“Gbogbo Ojúṣe Ènìyàn”
“Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ náà kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe ènìyàn.”—ONÍWÀÁSÙ 12:13, NW.
1, 2. Èé ṣe tí ó fi yẹ láti gbé ojúṣe wa sí Ọlọ́run yẹ̀ wò?
“KÍ NI Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?” Wòlíì ìgbàanì kan ni ó béèrè ìbéèrè yẹn. Lẹ́yìn náà, ó sọ ohun tí Jèhófà ń béèrè pàtó—lo ìdájọ́ òdodo, nífẹ̀ẹ́ inúrere, kí o sì rìn lọ́nà ìmẹ̀tọ́mọ̀wà pẹ̀lú Ọlọ́run.—Míkà 6:8, NW.
2 Ní àwọn àkókò oníkóńkó jabele àti ẹlẹ́mìí ìdáwàlómìnira yìí, ọ̀pọ̀ ni èrò náà pé Ọlọ́run ń béèrè ohun kan lọ́wọ́ wọn kò tù lára. Wọn kò fẹ́ ojúṣe kankan. Ṣùgbọ́n, ìparí èrò tí Sólómọ́nì dé nínú Oníwàásù ńkọ́? “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbogbo ohun tí a ti gbọ́, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ náà, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13, NW.
3. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ronú gidigidi lórí ìwé Oníwàásù?
3 Láìka ipò àyíká wa àti ojú ìwòye wa nípa ìgbésí ayé sí, a lè jàǹfààní gidigidi bí a bá gbé ohun tí ó ṣamọ̀nà sí ìparí èrò yẹn yẹ̀ wò. Ọba Sólómọ́nì, ẹni tí ó kọ ìwé tí a mí sí yìí, gbé díẹ̀ lára àwọn ohun tí ó jẹ́ apá kan ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ yẹ̀ wò. Àwọn kan lè hára gàgà parí èrò sí pé, àwọn ìfọ́síwẹ́wẹ́ rẹ̀ kò gbéni ró. Síbẹ̀, Ọlọ́run mí sí i, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àwọn ìgbòkègbodò àti àwọn ohun àkọ́múṣe wa yẹ̀ wò, tí yóò sì yọrí sí ìdùnnú tí ó pọ̀ sí i.
Kíkojú Lájorí Àníyàn Ìgbésí Ayé
4. Kí ni Sólómọ́nì ṣàyẹ̀wò tí ó sì jíròrò nínú Oníwàásù?
4 Sólómọ́nì yẹ ‘làálàá àwọn ọmọ ènìyàn’ wò kínníkínní. “Mo sì fi àyà mi sí àtiṣe àfẹ́rí òun àtiwádìí ọgbọ́n ní ti ohun gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.” Nípa “làálàá,” Sólómọ́nì kò fi dandan ní òwò tàbí iṣẹ́ lọ́kàn, bí kò ṣe gbogbo ohun tí ọkùnrin àti obìnrin ń sá sókè sódò lé lórí jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ ayé wọn. (Oníwàásù 1:13) Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn olórí àníyàn, tàbí làálàá kan yẹ̀ wò, kí a sì wá fi wọ́n wé àwọn ìgbòkègbodò àti ohun àkọ́múṣe àwa fúnra wa.
5. Kí ni ọ̀kan lára olórí làálàá ènìyàn?
5 Dájúdájú, owó ni lájorí ọ̀pọ̀ àníyàn àti ìgbòkègbodò ọ̀pọ̀ ènìyàn. Kò sí ẹni tí ó lè fẹ̀tọ́ sọ pé Sólómọ́nì ní ojú ìwòye aláìbìkítà nípa owó, tí àwọn olówó kan máa ń ní. Kò lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́wọ́ ìjẹ́pàtàkì níní owó díẹ̀ lọ́wọ́; níní owó tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́ sàn ju gbígbé ìgbésí ayé ìráàre tàbí ti òṣì. (Oníwàásù 7:11, 12) Ṣùgbọ́n, ó ti ṣeé ṣe kí o ti kíyè sí i pé, owó, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó lè rà, lè di góńgó àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé—fún àwọn òtòṣì àti fún àwọn ọlọ́rọ̀ pẹ̀lú.
