú kọjá kí ó sì padà sọ́dọ̀ Ọlọrun nígbà ikú. Gbólóhùn náà, ‘ẹ̀mí padà tọ Ọlọrun tí ó fi í fúnni,’ jẹ́ èdè ìṣàpẹẹrẹ tí ó túmọ̀sí pé ìrètí wíwàláàyè ọjọ́-ọ̀la ti ènìyàn kan tí ó ti kú sinmilé Ọlọrun nísinsìnyí. Ó dọwọ́ rẹ̀ láti pinnu ẹni tí òun yóò rántí tí òun yóò sì jí dìde ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Ìwọ fúnraàrẹ lè kíyèsí bí Bibeli ti fi èyí hàn ní kedere nínú Orin Dafidi 104:29, 30.
Jehofa Ọlọrun ti pète pé iye kéréje àwọn olùṣòtítọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, tí àpapọ̀ iye wọn jẹ́ 144,000 péré ni a óò jí dìde sí ìyè ti ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Ọlọrun. (Ìfihàn 14:1, 3) Àwọn wọ̀nyí parapọ̀ di ìjọba ọ̀run kan pẹ̀lú Kristi fún ìbùkún aráyé lórí ilẹ̀-ayé.
Àwọn ẹni àkọ́kọ́ láti mọ̀ nípa èyí ni àwọn aposteli Jesu olùṣòtítọ́, àwọn ẹni tí ó sọ fún pé: “Nínú ilé Baba [mi] ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà: ìbá máṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá ti sọ fún yín. Nítorí èmi ń lọ pèsè àyè sílẹ̀ fún yín. Bí mo bá sì lọ pèsè àyè sílẹ̀ fún yín, èmi óò tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkáraàmi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú.” (Johannu 14:2, 3) Àwọn aposteli wọnnì àti àwọn Kristian ìjímìjí mìíràn kú wọ́n sì níláti wà nínú ikú láìmọ ohunkóhun títí ìgbà wíwá Jesu láti fi àjíǹde sókè ọ̀run san èrè fún wọn. Ìdí nìyẹn tí a fi kà pé Kristian ajẹ́rìíkú àkọ́kọ́, Stefanu, “sùn nínú ikú.”—Iṣe 7:60; 1 Tessalonika 4:13.
Àjíǹde Sí Ìyè Lórí Ilẹ̀-Ayé
Ṣùgbọ́n ìlérí tí Jesu ṣe fún ọ̀daràn náà tí ó kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn Ju nígbà yẹn, ọkùnrin yìí gbàgbọ́ pé Ọlọrun yóò rán Messia kan tí yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ tí yóò sì mú àlàáfíà àti àìléwu padàbọ̀sípò fún orílẹ̀-èdè àwọn Ju lórí ilẹ̀-ayé. (Fi 1 Awọn Ọba 4:20-25 wéra pẹ̀lú Luku 19:11; 24:21 àti Iṣe 1:6.) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, aṣebi náà sọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ jáde pé Jesu ni Ẹni náà gan-an tí Ọlọrun yàn láti jẹ́ Ọba. Síbẹ̀, ní ìṣẹ́jú yẹn, ikú Jesu tí ó súnmọ́lé gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan tí a dẹ́bi fún mú kí èyí dàbí ohun kan tí kò lè rí bẹ́ẹ̀. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jesu tún fi mú un dá ọ̀daràn náà lójú nípa nínasẹ̀ ìlérí Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ní òótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Iwọ yoo wà pẹlu mi ni Paradise.”—Luku 23:42, 43, NW.
Àwọn ìtumọ̀ Bibeli tí wọ́n fi àmì ìdánudúró díẹ̀ ṣáájú “lónìí” dá ìṣòro kan sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ Jesu. Jesu kò lọ sí paradise kankan ní ọjọ́ yẹn gangan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sùn nínú ikú láìlèṣe ohunkóhun fún ọjọ́ mẹ́ta títí tí Ọlọrun fi jí i dìde. Àní lẹ́yìn àjíǹde àti ìgòkè re ọ̀run Jesu pàápàá, ó níláti dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Baba rẹ̀ títí tí àkókò náà fi dé fún un láti ṣàkóso lé aráyé lórí gẹ́gẹ́ bí Ọba. (Heberu 10:12, 13) Láìpẹ́, àkóso Ìjọba Jesu yóò mú ìtura wá fún aráyé yóò sì yí gbogbo ilẹ̀-ayé padà sí paradise. (Luku 21:10, 11, 25-31) Nígbà náà ni òun yóò mú ìlérí rẹ̀ fún ọ̀daràn náà ṣẹ nípa jíjí i dìde sí ìwàláàyè lórí ilẹ̀-ayé. Jesu yóò sì wà pẹ̀lú ọkùnrin náà níti pé Òun yóò ran ọkùnrin náà lọ́wọ́ láti bójútó àwọn àìní rẹ̀, títíkan àìní náà láti mú ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin òdodo ti Ọlọrun.
