Kí Ni Èrò Rẹ Nípa Ikú?
IKÚ ń kó jìnnìjìnnì báni bá a ṣe ń lọ, tí à ń bọ̀ lójoojúmọ́, à báà jẹ́ abarapá tàbí olówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ikú lè ká wa mọ́ ibi tá a ti fẹ́ sọdá títì, tàbí kó wọlé wẹ́rẹ́ báni lórí ibùsùn. Irú àjálù burúkú tó wáyé nígbà tí àwọn amòòkùn-ṣìkà ṣọṣẹ́ ní September 11, 2001, nílùú New York City àti nílùú Washington, D.C., jẹ́ ká rí i kedere pé ikú, tó jẹ́ “ọ̀tá ìkẹyìn,” ń pa àti olówó àti tálákà, àtọmọdé àtàgbà. Àní nígbà mìíràn ó ń pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:26.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú ń kó jìnnìjìnnì báni, síbẹ̀ ó jọ pé ó ń fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra. Ó jọ pé ìròyìn nípa ikú làwọn èèyàn máa ń fẹ́ kà jù lọ nínú ìwé ìròyìn, òun ni wọ́n sì máa ń wò jù lọ lórí tẹlifíṣọ̀n, àgàgà bó bá jẹ́ ìròyìn nípa àjálù burúkú tó pa àwọn èèyàn lọ rẹpẹtẹ. Ìròyìn nípa ikú kì í sú àwọn èèyàn, ì báà jẹ́ èyí tí ogun fà, tàbí èyí tí àjálù, ìwà ọ̀daràn tàbí àrùn fà. Ibi tí ọ̀ràn ikú gba àwọn èèyàn lọ́kàn dé tún máa ń hàn nínú bí wọ́n ṣe ń bara jẹ́ gan-an nígbà táwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn àtàwọn gbajúgbajà bá kú.
Gbogbo ìṣarasíhùwà yìí kò ṣeé sẹ́. Ọ̀rọ̀ nípa ikú ṣì ń gba àwọn èèyàn lọ́kàn—ìyẹn bó bá jẹ́ ikú tàwọn ẹlòmíràn. Àmọ́, wọn kì í fẹ́ ronú rárá nípa ikú tara wọn. Ọ̀ràn nípa ikú tiwa jẹ́ ọ̀kan lára kókó tí ọ̀pọ̀ nínú wa kì í fẹ́ ronú kàn rárá.
Ṣé Àdììtú Ni Ikú?
Àyà wa máa ń já nígbà tá a bá rántí pé ikú lè pa àwa alára. Kò sì lè ṣe kí ó máà rí bẹ́ẹ̀. Èé ṣe? Ìdí ni pé Ọlọ́run ti gbin ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé sí wa lọ́kàn. Oníwàásù 3:11 sọ pé: “O fi aiyeraiye si wọn li aiya,” gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ Bibeli Mimọ ṣe kà. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àìrí ọgbọ́n dá sọ́ràn ikú ń jẹ́ káwọn ìbéèrè kan tí ń dani lọ́kàn rú máa jà gùdù lọ́kàn ọmọ aráyé. Kí aráyé lè rí ojútùú sí ìbéèrè wọ̀nyí, kí ó sì ṣeé ṣe láti tẹ́ ìfẹ́ àdámọ́ni tí wọ́n ní láti máa wà láàyè nìṣó lọ́rùn, wọ́n ti gbé onírúurú ẹ̀kọ́ jáde, látorí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn títí dórí ìgbàgbọ́ nínú àtúnwáyé.
Bó ti wù kó rí, nǹkan ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ tí ń kóni láyà sókè ni ikú jẹ́. Ibi gbogbo làwọn èèyàn sì ti ń bẹ̀rù rẹ̀. Abájọ tí ọ̀ràn ikú fi di ẹtì sí ọmọ aráyé lọ́rùn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ikú jẹ́ kí ó ṣe kedere pé òtúbáńtẹ́ ni kéèyàn máa fi gbogbo ọjọ́ ayé lépa ọrọ̀ àti agbára.
Ṣé Kì Í Ṣe Pé Àwọn Èèyàn Ń Sá Fini Sílẹ̀ Lọ́jọ́ Ikú?