6. Kí ni a lè rí kọ́ nípa owó láti inú ọ̀kan nínú àwọn àkàwé Jésù, àti láti inú ìrírí Sólómọ́nì fúnra rẹ̀?
6 Rántí àkàwé Jésù nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ láti ní púpọ̀ sí i, nítorí àìní ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ọlọ́run kà á sí akúrí ènìyàn. Èé ṣe? Nítorí pé ‘ìwàláàyè wa kò wá láti inú àwọn ohun tí a ní.’ (Lúùkù 12:15-21) Ìrírí Sólómọ́nì—tí ó ṣeé ṣe kí ó pọ̀ ju tiwa lọ—fìdí ọ̀rọ̀ Jésù múlẹ̀. Ka àpèjúwe náà nínú Oníwàásù 2:4-9. Fún àwọn àkókò kan, Sólómọ́nì pọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí kíkó ọrọ̀ jọ. Ó kọ́ àwọn ilé tí ó jojú ní gbèsè, ó sì ṣe àwọn ọgbà tí ó pinminrin. Agbára rẹ̀ gbé e láti ní àwọn òrékelẹ́wà obìnrin, ó sì ní wọn. Ǹjẹ́ ọrọ̀ àti gbogbo ohun tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún un láti ṣe mú ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀, ojúlówó ẹ̀mí àṣeyọrí, àti ète wá fún un nínú ìgbésí ayé bí? Ó dáhùn láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: “Nígbà tí mo wo gbogbo iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ṣe, àti làálàá tí mo ṣe làálàá láti ṣe: sì kíyè sí i, asán ni gbogbo rẹ̀ àti ìmúlẹ̀mófo, kò sì sí èrè kan lábẹ́ oòrùn.”—Oníwàásù 2:11; 4:8.
7. (a) Kí ni ìrírí fi hàn nípa ìjẹ́pàtàkì owó? (b) Kí ni ìwọ fúnra rẹ ti rí, tí ó ti ìparí èrò tí Sólómọ́nì dé lẹ́yìn?
7 Òtítọ́ gan-an nìyẹn, tí ó hàn gbangba nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ ènìyàn. A gbọ́dọ̀ gbà pé níní owó púpọ̀ sí i kò yanjú gbogbo ìṣòro. Ó lè yanjú díẹ̀, irú bíi mímú kí níní oúnjẹ àti aṣọ túbọ̀ rọrùn sí i. Ṣùgbọ́n, aṣọ kan ṣoṣo ni ẹnì kan lè wọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, kìkì ìwọ̀n oúnjẹ àti omi díẹ̀ ni ó sì lè gbádùn níjokòó ẹ̀ẹ̀kan. O sì ti kà nípa àwọn ọlọ́rọ̀ tí ìkọ̀sílẹ̀, ìmukúmu tàbí ìjoògùnyó, àti aáwọ̀ pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí ń pọ́n lójú. Olówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ náà, J. P. Getty, sọ pé: “Owó kò fi dandan ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ayọ̀. Ó ṣeé ṣe kí ó ní í ṣe pẹ̀lú àìláyọ̀ ṣá.” Fún ìdí rere, Sólómọ́nì ka nínífẹ̀ẹ́ fàdákà sí asán. Fi òkodoro òtítọ́ yẹn wé àkíyèsí tí Sólómọ́nì ṣe pé: “Dídùn ni oorun oníṣẹ́, ì báà jẹ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀: ṣùgbọ́n ìtẹ́lọ́rùn ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.”—Oníwàásù 5:10-12.
8. Ìdí wo ni ó wà tí kò fi yẹ láti fojú bàbàrà wo ìjẹ́pàtàkì owó?
8 Owó àti ohun ìní kì í fúnni ní ẹ̀mí ìtẹ́lọ́rùn nípa ọjọ́ ọ̀la. Bí o bá ní owó àti ohun ìní púpọ̀ sí i, ó ṣeé ṣe kí o ní àfikún àníyàn nípa pípa wọ́n mọ́, síbẹ̀, ìwọ kò sì ní mọ ohun tí ọ̀la yóò mú wá. O ha lè pàdánù gbogbo wọn, pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ bí? (Oníwàásù 5:13-17; 9:11, 12) Níwọ̀n bí èyí ti lè rí bẹ́ẹ̀, kò yẹ kí ó nira láti rí ìdí tí ó fi yẹ kí ìgbésí ayé wa, tàbí làálàá wa, ní ète gíga, tí ó wà pẹ́ títí ju owó àti àwọn ohun ìní.
