Báwo Lo Ṣe Ń Fúnni Ní Ìmọ̀ràn?
Ǹjẹ́ wọ́n ti sọ fún ẹ rí pé kó o fún àwọn èèyàn kan ní ìmọ̀ràn? Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ wọ́n ti bi ẹ́ ní àwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ni kí n ṣe? Ṣé kí n lọ sí ibi àpèjẹ yìí? Ṣé kí n ṣe iṣẹ́ yìí? Ṣé mo lè máa fẹ́ ẹni yìí sọ́nà ká lè jọ ṣe ìgbéyàwó?’
Àwọn tí kò ní èrò burúkú lọ́kàn lè sọ fún ẹ pé kó o ran àwọn lọ́wọ́ lórí àwọn ìpinnu tí wọ́n fẹ́ ṣe. Ó lè jẹ́ àwọn ìpinnu tó máa nípa lórí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, ìdílé wọn tàbí Jèhófà pàápàá. Orí kí lo máa gbé ìdáhùn tó o máa fún wọn kà? Ọ̀nà wo lo máa ń gbà fún àwọn èèyàn ní ìmọ̀ràn? Yálà ọ̀rọ̀ náà jẹ́ èyí tí kò tó nǹkan tàbí kó jẹ́ èyí tó lágbára gan-an, máa fi ohun tí Òwe 15:28 sọ sọ́kàn pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” Jẹ́ ká wo bí àwọn ìlànà Bíbélì márùn-ún tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ń fúnni ní ìmọ̀ràn.
1 Fi Òye Mọ Bí Ọ̀rọ̀ Ṣe Rí Gan-an.
“Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.”—ÒWE 18:13.
Ká lè fúnni ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ipò tó yí ẹni tó fẹ́ gba ìmọ̀ràn náà ká àti ojú tó fi wo ọ̀ràn náà. Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé ẹnì kan pè ẹ́ tó sì ní kó o júwe ọ̀nà tó yá jù lọ tí òun lè gbà dé ilé rẹ, kí lo máa fẹ́ béèrè lọ́wọ́ ẹni náà kó lè rọrùn fún ẹ láti ràn án lọ́wọ́? Ṣé wàá lè sọ ọ̀nà tó dára jù lọ pé kí ẹni náà gbà fún un láìjẹ́ pé o kọ́kọ́ mọ ibi tó wà gan-an? Ó dájú pé o kò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Bákan náà, kó o tó lè fún ẹnì kan ní ìtọ́sọ́nà tó tọ́, o ní láti fòye mọ “ibi” tí ẹni tó fẹ́ gba ìmọ̀ràn náà wà, ìyẹn ni ipò tó yí i ká àti ojú tó fi ń wo ọ̀ràn náà. Ǹjẹ́ àwọn ohun kan wà tó jẹ́ pé tá a bá gbé wọn yẹ̀ wò, wọ́n lè nípa lórí èsì tá a máa fún onítọ̀hún? Tí a kò bá mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí gan-an, a lè fún ẹni náà ní ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ tojú sú u.—Lúùkù 6:39.
Mọ Ibi Tí Ẹni Náà Ti Ṣe Ìwádìí Dé. Ó tún máa bọ́gbọ́n mu láti bi ẹni tó fẹ́ gba ìmọ̀ràn ní àwọn ìbéèrè bíi: “Àwọn ìlànà Bíbélì wo lo rò pé ó bá ọ̀rọ̀ yìí mu?” “Àwọn àǹfààní àti àwọn ìpalára wo lo rò pé ó wà nínú àwọn nǹkan tó o ronú láti ṣe?” “Àwọn ìwádìí wo lo ti ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí?” “Ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn míì ti ṣe fún ẹ, bóyá àwọn alàgbà ìjọ rẹ, àwọn òbí rẹ tàbí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?”
Èsì tó bá fún wa máa jẹ́ ká mọ ìsapá tí ẹni náà ti ṣe láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ̀. Bákan náà, a lè jẹ́ kí ìmọ̀ràn wa dá lórí ohun tó ṣeé ṣe kí àwọn míì ti sọ fún un. A tún lè fòye mọ̀ bóyá ńṣe ni ẹni náà kàn ń wá agbaninímọ̀ràn tó máa ‘rìn ín ní etí’ nípa fífún un ní irú ìmọ̀ràn tó fẹ́ gbọ́.—2 Tím. 4:3.
2 Ronú Kó O Tó Dáhùn.
“Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—JÁK. 1:19.
A lè yára fún ẹni náà lésì, torí pé a fẹ́ ràn án lọ́wọ́. Àmọ́, ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu ká máa sọ̀rọ̀ lórí ohun kan tí a kò tíì ṣe ìwádìí nípa rẹ̀? Òwe 29:20 sọ pé: “Ìwọ ha ti rí ènìyàn tí ń fi ìkánjú sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ìrètí ń bẹ fún arìndìn jù fún un lọ.”