Láyé àtijọ́, wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn tí àìsàn tó máa yọrí sí ikú bá ń ṣe tàbí àwọn tó fara gbọgbẹ́ ikú, gbé ẹ̀mí mì síbi tí wọ́n ń gbé, ìyẹn ní ilé tiwọn fúnra wọn. Bó ṣe rí nìyẹn lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì. Àṣà yẹn ṣì wà láwọn àdúgbò kan lóde òní. (Jẹ́nẹ́sísì 49:1, 2, 33) Ní irú àdúgbò bẹ́ẹ̀, wọ́n á pèpàdé ẹbí, wọ́n á gbọ́ tẹnu kálukú, títí kan àwọn ọmọdé pàápàá. Èyí á jẹ́ kí kálukú nínú ìdílé náà mọ̀ pé òun nìkan kọ́ ni ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Yóò sì jẹ́ kí gbogbo ẹbí máa tu ara wọn nínú lẹ́nì kìíní kejì, kí wọ́n sì jẹ́ alábàárò ara wọn lákòókò ọ̀fọ̀ náà.
Èyí yàtọ̀ pátápátá sóhun tí ń ṣẹlẹ̀ ní àdúgbò tí sísọ̀rọ̀ nípa ikú ti jẹ́ èèwọ̀, tí wọ́n kà á sì nǹkan ẹrù jẹ̀jẹ̀, tọ́mọdé ò gbọ́dọ̀ dá sí, nítorí pé lójú tiwọn “kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọmọdé.” Báwọn èèyàn ṣe ń kú lóde òní yàtọ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà, kì í sábàá sí alábàárò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ni yóò fẹ́ láti fọwọ́ rọrí kú sínú ilé, lọ́dọ̀ àwọn ẹbí tó ń tọ́jú wọn. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó bani nínú jẹ́ pé ọsibítù ni wọ́n ń kú sí, láìrí ẹni fojú jọ, nínú ìrora, pẹ̀lú àwọn wáyà jáganjàgan tó wá látinú àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n so mọ́ wọn lára. Àwọn míì tún wà tí wọ́n ń kú túẹ́ láìsí ẹni tó mọ̀ wọ́n, bóyá tí wọ́n pa ní àpalù nínú ogun ìpẹ̀yàrun, tàbí tí ìyàn, àrùn éèdì, ogun abẹ́lé tàbí òṣì paraku gbẹ̀mí wọn.
Ohun Tó Yẹ Kéèyàn Ronú Lé Lórí Ni
Bíbélì kò sọ pé ó lòdì láti ronú nípa ikú. Kódà Oníwàásù 7:2 sọ fún wa pé: “Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àkànṣe àsè, nítorí pé ìyẹn ni òpin gbogbo aráyé.” Tá a bá rántí pé kò sẹ́ni tíkú ò lè pa, yóò jẹ́ ká mọ́kàn kúrò lórí àwọn àníyàn tàbí ìgbòkègbodò ojoojúmọ́, a ó sì ronú jinlẹ̀ lórí bí ìwàláàyè ṣe kúrú tó. Èyí lè jẹ́ ká gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó nítumọ̀, dípò fífi tàfàlà.
Kí ni èrò rẹ nípa ikú? Ǹjẹ́ o ti ronú lórí ìmọ̀lára rẹ, ìgbàgbọ́ rẹ, ìrètí rẹ àtàwọn ohun tí ń bà ọ́ lẹ́rù nípa òpin ìwàláàyè rẹ?
Bí ìwàláàyè ṣe jẹ́ àdììtú àti àwámárìídìí fọ́mọ aráyé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú jẹ́. Ẹlẹ́dàá wa nìkan ṣoṣo ló mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn yìí. Òun ni “orísun ìyè,” òun ló sì mọ “ọ̀nà àbájáde kúrò lọ́wọ́ ikú.” (Sáàmù 36:9; 68:20) Bá a bá fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ àwọn ìgbàgbọ́ tó wọ́pọ̀ nípa ikú wò, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí i pé ohun tó sọ ń tuni nínú, ó sì ń fúnni níṣìírí. Yóò fi hàn pé ikú kò fi dandan jẹ́ òpin ìrìn àjò ẹ̀dá.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Rírántí pé kò sẹ́ni tí ikú kò lè pa ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó nítumọ̀