Ìdílé, Òkìkí, àti Agbára
9. Èé ṣe tí ìgbésí ayé ìdílé fi jẹ yọ lọ́nà títọ́ nínú àyẹ̀wò Sólómọ́nì?
9 Ìfọ́síwẹ́wẹ́ tí Sólómọ́nì ṣe nípa ìgbésí ayé kan ọ̀ràn ṣíṣe làálàá nípa ìdílé. Bíbélì tẹnu mọ́ ìgbésí ayé ìdílé, títí kan ìdùnnú níní àwọn ọmọ àti títọ́ wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24; Orin Dáfídì 127:3-5; Òwe 5:15, 18-20; 6:20; Máàkù 10:6-9; Éfésù 5:22-33) Bí ó ti wù kí ó rí, ìyẹn ha ni apá tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé bí? Ó jọ bí ẹni pé ọ̀pọ̀ rò bẹ́ẹ̀, ní gbígbé ìtẹnumọ́ tí àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan gbé karí ìgbéyàwó, ọmọ, àti ìdè ìdílé yẹ̀ wò. Síbẹ̀, Oníwàásù 6:3 fi hàn pé, kódà níní ọgọ́rùn-ún ọmọ kì í ṣe àṣírí níní ìtẹ́lọ́rùn nínú ìgbésí ayé. Finú wòye iye òbí tí ó ti sapá nítorí àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n baà lè fún wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tí ó dára, kí wọ́n sì mú kí ìgbésí ayé wọn túbọ̀ rọrùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ohun tí ó wúni lórí, dájúdájú, Ẹlẹ́dàá wa kò ní i lọ́kàn pé kí lájorí ète wa nínú ìgbésí ayé jẹ́ bíbí ọmọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹranko tí máa ń ṣe lọ́nà àdánidá, láti lè mú kí irú ọ̀wọ́ wọn máa wà nìṣó.
10. Èé ṣe tí àfiyèsí tí kò tọ́ lórí ìdílé fi ń já sí asán?
10 Lọ́nà tí ó fi òye hàn, Sólómọ́nì mú àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ìgbésí ayé ìdílé jáde. Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè pọkàn pọ̀ sórí kíkó nǹkan jọ fún àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, wọn yóò ha jẹ́ ọlọgbọ́n bí? Àbí wọn yóò jẹ́ òmùgọ̀ ní ti ohun tí ó làkàkà láti kó jọ fún wọn? Bí ohun tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn bá ṣẹlẹ̀, ẹ wo irú ‘asán àti ibi ńláǹlà’ ti èyí yóò jẹ́!—Oníwàásù 2:18-21; Àwọn Ọba Kìíní 12:8; Kíróníkà Kejì 12:1-4, 9.
11, 12. (a) Ìlépa wo nínú ìgbésí ayé ni àwọn kan ti pọkàn pọ̀ lé lórí? (b) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé, lílépa òkìkí jẹ́ “ìmúlẹ̀mófo”?
11 Ní ìpẹ̀kun kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ ti fọwọ́ rọ́ ojúṣe ìgbésí ayé ìdílé tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu sẹ́yìn kí ọwọ́ wọn baà lè tẹ òkìkí tàbí agbára tí wọ́n ń fẹ́ láti ní lórí àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ọkùnrin ni wọ́n sábà máa ń jẹ̀bi èyí. Ìwọ ha ti rí èyí lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, tàbí àwọn aládùúgbò rẹ bí? Ọ̀pọ̀ ń gbékútà gidigidi láti di ẹni tí a kíyè si, láti di ènìyàn pàtàkì, tàbí láti lo agbára lórí àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n, báwo ni ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ ti ní ète nínú tó ní tòótọ́?
12 Ronú nípa bí àwọn kan ti ń làkàkà láti di olókìkí, bóyá ní ọ̀nà kékeré tàbí ní ọ̀nà ńlá. A ń rí i ní ilé ẹ̀kọ́, ní àdúgbò wa, àti ní onírúurú ẹgbẹ́ àwùjọ. Ó tún jẹ́ ipa tí ń ti àwọn tí ó fẹ́ di gbajúmọ̀ nínú iṣẹ́ ọgbọ́n ọnà, nínú eré ìnàjú, àti ìṣèlú. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ha ń ṣe ìsapá asán pátápátá bí? Sólómọ́nì, lọ́nà tí ó tọ́, pè é ní “ìmúlẹ̀mófo.” (Oníwàásù 4:4) Bí èwe kan tilẹ̀ di òléwájú nínú ẹgbẹ́, nínú ẹgbẹ́ eléré ìdíje, tàbí nínú ẹgbẹ́ olórin—tàbí ọkùnrin tàbí obìnrin kan ṣe orúkọ fún ara rẹ̀ ní ilé iṣẹ́ tàbí láwùjọ—ẹni mélòó ní ti gidi ni ó mọ̀ nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn ní apá ìbomíràn lágbàáyé (tàbí ní orílẹ̀-èdè kan náà pàápàá) mọ̀ pé ẹni náà ń bẹ láyé bí? Tàbí wọ́n wulẹ̀ ń bá ìgbésí ayé wọn lọ láìmọ nǹkan kan nípa òkìkí díẹ̀ tí ó ní? Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn rí ní ti agbára tàbí ọlá àṣẹ tí ẹnì kan lè ní lórí iṣẹ́, ní ìlú, tàbí láàárín àwùjọ.
13. (a) Báwo ni Oníwàásù 9:4, 5 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye títọ́ nípa lílépa òkìkí tàbí agbára? (b) Òkodoro òtítọ́ wo ni ó yẹ kí a dojú kọ bí ìgbésí ayé kò bá jù báyìí náà lọ? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.)
13 Kí ni irú òkìkí tàbí agbára bẹ́ẹ̀ ń yọrí sí nígbẹ̀yìngbẹ́yín? Bí ìran kan ti ń lọ, tí òmíràn sì ń bọ̀, àwọn olókìkí tàbí alágbára ènìyàn ń kú, a sì ń gbàgbé wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn rí ní ti àwọn kọ́lékọ́lé, òṣèré àti àwọn oníṣẹ́ ọnà míràn, àwọn atáwùjọtò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ti rí ní ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òṣèlú àti àwọn ọ̀gá ológun. Nínú gbogbo ẹ̀ka iṣẹ́ wọ̀nyẹn, ẹni mélòó ní pàtó ni o mọ̀, tí ó gbáyé láàárín àwọn ọdún 1700 sí 1800? Sólómọ́nì, ní ọ̀nà tí ó tọ́, sọ ọ̀rọ̀ sí ibi tí ọ̀rọ̀ wà, ní sísọ pé: “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ. Nítorí pé alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan, . . . ìrántí wọn ti di ìgbàgbé.” (Oníwàásù 9:4, 5) Bí ìgbésí ayé kò bá sì ju báyìí náà lọ, nígbà náà, lílépa òkìkí tàbí agbára jẹ́ asán ní tòótọ́.a
Ohun Tí A Darí Àfiyèsí Wa Sí àti Ojúṣe Wa
14. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ìwé Oníwàásù ràn wá lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan?
14 Sólómọ́nì kò sọ̀rọ̀ lórí ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò, góńgó, àti adùn tí àwọn ènìyàn gbé ìgbésí ayé wọn kà. Síbẹ̀, ohun tí ó kọ ti tó. Gbígbé ìwé náà yẹ̀ wò kò yẹ kí ó mú wa banú jẹ́ tàbí lérò òdì, nítorí pé a ti ṣàyẹ̀wò ìwé kan nínú Bíbélì tí Jèhófà Ọlọ́run dìídì mí sí fún àǹfààní wa láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀. Ó lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti mú ojú ìwòye wa nípa ìgbésí ayé àti ohun tí a darí àfiyèsí wa sí tọ́. (Oníwàásù 7:2; Tímótì Kejì 3:16, 17) Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì lójú ìwòye ìparí èrò tí Jèhófà ran Sólómọ́nì lọ́wọ́ láti dé.
15, 16. (a) Kí ni ojú ìwòye Sólómọ́nì nípa gbígbádùn ìgbésí ayé? (b) Kí ni Sólómọ́nì sọ, lọ́nà tí ó yẹ, pé ó pọn dandan láti lè gbádùn ìgbésí ayé?
15 Kókó kan tí Sólómọ́nì gbé dìde léraléra ni pé, ó yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ rí ìdùnnú nínú àwọn ìgbòkègbodò wọn níwájú Rẹ̀. “Èmi mọ̀ pé kò sí rere nínú wọn, bí kò ṣe kí ènìyàn kí ó máa yọ̀, kí ó sì máa ṣe rere ní ayé rẹ̀. Àti pẹ̀lú kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu, kí ó sì máa jadùn gbogbo làálàá rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníwàásù 2:24; 3:12, 13; 5:18; 8:15) Kíyè sí i pé, Sólómọ́nì kò fún wa níṣìírí láti máa ṣe àríyá aláriwo; bẹ́ẹ̀ sì ni kò fọwọ́ sí ẹ̀mí ìrònú ‘Ẹ jẹ́ kí á jẹ, kí á mu, kí á sì jayé orí wa, nítorí a óò kú lọ́la.’ (Kọ́ríńtì Kíní 15:14, 32-34) Ohun tí ó ní lọ́kàn ni pé, kí a rí ìgbádùn nínú adùn ojoojúmọ́, irú bíi jíjẹ àti mímu, bí a ti ‘ń ṣe rere nínú ayé wa.’ Ìyẹn, láìsí àníàní, darí ìgbésí ayé wa sórí ṣíṣe ìfẹ́ inú Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tí ń pinnu ohun tí ó jẹ́ rere ní tòótọ́.—Orin Dáfídì 25:8; Oníwàásù 9:1; Máàkù 10:17, 18; Róòmù 12:2.
16 Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Máa bá tìrẹ lọ, máa fi ayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, kí o sì máa fi inú dídùn mu ọtí wáìnì rẹ: nítorí pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ rẹ nísinsìnyí.” (Oníwàásù 9:7-9) Bẹ́ẹ̀ ni, ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó gbé ìgbésí ayé aláyọ̀, tí ó nítumọ̀ ní tòótọ́ jẹ́ ẹni tí ó kún fún iṣẹ́ tí inú Jèhófà dùn sí. Ìyẹn ń béèrè lọ́wọ́ wa láti máa ronú nípa rẹ̀ déédéé. Ẹ wo bí ojú ìwòye yìí ti yàtọ̀ tó sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn, tí wọ́n gbé ìgbésí ayé ka ìrònú ènìyàn!
17, 18. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe ń hùwà pa dà sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ìgbésí ayé? (b) Àbájáde wo ni ó yẹ kí a máa ní lọ́kàn nígbà gbogbo?
17 Bí àwọn ìsìn kan tilẹ̀ kọ́ni pé ayé mìíràn ń bẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ìgbésí ayé yìí nìkan ni ó dá àwọn lójú. O lè ti rí i kí wọ́n máa ṣe bí Sólómọ́nì ti ṣàpèjúwe: “Nítorí a kò mú ìdájọ́ ṣẹ kánkán sí iṣẹ́ búburú, nítorí náà àyà àwọn ọmọ ènìyàn múra pàápàá láti hùwà ibi.” (Oníwàásù 8:11) Àwọn tí kò tilẹ̀ kó wọnú àwọn iṣẹ́ búburú pàápàá fi hàn pé àwọn ohun ti ìsinsìnyí ni ó jẹ àwọn lógún. Ìdí kan nìyẹn tí owó, ohun ìní, ipò iyì, ọlá àṣẹ lórí àwọn ẹlòmíràn, ìdílé, tàbí irú àwọn ìfẹ́ ọkàn míràn bẹ́ẹ̀ fi ṣe pàtàkì ju bí ó ti yẹ lọ fún wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, Sólómọ́nì kò parí èrò síbẹ̀. Ó fi kún un pé: “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi nígbà ọgọ́rùn ún, tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, ṣùgbọ́n ní tòótọ́, èmi mọ̀ pé yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀: Ṣùgbọ́n kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gùn tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run.” (Oníwàásù 8:12, 13) Ní kedere, ó dá Sólómọ́nì lójú pé, yóò dára fún wa, bí a bá ‘bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.’ Ní ọ̀nà wo? A lè rí ìdáhùn nínú ìyàtọ̀ tí ó fà yọ. Jèhófà yóò ‘fa ọjọ́ wa gùn.’