Àjíǹde Ọ̀pọ̀ Ènìyàn
Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú ọ̀daràn tí ó ronúpìwàdà yẹn, àjíǹde àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jùlọ yóò wáyé níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ète Ọlọrun fún dídá ènìyàn. Ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ ni a fi sínú ọgbà paradise tí a sì sọ fún láti ṣèkáwọ́ ilẹ̀-ayé. Bí wọ́n bá ti jẹ́ onígbọràn sí Ọlọrun ni, wọn kìbá tí dàgbà di arúgbó kí wọ́n sì kú. Ní àkókò yíyẹ lójú Ọlọrun, gbogbo ilẹ̀-ayé pátá ni à bá ti ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí a sì sọ ọ́ di paradise yíká ilẹ̀-ayé kan nípasẹ̀ Adamu àti àwọn àtọmọdọ́mọ pípé rẹ̀.—Genesisi 1:28; 2:8, 9.
Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé Adamu àti Efa mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, wọ́n mú ikú wá sórí araawọn àti àwọn ọmọ wọn ọjọ́ iwájú. (Genesisi 2:16, 17; 3:17-19) Ìdí nìyẹn tí Bibeli fi sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti . . . ipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan [Adamu] wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀; bẹ́ẹ̀ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Romu 5:12.
Ènìyàn kanṣoṣo ni ó wà tí a tíì bí tí ó bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá. Ìyẹn ni Ọmọkùnrin pípé ti Ọlọrun, Jesu Kristi, ìwàláàyè ẹni tí a ta àtaré rẹ̀ láti ọ̀run sínú ilé-ọlẹ̀ wúndíá Ju kan, Maria. Jesu kò dẹ́ṣẹ̀ kò sì yẹ fún ṣíṣekúpa. Nítorí náà, ikú rẹ̀ ní ìtóye ìràpadà nítorí “ẹ̀ṣẹ̀ ayé.” (Johannu 1:29; Matteu 20:28) Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jesu fi lè sọ pé: “Èmi ni àjíǹde, àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.”—Johannu 11:25.
Bẹ́ẹ̀ni, níti gidi, ìwọ lè fọkànṣìkẹ́ ìrètí dídi ẹni tí a tún sopọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ rẹ tí wọ́n ti kú, ṣùgbọ́n èyí béèrè pé kí o lo ìgbàgbọ́ nínú Jesu gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà rẹ kí o sì ṣègbọ́ràn sí i gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọrun yànsípò. Láìpẹ́ Ìjọba Ọlọrun yóò gbá gbogbo ìwà búburú kúrò lórí ilẹ̀-ayé yìí. Gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n kọ̀ láti tẹríba fún ìṣàkóso rẹ̀ ni a óò parun. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ-abẹ́ Ìjọba Ọlọrun yóò làájá wọn yóò sì mú ọwọ́ araawọn dí nínú iṣẹ́ sísọ ilẹ̀-ayé di paradise.—Orin Dafidi 37:10, 11; Ìfihàn 21:3-5.
Lẹ́yìn náà ni àkókò tí ń múniláyọ̀ náà yóò dé fún àjíǹde láti bẹ̀rẹ̀. Ìwọ yóò ha wà níbẹ̀ láti kí àwọn òkú káàbọ̀ bí? Gbogbo rẹ̀ sinmi lórí ohun tí o bá ṣe nísinsìnyí. Àwọn ìbùkún àgbàyanu ń dúró de gbogbo àwọn tí wọ́n bá tẹríba nísinsìnyí fún ìṣàkóso Ìjọba Jehofa nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi.