Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Oníwàásù
JÓÒBÙ, baba ńlá ìgbàanì sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Ẹ ò rí i pé kò yẹ ká fi ìwàláàyè kúkúrú tá a ní tàfàlà lórí ṣíṣàníyàn láìnídìí àti lórí àwọn ìwéwèé tí kò ní láárí! Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa lo àkókò wa, agbára wa, àti ohun ìní wa fún? Àwọn nǹkan wo ló sì yẹ ká yàgò fún? Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó wà nínú ìwé Oníwàásù nínú Bíbélì fún wa nítọ̀ọ́ni tá a lè gbára lé lórí ọ̀ràn yìí. Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lè jẹ́ ká “fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà” wa, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó dára.—Hébérù 4:12.
Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí ọlọgbọ́n ló kọ ìwé Oníwàásù. Ìwé náà kún fún àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé èèyàn àtàwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì. Níwọ̀n bí Sólómọ́nì ti mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tó ṣe, ó ní láti jẹ́ pé ẹ̀yìn ìgbà tó kọ́ àwọn ilé náà tán ló wá kọ ìwé Oníwàásù, kò sì tíì yapa kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ lákòókò náà. (Nehemáyà 13:26) Èyí ló jẹ́ ká mọ̀ pé kó tó di ọdún 1000 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Sólómọ́nì kọ ìwé náà, ìyẹn nígbà tó ń sún mọ́ òpin ogójì ọdún tó fi jọba.
KÍ NI KÌ Í ṢE ASÁN?
Akónijọ náà sọ pé: “Asán ni gbogbo rẹ̀!” Ó wá béèrè pé: “Èrè kí ni ènìyàn jẹ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ tí ó ń ṣe kárakára lábẹ́ oòrùn?” (Oníwàásù 1:2, 3) Gbólóhùn náà “asán” àti “lábẹ́ oòrùn” fara hàn léraléra nínú ìwé Oníwàásù. Ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “asán” túmọ̀ sí ní olówuuru ni “èémí” tàbí “oruku,” ìyẹn sì fi hàn pé ohun tí kò ṣe pàtàkì, ohun tí kì í wà títí lọ, tàbí ohun tí kì í pẹ́ pòórá ni. Gbólóhùn náà, “lábẹ́ oòrùn,” túmọ̀ sí “lórí ilẹ̀ ayé yìí” tàbí “ní ayé yìí.” Nítorí náà, gbogbo nǹkan, ìyẹn gbogbo ohun tí èèyàn ń dáwọ́ lé láìfi ti Ọlọ́run ṣe, jẹ́ asán.
Sólómọ́nì sọ pé: “Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá ń lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́; kí sísúnmọ́ tòsí láti gbọ́ sì wà.” (Oníwàásù 5:1) Kíkópa nínú ìjọsìn tòótọ́ tó jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run kì í ṣe asán. Kódà, fífi ọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run ni olórí ohun tó lè mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:4-10—Kí nìdí tá a fi sọ pé ọ̀nà tí àwọn ìṣẹ̀dá gbà ń ṣiṣẹ́ wọn “ń mú kí àárẹ̀ múni”? Akónijọ mẹ́nu kan mẹ́ta péré lára àwọn ohun tó ń mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ni oòrùn, bí ẹ̀fúùfù ṣe ń fẹ́ lọ fẹ́ bọ̀, àti bí oòrùn ṣe máa ń fa omi lọ sójú ọ̀run tó sì máa ń padà rọ òjò sílẹ̀. Láìsí àní-àní, àwọn ìṣẹ̀dá wọ̀nyí pọ̀ lọ súà, wọ́n sì díjú gan-an. Èèyàn lè fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn, síbẹ̀ kó má lóye wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ká sòótọ́, ìyẹn lè “mú kí àárẹ̀ múni.” Ó sì tún ń tánni lókun tá a bá ń fi ọjọ́ ayé wa tó kúrú gan-an wéra pẹ̀lú ti àwọn ìṣẹ̀dá tí kò dáwọ́ iṣẹ́ dúró yìí. Kódà, gbígbìyànjú láti ṣàwárí àwọn ohun tuntun pàápàá lè mú kí àárẹ̀ múni. Ó ṣe tán, ńṣe làwọn ohun tuntun wulẹ̀ jẹ́ ohun táwọn èèyàn mú jáde látinú àwọn ìlànà tí Ọlọ́rùn tòótọ́ gbé kalẹ̀ tó sì lò láti dá àwọn nǹkan.