18 Ní pàtàkì, ó yẹ kí àwọn tí ọjọ́ orí wọ́n ṣì kéré sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí òkodoro òtítọ́ dídájú hán-únhán-ún, tí ó ṣeé gbára lé náà pé, yóò dára fún wọn bí wọ́n bá bẹ̀rù Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣeé ṣe kí ìwọ fúnra rẹ ti rí i, ẹni tí ó mọ eré sá jù lọ lè fẹsẹ̀ kọ, kí ó sì pàdánù eré ìje náà. A lè ṣẹ́gun ẹgbẹ́ ọmọ ogun lílágbára kan. Oníṣòwò tí orí rẹ̀ pé dáradára lè bá ara rẹ̀ nínú ipò òṣì. Ọ̀pọ̀ àìdánilójú mìíràn sì ń mú kí a máà lè sọ pàtó bí ìgbésí ayé yóò ti rí. Ṣùgbọ́n èyí lè dá ọ lójú hán-únhán-ún pé: Ọ̀nà tí ó bọ́gbọ́n mu, tí ó sì dáni lójú jù lọ ni láti gbádùn ìgbésí ayé, bí o ti ń ṣe rere nínú àwọn òfin ìwà híhù Ọlọ́run, àti ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú rẹ̀. (Oníwàásù 9:11) Èyí kan kíkẹ́kọ̀ọ́ ohun ti ìfẹ́ inú Ọlọ́run jẹ́ láti inú Bíbélì, yíya ìgbésí ayé ẹni sí mímọ́ fún un, kí a sì di Kristẹni tí a batisí.—Mátíù 28:19, 20.
19. Báwo ni àwọn èwe ṣe lè lo ìgbésí ayé wọn, ṣùgbọ́n ọ̀nà wo ni ó bá ọgbọ́n mu?
19 Ẹlẹ́dàá kì yóò fipá mú àwọn èwe tàbí àwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Wọ́n lè ri ara wọn bọ inú ẹ̀kọ́ ìwé, bóyá kí wọ́n tilẹ̀ di akẹ́kọ̀ọ́ àìlóǹkà ìwé èrò orí ènìyàn títí ayé wọn. Bópẹ́bóyá, ìyẹn yóò kó àárẹ̀ bá ara. Wọ́n sì lè rìn ní àwọn ọ̀nà àìpé ọkàn àyà wọn ti ẹ̀dá ènìyàn tàbí kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ohun tí ń fa ojú mọ́ra. Ìyẹn dájúdájú yóò mú ìrora ọkàn wá, ìgbésí ayé tí a sì tipa bẹ́ẹ̀ gbé yóò já sí asán. (Oníwàásù 11:9–12:12; Jòhánù Kíní 2:15-17) Nítorí náà, Sólómọ́nì pàrọwà fún àwọn èwe—àrọwà tí ó yẹ kí a gbé yẹ̀ wò dáradára, láìka ọjọ́ orí wa sí: “Rántí ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí ní ọjọ́ èwe rẹ, nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé, àti tí ọdún kò tí ì sún mọ́ etílé, nígbà tí ìwọ óò wí pé, èmi kò ní inú dídùn nínú wọn.”—Oníwàásù 12:1.
20. Ojú ìwòye wo ni ó wà déédéé nípa ìhìn iṣẹ́ tí ó wà nínú Oníwàásù?
20 Ìparí èrò wo ni ó yẹ kí a dé, nígbà náà? Tóò, ìparí èrò tí Sólómọ́nì dé ńkọ́? Ó rí, tàbí ṣàyẹ̀wò, “iṣẹ́ gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn; sì kíyè sí i, asán ni gbogbo rẹ̀ àti ìmúlẹ̀mófo.” (Oníwàásù 1:14) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọkùnrin olófìn-íntótó tàbí oníbànújẹ́ ọkàn ni a rí nínú ìwé Oníwàásù. Wọ́n jẹ́ apá kan Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, tí ó sì yẹ kí a gbé yẹ̀ wò.
21, 22. (a) Àwọn apá ìgbésí ayé wo ni Sólómọ́nì gbé yẹ̀ wò? (b) Orí ìparí èrò bíbọ́gbọ́nmu wo ni ó dé? (d) Báwo ni ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí ó wà nínú Oníwàásù ṣe nípa lórí rẹ?