Fi àkókò tó pọ̀ tó sílẹ̀ kí ọ̀nà tó o máa gbà bójú tó ọ̀rọ̀ náà lè bá ọgbọ́n Ọlọ́run mu. Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ìrònú àti “ẹ̀mí ayé” tó yí mi ká ò ti máa nípa lórí bí mo ṣe ń ronú?’ (1 Kọ́r. 2:12, 13) Má ṣe gbàgbé pé níní èrò tó dáa nìkan kò tó. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti gbọ́ nípa iṣẹ́ tó nira tó já lé Jésù léjìká, ó gbà á nímọ̀ràn pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Pétérù ṣe yìí? Bí ẹni tí kò ní ohun búburú lọ́kàn pàápàá kò bá ṣọ́ra, ó lè fúnni ní ìmọ̀ràn tó jẹ́ èrò èèyàn lásán, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ fún Pétérù pé, “kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.” (Mát. 16:21-23) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa ronú kó tó sọ̀rọ̀! Ó ṣe tán, ohun tá a mọ̀ kò tó nǹkan kan tá a bá fi wé ọgbọ́n Ọlọ́run.—Jóòbù 38:1-4; Òwe 11:2.
3 Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
“Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.”—JÒH. 8:28.
Ǹjẹ́ wàá sọ pé, “Tó bá jẹ́ èmi ni, ǹ bá . . .”? Kódà bí ìdáhùn sí ìbéèrè kan bá ṣe kedere, ó máa dára kó o kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà tí Jésù fi lélẹ̀. Ó ní ọgbọ́n àti ìrírí tó ju ti èèyàn èyíkéyìí lọ fíìfíì; síbẹ̀ ó sọ pé: “Èmi kò sọ̀rọ̀ láti inú agbára ìsúnniṣe ti ara mi, ṣùgbọ́n Baba fúnra rẹ̀ . . . ti fún mi ní àṣẹ kan ní ti ohun tí èmi yóò wí àti ohun tí èmi yóò sọ.” (Jòh. 12:49, 50) Gbogbo ìgbà ni ẹ̀kọ́ Jésù àti ìmọ̀ràn tó ń fúnni máa ń dá lórí ohun tí Baba rẹ̀ fẹ́.
Bí àpẹẹrẹ, a rí i kà nínú Lúùkù 22:49 pé nígbà tí wọ́n fẹ́ fi àṣẹ ọba mú Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé kí àwọn bá wọn jà. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn lo idà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tí Jésù wà ní àkókò yẹn kò fara rọ̀, àkọsílẹ̀ míì nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó wà nínú Mátíù 26:52-54, fi hàn pé ó fàyè sílẹ̀ láti fèròwérò pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà. Jésù mọ ìlànà tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 9:6 àti àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Sáàmù 22 àti Aísáyà 53, torí náà ó ṣeé ṣe fún un láti fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó mọ́gbọ́n dání èyí tó gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là, tó sì dùn mọ́ Jèhófà nínú.
4 Ṣe Ìwádìí Nínú Àwọn Ìtẹ̀jáde Ètò Ọlọ́run.
“Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?”—MÁT. 24:45.
Jésù ti yan ẹgbẹ́ ẹrú kan tó ṣeé fọkàn tán tó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì gan-an. Tó o bá ń fúnni ní ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà nípa àwọn ọ̀ràn pàtàkì kan, ǹjẹ́ o máa ń fi àkókò sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì?
A máa ń rí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tó ṣe kedere nínú ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index àti àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM, [Watchtower Library on CD-ROM].a Àṣìṣe ló máa jẹ́ tá a bá gbójú fo ohun èlò tó ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tó jíire yìí! Ó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àkòrí àti ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ tó máa ṣèrànwọ́ fún ẹni tó ń wá ìmọ̀ràn. Báwo lo ṣe já fáfá tó nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá àwọn ìlànà Bíbélì lórí ọ̀ràn kan, kí wọ́n sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ? Bí àwòrán ilẹ̀ tó péye ṣe lè tọ́ ẹnì kan sọ́nà kó bàa lè dé ibi tó ń lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ṣíṣe ìwádìí nínú àwọn ohun èlò wọ̀nyí ṣe lè jẹ́ kí ẹnì kan mọ ọ̀nà tí òun ń tọ̀, kó sì fòye mọ bí yóò ṣe máa rìn nìṣó ní ojú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.
Ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà ló ti kọ́ àwọn akéde láti wá àwọn àpilẹ̀kọ nínú ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index àti àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM, [Watchtower Library on CD-ROM], wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ ran àwọn ará lọ́wọ́ láti lè máa ronú lórí ohun tí wọ́n bá kà nínú Ìwé Mímọ́. Irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí àwọn akéde lè máa mójú tó ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn lọ́wọ́lọ́wọ́, wọ́n á sì tún mọ bí èèyàn ṣe ń dá ṣe ìwádìí, kí wọ́n sì gbára lé àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Héb. 5:14.
5 Ṣọ́ra fún Ṣíṣe Ìpinnu fún Àwọn Èèyàn.
“Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”—GÁL. 6:5.
Lákòótán, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa dá pinnu irú ìtọ́sọ́nà àti ìmọ̀ràn tí òun máa tẹ̀ lé. Jèhófà fún gbogbo wa ní òmìnira láti pinnu bóyá a ó gbà kí àwọn ìlànà òun máa darí wa tàbí a kò ní gbà. (Diu. 30:19, 20) Àwọn ipò kan máa ń gba pé kéèyàn lo àwọn ìlànà mélòó kan nínú Bíbélì, àmọ́ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ẹni tó ń wá ìmọ̀ràn fúnra rẹ̀ ló máa pinnu ohun tó máa ṣe. Ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan fi lọ̀ wá àti ọjọ́ orí ẹni náà tún lè mú ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo tiẹ̀ ní àṣẹ láti bojú tó ọ̀rọ̀ yìí?’ Àwọn ọ̀rọ̀ míì wà tó jẹ́ pé àwọn alàgbà ìjọ ló máa dára ká darí rẹ̀ sí, tó bá sì jẹ́ ọmọdé lẹni tó fẹ́ gba ìmọ̀ràn náà, ká sọ fún un pé kó lọ sọ fáwọn òbí rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM, [Watchtower Library on CD-ROM] wà ní èdè mọ́kàndínlógójì [39]. Ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index wà ní èdè márùnlélógójì [45].
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Iṣẹ́ Àjùmọ̀ṣe Nígbà Ìjọsìn Ìdílé
Nígbà Ìjọsìn Ìdílé, ẹ jùmọ̀ ṣe ìwádìí kẹ́ ẹ lè wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn ti béèrè lọ́wọ́ yín lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn ìlànà Bíbélì wo lẹ lè rí tó máa ran ẹni tó bi yín ní irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan bi ẹ́ nípa fífẹ́ ẹnì kan sọ́nà. Tó o bá ń lo atọ́ka Watch Tower Publications Index tàbí àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM, [Watchtower Library on CD-ROM] kókó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ohun tó ò ń wá jù lọ ni kó o kọ́kọ́ wò. Bí àpẹẹrẹ, nínú atọ́ka, o lè wo kókó ọ̀rọ̀ náà, “Dating” [Fífẹ́ra ẹni] tàbí “Marriage” [Ìgbéyàwó]. Lẹ́yìn náà, kó o wá wo àwọn ìsọ̀rí tó wà lábẹ́ kókó ọ̀rọ̀ yẹn láti wá àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tó o bá ń wo kókó ọ̀rọ̀ kan, kíyè sí i bóyá wàá rí gbólóhùn náà, “See also” [Tún wo], èyí tó ṣeé ṣe kó túbọ̀ tọ́ka ní tààràtà sí ohun tó ò ń wá.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
A dúpẹ́ fún àwọn ohun tí Jèhófà pèsè fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀, a lè fúnni ní ìmọ̀ràn tó dára, a sì tún lè rí ìmọ̀ràn tó dára gbà. Oníwàásù 12:11 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣó tí a gbá wọlé ni àwọn tí ó jọ̀wọ́ ara wọn fún àkójọ àwọn gbólóhùn; láti ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan ni a ti fi wọ́n fúnni.” Bí “ọ̀pá kẹ́sẹ́,” ìyẹn igi ẹlẹ́nu ṣóńṣó tí wọ́n fi máa ń darí ẹran tó ń fa ẹrù, bẹ́ẹ̀ náà ni ìtọ́sọ́nà tá a fúnni tìfẹ́tìfẹ́ tó sì wúlò ṣe máa ń tọ́ àwọn olóòótọ́ ọkàn sí ọ̀nà tó tọ́. “Ìṣó tí a gbá wọlé” máa ń jẹ́ kí nǹkan dúró sán-ún. Bákan náà, tá a bá fúnni ní ìmọ̀ràn tó dára, ó máa ń jẹ́ kéèyàn kẹ́sẹ járí. Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń ‘jọ̀wọ́ ara wọn fún àkójọ àwọn gbólóhùn’ tó ṣàgbéyọ ọgbọ́n Jèhófà tó jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn” wọn tàbí kí wọ́n ní inú dídùn sí i.
Jẹ́ kí ìmọ̀ràn rẹ máa dá lórí ọ̀rọ̀ Olùṣọ́ Àgùntàn náà. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti tẹ́tí sí àwọn èèyàn ká sì fún wọn ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ nígbà tá a bá lè ṣe bẹ́ẹ̀! Tá a bá gbé ìmọ̀ràn wa karí àwọn ìlànà Bíbélì, ó máa jẹ́ èyí tó wúlò, ó sì lè ṣe ẹni tá a bá fún ní àǹfààní ayérayé.