2:1, 2—Kí nìdí tá a fi pe ẹ̀rín ní “ìsínwín”? Ẹ̀rín lè jẹ́ ká gbàgbé àwọn ìṣòro wa fúngbà díẹ̀, bákan náà ni fàájì ṣíṣe lè mú ká máa wo àwọn ìṣòro wa bíi pé wọn ò jẹ́ nǹkan kan. Àmọ́ ẹ̀rín kò lè mú káwọn ìṣòro wa pòórá. Ìdí nìyẹn tá a fi sọ pé “ìsínwín” ni kéèyàn rò pé òun lè láyọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀rín rírín.
3:11—Kí ni Ọlọ́run ti ṣe “rèterète ní ìgbà tirẹ̀”? Lára àwọn nǹkan tí Jèhófà Ọlọ́run ti ṣe “rèterète,” tàbí tó ṣe lọ́nà tó tọ́ tó sì dára ní àsìkò tó yẹ ni: dídá tó dá Ádámù àti Éfà, májẹ̀mú tó ṣe nípa òṣùmàrè, májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá, májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá, bíbọ̀ Mèsáyà, àti gbígbé Jésù Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, nǹkan mìíràn tún wà tí Jèhófà máa ṣe “rèterète” lọ́jọ́ iwájú. Ó dá wa lójú pé ayé tuntun òdodo máa dé ní àkókò tó tọ́ lójú Ọlọ́run.—2 Pétérù 3:13.
3:15b—Báwo ni ‘Ọlọ́run tòótọ́ ṣe ń wá èyí tí a ń lépa’? ‘Ohun tí a ń lépa’ lè tọ́ka sí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé látìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá èèyàn làwọn èèyàn ti ń bímọ, tí èèyàn ń kú, tí ogun àti àlàáfíà sì ń bá a lọ, ìyẹn lè mú kí ìgbésí ayé tojú súni, ká máa ronú pé ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni yóò máa ṣẹlẹ̀ títí lọ, àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ lè lépa gbogbo ohun tó fẹ́ ṣe kó sì ṣe wọ́n láṣeparí. (Oníwàásù 3:1-10, 15a) ‘Ohun tí a ń lépa’ tún lè tọ́ka sí àwọn olódodo, táwọn ẹni ibi sábà máa ń lépa. Lórí èyí, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń wá àwọn olódodo kí ó lè “fi okun rẹ̀ hàn” nítorí wọn.—2 Kíróníkà 16:9.
5:9—Báwo ni ‘èrè ilẹ̀ ayé ṣe wà láàárín gbogbo wọn’? Gbogbo àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé ló gbára lé “èrè ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ohun tí ilẹ̀ ń mú jáde. Ọba pàápàá gbára lé e. Kí ọba tó lè rí irè oko rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní láti ṣe iṣẹ́ àṣekára nínú oko náà.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:15. Asán lórí asán ni kéèyàn máa lo gbogbo àkókò rẹ̀ àti okun rẹ̀ láti mú ìnilára àti ìwà ìrẹ́nijẹ tá à ń rí lóde òní kúrò. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú ìwà ibi kúrò.—Dáníẹ́lì 2:44.
2:4-11. Àwọn iṣẹ́ tí ẹ̀dá èèyàn ń ṣe bíi ká yàwòrán ilé, ká ṣiṣẹ́ nínú ọgbà, àti orin kíkọ, títí kan gbígbé ìgbésí ayé ọlọ́rọ̀ jẹ́ “lílépa ẹ̀fúùfù” nítorí pé wọn ò lè mú kí ìgbésí ayé ẹni nítumọ̀, wọn ò sì lè fúnni láyọ̀ tó máa wà títí lọ.
2:12-16. Ọgbọ́n ṣàǹfààní ju ìwà òmùgọ̀ lọ ní ti pé, ó lè ranni lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro kan. Àmọ́ tó bá kan ọ̀ràn ikú, ọgbọ́n èèyàn kò ní àǹfààní kankan. Kódà bí ọgbọ́n yẹn tiẹ̀ ti sọ èèyàn di olókìkí, síbẹ̀ onítọ̀hún á dẹni ìgbàgbé láìpẹ́.