21 Sólómọ́nì ṣèwádìí làálàá, ìsásókèsódò, àti ìlépa ènìyàn. Ó ronú lórí bí àwọn nǹkan ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́, ìjákulẹ̀ àti òfo tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń nírìírí rẹ̀. Ó gbé ìjóòótọ́ àìpé ènìyàn àti ikú tí ó yọrí sí yẹ̀ wò. Ó gbé ipò àwọn òkú àti ìrètí ìgbésí ayé ọjọ́ ọ̀la èyíkéyìí yẹ̀ wò, nínú ìmọ̀ tí Ọlọ́run fi fún un. Gbogbo èyí ni ọkùnrin tí Ọlọ́run ṣàlékún ọgbọ́n rẹ̀ gbé yẹ̀ wò, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀kan lára àwọn ènìyàn ọlọgbọ́n jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí. Lẹ́yìn náà, a kọ ìparí èrò tí ó dé sínú Ìwé Mímọ́, fún àǹfààní gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ìgbésí ayé tí ó ní ète. Kò ha yẹ kí a fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ bí?
22 “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbogbo ohun tí a ti gbọ́, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ náà kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe ènìyàn. Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ fúnra rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sí ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó fara sin, yálà ó jẹ́ rere tàbí ibi.”—Oníwàásù 12:13, 14, NW.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà kan, Ilé Ìṣọ́ ṣe àlàyé yìí tí ó fi ìjìnlẹ̀ òye hàn pé: “Kò yẹ kí a fi ìgbésí ayé yìí ṣòfò sórí àwọn ohun asán . . . Bí ìgbésí ayé kò bá ju báyìí náà lọ, a jẹ́ wí pé kò ṣe pàtàkì. Ìgbésí ayé yìí dà bíi bọ́ọ̀lù tí a jù sókè, tí kò pẹ́ tí ó fi tún bọ́ sílẹ̀. Ó dà bí òjìji tí ń sáré kọjá lọ, bí òdòdó tí ń rọ, bíi gaga ewé tí a óò gé kúrò, tí yóò sì gbẹ láìpẹ́. . . . Lórí ìwọ̀n ayérayé, gígùn ọjọ́ ayé wa jẹ́ eruku bíńtín. Bí a bá fi àkókò wé odò tí ń ṣàn, ìgbésí ayé wa kò tilẹ̀ tó èékán kan. Dájúdájú, [Sólómọ́nì] tọ̀nà nígbà tí ó ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ ìdàníyàn àti ìgbòkègbodò ènìyàn nínú ìgbésí ayé, tí ó sì sọ pé asán ni wọ́n. A kì í pẹ́ kú, ì bá tilẹ̀ dára kání a kò wá rárá, ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tí ń wá tí ń lọ, tí ọ̀pọ̀ kò tilẹ̀ mọ̀ pé a wá rárá. Ojú ìwòye yìí kì í ṣe ti aṣòfìn-íntótó tàbí ti amúnibanújẹ́ tàbí ti amúnisoríkọ́ tàbí ti amúnigbọ̀n-jìnnìjìnnì. Bí ìgbésí ayé kò bá ju báyìí náà lọ, a jẹ́ pé ojú ìwòyé yìí jẹ́ òtítọ́, òkodoro òtítọ́ pọ́nńbélé, tí ó sì gbéṣẹ́.”—August 1, 1957, ojú ìwé 472 (Gẹ̀ẹ́sì).
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni àgbéyẹ̀wò bíbọ́gbọ́nmu nípa ipa tí ohun ìní ń kó nínú ìgbésí ayé rẹ?
◻ Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a gbé àfiyèsí tí kò yẹ karí ìdílé, òkìkí, tàbí ọlá àṣẹ lórí àwọn ẹlòmíràn?
◻ Ẹ̀mí ìrònú àtọ̀runwá wo nípa ìgbádùn ni Sólómọ́nì fún níṣìírí?
◻ Báwo ni o ṣe jàǹfààní tó nínú gbígbé ìwé Oníwàásù yẹ̀ wò?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Owó àti ohun ìní kò mú ìtẹ́lọ́rùn dáni lójú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
A lè mú un dá àwọn ọ̀dọ́ lójú pé yóò dára fún wọn bí wọ́n bá bẹ̀rù Ọlọ́run