Orí Kọkàndínlọ́gbọ̀n
Ọba Kan Jẹ Èrè Ìgbàgbọ́ Rẹ̀
1, 2. Báwo ni Hesekáyà ṣe jẹ́ ọba tó sàn ju Áhásì?
ẸNI ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni Hesekáyà nígbà tó jọba Júdà. Irú ọba wo ló máa wá jẹ́? Ṣé bíi bàbá rẹ̀, Áhásì Ọba, ti ṣe lòun náà máa ṣe, kó wá mú kí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ máa tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn? Àbí yóò ṣe bíi baba ńlá rẹ̀, Dáfídì Ọba, nípa ṣíṣáájú àwọn èèyàn náà nínú ìjọsìn Jèhófà?—2 Àwọn Ọba 16:2.
2 Kò pẹ́ tí Hesekáyà gorí ìtẹ́, tó fi wá hàn pé ó ń fẹ́ ṣe “ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.” (2 Àwọn Ọba 18:2, 3) Lọ́dún àkọ́kọ́ ìjọba rẹ̀, ó pàṣẹ pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn padà ní tẹ́ńpìlì. (2 Kíróníkà 29:3, 7, 11) Lẹ́yìn náà, ó ṣètò àjọyọ̀ Ìrékọjá ńlá kan, ó wá pe gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn síbẹ̀, títí kan àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì níhà àríwá pàápàá. Áà, mánigbàgbé gbáà làjọyọ̀ yẹn! Kò tíì sí èyí tó dà bíi rẹ̀ láti ìgbà ayé Sólómọ́nì Ọba.—2 Kíróníkà 30:1, 25, 26.
3. (a) Kí ni àwọn ará Ísírẹ́lì àti Júdà tó wá sí ibi Ìrékọjá tí Hesekáyà ṣètò ṣe? (b) Ẹ̀kọ́ wo làwọn Kristẹni òde òní rí kọ́ látinú ohun tí àwọn tó wá síbi Ìrékọjá yẹn ṣe láìjáfara?
3 Nígbà tí àjọyọ̀ Ìrékọjá yẹn fi parí, ṣe làwọn tó wá síbẹ̀ tú yáyá sóde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀, wọ́n ń fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ túútúú, wọ́n sì ń bi àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ òrìṣà wọn wó, lẹ́yìn náà, wọ́n wá padà sí ìlú wọn pẹ̀lú ìpinnu pé Ọlọ́run tòótọ́ làwọn ó máa sìn. (2 Kíróníkà 31:1) Èyí yàtọ̀ gbáà sí ìṣarasíhùwà wọn àtẹ̀yìnwá nípa ìjọsìn! Ẹ̀kọ́ sì lèyí jẹ́ fáwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní, nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé ‘kí wọ́n má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀.’ Ńṣe ni irú àwọn ìpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀, ì báà jẹ́ tinú ìjọ kọ̀ọ̀kan, tàbí ti àwọn tó tóbi ju ìyẹn lọ tó ń wáyé ní àwọn àpéjọ àkànṣe, ti àyíká tàbí ti àgbègbè, máa ń kó ipa pàtàkì nínú bí wọ́n ṣe ń rí ìṣírí gbà, tí wọ́n sì ń di ẹni tí ẹgbẹ́ àwọn ará àti ẹ̀mí Ọlọ́run pẹ̀lú ń ‘ru sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’—Hébérù 10:23-25.
A Dán Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ Wò
4, 5. (a) Báwo ni Hesekáyà ṣe fi hàn pé òun ò gbára lé Ásíríà? (b) Ìgbésẹ̀ wo ni Senakéríbù gbé láti gbógun ja Júdà, àwọn ìgbésẹ̀ wo sì ni Hesekáyà gbé kí Jerúsálẹ́mù lè bọ́ lọ́wọ́ ìkọlù ojú-ẹsẹ̀? (d) Báwo ni Hesekáyà ṣe wá gbára dì láti gba Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà?
4 Àdánwò lílekoko ń bẹ níwájú fún Jerúsálẹ́mù. Hesekáyà ti fòpin sí gbogbo májẹ̀mú tí Áhásì bàbá rẹ̀ aláìnígbàgbọ́ bá àwọn ará Ásíríà dá. Ó tiẹ̀ tún ti tẹ àwọn Filísínì tó jẹ́ alájọṣepọ̀ Ásíríà lórí ba. (2 Àwọn Ọba 18:7, 8) Èyí ti wá bí ọba Ásíríà nínú. Nípa bẹ́ẹ̀, a kà á pé:“Ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹrìnlá Hesekáyà Ọba pé Senakéríbù ọba Ásíríà gòkè wá gbéjà ko gbogbo ìlú ńlá olódi ti Júdà, ó sì tẹ̀ síwájú láti gbà wọ́n.” (Aísáyà 36:1) Bóyá Hesekáyà ń fẹ́ dáàbò bo Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ àtakò òjijì látọ̀dọ̀ èṣùbèlèké agbo ọmọ ogun Ásíríà ló ṣe gbà láti san adúrú owó òde tó jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún tálẹ́ńtì fàdákà àti ọgbọ̀n tálẹ́ńtì wúrà fún Senakéríbù.a—2 Àwọn Ọba 18:14.
5 Nígbà tí wúrà àti fàdákà tí Hesekáyà rí látinú ìṣúra ọba kò sì tó láti fi san owó tí wọ́n bù lé e, ló bá ko gbogbo àwọn èyí tó jẹ́ ti ohun iyebíye tó lè rí kó nínú tẹ́ńpìlì. Ó tún gé àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì tí wọ́n fi wúrà bò, ó sì kó wọn ránṣẹ́ sí Senakéríbù. Ìyẹn mú kí ọkàn ará Ásíríà yìí rọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni. (2 Àwọn Ọba 18:15, 16) Ó jọ pé Hesekáyà mọ̀ pé ará Ásíríà yìí kò ní fi Jerúsálẹ́mù lọ́rùn sílẹ̀ pẹ́ lọ títí. Nítorí náà, wọ́n ní láti gbára dì. Ni àwọn èèyàn bá dínà omi tí àwọn ará Ásíríà tó ń ṣígun bọ̀ lé rí lò. Hesekáyà sì tún mú kí àwọn odi agbára Jerúsálẹ́mù túbọ̀ lágbára sí i, ó sì kó àwọn ohun ìjà jọ pelemọ, títí kan “àwọn ohun ọṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu àti àwọn apata.”—2 Kíróníkà 32:4, 5.
6. Ta ni Hesekáyà gbẹ́kẹ̀ lé?
6 Àmọ́ ṣá o, ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ogun tàbí àwọn odi agbára kọ́ ni Hesekáyà gbẹ́kẹ̀ lé, Jèhófà ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni. Ó rọ àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà nítorí ọba Ásíríà àti ní tìtorí gbogbo ogunlọ́gọ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀; nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Apá tí ó jẹ́ ẹran ara ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run wa ni ó wà pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja àwọn ìjà ogun wa.” Àwọn ènìyàn náà sì gbà bó ṣe wí lóòótọ́, wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ Hesekáyà ọba Júdà gbé ara wọn ró.” (2 Kíróníkà 32:7, 8) Ìwọ fojú inú wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amárayágágá tó tẹ̀ lé e bí a ṣe ń gbé orí kẹrìndínlógójì títí dé ìkọkàndínlógójì àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yẹ̀ wò.
Rábúṣákè Gbẹ́nu Lé Àlàyé Rẹ̀
7. Ta ni Rábúṣákè, èé ṣe tí wọ́n sì fi rán an sí Jerúsálẹ́mù?
7 Senakéríbù rán Rábúṣákè (kì í ṣe orúkọ èèyàn o, oyè ológun ni) àti ẹni sàràkí méjì wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá sọ fún wọn pé kí ìlú yẹn juwọ́ sílẹ̀ fóun. (2 Àwọn Ọba 18:17) Àwọn aṣojú mẹ́ta tí Hesekáyà rán, ìyẹn Élíákímù alábòójútó agboolé Hesekáyà, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọ Ásáfù tó ń ṣe àkọsílẹ̀, ló lọ pàdé wọn lẹ́yìn odi ìlú.—Aísáyà 36:2, 3.
8. Báwo ni Rábúṣákè ṣe gbìyànjú láti mú kí ọwọ́ Jerúsálẹ́mù rọ?
8 Ohun tí Rábúṣákè bá wá kò le, àní kó sáà ti mú kí Jerúsálẹ́mù gbà láti juwọ́ sílẹ̀ láìwulẹ̀ jà rárá. Ló bá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ lédè Hébérù, ó kígbe pé: “Kí ni ohun ìgbọ́kànlé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé? . . . Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi?” (Aísáyà 36:4, 5) Ni Rábúṣákè bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣáátá àwọn Júù ti ẹ̀rù ti bà yìí, ó rán wọn létí pé àwọn nìkan ṣoṣo gíro ló dá wà o. Ta ni wọ́n wá fẹ́ yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Ṣé Íjíbítì tó jẹ́ “esùsú fífọ́” yẹn ni? (Aísáyà 36:6) Íjíbítì ò sì yàtọ̀ sí esùsú fífọ́ lásìkò yẹn lóòótọ́; kódà látìgbà díẹ̀ wá ni Etiópíà ti ṣẹ́gun Íjíbítì tó jẹ́ agbára ayé tẹ́lẹ̀ rí yìí, pẹ̀lúpẹ̀lù, Tíhákà Ọba tó jẹ Fáráò Íjíbítì nígbà tí a ń wí yìí kì í ṣe ọmọ Íjíbítì, ará Etiópíà ni. Ásíríà sì máa tó ṣẹ́gun rẹ̀. (2 Àwọn Ọba 19:8, 9) Níwọ̀n bí Íjíbítì kò ti lè gba ara rẹ̀, kò ní lè ṣèrànwọ́ gidi kankan fún Júdà.
9. Kí ló dájú pé ó sún Rábúṣákè láti gbà pé Jèhófà yóò kọ àwọn èèyàn Rẹ̀ sílẹ̀, ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀ ní ti gidi?
9 Rábúṣákè wá ṣàlàyé pé Jèhófà ti bínú sí àwọn èèyàn Rẹ̀ nítorí náà kò ní gbèjà wọn rárá. Rábúṣákè sọ pé: “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ìwọ sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni ẹni tí àwa gbẹ́kẹ̀ lé,’ òun ha kọ́ ni ẹni tí Hesekáyà ti mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò?” (Aísáyà 36:7) Ní tòdodo, àwọn Júù kò kọ Jèhófà sílẹ̀ rárá nígbà tí wọ́n bi àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ wó ní ilẹ̀ náà, ńṣe làwọn Júù mà fi ìyẹn padà sọ́dọ̀ Jèhófà o.
10. Èé ṣe tí ọ̀ràn pé àwọn tó ń jà fún Júdà pọ̀ tàbí pé wọ́n kéré kò fi ní ohunkóhun í ṣe nínú ọ̀ràn yìí?
10 Lẹ́yìn náà, Rábúṣákè rán àwọn Júù létí pé, bó bá wá di ti ogun jíjà, ọ̀ràn wọn yóò dà bí ìgbà tí ọlọ́mọlanke bá dúró de rélùwéè ni. Ló bá pè wọ́n níjà lọ́nà ìfẹgẹ̀, ó ní: “Kí n . . . fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin láti rí i bóyá ìwọ, níhà ọ̀dọ̀ rẹ, lè fi olùgun ẹṣin sórí wọn.” (Aísáyà 36:8) Àmọ́, ká sòótọ́, yálà àwọn ògbówọ́ agẹṣinjagun tí Júdà ní pọ̀ o tàbí wọ́n kéré o, ǹjẹ́ ìyẹn ní ohunkóhun í ṣe nínú ọ̀ràn yìí? Rárá o, nítorí ìgbàlà Júdà kò sinmi lórí bó ṣe lágbára ìjà tó. Òwe 21:31 ṣàlàyé ọ̀ràn yẹn báyìí pé: “Ẹṣin ni ohun tí a pèsè sílẹ̀ fún ọjọ́ ìjà ogun, ṣùgbọ́n ti Jèhófà ni ìgbàlà.” Rábúṣákè wá sọ pé àwọn ará Ásíríà ni Jèhófà ń tì lẹ́yìn, kì í ṣe àwọn Júù. Ó ní láìṣe bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Ásíríà kì bá tí lè wọnú ìpínlẹ̀ Júdà jìnnà dé ibi tí wọ́n dé.—Aísáyà 36:9, 10.
11, 12. (a) Èé ṣe tí Rábúṣákè fi ní “èdè àwọn Júù” lòun ó sọ dandan, báwo ló sì ṣe gbìyànjú láti kẹ́dẹ mú àwọn Júù tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀? (b) Ipa wo ni ọ̀rọ̀ Rábúṣákè lè ní lórí àwọn Júù?
11 Ọkàn àwọn aṣojú Hesekáyà ò wá balẹ̀ mọ́ nípa ipa tí ọ̀rọ̀ Rábúṣákè yóò ní lórí àwọn ọkùnrin tó lè máa gbọ́ ọ láti orí odi ìlú. Làwọn Júù òṣìṣẹ́ ọba yìí bá sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Síríà, nítorí àwa gbọ́; má sì bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Júù ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri.” (Aísáyà 36:11) Ṣùgbọ́n Rábúṣákè kò fẹ́ sọ̀rọ̀ lédè Síríà rárá. Ńṣe ló mà fẹ́ mú kí àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì o, kí ẹ̀rù bà wọ́n, kí wọ́n fi lè juwọ́ sílẹ̀, kí àwọn sì ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù láìtiẹ̀ jagun rárá! (Aísáyà 36:12) Ni ará Ásíríà yìí bá tún gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ ní “èdè àwọn Júù.” Ló bá kìlọ̀ fún àwọn ará Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè dá yín nídè.” Lẹ́yìn èyí, ó gbìyànjú láti kẹ́dẹ mú àwọn Júù tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ nípa ṣíṣàpèjúwe bí ìgbésí ayé ṣe lè rí fún àwọn Júù bí Ásíríà bá ń ṣàkóso wọn, ó ní: “Ẹ túúbá fún mi, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá, kí olúkúlùkù sì máa jẹ láti inú àjàrà tirẹ̀ àti olúkúlùkù láti inú igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀, kí olúkúlùkù sì máa mu omi inú ìkùdu tirẹ̀, títí èmi yóò fi wá, tí èmi yóò sì kó yín lọ ní ti tòótọ́ sí ilẹ̀ tí ó dà bí ilẹ̀ tiyín, ilẹ̀ ọkà àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti àwọn ọgbà àjàrà.”—Aísáyà 36:13-17.
12 Lọ́dún yẹn, àwọn Júù kò ní rí ohunkóhun kórè, nítorí àwọn Ásíríà tó ṣígun tọ̀ wọ́n wá kò jẹ́ kí wọ́n fúnrúgbìn rárá. Ìrètí pé àwọn lè rí èso àjàrà tó ṣe rọ̀múrọ̀mú jẹ, kí àwọn sì tún rí omi tútù bù mu ti ní láti fa àwọn ọkùnrin tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ látorí odi mọ́ra gidigidi. Àmọ́ ìsapá Rábúṣákè láti mú kí àwọn Júù rẹ̀wẹ̀sì kò tíì parí.
13, 14. Láìka gbogbo àròyé Rábúṣákè sí, kí ni ìdí tí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Samáríà kò fi ṣeé fi wé ọ̀ràn ti Júdà?
13 Ni Rábúṣákè bá tún yọ ọfà ọ̀rọ̀ mìíràn látinú apó ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó kìlọ̀ fáwọn Júù pé kí wọ́n má ṣe gba Hesekáyà gbọ́ o tó bá sọ fún wọn pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò dá wa nídè.” Rábúṣákè wá rán àwọn Júù létí pé ṣebí àwọn òrìṣà Samáríà kò lè gba àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá sílẹ̀ kí àwọn ará Ásíríà má lè borí wọn. Ti àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Ásíríà ti ṣẹ́gun tún ńkọ́? Ó béèrè pé: “Àwọn ọlọ́run Hámátì àti Áápádì dà? Àwọn ọlọ́run Séfáfáímù dà? Wọ́n ha sì ti dá Samáríà nídè kúrò lọ́wọ́ mi?”—Aísáyà 36:18-20.
14 Ó dájú pé Rábúṣákè tó jẹ́ abọ̀rìṣà, kò mọ̀ pé ìyàtọ̀ ńlá ń bẹ láàárín Samáríà apẹ̀yìndà àti Jerúsálẹ́mù ti ìgbà ìṣàkóso Hesekáyà. Lóòótọ́, àwọn òrìṣà Samáríà kò lágbára láti gba ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá sílẹ̀. (2 Àwọn Ọba 17:7, 17, 18) Ṣùgbọ́n Jerúsálẹ́mù ti ìgbà Hesekáyà ti kẹ̀yìn sí àwọn òrìṣà, wọ́n sì ti padà sẹ́nu sísin Jèhófà. Àmọ́ ṣá, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó jẹ́ aṣojú Jùdíà kò gbìyànjú láti ṣàlàyé ìyẹn fún Rábúṣákè. “Wọ́n sì ń bá a lọ ní dídákẹ́, wọn kò sì dá a lóhùn ọ̀rọ̀ kan, nítorí àṣẹ ọba ni pé: ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.’” (Aísáyà 36:21) Ni Élíákímù, Ṣébínà àti Jóà bá padà lọ bá Hesekáyà, wọ́n sì jíṣẹ́ Rábúṣákè fún ọba.—Aísáyà 36:22.
Hesekáyà Ṣèpinnu
15. (a) Ìpinnu wo ni Hesekáyà dojú kọ wàyí? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe wá fi àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀?
15 Hesekáyà Ọba ní láti ṣèpinnu wàyí. Ṣé Jerúsálẹ́mù yóò wá juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ará Ásíríà ni? kí wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Íjíbítì ni? àbí kí wọ́n dúró bí akin, kí wọ́n sì jagun? Ìrònú ńlá bá Hesekáyà. Bó ṣe ń rán Élíákímù àti Ṣébínà, pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin lára àwọn àlùfáà pé kí wọ́n lọ bá wòlíì Aísáyà láti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà, lòun alára gbọ̀nà tẹ́ńpìlì Jèhófà lọ. (Aísáyà 37:1, 2) Tàwọn ti aṣọ àpò ìdọ̀họ lọ́rùn ni àwọn ońṣẹ́ ọba tọ Aísáyà lọ, wọ́n ní: “Ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ wàhálà àti ti ìbáwí mímúná àti ti àfojúdi tí ó kún fún ìpẹ̀gàn . . . Bóyá Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè, ẹni tí olúwa rẹ̀ ọba Ásíríà rán láti ṣáátá Ọlọ́run alààyè, òun yóò sì pè é wá jíhìn ní ti tòótọ́ fún àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti gbọ́.” (Aísáyà 37:3-5) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run alààyè làwọn ará Ásíríà ń pè níjà o! Ǹjẹ́ Jèhófà yóò fiyè sí ìṣáátá wọn? Jèhófà gbẹnu Aísáyà fi àwọn Júù lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Má fòyà nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, èyí tí àwọn ẹmẹ̀wà ọba Ásíríà sọ sí mi tèébútèébú. Kíyè sí i, èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀, òun yóò sì gbọ́ ìròyìn kan, yóò sì padà sí ilẹ̀ tirẹ̀; dájúdájú, èmi yóò mú kí ó tipa idà ṣubú ní ilẹ̀ tirẹ̀.”—Aísáyà 37:6, 7.
16. Irú àwọn lẹ́tà wo ni Senakéríbù kọ ránṣẹ́?
16 Láàárín àkókò náà, Rábúṣákè gba ìpè pé kó wá dúró ti Senakéríbù bí ọba yẹn ṣe ń jagun ní Líbínà. Senakéríbù ṣì fẹ́ sún ìyà Jerúsálẹ́mù síwájú ná. (Aísáyà 37:8) Síbẹ̀síbẹ̀, lílọ tí Rábúṣákè lọ kò mú kí nǹkan rọlẹ̀ díẹ̀ fún Hesekáyà. Ńṣe ni Senakéríbù ń kọ àwọn lẹ́tà ìhàlẹ̀ láti fi ṣàpèjúwe ohun tí ojú àwọn ará Jerúsálẹ́mù máa rí bí wọ́n bá kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀, ó ní: “Ìwọ alára ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Ásíríà ṣe sí gbogbo ilẹ̀ nípa yíyà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun, a ó ha sì dá ìwọ alára nídè bí? Àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi run ha ti dá wọn nídè bí? . . . Ọba Hámátì àti ọba Áápádì àti ọba ìlú ńlá Séfáfáímù—ti Hénà àti ti Ífáhì dà?” (Aísáyà 37:9-13) Ní kúkúrú, ohun tí ará Ásíríà yìí ń sọ ni pé kí wọ́n má wulẹ̀ dán an wò pé àwọn fẹ́ ṣagídí o, bí wọ́n bá ṣagídí pẹ́nrẹ́n, wọ́n gbé!
17, 18. (a) Kí ló sún Hesekáyà máa béèrè fún ààbò Jèhófà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe gbẹnu Aísáyà fún ará Ásíríà yẹn lésì?
17 Ìdààmú bá Hesekáyà gidigidi lórí ohun tó lè tẹ̀yìn ìpinnu tóun ní láti ṣe yìí yọ, ló bá tẹ́ àwọn lẹ́tà Senakéríbù sílẹ̀ níwájú Jèhófà ní tẹ́ńpìlì. (Aísáyà 37:14) Nínú àdúrà àtọkànwá tó gbà, ó bẹ Jèhófà pé kó gbọ́ bí Ásíríà ṣe ń halẹ̀, ó wá parí àdúrà rẹ̀ báyìí pé: “Wàyí o, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, gbà wá là lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.” (Aísáyà 37:15-20) Ó wá hàn kedere látinú èyí pé kì í ṣe bí Hesekáyà ṣe máa rí ọ̀nà àbáyọ tirẹ̀ ló jẹ ẹ́ lógún, bí kò ṣe ẹ̀gàn tí yóò bá orúkọ Jèhófà bí Ásíríà bá lọ ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù.
18 Jèhófà gbẹnu Aísáyà dáhùn àdúrà Hesekáyà. Jerúsálẹ́mù ò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún Ásíríà; kó dúró bí akin ni. Aísáyà sì wá sọ̀rọ̀ bíi pé Senakéríbù ló ń bá sọ̀rọ̀, ó fi ìgboyà jíṣẹ́ Jèhófà fún ará Ásíríà yẹn, ó ní: “Wúńdíá ọmọbìnrin Síónì ti tẹ́ńbẹ́lú rẹ, ó ti fi ọ́ ṣẹ̀sín. Ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù ti mi orí rẹ̀ [lọ́nà ìfiniṣẹlẹ́yà] lẹ́yìn rẹ.” (Aísáyà 37:21, 22) Jèhófà wá sọ̀rọ̀ síwájú sí i, àfi bí ẹní ń sọ pé: ‘Kí lo já mọ́ tóo fi ń ṣáátá Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì? Gbogbo bí o ṣe ń ṣe ni mo ń wò o. Àwọn ohun ńláńlá lò ń lépa; o sì ń pariwo ẹnu. Agbára ogun tóo ní lo gbẹ́kẹ̀ lé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ lo sì ti ṣẹ́gun. Ṣùgbọ́n, o kì í ṣe ẹni tápá ò ká. Ṣe ni n ó da àwọn ìwéwèé rẹ rú. N óò ṣẹ́gun rẹ. N ó sì wá ṣe ọ́ bóo ti ṣe àwọn ẹlòmíràn. Imú rẹ ni n ó fi ìwọ̀ kọ́, tí n ó sì fà ọ́ padà lọ sí Ásíríà!’—Aísáyà 37:23-29.
‘Èyí Ni Yóò Jẹ́ Àmì fún Ọ’
19. Àmì wo ni Jèhófà fún Hesekáyà, kí ló sì túmọ̀ sí?
19 Ẹ̀rí wo ni Hesekáyà fi mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yóò ṣẹ? Jèhófà dáhùn pé: “Èyí ni yóò sì jẹ́ àmì fún ọ: Ní ọdún yìí, jíjẹ láti inú èéhù àwọn kóró dídàálẹ̀ yóò wáyé, àti ní ọdún kejì, ọkà tí ó lalẹ̀ hù; ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ fún irúgbìn, kí ẹ sì kárúgbìn, kí ẹ sì gbin ọgbà àjàrà, kí ẹ sì jẹ èso rẹ̀.” (Aísáyà 37:30) Jèhófà yóò pèsè oúnjẹ fáwọn Júù tí ogun há mọ́ yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé yíya tí àwọn Ásíríà ya bò wọ́n kò jẹ́ kí wọ́n lè fúnrúgbìn, wọn yóò máa jẹ látinú èéṣẹ́ ìkórè wọn ti èṣí. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, tó jẹ́ ọdún sábáàtì, wọ́n ní láti fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ láìfi dáko, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò fararọ fún wọn. (Ẹ́kísódù 23:11) Jèhófà ṣèlérí fáwọn èèyàn rẹ̀ pé bí wọ́n bá ṣe bóun ṣe wí, èso tó pọ̀ tó yóò hù nínú oko fún wọn láti jẹ. Lọ́dún tó wá tẹ̀ lé e, kí àwọn èèyàn fúnrúgbìn bíi tàtẹ̀yìnwá, kí wọ́n sì jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
20. Ọ̀nà wo ni àwọn tó bá bọ́ lọ́wọ́ ìkọlù Ásíríà yóò gbà ‘ta gbòǹgbò lọ sísàlẹ̀ tí wọn yóò sì so èso sókè’?
20 Jèhófà wá fi àwọn èèyàn rẹ̀ wé ewéko tí kò yáá fà tu, ó ní: “Àwọn tí ó sì sá àsálà lára ilé Júdà . . . yóò sì ta gbòǹgbò lọ sísàlẹ̀ dájúdájú, wọn yóò sì so èso sókè.” (Aísáyà 37:31, 32) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀rù kankan ò sí fáwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Mìmì kan ò ní mi àwọn àti irú ọmọ wọn ní ilẹ̀ náà.
21, 22. (a) Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ sọ nípa Senakéríbù? (b) Ìgbà wo ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Senakéríbù ṣẹ, báwo ló sì ṣe ṣẹ?
21 Gbogbo híhàlẹ̀ tí ará Ásíríà yìí ti halẹ̀ mọ́ Jerúsálẹ́mù wá ńkọ́? Jèhófà dáhùn pé: “Kì yóò wá sínú ìlú ńlá yìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ta ọfà kan sí ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi apata kò ó lójú, bẹ́ẹ̀ ni kì yòó mọ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì nà ró tì í. Ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóò gbà padà, kì yóò sì wá sínú ìlú ńlá yìí.” (Aísáyà 37:33, 34) Ásíríà àti Jerúsálẹ́mù ò tiẹ̀ ní wọ̀jà rárá o. Ìyàlẹ́nu ló sì máa wá jẹ́ pé àwọn ará Ásíríà ni yóò ṣubú láìsí ìjà rárá, dípò kó jẹ́ àwọn Júù.
22 Bí Jèhófà ṣe sọ lóòótọ́, ó rán áńgẹ́lì kan ṣoṣo, ìyẹn sì ṣá àwọn akọgun nínú agbo ọmọ ogun Senakéríbù balẹ̀, ìyẹn ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] èèyàn. Ó jọ pé Líbínà nìyẹn ti ṣẹlẹ̀, tó fi jẹ́ pé, jíjí tí Senakéríbù alára máa jí, òkú àwọn aṣáájú, àwọn olórí, àti àwọn akíkanjú nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ló bá nílẹ̀. Ìtìjú bò ó wẹ̀lẹ̀mù, ló bá kọrí sí Nínéfè, ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣì ṣe bá a kanlẹ̀ yìí náà, kò jẹ́ padà lẹ́yìn Nísírọ́kì òrìṣà rẹ̀. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Senakéríbù ń bọ Nísírọ́kì lọ́wọ́ nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀, ni méjì lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ bá lù ú pa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Nísírọ́kì ọmọlangidi kò lágbára láti gbà á là.—Aísáyà 37:35-38.
A Fún Ìgbàgbọ́ Hesekáyà Lágbára Sí I
23. Ìṣòro wo ló bá Hesekáyà nígbà tí Senakéríbù kọ́kọ́ gbógun gòkè tọ Júdà wá, kí ló sì lè tẹ̀yìn ìṣòro yẹn yọ?
23 Lákòókò tí Senakéríbù kọ́kọ́ gbógun gòkè tọ Júdà wá, àìsàn ńlá kan ṣe Hesekáyà. Aísáyà sọ fún un pé yóò kú. (Aísáyà 38:1) Ìdààmú ọkàn ńlá wá dé bá ọba tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì yìí. Ìlera tirẹ̀ nìkan kọ́ ló ń kó ìdààmú bá a, ọjọ́ ọ̀la àwọn èèyàn rẹ̀ náà tún pẹ̀lú. Ó ṣeé ṣe kí àwọn Ásíríà gbógun wá ja Jerúsálẹ́mù àti Júdà. Bí Hesekáyà bá wá kú, ta ló fẹ́ kó wọn lọ jagun? Lásìkò yẹn, Hesekáyà kò lọ́mọ tí yóò bọ́ sípò àkóso. Hesekáyà gbàdúrà kíkankíkan, ó wá bẹ Jèhófà pé kò má ṣàìṣàánú òun.—Aísáyà 38:2, 3.
24, 25. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi inúure dáhùn àdúrà Hesekáyà? (b) Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jèhófà ṣe, bí Aísáyà 38:7, 8 ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀?
24 Aísáyà ò tíì kúrò nínú ààfin tí Jèhófà fi rán an níṣẹ́ padà lọ bá ọba tí ìyọnu bá yìí níbi àkéte rẹ̀, ó ní: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ. Mo ti rí omijé rẹ. Kíyè sí i, èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ rẹ; èmi yóò sì dá ìwọ àti ìlú ńlá yìí nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Ásíríà, èmi yóò sì gbèjà ìlú ńlá yìí dájúdájú.” (Aísáyà 38:4-6; 2 Àwọn Ọba 20:4, 5) Àmì àrà ọ̀tọ̀ kan ni Jèhófà yóò fi jẹ́rìí sí ìlérí rẹ̀, ó ní: “Kíyè sí i, èmi yóò mú kí òjìji tí ń bẹ lára àwọn ìdásẹ̀lé ara àtẹ̀gùn, tí oòrùn ti mú kí ó sọ̀ kalẹ̀ sára àtẹ̀gùn Áhásì, kí ó tọsẹ̀ padà sẹ́yìn ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá ara àtẹ̀gùn.”—Aísáyà 38:7, 8a.
25 Bí Júù òpìtàn náà, Josephus, ṣe wí, àtẹ̀gùn kan wà ní ààfin ọba, ó sì jọ pé òpó kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ìtànṣán oòrùn bá ti ń dé ara òpó yẹn, ni òjìji rẹ̀ ń hàn lára àtẹ̀gùn náà. Èèyàn lè wá mọ ibi tí ọjọ́ dé bó bá ti wo ibi tí òjìji dé lára àtẹ̀gùn yẹn. Wàyí o, Jèhófà fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan. Lẹ́yìn tí òjìji ti sún lọ sí ìsàlẹ̀ bó ṣe máa ń ṣe lórí àtẹ̀gùn yẹn, yóò tún wá tọsẹ̀ ara rẹ̀ padà sẹ́yìn títí dórí ìdásẹ̀lé kẹwàá. Ta ní tíì gbọ́ irú ẹ̀ rí? Bíbélì sọ pé: “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, oòrùn padà sẹ́yìn ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá ara àtẹ̀gùn lórí àtẹ̀gùn tí ó ti sọ̀ kalẹ̀ lé.” (Aísáyà 38:8b) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Hesekáyà sàn nínú àìsàn rẹ̀. Ìròyìn èyí tàn dé iyàn-níyàn Bábílónì. Bí ọba Bábílónì ṣe gbọ́ ló bá rán ońṣẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ gbọ́ òkodoro ọ̀ràn náà.
26. Kí ni ọ̀kan nínú àbáyọrí gígùn tí ìgbésí ayé Hesekáyà gùn sí i?
26 Nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí ara Hesekáyà mókun lọ́nà ìyanu, ó bí Mánásè, tó jẹ́ ọmọkùnrin àkọ́bí. Ni Mánásè wá dàgbà tán o, ni kò bá mọrírì ìyọ́nú Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ pé, láìṣe tìyẹn ni, wọn ì bá máà bí i o! Dípò ìyẹn, èyí tó pọ̀ jù nínú ọjọ́ ayé Mánásè ló fi ṣe ohun búburú lọ́nà tó bùáyà ní ojú Jèhófà.—2 Kíróníkà 32:24; 33:1-6.
Ó Ṣe Ohun Tó Kù Káàtó
27. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Hesekáyà gbà fi ìmoore hàn fún Jèhófà?
27 Ẹni ìgbàgbọ́ ni Hesekáyà, gẹ́lẹ́ bíi Dáfídì baba ńlá rẹ̀. Ohun iyebíye ló ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí. Bí Òwe 25:1 ṣe wí, òun ló ṣètò pé kí wọ́n ṣàkójọ àwọn ohun tó wà nínú Òwe orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n títí dé orí kọkàndínlọ́gbọ̀n. Àwọn kan gbà gbọ́ pé òun náà ló kọ ọ̀rọ̀ inú Sáàmù orí kọkàndínlọ́gọ́fà. Orin ọpẹ́ tó wúni lórí tí Hesekáyà kọ lẹ́yìn tó sàn nínú àìsàn rẹ̀ fi hàn pé ẹni tó moore gan-an ni. Ó wá parí rẹ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé ẹni ni pé kéèyàn lè máa yin Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì Rẹ̀ “ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.” (Aísáyà 38:9-20) Ǹjẹ́ kí èrò gbogbo wa nípa ìsìn mímọ́ gaara rí bí èyíinì o!
28. Ohun tó kù káàtó wo ni Hesekáyà ṣe ní ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà wò ó sàn lọ́nà ìyanu?
28 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olóòótọ́ ni Hesekáyà, aláìpé ló jẹ́. Nígbà díẹ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà wò ó sàn, ó ṣe ohun kan tó kù káàtó gidigidi. Aísáyà ṣàlàyé pé: “Ní àkókò yẹn, Merodaki-báládánì ọmọkùnrin Báládánì ọba Bábílónì fi àwọn lẹ́tà àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekáyà, lẹ́yìn tí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn, ṣùgbọ́n ti ara rẹ̀ ti le padà. Nítorí náà, Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nítorí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n, fàdákà àti wúrà àti òróró básámù àti òróró dáradára àti gbogbo ilé ìhámọ́ra rẹ̀ àti gbogbo ohun tí a rí nínú àwọn ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan kan tí Hesekáyà kò fi hàn wọ́n nínú ilé tirẹ̀ àti nínú gbogbo àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀.”—Aísáyà 39:1, 2.b
29. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ète Hesekáyà nígbà tó fi fi ìṣúra rẹ̀ han àwọn aṣojú láti Bábílónì? (b) Kí ni yóò tẹ̀yìn ohun tó kù káàtó tí Hesekáyà ṣe yìí yọ?
29 Kódà lẹ́yìn ṣíṣẹ́gun tí áńgẹ́lì Jèhófà ṣẹ́gun Ásíríà lọ́nà tó wọ̀ ọ́ lára gidigidi, Ásíríà ò yéé da ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láàmú, títí kan Bábílónì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Hesekáyà wá fẹ́ mú ìwúrí bá ọba Bábílónì gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n lè jùmọ̀ wọ àjọṣe lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n, Jèhófà ò fẹ́ kí àwọn ará Júdà máa bá àwọn ọ̀tá wọn ṣe wọlé-wọ̀de; òun ló mà fẹ́ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé o! Jèhófà wá gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹ lọ́jọ́ ọ̀la fún Hesekáyà, ó ní: “Àwọn ọjọ́ ń bọ̀, gbogbo ohun tí ó sì wà nínú ilé tìrẹ àti èyí tí àwọn baba ńlá rẹ ti tò jọ pa mọ́ títí di òní yìí ni a óò kó lọ sí Bábílónì ní ti tòótọ́. Kì yóò ṣẹ́ ku nǹkan kan . . . Àwọn kan lára ọmọ tìrẹ tí yóò ti inú rẹ jáde wá, àwọn tí ìwọ yóò bí, àwọn pàápàá ni a óò kó, ní ti tòótọ́ wọn yóò di òṣìṣẹ́ láàfin ọba Bábílónì.” (Aísáyà 39:3-7) Bẹ́ẹ̀ ni o, àní orílẹ̀-èdè tí Hesekáyà fẹ́ mú ìwúrí bá gan-an ni yóò padà wá kó àwọn ìṣúra Jerúsálẹ́mù lọ níkẹyìn, tí yóò sì kó àwọn èèyàn ibẹ̀ lẹ́rú. Fífi tí Hesekáyà fi ìṣúra rẹ̀ han àwọn ará Bábílónì gan-an ni yóò sì mú kí ẹ̀mí ìwọra tí wọ́n ní túbọ̀ máa fà síbẹ̀.
30. Báwo ni Hesekáyà ṣe fi ẹ̀mí tó dáa hàn?
30 Ó jọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìyẹn fífi tí Hesekáyà fi ìṣúra rẹ̀ han àwọn ará Bábílónì, ni 2 Kíróníkà 32:26 ń tọ́ka sí tó fi sọ pé: “Hesekáyà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ìrera ọkàn-àyà rẹ̀, òun àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, ìkannú Jèhófà kò sì wá sórí wọn ní àwọn ọjọ́ Hesekáyà.”
31. Báwo lọ̀ràn ṣe wá rí fún Hesekáyà, ẹ̀kọ́ wo ni èyí sì kọ́ wa?
31 Ẹni ìgbàgbọ́ ṣì ni Hesekáyà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìpé dà á láàmú. Ó mọ̀ pé Jèhófà, Ọlọ́run òun, jẹ́ ẹni gidi tó ń gba tẹni rò. Nígbà tí ìdààmú ọkàn dé bá Hesekáyà, ṣe ló gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà, Jèhófà sì dá a lóhùn. Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀, Hesekáyà sì dúpẹ́ fún ìyẹn. (Aísáyà 39:8) Bẹ́ẹ̀ gan-an ló ṣe yẹ kí Jèhófà jẹ́ ẹni gidi lójú tiwa lóde òní. Bí ìṣòro bá dé bá wa, ǹjẹ́ kí àwa náà ṣe bíi Hesekáyà, ká yíjú sí Jèhófà fún ọgbọ́n àti ọ̀nà àbáyọ, “nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni.” (Jákọ́bù 1:5) Bí a bá ń forí tì í nìṣó, tí a sì lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, kí ó dá wa lójú pé òun yóò jẹ́ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a,” nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.—Hébérù 11:6.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Iye rẹ̀ ju mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ààbọ̀ owó dọ́là (ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà) lọ bí a bá gbé e karí ìdiwọ̀n ti lọ́ọ́lọ́ọ́.
b Lẹ́yìn tí Senakéríbù ṣubú, àwọn orílẹ̀-èdè àgbègbè ibẹ̀ wá kó wúrà, fàdákà, àtàwọn ohun iyebíye mìíràn wá fún Hesekáyà. Nínú 2 Kíróníkà 32:22, 23, 27, a kà á pé, “Hesekáyà sì wá ní ọrọ̀ àti ògo ní iye púpọ̀ gan-an” àti pé “ó sì wá di ẹni tí a gbé ga ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀bùn wọ̀nyí ló jẹ́ kí ó rí ìṣúra tò padà sí ilé ìṣúra rẹ̀ tó ti gbọ́n gbẹ nígbà tó san owó òde fún àwọn ará Ásíríà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 383]
Hesekáyà Ọba gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó dojú kọ agbára Ásíríà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 384]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 389]
Ọba rán ońṣẹ́ sí Aísáyà láti gbọ́ ìmọ̀ràn Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 390]
Hesekáyà gbàdúrà pé kí ìṣẹ́gun lórí Ásíríà gbé orúkọ Jèhófà lékè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 393]
Áńgẹ́lì Jèhófà ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ará Ásíríà balẹ̀