2:24; 3:12, 13, 22. Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
2:26. ‘Ẹni rere níwájú Jèhófà’ ni Ọlọ́run máa ń fún ní ọgbọ́n rẹ̀ tó ń fúnni láyọ̀. Kò ṣeé ṣe láti ní ọgbọ́n tá à ń wí yìí láìjẹ́ pé àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run gún régé.
3:16, 17. Kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa retí pé kó má sí ìwà ìrẹ́jẹ rárá. Dípò ká máa dààmú nítorí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé lónìí, ńṣe ló yẹ ká dúró de Jèhófà láti wá tún ohun gbogbo ṣe.
4:4. Iṣẹ́ téèyàn ṣe láṣekára téèyàn sì ṣe dáadáa lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Àmọ́ téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ àṣekára nítorí kó bàa lè ta àwọn tó kù yọ, ìyẹn lè fa ẹ̀mí ìbánidíje, ìbínú, àti owú. Iṣẹ́ àṣekára tá à ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tá a ń fi ọkàn tó dáa ṣe.
4:7-12. Àjọṣe àárín àwa èèyàn ṣe pàtàkì gan-an ju ohun ìní ti ara lọ, kò sì yẹ ká tìtorí lílé ọrọ̀ gbójú fo àjọṣe yìí dá.
4:13. Kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fúnni nítorí ipò ẹni tàbí nítorí ọjọ́ orí ẹni. Nítorí náà, àwọn tó wà nípò àṣẹ gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n hùwà.
4:15, 16. “Ọmọ, tí ó jẹ́ ìkejì,” ìyẹn ọmọ tó di ọba tẹ̀ lé bàbá rẹ̀, lè kọ́kọ́ máa rí ìtìlẹ́yìn ‘gbogbo àwọn tó wà ṣáájú rẹ̀,’ àmọ́ ‘tó bá yá àwọn èèyàn náà kì yóò yọ̀ nínú rẹ̀ mọ́.’ Láìsí àní-àní òkìkí kì í tọ́jọ́.
5:2. Àdúrà wa gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tá a ronú lé lórí dáadáa ká tó gbà á, kí ó fi hàn pé a fọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, kó má sì gùn jù.
5:3-7. Téèyàn bá jẹ́ kí lílépa ọrọ̀ gba gbogbo àkókò òun, ìyẹn lè jẹ́ kéèyàn máa fi gbogbo ìgbà ronú nípa ohun tó fẹ́ kí ọwọ́ òun tẹ̀. Ó lè má jẹ́ kéèyàn nísinmi, kó máa fi gbogbo òru ronú nípa àwọn nǹkan náà, kó má sì lè sùn wọra. Àsọjù ọ̀rọ̀ lè mú kéèyàn dà bí òmùgọ̀ lójú àwọn ẹlòmíràn, ó sì lè mú kéèyàn fi ìwàǹwára jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run. ‘Ìbẹ̀rù Ọlọ́run’ kò ní jẹ́ ká ṣe èyíkéyìí lára àwọn nǹkan wọ̀nyí.
6:1-9. Àǹfààní wo ló wà nínú ọrọ̀, ògo, ẹ̀mí gígùn, àti ìdílé ńlá, tí ipò nǹkan ò bá jẹ́ ká gbádùn wọn? Àti pé “fífi ojú rí” tàbí kéèyàn gbà bí nǹkan bá ṣe rí “sàn ju kí ọkàn máa rìn káàkiri,” ìyẹn ni pé kéèyàn máa ronú ṣáá nípa àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ̀ kò lè tẹ̀. Nítorí náà, ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé ni pé kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú “ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ,” kó sì máa ṣe àwọn ohun tó lè múnú rẹ̀ dùn, kó tún ní àjọṣe tó dára gan-an pẹ̀lú Jèhófà.—1 Tímótì 6:8.
ÌMỌ̀RÀN FÚN ÀWỌN ỌLỌGBỌ́N
Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí orúkọ rere wa bà jẹ́? Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn alákòóso ayé, kí ló sì yẹ ká ṣe nígbà tá a bá rí àwọn ìwà ìrẹ́jẹ tó ń lọ nínú ayé? Níwọ̀n bí àwọn òkú kò ti mọ ohunkóhun, báwo ló ṣe yẹ ká máa lo ìgbésí ayé wa nísinsìnyí? Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lo àkókò wọn àti agbára wọn lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání? Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí akónijọ gba àwa èèyàn lórí ọ̀ràn yìí àtàwọn ọ̀ràn mìíràn wà lákọsílẹ̀ fún wa nínú orí keje sí ìkejìlá ìwé Oníwàásù.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
7:19—Báwo ni ọgbọ́n ṣe lágbára ju “ọkùnrin mẹ́wàá tí ó wà ní ipò agbára”? Nígbà tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà, mẹ́wàá lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ohun tó pé pérépéré ló dúró fún. Ohun tí Sólómọ́nì ń sọ ni pé ọgbọ́n lè dáàbò boni ju kí odindi ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan máa ṣọ́ ìlú kan.
10:2—Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì bá sọ pé ọkàn èèyàn wà “ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀” tàbí “ní ọwọ́ òsì rẹ̀”? Níwọ̀n bí ọwọ́ ọ̀tún ti sábà máa ń túmọ̀ sí pé èèyàn wà nípò ojú rere, kí ọkàn èèyàn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ túmọ̀ sí pé ọkàn onítọ̀hún ń sún un láti ṣe ohun tó dára. Àmọ́ tí ọkàn ẹnì kan bá ń sún un láti ṣe ohun tí kò tọ́, a jẹ́ pé ọkàn onítọ̀hún wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀ nìyẹn.
10:15—Báwo ni ‘iṣẹ́ àṣekára àwọn arìndìn ṣe máa ń tán wọn lókun’? Bí ẹnì kan kò bá ní òye, iṣẹ́ àṣekára tí onítọ̀hún ń ṣe kò ní lè mú ohunkóhun tó ní láárí jáde. Kò ní rí ayọ̀ kankan nínú iṣẹ́ tó ń ṣe. Kéèyàn kàn máa da ara ẹ̀ láàmú lọ́nà yìí lè tánni lókun.
11:7, 8—Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà: “Ìmọ́lẹ̀ dùn pẹ̀lú, ó sì dára kí ojú rí oòrùn”? Ìmọ́lẹ̀ àti oòrùn máa ń múnú ọmọ aráyé dùn. Ohun tí Sólómọ́nì ń sọ níbí yìí ni pé ó yẹ kínú wa máa dùn pé a wà láàyè, ó sì yẹ ká máa “yọ̀” kí ọjọ́ ogbó tó dé, tí kò ní sí okun àti agbára mọ́.
11:10—Kí nìdí tí “ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀ṣìngín nínú ìgbésí ayé” fi jẹ́ àsán? Téèyàn ò bá lo ìgbà èwe rẹ̀ dáadáa, asán ló máa jẹ́, nítorí pé bí ìkùukùu lásán ni okun ìgbà èwe ṣe máa ń lọ ní kíámọ́sá.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
7:6. Ẹ̀rín rírín lákòókò tí kò tọ́ máa ń kó àwọn èèyàn nírìíra, kò sì wúlò rárá, ńṣe ló máa ń dà bí ìgbà tí ẹ̀gún bá ń ta pàrà nígbà tó bá ń jóná lábẹ́ ìkòkò. A gbọ́dọ̀ yẹra fún irú ẹ̀rín bẹ́ẹ̀.
7:21, 22. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kóhun táwọn èèyàn ń sọ nípa wa ká wa lára ju bó ti yẹ lọ.
8:2, 3; 10:4. Nígbà tí ọ̀gá wa tàbí ẹni tó gbà wá síṣẹ́ bá ń bá wa wí, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká ní sùúrù. Èyí dára ju ká ‘kánjú jáde kúrò níwájú rẹ̀,’ ìyẹn ni pé ká fi ìwàǹwára kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀.
8:8; 9:5-10, 12. Ìgbésí ayé wa lè dópin láìròtẹ́lẹ̀ bí ìgbà tí ẹja bá kó sínú àwọ̀n tàbí tí ẹyẹ ṣèèṣì kó sínú àgò. Yàtọ̀ síyẹn, kò sẹ́ni tó lè dá ẹ̀mí ara rẹ̀ dúró nígbà tí ikú bá dé, kò sì sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ ikú. Ìdí nìyẹn tí kò fi yẹ ká máa fi àkókò wa ṣòfò. Jèhófà fẹ́ ká mọyì ìwàláàyè tá a ní ká sì gbádùn rẹ̀ lọ́nà tó dára. Kí èyí tó lè ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa.
8:16, 17. Kò sí bá a ṣe lè lóye gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe àtàwọn ohun tó fàyè gbà pé kó máa ṣẹlẹ̀ láàárín ọmọ aráyé, kódà, bá ò tiẹ̀ sùn nítorí ká lè lóye wọn. Dída ara wa láàmú nítorí gbogbo ohun búburú táwọn èèyàn ń ṣe yóò wulẹ̀ mú ká dẹni tí kò gbádùn ìgbésí ayé ni.
9:16-18. Ó yẹ ká mọyì ọgbọ́n, kódà báwọn èèyàn tó yí wa ká kò tiẹ̀ mọyì rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí ọlọgbọ́n èèyàn rọra sọ dára gan-an ju igbe arìndìn lọ.
10:1. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Ìwà òmùgọ̀ kan téèyàn kàn hù lẹ́ẹ̀kan péré ti tó láti ba orúkọ rere rẹ̀ táwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fún jẹ́. Irú àwọn ìwà òmùgọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kéèyàn bínú kó sì fara ya, kó mutí yó kẹ́ri, tàbí kó hu ìwà kan tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe.
10:5-11. Kò yẹ ká máa ṣe ìlara ẹni tó wà nípò gíga àmọ́ tí kò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ náà. Béèyàn ò bá kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ kan, bó ti wù kí iṣẹ́ náà kéré tó, ó lè yọrí sí jàǹbá. Kàkà bẹ́ẹ̀, mímọ bá a ṣe lè ‘lo ọgbọ́n láti ní àṣeyọrí sí rere’ yóò ṣeni láǹfààní. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká kúnjú ìwọ̀n nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn!
11:1, 2. A gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó lawọ́, ká sì máa ṣe é tọkàntọkàn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn yóò máa fún àwa náà ní nǹkan pẹ̀lú.—Lúùkù 6:38.
11:3-6. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé èèyàn tá ò lè ṣe ohunkóhun nípa wọn, kò gbọ́dọ̀ sọ wa dẹni tí kò lè pinnu ohun tó yẹ ní ṣíṣe.
11:9; 12:1-7. Àwọn ọ̀dọ́ máa jíhìn níwájú Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ lo àkókò àti agbára wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kí ọjọ́ ogbó tó dé tí wọn kò ní lókun àti agbára mọ́.
“Ọ̀RỌ̀ ÀWỌN ỌLỌGBỌ́N” LÁTI TỌ́ WA SỌ́NÀ
Ojú wo ló yẹ ká fi wo “àwọn ọ̀rọ̀ dídùn” tí akónijọ ṣàwárí rẹ̀ tó sì kọ sílẹ̀? Ọ̀rọ̀ akónijọ yàtọ̀ gan-an sí “ìwé púpọ̀” tí wọ́n fi ọgbọ́n èèyàn kọ. Ó jẹ́ ‘ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n tó rí bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣó tí a gbá wọlé ni àwọn tí ó jọ̀wọ́ ara wọn fún àkójọ àwọn gbólóhùn; láti ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan ni a ti fi wọ́n fúnni.’ (Oníwàásù 12:10-12) Ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó wá látẹnu “olùṣọ́ àgùntàn kan,” ìyẹn Jèhófà, lè mú kí ayé wa dùn bí oyin.
Tá a bá fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú ìwé Oníwàásù sílò, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ tó sì láyọ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún dá wa lójú pé: “Yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.” Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ fi ṣe ìpinnu wa láti máa ‘bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí a sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.’—Oníwàásù 8:12; 12:13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọ̀kan lára àwọn ohun tó dára jù lọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Oúnjẹ, ohun mímú, àti kéèyàn rí adùn nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ ara àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run